Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128


Ìpín 128

Èpístélì kan láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith sí Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn, tí ó ní àwọn ìtọ́nisọ́nà síwájú síi nínú nípa ìrìbọmi fún àwọn òkú, ti ònkà ọjọ́ 6 Oṣù Kẹsãn 1842 ní Nauvoo, Illinois.

1–5, Àwọn akọ̀wé ìrántí ti ìbílẹ̀ àti ti gbogbogbò gbọ́dọ̀ fi ìdí òtítọ́ àwọn ìrìbọmi fún àwọn òkú múlẹ̀; 6–9, Àwọn àkọsílẹ̀ wọn jẹ́ èdídí a sì ṣe àkọsílẹ̀ wọn ní ayé àti ní ọ̀run; 10–14, Àwo omi ìrìbọmi jẹ́ àfiwé ibojì; 15–17, Èlíjah mú agbára padà bọ̀ sípò tí ó ní í ṣe sí ìribọmi fún àwọn òkú; 18–21, Gbogbo àwọn kọ́kọ́rọ́, àwọn agbára, àti àwọn àṣẹ ti àwọn ìgbà ìríjú tí ó ti kọjá ni a ti múpadà bọ̀ sípò; 22–25, Àwọn ìhìn ayọ̀ àti ológo ni a kéde fún àwọn alààyè àti àwọn òkú.

1 Bí mo ti ṣe ìkéde sí yín nínú ìwé tí mo kọ síwájú kí èmi tó kurò ní ibi ààyè mi, pé èmi yíò kọ̀wé síi yín láti àkókò dé àkókò kí nsì fún yín ní ìrohìn tí ó jẹ mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkòrí, nísisìyí mo tún bẹ̀rẹ̀ ní orí àkòrí ọ̀rọ̀ ti ìrìbọmi fún àwọn òkú, bí àkòrí náà ṣe dàbí pé ó gba ọkàn mi, tí ó sì tẹ ara rẹ̀ mọ́ ìmọ̀lára mi ní níní agbára jùlọ, láti ìgbàtí àwọn ọ̀tá mi ti ndọdẹ mi.

2 Èmi kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfihàn díẹ̀ sí yín nípa akọ̀wé ìrántí. Mo ti ní àfikún àwọn èrò díẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, èyítí èmi fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nísisìyí. Èyí ni pé, a ti kéde rẹ̀ nínú ìwé mi ti ìsaájú pé ó yẹ kí àkọ̀wé ìrántí kan ó wà, ẹnití yíò jẹ́ ẹlérìí óṣojú-mi-kòró, àti bákannáà láti gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ̀, kí òun ó lè ṣe àkọsílẹ̀ ti òtítọ́ kan niwájú Olúwa.

3 Nísisìyí, nípa ọ̀rọ̀ yìí, yíò ṣòro gidi fún àkọwé ìrántí kan láti máa wà ní gbogbo ìgbà, àti láti ṣe gbogbo iṣẹ́. Láti yẹra fún ìṣoro yìí, a lè ní akọ̀wé ìrántí kan ní yíyàn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àdúgbò ìlú nlá náà, ẹnití ó kún ojú òsùnwọ̀n dáradára fún ṣíṣe àkọsílẹ̀ ìròhìn ní pípé; ẹ sì jẹ́kí òun ó ṣe òfíntótó àti rẹ́gí gan an ní ṣíṣe àkọsílẹ̀ ìròhìn gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ní jíjẹ́ ẹ̀rí nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé òun rí pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ̀, ní fífi ònkà ọjọ́ síi, àti àwọn orúkọ, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, àti ìtàn ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀; bákannáà ní dídárúkọ ẹni mẹ́ta tí wọ́n wà níbẹ̀, bí a bá rí ẹnikẹ́ni tí ó wà níbẹ̀, ẹnití yíò lè jẹ́rìí sí ohun kannáà nígbàkugbà tí a bá pè, pé ní ẹnu ẹlérìí méjì tàbí mẹ́ta kí á lè fi ìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.

