Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 82


Ìpín 82

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith, ní Independence, Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, 26 Oṣù Kẹrin 1832. Àkókò náà jẹ́ ìgbà ìpàdé ìgbìmọ̀ ti àwọn àlùfáà gíga àti àwọn alàgbà Ìjọ. Nínú ìgbìmọ̀ náà, wọ́n ṣe ìmúdúró Joseph Smith bíi Ààrẹ ti àwọn Olóyè Àlùfáà Gíga, sí ipò iṣẹ́ èyí tí wọ́n ti yàn án tẹ́lẹ̀ níbi àpéjọpọ̀ kan ti àwọn àlùfáà gíga, àwọn alàgbà, àti àwọn ọmọ ìjọ, ní Amherst, Ohio, 25 Oṣù Kínní 1832 (wo àkọlé sí ìpín 75). Ìfihàn yìí ṣe àtúnsọ àwọn àṣẹ tí a ti fi fúnni tẹ́lẹ̀ nínú ìfihàn kan (ìpín 78) láti ṣe ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ kan—tí a mọ̀ sí Ilé Iṣẹ́ Ìṣọ̀kan (ní abẹ́ ìdarí ti Joseph Smith, ìtọ́kasí “àjọ” ní ìgbẹ̀hìn rọ́pò “ilé iṣẹ́”)—láti ṣe àkóso aápọn okòwò àti ìtẹ̀wé ti Ìjọ.

1–4 Níbi tí a fi púpọ̀ fúnni, púpọ̀ ni a béèrè; 5–7, Òkùnkùn njọba nínú ayé; 8–13, Olúwa ní ojúṣe dandan nígbàtí a bá ṣe ohun tí Ó wí; 14–18, Síónì yíò pọ̀ síi ní ẹwà àti ìwà mímọ́; 19–24, Olúkúlùkù ènìyàn níláti wá ìfẹ́ inú aládùúgbò rẹ̀.

1 Lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi, pé níwọ̀nbí ẹ̀yin ti dári àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ji ara yín, àní bẹ́ẹ̀ni èmi, Olúwa, dárí jì yín.

2 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan wà lààrin yín tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ́ẹ̀ni, àní gbogbo yín ni ẹ ti dẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ kíyèsára láti àkókò yìí lọ, kí ẹ sì fàsẹ́hìn kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ àwọn ìdájọ́ dídunni yíò ṣubú sí orí yín.

3 Nítorí lọ́dọ̀ ẹnití a bá fí púpọ̀ sí ni a ó ti béèrè púpọ̀; àti pé ẹni náà tí ó bá ṣẹ̀ tako ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbijù yíò gba ìdálẹ́bi tí ó tóbijù.

4 Ẹ̀yin ké pe orúkọ mi fún àwọn ìfihàn, èmi sì fi wọ́n fun yín; àti níwọ̀nbí ẹ̀yin kò ti pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́, eyí tí èmi fi fún yín, ẹ̀yin di arúfin; àti pé òdodo àti ìdájọ́ ni ìjìyà èyí tí a ti so mọ́ òfin mi.

5 Nítorínáà, ohun tí èmi wí fún ọ̀kan mo wí fún gbogbo ènìyàn: Ẹ kíyèsára, nítorí ọ̀tá náà ntan ìjọba rẹ̀ ká, àti pé òkùnkùn njọba;

6 Ìbínú Ọlọ́run sì ru sókè sí àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé; kò sì sí ẹni tí ó ṣe rere, nítorí gbogbo ènìyàn ti lọ kúrò ní ojú ọnà náà.

7 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi, Olúwa, kì yíò ka ẹ̀ṣẹ̀ kankan sí yín lọ́rùn; ẹ lọ ní àwọn ọ̀nà yín kí ẹ sì máṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́; ṣùgbọ́n sí ọkàn tí ó bá ṣẹ̀ ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ yíò padà sí, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

8 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, èmi fi òfin titun kan fún yín, pé kí ẹ̀yin ó lè ní òye ìfẹ́ inú mi nípa yín;

9 Tàbí, ní ọ̀nà míràn, èmi fún yín ní àwọn ìtọ́sọ́nà nípa bí ẹ̀yin ṣe lè hùwà níwájú mi, kí ó baà lè yípadà síi yín fún ìgbàlà yín.

10 Èmi, Olúwa, wà ní abẹ́ ojúṣe nígbàtí ẹ bá ṣe ohun tí èmi wí; ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀yin kò bá ṣe ohun tí èmi wí, ẹ kò ní ìlérí.

