Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 29


Ìpín 29

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní ojú àwọn alàgbà mẹ́fà, ní Fayette, New York, Oṣù Kẹsãn 1830. Ìfihàn yìí ni a fi fúnni ní bíi ọjọ́ díẹ̀ síwájú ìpàdé àpéjọpọ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 26 Oṣù Kẹsãn 1830.

1–8, Krístì kó àwọn àyànfẹ́ Rẹ̀ jọ; 9–11, Bíbọ̀ Rẹ̀ mú ẹgbẹ̀rún ọdún wọlé; 12–13, Àwọn méjìlá nnì yíò ṣe ìdájọ́ gbogbo Isráẹ́lì; 14–21, Àwọn àmì, àjàkálẹ̀ àrùn, àti àwọn ìsọ̀dahoro ni wọn yíò síwájú Wíwá Ẹ̀ẹ̀kejì; 22–28, Àjínde ìkẹhìn àti ìdájọ́ ìparí ni yíò tẹ̀lé Ẹgbẹ̀rún ọdún náà; 29–35, Ohun gbogbo jẹ́ nípa ti ẹ̀mí sí Olúwa; 36–39, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni a lé jáde kúrò ní ọ̀run láti dán èniyàn wò; 40–45, Ìṣubú àti Ètùtù mú ìgbàlà wá; 46–50, Àwọn ọmọdé ni a ràpadà nípasẹ̀ Ètùtù.

1 Ẹ tẹ́tí sí ohùn Jésù Krístì, Olùràpadà yín, Èmi Ni Nlá náà, ẹnití apá àánú rẹ̀ ti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

2 Ẹnití yíò kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ àní bí àgbébọ̀ ti í ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀, àní iye àwọn tí wọn bá fetísílẹ̀ sí ohùn mi tí wọ́n sì rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi, àti pé tí wọn nké pè mí nínú àdúrà nlá.

3 Kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, pé ní àkókò yìí, a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, nítorínáà ẹ̀yin gba àwọn nkan wọ̀nyí; ṣùgbọ́n ẹ rantí láti máṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìparun yíò wá sí orí yín.

4 Lõtọ́, ni mo wí fún yín pé a ti yàn yín lààrin àwọn èniyàn ayé láti kéde ìhìnrere mi pẹ̀lú ìró ìdùnnú, gẹ́gẹ́bí ìró fèrè ogun.

5 Ẹ gbé ọkàn yín sókè kí ẹ sì yọ̀, nítorí èmi wà ní ààrin yín, àti pé èmi ni alágbàwí yín pẹ̀lú Baba; ó sì jẹ́ ìfẹ́ inú rere rẹ̀ láti fún yín ní ìjọba náà.

6 Àti pé, bí a ṣe kọọ́—Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí ẹ wà ní ìṣọ̀kàn nínú àdúrà gẹ́gẹ́bí àṣẹ mi, ẹ̀yin yíò rí gbà.

7 Àti pé ẹ̀yin ni a pè láti ṣe ìmúṣẹ àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ mi; nítorí àwọn àyànfẹ́ mi gbọ́ ohùn mi wọn kò sì sé ayà wọn le.

8 Nítorínáà àṣẹ náà ti jade lọ láti ọ̀dọ̀ Baba pé a ó kó wọn jọ pọ̀ sí ojú kan ní orí ilẹ̀ yìí, láti pèsè ọkàn wọn sílẹ̀ àti lati wà ní ìmúrasílẹ̀ nínú ohun gbogbo fún ọjọ́ tí a ó rán ìpọ́njú àti ìsọdahoro jáde sí orí àwọn ènìyàn búburú.

9 Nítorí wákàtí náà dé tán àti pé ọjọ́ náà kù sí dẹ̀dẹ̀ nígbàtí ayé yíò di ogbó; ati tí gbogbo àwọn agbéraga ati àwọn olùṣebúburú yíò dàbí àkékù koríko; èmi ó sì jó wọn gúrúgúrú, ni Olúwa àwọn Ọmọ Ogun wí, tí kì yíò sì sí ìwà búburú ní orí ilẹ̀ ayé;

10 Nítorí wákàtí náà dé tán, àti èyíinì tí a ti sọ láti ẹnu àwọn àpóstélì mi gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ; nítorí bí wọ́n ṣe sọ bẹ́ẹ̀ ni yíò rí;

11 Nítorí èmi yíò fi ara mi hàn láti ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo nlá, pẹ̀lú gbogbo awọn ọmọ ogun rẹ̀, èmi yíò sì gbé nínú òdodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní orí ilẹ̀ ayé fún ẹgbẹ̀rún ọdún, àti pé àwọn ènìyàn búburú kì yíò lè dúró.