4 Nígbànáà, ẹ jẹ́kí akọ̀wé ìránti gbogbogbò kan kí ó wà, ẹnití a ó le fi àwọn àkọsílẹ̀ míràn wọ̀nyìí lé lọ́wọ́, tí wọ́n ti ṣe pẹ̀lú àwọn ìwé ẹ̀rí ní orí àwọn ìfọwọ́sí ti ara wọn, ní jíjẹ́ ẹ̀rí pé àkọsílẹ̀ tí wọ́n ṣe jẹ́ òtítọ́. Lẹ́hìnnáà akọ̀wé ìrántí gbogbogbò ti ìjọ lè kọ àkọsílẹ̀ náà sí orí ìwé àkọsílẹ̀ gbogbogbò ti ìjọ, pẹ̀lu àwọn ìwé ẹ̀rí àti gbogbo àwọn ẹlérìí tí wọ́n wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ tírẹ̀ pé òun gbàgbọ́ lõtọ́ pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yìí àti àwọn àkọsílẹ̀ jẹ́ òtítọ́, lati inú ìmọ̀ rẹ̀ nípa gbogbo ìwà rere àti yíyàn àwọn ènìyàn wọnnì nípasẹ̀ ìjọ. Nígbàtí a bá sì ṣe èyí ninú ìwé gbogbogbò ti ìjọ, àkọsílẹ̀ náà yíò jẹ́ mímọ́ gẹ́gẹ́, yíò sì dáhùn ìlànà náà ní ọ̀nà kan náà gẹ́gẹ́bí ẹnipé ó rí pẹ̀lú ojú rẹ̀ àti gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ̀, tí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ ti ọ̀kan náà sí orí ìwé gbogbogbò ìjọ.

5 Ẹ̀yin le rò ní ti ètò àwọn ohun yìí lati jẹ́ òfíntótó jù; ṣugbọ́n ẹ jẹ́kí nsọ fún yín pé ó jẹ́ láti dáhùn ìfẹ́ inú ti Ọlọ́run nìkan, nípa ṣíṣe ìbámu sí ìlànà àti ìpalẹ̀mọ́ tí Olúwa ti yàn tí ó sì pèsè ṣaájú ìpìlẹ̀ ayé, fún ìgbàlà àwọn òkú tí wọ́n bá kú láìní ìmọ̀ ìhìnrere.

6 Àti síwájú, mo fẹ́ kí ẹ rantí pé Jòhánnù olùfihàn náà ṣe àṣàrò ní orí àkòrí ọ̀rọ̀ yìí gan an nípa ti àwọn òkú, nígbàtí ó kéde, bí ẹ̀yin yíò ṣe ríi ní kíkọ̀ sílẹ̀ nínú Ìfihàn 20:12Èmí sì rí àwọn òkú, kékeré àti nlá, wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run; a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀; a sì ṣí ìwé míràn kan sílẹ̀, tí iṣe ìwé ìyè; a sì ṣe ìdájọ́ àwọn òkú láti inú àwọn ohun wọnnì tí a ti kọ́ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wọn.

7 Ẹ̀yin yíò rí nínú àtúnwí ọ̀rọ̀ yìí pé a ṣí àwọn ìwé; a sì ṣí ìwé míràn, èyítí í ṣe ìwé ìyè; ṣùgbọ́n a ṣe ìdájọ́ àwọn òkú láti inú àwọn ohun wọnnì tí a kọ sínú àwọn ìwé, gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ wọn; nítorínáà, àwọn ìwé tí a sọ nípa wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn ìwé tí ó ní àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ wọn nínú, ó sì tọkasí àwọn àkọ̀sílẹ̀ tí a pamọ́ ní orí ilẹ̀ ayé. Àti pé ìwé èyítí ó jẹ́ ìwé ìyè ni àkọsílẹ̀ èyítí a pamọ́ ní ọ̀run; ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ó báramu rẹ́gí pẹ̀lú ẹ̀kọ́ èyítí a pàṣẹ fún yín nínú ìfihàn tí ó wà nínú ìwé tí mo kọ sí yín síwájú kíkúrò mi ní ibi ààyè mi—pé ní gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ yín yíó lè jẹ́ kíkọ sílẹ̀ ní ọ̀run.

