Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 127


Ìpín 127

Èpístélì kàn láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith sí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní Nauvoo, Illinois, tí ó ní ìtọ́nisọ́nà ní orí ìrìbọmi fún àwọn òkú nínú, tí a fi ọjọ́ sí ní Nauvoo, 1 Oṣù Kẹwàá 1842.

1–4, Joseph Smith nṣògo nínú inúnibíni àti ìpọ́njú; 5–12, Àwọn àkọsílẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ fi pamọ́ nípa ìrìbọmi fún àwọn òkú.

1 Nítorí níwọ̀nbí Olúwa ṣe fi hàn sí mi pé àwọn ọ̀tá mi, méjèèjì yí ní Missouri àti ní Ìpínlẹ̀ yìí, wà ní lílépa mi lẹ́ẹ̀kansíi; àti níwọ̀nbí wọ́n ṣe lépa mi láìnídĩ kan, tí wọn kò sí ní òjììji tàbí àwọ̀ kíkùn tí ó kéré jùlọ ti ìdájọ́ tàbí ẹ̀tọ́ ní ìhà ọ̀dọ̀ wọn ní gbígbé àwọn ẹ̀sùn wọn sókè takò mí; àti níwọ̀nbí àwọn ìdíbọ́n wọn gbogbo bá jẹ́ gbígbékalẹ̀ ní orí èké bíi aró tí ó dúdú jùlọ, èmi ti rò ó pé ó tọ̀nà ó sì jẹ́ ọgbọn nínú mi láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kan, fún ààbò ti ara mi àti ààbò àwọn ènìyàn yìí. Èmi ó wí fún gbogbo àwọn wọnnì pẹ̀lú àwọn tí mo ní iṣẹ́, pé mo ti fi àwọn ọ̀rọ̀ mi fún àwọn aṣojú àti àwọn akọ̀wé àwọn ẹnití yíò máa ṣe gbogbo iṣẹ òwò ní kánkán àti ní ọ̀nà tí ó yẹ, wọn yíò sì ríi pé gbogbo àwọn gbèsè mi ni wọ́n parẹ́ ní àkókò tí ó yẹ, nípa gbígbé ohun ìní jade, tàbí ní ọ̀nà míràn, bí ọ̀rọ̀ bá ṣe bèèrè, tàbí bí ipò àyíká bá ṣe fi àyè gbà. Nígbàtí mo bá ní ìmọ̀ pé ìjì náà ti fẹ́ kúrò tán, nígbànáà èmi yíò padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kansíi.

2 Àti nípa ti àwọn ewu èyítí a pè mí láti là kọjá, wọ́n dà bíi, ṣùgbọ́n ohun kékeré kan sí mi, bí ìlara àti ìbínú ènìyàn ṣe jẹ́ ìpín mi tí ó wọ́pọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi; àti fún ìdí èyítí ó dàbíi ohun ìjìnlẹ̀, bíkòṣe pé a ti yàn mi láti ìsaájú ìpilẹ̀sẹ̀ ayé fún àwọn ìdí rere, tàbí búburú, bí ẹ ṣe le yàn láti pèé. Ẹ ṣe ìdájọ́ fún ara yín. Ọlọ́run mọ gbogbo ohun wọ̀nyí, bóyá ó jẹ́ dídára tàbí búburú. Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, omi jíjìn ni ohun tí ó ti mọ́ èmi lára láti wẹ̀ nínú rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ti di àdánidá kejì sí mi; mo sì ní ìmọ̀lára, bíi Paulù, láti ṣògo nínú ìpọ́njú; nítorí títí di ọjọ́ yìí ni Ọlọ́run àwọn bàbá mi ti gbà mí nínú wọn gbogbo, yíò sì gbà mí láti ìsisìyí lọ; nítorí kíyèsíi, sì wòó, èmi yíò borí gbogbo àwọn ọ̀tá mi, nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ́.

