Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 34


Ìpín 34

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Orson Pratt, ní Fayette, NewYork, 4 Oṣù Kọkànlá, 1830. Arákùnrin Pratt jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ní àkókò náà. A ti yíi lọ́kàn padà òun sì ti ṣe ìribọmi nígbàtí ó kọ́kọ́ gbọ́ ìwàásù ìhìnrere tí a múpadà sípò nípasẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin, Parley P. Pratt, ní ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ṣaájú. Ìfihàn yìí ni a gbà nínú ilé Peter Whitmer Agbà.

1–4, Àwọn olóotọ́ di ọmọ Ọlọ́run nípa Ètùtù; 5–9, Ìwàásù ìhìnrere npèsè ọ̀nà fún Bíbọ̀ Èẹ̀kejì; 10–12, Ìsọtẹ́lẹ̀ máa nwá nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Ọmọ mi Orson, fetísílẹ̀ kí o sì gbọ́, kí o sì kíyèsíi ohun tí èmi, Olúwa Ọlọ́run, yíò sọ fún ọ, àní Jésù Krístì Olùràpadà rẹ.

Ìmọ́lẹ̀ náà àti ìyè ayé, ìmọ́lẹ̀ kan tí ó ntàn nínú òkùnkùn tí òkùnkùn náà kò sì leè borí rẹ̀.

Ẹnití Ó fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbàá gbọ́ ó lè di àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorínáà ìwọ jẹ́ ọmọ mi;

Àti pé ìbùkún ni fún ọ nítorípé ìwọ ti gbàgbọ́;

Àti pé alábùkún fún púpọ̀ síi ni ìwọ nítorípé a pè ọ́ láti ọwọ́ mi láti wàásù ìhìnrere mi—

Láti gbé ohùn rẹ sókè bíi ìró fèrè kan, ní gígùn àti aláriwo, kí o sì kígbe ironúpìwàdà sí ìran oníwà rúdurùdu àti alárékérekè kan, nípa títún ọ̀nà Olúwa ṣe fún bíbọ̀ rẹ̀ ẹ̀ẹ̀kejì.

Nítorí kíyèsíi, lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún ọ, àkókò náà ti kù sí dẹ̀dẹ̀ tí èmi yíò wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo nlá.

Yíò sì jẹ́ ọjọ́ nla ní àkókò ìpadàbọ̀ mi, nítorí gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ni wọn yíò wárìrì.

Ṣùgbọ́n ṣaájú dídé ọjọ́ nla yìí, oòrùn yíò sókùnkùn, òṣùpá yíò sì di ẹ̀jẹ̀; àwọn ìràwọ̀ yíò sì kọ̀ láti fi dídán wọn hàn, àti pé àwọn kan yíò tilẹ̀ jábọ́, ìparun nlá sì dúró de àwọn ènìyàn búburú.

10 Nísisìyí, gbé ohùn rẹ sókè àti pé kí ìwọ máṣe dásí, nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ̀rọ̀ náà; nítórináà sọtẹ́lẹ̀, àti pé a ó sì fi fún ọ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

11 Àti pé bí ìwọ bá jẹ́ olóotọ́, kíyèsíi, èmi wà pẹ̀lú rẹ títí tí Èmí yíò fi dé—

12 Àti pé lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún ọ, èmi nbọ̀ kánkán. Èmi ni Olúwa àti Olùràpadà rẹ. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.