Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 48


Ìpín 48

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 10 Oṣù Kejì 1831. Wòlíì náà ti béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ọ̀nà ìgbésẹ̀ ti ríra àwọn ìlẹ̀ fún títẹ̀dó àwọn Ènìyàn Mímọ́. Èyí jẹ́ ohun pàtàkì bí a bá wo ìrìn àjò àwọn ọmọ ìjọ ní ṣíṣí láti ìhà ìlà oòrun Ìlẹ̀ Amẹ́ríkà, ní ìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa wipe wọ́n níláti kó ara wọn jọ ní Ohio (wo àwọn ìpín 37:1–3; 45:64).

1–3 Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Ohio níláti pín àwọn ilẹ̀ wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn; 4–6, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nílati ra àwọn ilẹ̀, kọ́ ilú nlá kan, àti kí wọn tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn olórí wọn.

1 O ṣe dandan pé kí ẹ̀yin ó dúró ní àwọn ibi ìtẹdó tí ẹ wà ní àkókò yìí, nítorí yíò wà ní ìbámu sí àwọn ipò yín.

2 Àti pé níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin bá ní ilẹ̀, ẹ̀yin yíò pín fún àwọn arákùnrin yín ní ìlà oòrùn.

3 Àti níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin kò bá ní ilẹ̀, ẹ jẹ́ kí wọn rà fún àkòkò yìí ní àwọn agbègbè yíká, bí wọ́n ṣe ríi pé ó dára, nítorí ó gbọdọ̀ di dandan pé kí wọn ní àwọn ibi tí wọn yíò gbé fún àkókò yìí.

4 Ó gbọdọ̀ jẹ́ dandan pé kí ẹ̀yin ó ṣe ìpamọ́ gbogbo owó tí ẹ bá le fi pamọ́, àti pé kí ẹ̀yin gba gbogbo ohun tí ẹ bá lè gbà ní òdodo, pé ní àìpẹ́ ẹ̀yin yíó lè ra ilẹ̀ fún ogún ìní, àní ìlú nlá náà.

5 Ibi ilẹ̀ náà ni a kò tíì fi han; ṣùgbọ́n lẹ́hìn ìgbà tí àwọn arákùnrin yín bá dé láti ìlà oòrùn nígba náà ni a ó yàn àwọn ènìyàn kan, àti pé a ó fi fún wọn láti mọ ibẹ̀, tàbí sí wọn ní a ó fi hàn.

6 A ó sì yàn wọ́n láti ra awọn ilẹ̀ náà, àti lati ṣe bíbẹ̀rẹ̀sí máa fi ìpìlẹ̀ ìlú nlá náà lélẹ̀; àti nígbà náà ni a ó bẹ̀rẹ̀sí kóo yín jọ pẹ̀lú àwọn ẹbí yín, ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ipò tí òun wà, àti pé gẹ́gẹ́bí a ṣe yàn án fún un láti ọwọ́ àjọ ààrẹ àti bíṣọ́pù ìjọ, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin àti àṣẹ èyítí ẹ̀yin ti gbà, àti èyí tí ẹ̀yin yíò gbà lẹ́hìnwá. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.