12 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, ó sì ti jade lọ nínú àṣẹ kan tí ó dúró ṣinṣin, nípa ìfẹ́ inú Bàbá, pé àwọn àpóstélì mi, àwọn Méjìlá nnì tí wọ́n wà pẹ̀lú mi nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi ní Jerúsálẹmù, ni wọn yíò dúró ní apá ọ̀tún mi ní ọjọ́ náà ti bíbọ̀ mi nínú ọwọ̀n iná, ní fífi àwọn aṣọ òdodo wọ̀, pẹ̀lú àwọn adé ní orí wọn, nínú ògo àní bíi èmi náà, láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ilé Isráẹ́lì, àní bí iye àwọn tí wọ́n ti fẹ́ràn mi tí wọ́n sì ti pa àwọn òfin mi mọ́, kò sì sí ẹlòmíràn.

13 Nítorí ìpè kan yíò dún fún ìgbà pípẹ́ ati pẹ̀lú ariwo, àní bíi ti orí òkè Sínáì, àti pé gbogbo ilẹ̀ ayé ni yíò mì tìtì, tí wọn yíò sì jade wá—bẹ́ẹ̀ni, àní àwọn òkú tí wọ́n kú nínú mi, láti gba adé òdodo, àti kí á lè wọ̀ wọ́n láṣọ, àní bíi ti èmi, lati wà pẹ̀lú mi, kí á lè di ọ̀kan.

14 Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín pé kí ọjọ́ nla yìí tó dé a ó sọ òòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, àti àwọn ìràwọ̀ yíò já bọ́ láti ọ̀run, ati àwọn àmì títóbi jù yío sì wà ní òkè ọ̀run àti ní ìsàlẹ̀ ìlẹ̀;

15 Àti pé ẹkún àti ìpohùnréré ẹkún yíò wà lààrin ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn;

16 Àti pé ìjì yìnyín nlá ni a ó rán wá láti pa àwọn ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ ayé run.

17 Yíò sì ṣe, nítorí ìwà búbúrú ayé, pé èmi Olúwa yíò gba ẹ̀san lára àwọn ènìyàn búburú, nítorí wọn kì yíò ronúpìwàdà; nítorí ago ìbínú mi ti kún; nítorí kíyèsíi, ẹ̀jẹ̀ mi kì yíò wẹ̀ wọ́n mọ́ bí wọn kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

18 Nítorínáà, èmi Olúwa Ọlọ́run yíò rán àwọn eṣinṣin wá sí orí ilẹ̀ ayé, èyítí yíò bo àwọn olùgbé inú rẹ̀, wọn yíò sì jẹ ẹran ara wọn, wọn yíò sì mú kí àwọn ìdin ó wá sí orí wọn;

19 Àti pé a ó mú kí ahọ́n wọn dúró kí wọn má sì sọ̀ ọ̀rọ̀ lòdì sí mi; àti ẹran ara wọn yíò sì já kúrò lára eegun wọn, àti àwọn ojú wọn kúrò nínú àwọn ihò wọn;

20 Ati pé yíò sì ṣe pé àwọn ẹranko inú ìgbẹ́ àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yíò sì jẹ wọ́n run.

21 Àti pé ìjọ nlá àti tí ó ríni lára nnì, èyí tí ṣe àgbéèrè gbogbo ayé, ni yíò di píparun pẹ̀lú iná ajónirun, gẹ́gẹ́bí a ṣe sọ́ láti ẹnu Wòlíì Esikiẹlì, ẹni tí ó sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí, èyítí a kò tíì múṣẹ ṣùgbọ́n tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣẹ dájú, bí èmi ṣe wà láàyè, nítorí àwọn ohun ìríra kì yíò jọba.

22 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín pé nígbàti ẹgbẹ̀rún ọdún bá parí, àti tí àwọn ènìyàn bá tún bẹ̀rẹ̀sí sẹ́ Ọlọ́run wọn, nígbànáà ni èmi yíò ṣàánú fún ayé ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀;

23 Òpin yíò sì dé, ọ̀run àti ayé yíò sì parun wọn yíò sì kọjá lọ, ọ̀run titun àti ayé titun kan yíò sì wà.