8 Nísisìyí, pàtàkì wíwà ìlànà yìí wà nínú agbára oyè àlùfáà, nípasẹ̀ ìfihàn ti Jésù Krístì, nínú èyítí a fi fúnni pé ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé yíò jẹ́ dídè ní ọ̀run, àti ohunkóhun tí ẹ̀yin bá tú ní ayé ni a ó tú ní ọ̀run. Tàbí, ní ọ̀nà míràn, ní wíwo ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá kọ sílẹ̀ ní ayé ni a ó kọ sílẹ̀ ní ọ̀run, àti pé ohunkóhun tí ẹ̀yin kò bá kọ sílẹ̀ ní ayé kì yíò jẹ́ kíkọ sílẹ̀ ní ọ̀run; nítorí nínú àwọn ìwé náà ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn òkú yín, gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ tiwọn, bóyá àwọn tìkara wọn ti ṣe àwọn ìlànà náà fúnra ara wọn propria persona, tàbí nípa ọ̀nà àwọn aṣojú tiwọn, gẹ́gẹ́bí ìlànà tí Ọlọ́run ti pèsè fún ìgbàlà wọn láti ìṣaájú ìpìlẹ̀sẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́bí àwọn àkọsílẹ̀ èyítí wọn ti pamọ́ nípa àwọn òkú wọn.

9 Sí àwọn kan ó lè dábí pé ó jẹ́ ẹ̀kọ́ ìgboyà gan an ni a sọ̀rọ̀ rẹ̀—agbára kan tí ó nṣe àkọsílẹ̀ tàbí tí ó ndè ní ìlẹ̀ àyé àti tí ó ndè ní ọ̀run. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní gbogbo àwọn ọjọ́ ayé, nígbàkugbà tí Olúwa bá fi ìgbà ìríjú oyè àlùfáà kan fún ẹ̀nikẹ́ni nípasẹ̀ ìfihàn tòótọ́, tàbí èyíkéyìí àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn, agbára yìí ni a ti máa nfi fúnni ní gbogbo ìgbà. Nítorínáà, ohunkóhun tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ṣe ní ipò àṣẹ, ní orúkọ Olúwa, tí wọ́n sì ṣe é ní òtítọ́ àti òdodo, àti tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ tí ó dára ati tí ó jẹ́ pípé pamọ́ nípa ohun kannáà, ó ti di òfin ní ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run, a kì yíò sì lè paárẹ́, gẹ́gẹ́bí àwọn àṣẹ ti Jèhófàh nlá. Èyí ni ọ̀rọ̀ sísọ òtítọ́. Taani ó le gbọ́ ọ?

10 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, fún àpẹrẹ, Matteu 16:18, 19: Èmi sì wí fún ọ pẹ̀lú pé, ìwọ ni Peteru, orí àpáta yìí ni èmi ó sì kọ́ ìjọ mi lé; ẹnu-ọ̀nà ipò-òkú kì yíò sì lè borí rẹ̀. Èmi ó sì fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run: ohunkóhun tí ìwọ bá dè ní ayé a ó dè é ní ọ̀run; ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé, a ó tú u ní ọ̀run.

11 Nísisìyí ohun àṣírí nlá tí ó sì wuyì ti gbogbo ọ̀rọ̀ náà, àti èyítí ó jẹ́ dídára ga jùlọ summum bonum ti àkòrí tí ó wà níwájú wa, ní gbígba àwọn agbára ti Oyè-Àlùfáà Mímọ́ nínú. Fún òun ẹnití a fi àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí fún kò sí ìṣòro ní gbígba ìmọ̀ ti àwọn òtítọ́ nípa ìgbàlà àwọn ọmọ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, méjèèjì fún àwọn òkú àti fún àwọn tí wọ́n wà láàyè.

12 Nínú èyí ni ògo àti ọlá wà, àti àìkú àti ìyè ayérayé—Ìlànà ti ìrìbọmi nípa omi, láti rì bọ inú rẹ̀ ní ọ̀nà láti dáhùn sí àfijọ ti òkú, kí ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ kan ó le ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú òmíràn, láti jẹ́ rírì bọ inú omi kí ó sì jade wá kúrò nínú omi jẹ́ àfijọ àjínde òkú ní jíjáde wá láti inú àwọn ibojì wọn; nítorínáà, ìlànà yí ni a gbé kalẹ̀ láti ṣe àjọṣepọ̀ kan pẹ̀lú ìlànà ti ìrìbọmi fún àwọn òkú, ní jíjẹ́ àfijọ ti àwọn òkú.