3 Ẹ jẹ́kí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ ó yọ̀, nítorínáà, kí wọ́n ó sì yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorí Ọlọ́run Isráẹ́lì ni Ọlọ́run wọn, òun yíò sì ṣe ẹ̀san tí ó tọ́ bíi èrè sí orí gbogbo àwọn aninilára wọn.

4 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí: Ẹ jẹ́kí iṣẹ́ ti tẹ́mpìlì mi, àti gbogbo àwọn iṣẹ́ tí èmi ti yàn fún yín, kí ó tẹ̀síwájú kí ó má sì ṣe dúró; ẹ sì jẹ́kí aápọn yín, àti ìpamọ́ra yín, àti sùúrù, àti àwọn iṣẹ́ yín kí ó di ìlọ́po lẹ́ẹ̀méjì, àti pé ẹ̀yin, bí ó ti wù kí ó rí kì yíò pàdánù èrè yín, ni Olúwa awọn Ọmọ Ogun wí. Àti bí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì àti àwọn olódodo tí wọ́n ti wà ṣaájú yín. Fún gbogbo èyí èrè kan wà ní ọ̀run.

5 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi fi ọ̀rọ̀ kan fún yín nípa ìrìbọmi fún àwọn òkú yín.

6 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín nípa àwọn òkú yín: Nígbàtí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣe ìrìbọmi fún òkú yín, ẹ jẹ́kí akọ̀wé ìrántí kan kí ó wà, ẹ sì jẹ́kí òun ó jẹ́ ẹlérìí óṣojú-mi-kòró sí àwọn ìrìbọmi yín; ẹ jẹ́kí òun gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ̀, pé kí òun lè jẹ́rìí ti òtítọ́ kan, ni Olúwa wí;

7 Pé nínú gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ ṣíṣe yín kí ó lè jẹ́ kíkọ̀ sílẹ̀ ní ọ̀run; ohunkóhun tí ẹyin bá dè ní ayé, kí ó lè jẹ́ dídè ní ọ̀run; ohunkóhun tí ẹyin bá tú ní ayé kí ó lè jẹ́ títú ní ọ̀run;

8 Nitorí èmi ti fẹ́rẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun padàbọ̀sípò sí ilẹ̀ ayé, tí ó ní í ṣe sí oyè àlùfáà, ni Olúwa àwọn Ọmọ Ogun wí.

9 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́kí gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ ó wà létò, kí wọn ó lè jẹ́ fífi sí inú ibi ìpamọ́ ti àwọn iwé ìtàn nínú tẹ́mpìlì mímọ́ mi, láti wà ní ìrántí láti ìran dé ìran, ni Olúwa Àwọn Omọ Ogun wí.

10 Èmi yíò sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, pé mo ti fẹ́, pẹ̀lú ìfẹ́ tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀, làti bá wọn sọ̀rọ̀ láti ibi ìdúró kan ní orí àkòrí ọ̀rọ̀ ìrìbọmi fún àwọn òkú, ní ọjọ́ Ìsìnmi tí ó tẹ̀lée. Ṣùgbọ́n níwọ̀nbí kò ṣe sí ní agbára mi láti ṣe bẹ́ẹ̀, èmi yíò kọ ọ̀rọ̀ Olúwa láti àkókò dé àkókò, nípa àkòrí ọ̀rọ̀ náà, èmi yío sì fi ránṣẹ́ sí yín nípa ìfìwéránṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun míràn.

11 Nísisìyí èmi parí ìwé kíkọ mi fún ìgbà yìí, nítorí mo fẹ́ àkókò díẹ̀ síi; nítorí ọ̀tá ti wà ní ìsọ́ra, àti bí Olùgbàlà ti wí, ọmọ aláde ti ayé yìí dé tán, ṣùgbọ́n òun kò ní ohunkóhun nínú mi.

12 Kíyèsíi, àdúrà mi sí Ọlọ́run ni pé kí gbogbo yín ó lè di gbígbàlà. Mo sì ka ara mi sí ìránṣẹ́ yín nínú Olúwa, wòlíì àti aríran ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Joseph Smith.