Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 12


Ìpín 12

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Joseph Knight Àgbà, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Karũn 1829. Joseph Knight gba àwọn ohun tí Joseph Smith kéde gbọ́ nípa níní àwọn àwo Ìwé Ti Mómónì ní ìkáwọ́ rẹ̀, àti ìṣẹ́ ìtumọ́ tí ó nlọ lọ́wọ́ nígbànáà, òun sì ti fi ọ̀pọ̀ ìgbà ṣe àtìlẹ́hìn fún Joseph Smith àti akọ̀wé rẹ̀, èyí tí ó mú kí ó ṣèéṣe fún wọn láti tẹ̀ síwájú nínú ìtumọ̀. Nítorí ẹ̀bẹ̀ Joseph Knight, Wolíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa ó sì gba ìfihàn.

1–6, Àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà yíò gba èrè ìgbàlà; 7–9, Gbogbo ẹnití ó bá fẹ́ tí wọ́n sí kún ojú òsùnwọ̀n lè ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Olúwa.

1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan ti fẹ́ jáde wá ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn.

2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, èyítí ó yè tí ó sì ní agbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ, láti pín sí ọ̀tọọ̀tọ̀ oríkèé àti mùndùnmúndùn; nítorínáà tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi.

3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè, nítorínáà ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè, ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ gún un pẹ̀lú ipá rẹ̀, kí òun sì kórè nígbàtí ọjọ́ sì wà, kí òun baa lè kó o pamọ́ fún ìgbàlà àìlópin ọkàn rẹ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run.

4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ tí ó sì kórè, ẹni náà ni Ọlọ́run pè.

5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn a ó ṣí i fún ọ.

6 Nísisìyí, bí ìwọ ti béèrè, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì lépa lati mú jáde wá ati lati ṣe àgbékalẹ̀ ipa ọ̀nà Síónì.

7 Kíyèsíi, èmi nba ọ sọ̀rọ̀, àti bákannáà sí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ láti mú iṣẹ́ yìí jade wá àti láti ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀.

8 Àti pé ẹnikẹ́ni kò lè ṣe ìrànwọ́ nínú iṣẹ́ yìí bí kò ṣe pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì kún fún ìfẹ́, pẹ̀lú níní ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, pẹ̀lú wíwà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nínú ohun gbogbo, èyíkéyìí tí a lè fi sí abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.

9 Kíyèsíi, èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé, tí ó nsọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorínáà fi etí sí ọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú agbára rẹ, nígbànáà ìwọ ni a pè. Amin.