13 Nítorínáà, àwo omi ìrìbọmi ni a gbe kalẹ̀ bíi àpẹrẹ ìbojì, a sì pàṣẹ pé kí ó wà ní ibìkan ní ìsàlẹ̀ íbití àwọn alààyè máa npéjọ sí, láti ṣe àfihàn àwọn alààyè àti àwọn òkú, àti kí ohun gbogbo le ní àwọn àfijọ wọn, àti kí wọ́n lè ní ìbáṣepọ̀ ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn—èyíinì tí i ṣe ti ayé ní síṣe déédé sí èyíinì tí i ṣe ti ọ̀run, bí Paulù ti kéde rẹ̀, 1 Kọ́ríntì 15:46, 47, àti 48:

14 Ṣùgbọ́n kìí ṣe àkọ́kọ́ ni èyí tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ ti ara; àti lẹ́hìnnáà èyí tí í ṣe ti ẹ̀mí. Ẹni àkọ́kọ́ jẹ́ ti ilẹ̀ ayé, ti erùpẹ̀; ẹ̀nì èkejì ni Olúwa láti ọ̀run wá. Bí ti erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bákannáà ti wọ́n jẹ́ ti erùpẹ̀; àti bí ti ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ ni wọn bákannáà tí wọ́n jẹ́ ti ọ̀run. Àti bí àwọn àkọsílẹ̀ ṣe rí ní orí ilẹ̀ ayé nípa àwọn òkú yín, èyítí a ṣe jade ní tóòtọ́, bákannáà gẹ́gẹ́ ni àwọn àkọsílẹ̀ ní ọ̀run. Èyí, nítorínáà, ni agbára fífi èdídí dì àti dídèpọ̀, àti, ọ̀nà kan lati ní òye ọ̀rọ̀ yìí, àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba náà, èyítí ó ní kọ́kọ́rọ́ ti ìmọ̀ nínú.

15 Àti nísìsìyìí, ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ẹ jẹ́ kí nfi dáa yín lójú pé àwọn wọ̀nyìí ní ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ó jẹmọ́ ti àwọn òkú àti alààyè tí a kò le rékọjá lásán bẹ́ẹ̀, bí ó ṣe jẹmọ́ ìgbàlà wa. Nítorí ìgbàlà wọn ṣe dandan àti kòṣeémáni sí ìgbàlà wa, bí Paulù ti sọ nípa àwọn bàbá—pé a kò lè ṣe àwọn ní pípé láìsí àwa—bákannáà a kò lè ṣe àwa ní pípé láìsí àwọn òkú wa.

16 Àti nísisìyí, ní ìbáṣe pẹ̀lú ìrìbọmi fún àwọn òkú, èmi yíò fún yín ní àtúnwí ọ̀rọ̀ Paulu míràn, 1 Kọrintì 15:29; Njẹ́ kínni àwọn tí nṣe ìrìbọmi fún nítorí òkú yíò ha ṣe, bí àwọn òkú kò bá jínde rárá? Kínni ṣe nígbànáà ti wọ́n nṣe ìrìbọmi fún àwọn òkú?

17 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ní àsopọ̀ pẹ̀lú àtúnwí ọ̀rọ̀ yìí èmi yíò fún yín ní àtúnwí ọ̀rọ̀ kan lati ọ̀dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn wòlíì, ẹnití ó fi ojú rẹ̀ sùn sí ìmúpadàsípò oyè àlùfáà, àwọn ògo tí a ó fi hàn ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, àti ní ọ̀nà kan pàtàkì èyí tí ó logo jùlọ nínú gbogbo àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ti ìhìnrere àìlópin, orúkọ wọn ni, ìrìbọmi fún àwọn òkú; nítorí Málakì wipe, ní orí ìwé tí ó kẹ́hìn, àwọn ẹsẹ ẹ̀karũn àti ẹ̀kẹfà: Kíyèsíi, èmi yíò rán wòlíì Elijah sí yín síwájú dídé ọjọ́ nlá àti bíbanilẹ́rù ti Olúwa: Òun yíò sì yí ọkàn àwọn bàbá sí àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sí àwọn bàbá wọn, kí èmi kí ó má baà kọlu ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ègún.

