Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 65


Ìpín 65

Ìfihàn nípa àdúrà tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 30 Oṣù Kẹ̀wàá 1831.

1–2, Àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba Ọlọ́run ni a fi lé ènìyàn lọ́wọ́ ní orí ilẹ̀ ayé, àti pé iṣẹ́ ìhìnrere náà yíò borí; 3–6, Ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún ti ọ̀run yíò wá tí yío sì darapọ̀ mọ́ ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé.

1 Ẹ fetísílẹ̀, kí ẹ sì wòó, ohùn kan bíi èyí tí a rán wá sílẹ̀ láti ibi gíga, ẹnití ó ní ipá ati agbára, ẹni tí jíjáde lọ rẹ̀ jẹ́ sí àwọn òpin ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ni, ẹni tí ohùn rẹ̀ kọ sí àwọn ènìyàn—Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.

2 Àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba Ọlọ́run ni a fi lé ènìyàn lọ́wọ́ ní orí ilẹ̀ ayé, àti láti ibẹ̀ lọ ni ìhìnrere yíò ti yí lọ dé àwọn òpin ilẹ̀ ayé, bí òkúta kan tí a ké jáde lára òkè láì lo ọwọ́ yíò ti yí lọ, títí tí yíò fi kún gbogbo ilẹ̀ ayé.

3 Bẹ́ẹ̀ni, ohùn kan nkígbe—Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ pèsè oúnjẹ alẹ́ ti Ọ̀dọ́-Agùntàn, ẹ pèsè sílẹ̀ de Ọkọ Ìyàwó náà.

4 Ẹ gbàdúrà sí Olúwa, ẹ ké pe orúkọ mímọ́ rẹ̀, ẹ sọ àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ di mímọ̀ lààrin àwọn ènìyàn.

5 Ẹ ké pe Olúwa, kí ìjọba rẹ̀ ó lè tẹ̀síwájú ní orí ilẹ̀ ayé, kí àwọn olùgbé ibẹ̀ ó lè gbà á, kí wọ́n ó sì múrasílẹ̀ fún àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, nínú èyí tí Ọmọ Ènìyàn yíò sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀run, nínú wíwọ ìtànsán ògo rẹ̀, láti pàdé ìjọba Ọlọ́run èyí tí a gbé kalẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé.

6 Nísisìyí, kí ìjọba Ọlọ́run lè tẹ̀síwájú, kí ìjọba ọ̀run ó sì lè dé, kí ìwọ, Áà Ọlọ́run, lè jẹ́ yíyìn lógo ní ọ̀run bẹ́ẹ̀ náà ní ilẹ̀ ayé, kí àwọn ọ̀tá yín lè di aláìlágbára; nítorí tìrẹ ni ọlá, agbára àti ògo, láéláé àti títí láé. Amin.