Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 114


Ìpín 114

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Far West, Missouri, 11 Oṣù Kẹrin 1838.

1–2, Àwọn ipò iṣẹ́ nínú ìjọ tí àwọn aláìṣòótọ́ dìmú ni a ó fi fún àwọn ẹlòmíràn.

1 Lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí: Ó jẹ́ ọgbọ́n nínú ìránṣẹ́ mi David W. Patten, pé kí òun yanjú gbogbo iṣẹ́ òwò rẹ̀ ní àìpẹ́ bí ó ṣe lè yá fún un tó, kí ó sì fi ọjà títà rẹ̀ sílẹ̀, kí òun ó lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan fún mi ní àkókò ìrúwé tí ó nbọ̀, ní ọ̀wọ́ pẹ̀lú àwọn míràn, àní àwọn méjìlá tí òun náà wà nínú wọn, láti jẹ́rìí orúkọ mi àti láti kéde àwọn ìhìn ayọ̀ sí gbogbo ayé.

2 Nítorí lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí, pé níwọ̀nbí àwọn wọnnì bá wà ní ààrin yín tí wọ́n sẹ́ orúkọ mi, àwọn ẹlòmíràn ní a ó fi rọ́pò wọn ti yíò sì gba àjọ bíṣọ́ọ̀pù wọn. Àmín.