18 Èmi ìbá ṣe ìtúmọ̀ kan tí ó já gaara jù sí èyí, ṣùgbọ́n ó já gaara tó láti mú yẹ fún èrò mi bí ó ṣe dúró. Ó tó láti mọ̀, nínú ọ̀rọ̀ yìí, pé a ó kọlu ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ègún bìkòṣepé irú àsopọ̀ kan tàbí òmíràn wà lààrin àwọn bàbá àti àwọn ọmọ, ní orí àwọn àkòrí kan tàbí òmíràn—sì kíyèsíi kínni àkòrí náà? Òun ni ìrìbọmi fún àwọn òkú. Nítorí àwa láìsí àwọn a kì yíò lè sọ wá di pípé; bẹ́ẹ̀ a kì yío le sọ àwọn láìsí àwa di pípé. Bẹ́ẹ̀ a kì yío lè sọ àwọn tàbí àwa di pípé láì sí àwọn tí wọ́n ti kú nínú ìhìnrere bákannáà; nítorí ó ṣe pàtàkì ní gbígbà wọlé ti ìgbà ìríjú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò, ìgbà ìríjú náà èyítí ó bẹ̀rẹ̀ nísìsìyìí láti jẹ́ gbígbà wọlé, pé kí odidi àti tí ó pé àti ìdàpọ̀ dídára, àti àsopọ̀ àwọn ìgbà ìríjú, àti àwọn kọ́kọ́rọ́, àti àwọn agbára, àti àwọn ògo yíò ṣẹlẹ̀, tí a ó sì fihàn láti àwọn ọjọ́ ti Ádámù àní sí àkókò tí a wà yìí. Kìí sì ṣe èyí nìkan, ṣùgbọ́n àwọn ohun wọnnì èyítí a kò tĩ fi hàn rí láti ìpìlẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a ti fi pamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti olóye, yíò di fífihàn sí àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọ ọmú nínú èyí, ìgbà ẹ̀kúnrẹrẹ ti àwọn àkókò.

19 Nísisìyí, kínni a gbọ́ nínú ìhìnrere èyítí a ti gbà? Ohùn kan ti ìdùnnú! Ohùn kan ti àánú láti ọ̀run wá; àti ohùn kan ti òtítọ́ jáde láti ilẹ̀ ayé; àwọn ìhìn ayọ̀ fún àwọn òkú; ohùn kan ti ìdùnnú fún àwọn alààyè àti àwọn òkú; àwọn ìhìn ayọ̀, ti ayọ̀ nla. Ó ṣe lẹ́wà tó ní orí àwọn òkè ni ẹsẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n mú àwọn ìhìn ti àwọn ohun rere wá, àti tí wọ́n sọ sí Síónì: Kíyèsíi, Ọlọ́run yín njọba! Bí àwọn ìrì ti Karmẹ́lì, bẹ́ẹ̀ni ìmọ̀ Ọlọ́run yíò sọ̀kalẹ̀ sí orí wọn!

20 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, kínni a gbọ́? Àwọn ìhìn ayọ̀ láti Kúmorà! Móronì, ángẹ́lì kan láti ọ̀run ní kíkéde ti ìmúṣẹ àwọn wòlíì—ìwé náà tí a ó fihàn. Ohùn Olúwa nínú ijù ti Fayette, ìjọba ìbílẹ̀ Seneca, ní kíkéde àwọn ẹlérìí mẹ́ta láti jẹ́rìí sí ìwé náà! Ohùn ti Mikaẹlì ní bèbè odò Susquehanna, ní dídá èṣù mọ̀ nígbàtí ó fi ara hàn bí ángẹ́lì ti ìmọ́lẹ̀! Ohùn ti Petérù, Jakọ́bù, àti Johánnù nínú ijù lààrin Harmony, ìjọba ìbílẹ̀ Susquehanna, àti Colesville, ìjọba ìbílẹ̀ Broome, ní orí odò Susquehanna, ní kíkéde ara wọn bí àwọn tí wọ́n ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba náà, àti ti ìgbà ìríjú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti àwọn àkókò!

21 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ohùn Ọlọ́run nínú ìyẹ̀wù ti Bàbá arúgbó Whitmer, ní Fayette, ìjọba ìbílẹ̀ Seneca, àti ní onírúurú àwọn àkókò, àti ní àwọn oríṣĩríṣĩ ibi la gbogbo ìrìnàjò àti àwọn ìpọ́njú ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yìí já! Àti ohùn ti Mikaẹ́lì, olórí ángẹ́lì; ohùn ti Gabríẹlì, àti ti Ráfaẹlì, àti ti onírúurú àwọn ángẹ́lì, láti Míkáẹ́lì tàbí Ádámù wá sí àkókò tí a wà yìí, tí gbogbo wọn nkéde ìgbà ìríjú tiwọn, àwọn ẹ̀tọ́ wọn, àwọn kọ́kọ́rọ́ wọn, àwọn iyì wọn, àwọn ọlánlá àti ògo wọn, àti agbára oyè-àlùfáà wọn; ní fífúnni ni ẹsẹ lé ẹsẹ, ẹ̀kọ́ lé ẹ̀kọ́; díẹ̀ ní ìhín, àti díẹ̀ ní ọ̀hún; ní fífúnwa ní ìtùnú nípasẹ̀ mímú èyíinì tí ó nbọ̀ jáde lọ, ní fífi ìrètí wa múlẹ̀!

