Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Sydney Rigdon, Parley P. Pratt, àti Leman Copley, ní Kirtland, Ohio, 7 Oṣù Karun 1831. Leman Copley ti tẹ́wọ́gba ìhìnrere ṣùgbọ́n síbẹ̀ òun tún dìmọ́ díẹ̀ nínú àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ti Shakers (Ìṣọ̀kan Ẹgbẹ́ Onígbàgbọ́ nínú Fífarahàn Krístì Ẹ̀ẹ̀kejì), nínú èyí tí òun ti wà tẹ́lẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn ohun ìgbàgbọ́ ti àwọn Shakers náà ni pé Bíbọ̀ Krístì Ẹ̀ẹ̀kejì ti wáyé àti pé Ó fi ara hàn ní ẹ̀yà obìnrin kan, Ann Lee. Wọn kò ka ìrìbọmi nípa omi sí pàtàkì. Wọ́n kọ ìgbeyàwó sílẹ̀ wọ́n sì gbàgbọ́ nínú ìgbé ayé àìgbéyàwó àti àìsí ìbálòpọ̀ rárá takọtabo. Àwọn Shakers kan bákannáà ka ẹran jíjẹ sí èèwọ̀. Ní kíkọ ọ̀rọ̀ ìṣaájú sí ìfihàn yìí, ìtàn ti Joseph Smith sọ pé, “Kí á lè ní òye pípé [kan] síi nípa kókó ọ̀rọ̀ náà, mo béèrè lọ́wọ́ Olúwa, mo sì gba àtẹ̀lé yìí.” Ìfihàn náà tako díẹ̀ lára àwọn ìpìlẹ̀ èrò àwọn ẹgbẹ́ Shakers. Àwọn arákùnrin tí a ti dárúkọ ṣíwájú mú ẹ̀dà ìfihàn náà lọ sí àwùjọ àwọn Shakers (nítòsí Cleveland, Ohio) wọ́n sì kàá fún wọn pátápátá, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ ọ́.