24 Nítorí gbogbo ohun àtijọ́ yíò kọjá lọ, ohun gbogbo yíò sì di titun, àní ọ̀run àti ayé, àti gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ inú rẹ̀, àti ènìyàn àti àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àti àwọn ẹja inú òkun;

25 Àti pé kò sí ẹyọ irun orí kan, tàbí èérún igi, tí yíò ṣègbé, nítorí ó jẹ́ iṣẹ́ ọwọ mi.

26 Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé kí ayé ó tó kọjá lọ, Míkáẹ́lì, olórí ángẹ́lì mi, yíò fọn fèrè rẹ̀, àti nigbànáà ni gbogbo àwọn òkú yíò sì dìde, nítorí a ó ṣí àwọn ibojì wọn sílẹ̀, wọn yíò sì jade wá—bẹ́ẹ̀ni, àní gbogbo wọn.

27 Àti pé a ó kó àwọn olódodo jọ pọ̀ sí apá ọ̀tún mi sí ìyè ayérayé; àti àwọn ènìyàn búburú ní apá òsì mi ni ojú yíò tì mí láti pè ní tèmi ní iwájú Bàbá;

28 Nítorínáà èmi yíò wí fún wọn pé—Ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin tí a ti fi gégũn, sínú iná àìlópin, tí a pèsè fún èṣù àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀.

29 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín, kò sí ìgba kankan tí mo sọ jade láti ẹnu mi pé wọn yíó padà wá, nítorí ibi tí èmi wà wọn kì yíò lè wá, nítorí wọn kò ní agbára.

30 Ṣùgbọ́n rantí pé gbogbo àwọn ìdájọ́ mi ni a kò fi fún ènìyàn; àti pé bí àwọn ọ̀rọ̀ náà ṣe jade lọ láti ẹnu mi àní bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní wọn yíò wá sí ìmúṣẹ, pé ẹni ìsaájú yíó di ẹni ìkẹhìn, àti pé ẹni ìkẹhìn yíó di ẹni ìṣaájú nínú ohun gbogbo èyíkéyìí tí mo dá nípa ọ̀rọ̀ agbára mi, èyí tí ṣe agbára Ẹ̀mí mi.

31 Nítorí nípa agbára Ẹ̀mí mi ni mo dá wọn; bẹ́ẹ̀ni, ohun gbogbo ní ti ẹ̀mí àti ní ti ara—

32 Ní àkọ́kọ́ ti ẹ̀mí, lẹ́ẹ̀kejì ti ara, èyí tí ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi; àti lẹ́ẹ̀kansíi, ní àkọ́kọ́ ti ara, àti lẹ́ẹ̀kejì ti ẹ̀mí, èyí tí ó jẹ́ ìkẹhìn nínú iṣẹ́ mi—

33 Ní bíbá yín sọ̀rọ̀ pé kí ó lè yée yín ní àdánidá yín; ṣùgbọ́n sí èmi tìkara mi àwọn iṣẹ́ mi kò ní òpin, tàbí ìbẹ̀rẹ̀; ṣùgbọ́n a fi fún yín kí ó baà lè yé yín, nítorípé ẹ̀yin ti béèrè rẹ̀ ní ọwọ́ mi ẹ sì ti fi ohùn ṣe ọ̀kan.

34 Nítorínáà, lõtọ́ ni mo wí fún yín pé ohun gbogbo níwájú mi jẹ́ ti ẹ̀mí, àti pé kò sí ìgbà kan tí èmi fún yín ní òfin kan èyí tí ó jẹ́ ti ara, bóyá sí ẹnikan, tàbí sí àwọn ọmọ ènìyàn; tàbí sí Adámù, bàbá yín, ẹ̀nití èmi dá.

35 Kíyèsíi, èmi fi fún un pé kí òun jẹ́ aṣojú fún ara rẹ̀; àti pé èmi fún un ní òfin, ṣùgbọ́n èmi kò fún un ní òfin ti ara, nítorí àwọn òfin mi jẹ́ ti ẹ̀mí; wọn kìí ṣe ti àdánidá tàbí ti ara, tàbí ti ìfẹ́ ẹran ara tàbí ti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

36 Ó sì ṣe pé Ádámù, nítorítí èṣù dán an wò—nítorí, kíyèsíi, èṣù wà ṣaájú Adámù, nítorí òun ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi, ní sísọ pé, Fún mi ní ọlá rẹ, èyítí ó jẹ́ agbára mi; àti bákannáà ìdá kẹta àwọn ogun ọrun ni òun mú kí wọ́n ó yípadà kúrò ní ẹ̀hìn mi nítorí òmìnira wọn láti yàn.