22 Ẹ̀yin arákùrin, àwa kì yíò ha tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí ó tóbi tóbẹ́ẹ̀? Ẹ tẹ̀síwájú kìí sì í ṣe sẹ́hìn. Ìgboyà, ẹ̀yin arákùnrin; ẹ sì tẹ̀síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun! Ẹ jẹ́kí ọkàn yín kí ó yọ̀, kí ẹ sì dunnú gidigidi. Ẹ jẹ́kí ilẹ̀ ayé kí ó bú jáde sí orin kíkọ. Ẹ jẹ́kí àwọn òkú kí ó sọ àwọn orin àdákọ ti ìyìn ayérayé sí Ọba Ìmmanúẹ́lì, ẹnití ó ti yàn, kí ayé ó tó wà, èyí tí yíò mú wa rà wọ́n padà jade láti túbú wọn; nítorí àwọn ará túbú yíò lọ ní òmìnira.

23 Ẹ jẹ́kí àwọn òkè kí wọn hó fún ayọ̀, àti gbogbo ẹ̀yin àfonífojì kí ẹ ké ní ohùn rara; àti gbogbo ẹ̀yin òkun àti ẹ̀yin ìyàngbẹ ilẹ̀ kí ẹ sọ àwọn iṣẹ́ ìyanu ti Ọba Ayerayé yín! Àti ẹ̀yin odò, àti ẹ̀yin odò kékèké, àti ẹ̀yin ìṣàn omi, ẹ ṣàn wálẹ̀ pẹ̀lú inú dídùn. Ẹ jẹ́kí àwọn igbó àti gbogbo igi oko kí ó yin Olúwa; àti ẹ̀yin àpáta ẹ sunkún fún ayọ̀! Ẹ sì jẹ́kí oòrun, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ kí ó kọrin papọ̀, àti pé ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run kí ó hó fún ayọ̀! Ẹ sì jẹ́kí àwọn ẹ̀dá ayérayé ó kéde orúkọ rẹ̀ títí láéláé! Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí, báwo ní ohùn tí a gbọ́ láti ọ̀run ṣe logo tó, ní kíkéde sínú etí wa, ògo, àti ìgbàlà, àti ọlá, àti àìkú, àti ìyè ayérayé; àwọn ìjọba, àwọn ìjòyè, àti àwọn agbára!

24 Kíyèsíi, ọjọ́ nlá Olúwa náà súnmọ́ etílé; taani ó sì lè fi ara da ọjọ́ bíbọ̀ rẹ̀, àti taani ó lè dúró nígbàtí òun bá fi ara hàn? Nítorí òun dàbí iná ayọ́rin, àti bí ọṣẹ afọṣọ; òun yíò sì jókòó bí ẹnití nyọ́ àti tí ó nda fàdákà, òun yíò sì ṣe àfọ̀mọ́ àwọn ọmọ Lefì yío sì jọ̀ wọ́n mọ́ bí wúrà àti fàdákà, kí wọn kí ó lè rú ẹbọ sí Olúwa ẹbọ-ọrẹ kan nínú òdodo. Ẹ jẹ́kí àwa, nítorínáà, bí ìjọ kan àti àwọn ènìyàn kan, àti bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, rú ẹbọ sí Olúwa ẹbọ-ọrẹ kan nínú òdodo; ẹ sì jẹ́kí a gbé e kalẹ̀ nínú tẹ́mpìlì mímọ́ rẹ̀, nígbàtí ó bá parí, ìwé kan tí ó ní àkọsílẹ̀ àwọn òkú wa nínú, èyítí yíò jẹ́ yíyẹ fún gbogbo ìtẹ́wọ́gbà.

25 Ẹ̀yin arákùnrin, mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan láti sọ fún yín ní orí àkòrí náà; ṣùgbọ́n èmi yíò dánu dúró fún ìsisìyí, kí nsì tẹ̀síwájú lóri àkórí náà ní àkókò míràn. Èmi, bíi ti láélaé, ìránṣẹ́ yín onírẹ̀lẹ̀ ati ọ̀rẹ́ yín tí kò jẹ́ yapa láé,

Joseph Smith.