11 Nítorínáà, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ó tọ̀nà fún àwọn ìránṣẹ́ mi Edward Partridge àti Newel K. Whitney, A. Sidney Gilbert àti Sidney Rigdon, àti ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, àti John Whitmer àti Oliver Cowdery, àti W. W. Phelps àti Martin Harris láti ní ojúṣe papọ̀ pẹ̀lú àdéhùn àti májẹ̀mú kan tí kò leè jẹ́ sísẹ́ nípa ìrékọjá, bíkòṣepé ìdájọ́ yíò tẹ̀lé lójúkannáà, nínú gbogbo iṣẹ́ ìríjú yín—

12 Láti mójútó ọ̀rọ̀ àwọn tálákà, àti ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àjọ bíṣọ́ọ̀pù ní ilẹ̀ Síónì àti ní ilẹ̀ Kirtland;

13 Nítorí èmi ti ya ilẹ̀ Kirtland sí mímọ́ ní àkókò tí ó tọ́ lójú mi fún ire àwọn ènìyàn mímọ́ ti Ọ̀gá Ògo Jùlọ, àti fún èèkàn kan sí Síónì.

14 Nítorí Síónì gbọ́dọ̀ pọ̀ síi ní ẹwà, àti ní ìwà mímọ́; àwọn ààlà rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbòòrò síi; a gbọ́dọ̀ fún àwọn èèkàn rẹ̀ ní okun; bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́ ni mo wí fún yín, Síónì gbọ́dọ̀ dìde kí ó sì gbé àwọn aṣọ rẹ̀ tí ó rẹwà wọ̀.

15 Nítorínáà, èmi fi òfin yìí fún yín, pé kí ẹ so ara yín pọ̀ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí, a ó sì ṣe é gẹ́gẹ́bí àwọn òfin Olúwa.

16 Kíyèsíi, èyí jẹ́ ọgbọ́n bákannáà nínú mi fún ire yín.

17 Àti pé ẹ níláti dọ́gba, tàbí ní ọ̀nà míràn, ẹ níláti ní ẹ̀tọ́ tí ó dọ́gba ní orí àwọn ohun ìní náà, fún ànfààní ṣíṣe àmójútó àwọn àníyàn àwọn iṣẹ́ ìríjú yín, olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí ohun tí ó fẹ́ ati àwọn àìní rẹ̀, níwọ̀nbí àwọn ohun tí ó fẹ́ bá yẹ—

18 Àti gbogbo ìwọ̀nyí fún ànfààní ìjọ Ọlọ́run alààyè, pé kí olúkúlùkù ènìyàn le mú tálẹ́ntì rẹ̀ dára síi, kí olúkúlùkù ènìyàn ó lè jèrè àwọn tálẹ́ntì míràn, bẹ́ẹ̀ni, àní ni ìlọ́po ọgọgọ́rún, lati jẹ́ gbígbé sí ilé ìṣura Olúwa, láti di ohun ìní àjùmọ̀ni ti gbogbo ìjọ—

19 Olúkúlùkù ènìyàn nítí wíwá ìfẹ́ inú aládũgbò rẹ̀, àti ní ṣíṣe ohun gbogbo pẹ̀lú fífí ojú sí ògo Ọlọ́run nìkan.

20 Ètò yìí ni èmi ti yàn lati jẹ́ ètò àìlópin fún yín, àti fún àwọn tí wọn yíò rọ́pò yín, níwọ̀nbí ẹ̀yin kò bá dá ẹ̀ṣẹ̀.

21 Àti pé ọkàn tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ sí májẹ̀mú yìí, àti tí ó sé ọkàn rẹ̀ le lòdì síi, ni a ó ṣe sí gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ìjọ mi, a ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún ìjẹníyà ti Sátánì títí di ọjọ́ ìràpadà.

22 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èyí sì jẹ́ ọgbọ́n, ẹ ṣe àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín pẹ̀lú mámmónì ti àìṣòdodo náà, wọn kì yíò sì pa yín run.

23 Ẹ fi ìdájọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú èmi nìkan, nítorí tèmi ní í ṣe, èmi yíò sì san padà. Kí àlãfíà wà pẹ̀lú yín; kí àwọn ìbukún mi ó máa wà pẹ̀lú yín títí.

24 Nítorí àní síbẹ̀ tiyín ni ìjọba náà, bẹ́ẹ̀ ni yíò sì wà títí láé, bí ẹ̀yin kò bá ṣubú kúrò nínú ìdúróṣinṣin yín. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.