37 A sì jù wọ́n sí ìsàlẹ̀, báyìí sì ni èṣù wá pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì rẹ̀;

38 Àti pé, kíyèsíi, ibi kan wà tí a ti pèsè fún wọn láti ìbẹ̀rẹ̀, ibi èyí tí ṣe ọ̀run apáàdì.

39 Àti pé ó di dandan kí èṣù dán àwọn ọmọ ènìyàn wò, bíbẹ́ẹ̀kọ́ wọn kì yíò lè jẹ́ aṣojú fún ara wọn; nítorí bí wọn kò bá tọ́ ìkorò wò wọn kì yíò mọ adùn—

40 Nítorínáà, ó sì ṣe tí èṣù dán Adamù wò, òun sì jẹ èso àìgbọdọ̀ jẹ náà ó sì rú òfin, nínú èyi tí ó bọ́ sí abẹ́ ìdarí ìfẹ́ inú ti èṣù, nítorípé òun fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdánwò.

41 Nítorínáà, èmi, Olúwa Ọlọ́run, mú kí á lé e jáde kúrò nínú ọgbà Edẹ́nì, kúrò ní iwájú mi, nítorí ìrékọjá rẹ̀, nínú èyítí òun di òkú nípa ti ẹ̀mí, èyítí ó jẹ́ ikú àkọ́kọ́, àní ikú kannáà èyítí ó jẹ́ ikú ìkẹhìn, èyítí í ṣe ti ẹ̀mí, èyítí a ó kéde sí orí àwọn ènìyàn búburú nígbàtí èmi yíò wípé: Ẹ lọ kúrò, ẹ̀yin ẹni ìfibú.

42 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, mo wí fún yín pé èmi, Olúwa Ọlọ́run, fi fún Ádámù àti fún irú àwọn ọmọ rẹ̀, pé wọn kì yíò kú nípa ikú ti ara, títí tí èmi, Olúwa Ọlọ́run, yíò fi rán àwọn ángẹ́lì láti wá kéde ironúpìwàdà àti ìràpadà sí wọn, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo.

43 Àti bayìí ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, ṣe yàn àwọn ọjọ́ ìdánwò fún ènìyàn—pé nípa ikú ara, a lè jí i dìdé nínú ara àìkú sí ìyè ayerayé, àní iye àwọn tí wọ́n gbàgbọ́;

44 Àti pé àwọn tí wọn kò gbàgbọ́ sí ẹ̀bi ayérayé; nítorí a kò lè ra wọ́n padà nínú ìṣubú ẹ̀mí wọn, nítorípé wọn kò ronúpìwàdà;

45 Nítorí wọ́n fẹ́ràn òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, àti pé àwọn iṣe wọ́n jẹ́ ibi, wọ́n sì gba èrè wọn lati ọ̀dọ̀ ẹnití wọ́n yàn láti gbọ́ràn sí;

46 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, mo wí fún yín, pé àwọn ọmọdé ni a ti ràpadà láti ìpilẹ̀sẹ̀ ayé nípasẹ̀ Ọmọ bíbí mi Kanṣoṣo;

47 Nítorínáà, wọn kò lè dẹ́ṣẹ̀, nítorí a kò fi agbára fún Sátánì láti dán àwọn ọmọdé wò, títí tí wọn yíò fi le dáhùn fún ara wọn níwájú mi;

48 Nítorí a ti fi fún wọn àní bí mo ṣe fẹ́, àti gẹ́gẹ́bí inú dídùn mi, pé kí á lè béèrè àwọn ohun nla ní ọwọ́ àwọn bàbá wọn.

49 Àti, lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìmọ̀, njẹ́ èmi kò ha ti pàṣẹ kí ó ronúpìwàdà bí?

50 Àti pé ẹnití kò bá ní òye, ó wà nínú mi láti ṣe gẹ́gẹ́bí a ṣe kọ̀wé rẹ̀. Àti nísisìyí èmi kì yíò kéde fún yin mọ́ ní àkókò yìí. Amin.