Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93


Ìpín 93

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 6 Oṣù Keje 1833.

1–5, Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ olõtọ́ yíò rí Olúwa; 6–18, Jòhánnù jẹ́rìí pé Ọmọ Ọlọ́run lọ láti oore ọ̀fẹ́ sí oore ọ̀fẹ́ títí tí Òun fi gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ògo ti Bàbá; 19–20, Àwọn olõtọ́ ènìyàn, tí wọ́n nlọ láti oore ọ̀fẹ́ sí oore ọ̀fẹ́, yíò gba nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Rẹ̀ bákannáà; 21–22, Àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí nípasẹ̀ Krístì ni Ìjọ Àkọ́bí náà; 23–28, Krístì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbogbo òtítọ́, àti ènìyàn nípa ìgbọràn lè ṣe bákanáà; 29–32, Ènìyàn wà ní àtètèkọ́ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run; 33–35, Àwọn ohun tó gbé ayé ró jẹ́ ti ayérayé, àti pé ènìyàn lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ ní Àjínde; 36–37, Ògo Ọlọ́run ni ẹ̀mí òye; 38–40, Àwọn ọmọdé jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀ níwájú Ọlọ́run nítorí ìràpadà ti Krístì; 41–53, Àwọn arákùnrin tí wọ́n nṣíwájú ni a pàṣẹ fún lati ṣe ẹbí wọn létòlétò.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí: Yíò sì ṣe pé olúkúlùkù ọkàn tí ó bá kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti tí ó ké pe orúkọ mi, tí ó sì gbọ́ràn sí ohùn mi, àti tí ó pa àwọn òfin mi mọ́, yíò rí ojú mi yíò sì mọ̀ pé Èmi Ni;

2 Àti pé Èmi ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí ó ntàn ìmọ́lẹ̀ sí olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé;

3 Àti pé èmi wà nínú Bàbá, àti Bàbá nínú mi, àti Bàbá àti èmi jẹ́ ọ̀kan—

4 Bàbá nítorítí ó fún mi nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, àti Ọmọ nítorí èmi wà nínú ayé mo sì fi ẹran ara ṣe àgọ́ mi, mo sì gbé láàrin àwọn ọmọ ènìyàn.

5 Èmi wà nínú ayé mo sì gbà lati ọ̀dọ̀ Bàbá mi, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni a sì fi hàn kedere.

6 Jòhánnù sì rí àti jẹ́rìí sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ògo mi, àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti ẹ̀rí Jòhánnù ni a ó fi hàn lẹ́hìnwá.

7 Òun sì jẹ́rìí, wípé: Èmi rí ògo rẹ̀, pé òun ti wà láti àtètekọ́ṣe, kí ayé tó wà;

8 Nítorínáà, ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ ti wà, nítorí òun ni Ọ̀rọ̀ náà, àní ìránṣẹ́ ìgbàlà—

9 Ìmọ́lẹ̀ náà àti Olùràpadà ayé; Ẹ̀mí òtítọ́, ẹnití ó wá sí inú ayé, nítorípe a dá ayé lati ọwọ́ rẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni ìyè àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn wà.

10 Àwọn ayé ni a dá láti ọwọ́ rẹ̀; àwọn ènìyàn ni a dá láti ọwọ́ rẹ̀; ohun gbogbo ni a dá láti ọwọ́ rẹ̀, àti nípasẹ̀ rẹ̀, àti láti ara rẹ̀.

11 Àti pé èmi, Jòhannù, jẹ́rìí pé Èmi rí ògo rẹ̀, bíi ògo ti Ọmọ Bíbí Kan ṣoṣo ti Bàbá, tí ó kún fún oore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́, àní Ẹ̀mí òtítọ́, èyítí ó wá tí ó sì gbé nínú ẹran ara, ó sì gbé ní ààrin wa.

12 Àti pé èmi, Jòhánnù, ríí pé òun kò gba lára ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n ó gba oore ọ̀fẹ́ fún oore ọ̀fẹ́;

13 Òun kò sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ ní àkọ́kọ́, ṣugbọ́n ó tẹ̀síwájú láti oore ọ̀fẹ́ sí oore ọ̀fẹ́, títí tí òun fi gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ kan;

14 Àti báyìí ni a pè é ní Ọmọ Ọlọ́run, nitorípé òun kò gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ ní àkọ́kọ́.

15 Àti pé èmi, Jòhánnù, jẹ́rìí, sì wòó, a ṣí àwọn ọ̀run sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ lé e ní orí ní ìrí àdàbà, ó sì bà lé e ní orí, ohùn kan sì wá láti ọ̀run wípé: Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi.

16 Àti pé Èmi, Jòhánnù, jẹ́rìí pé òun gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ kan nínú ògo ti Bàbá;

17 Òun sì gba gbogbo agbára, ní ọ̀run àti ní ayé, ògo ti Bàbá sì wà pẹ̀lú rẹ̀, nítorí òun ngbé nínú rẹ̀.

18 Yíò sì ṣe, pé bí ẹ̀yin bá jẹ́ olõtọ́ ẹ̀yin yíò gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ ti Jòhánnù.

19 Èmi fún yín ní àwọn ọ̀rọ̀ sísọ wọ̀nyìí kí ẹ̀yin ó lè ní òye àti kí ẹ lè mọ̀ bí ẹ ó ṣe jọ́sìn, àti kí ẹ mọ ohun tí ẹ̀yin njọ́sìn, kí ẹ̀yin ó lè wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá ní orúkọ mi, àti ni àkókò tí ó yẹ kí ẹ gbà nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀.

20 Nítorí bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò gba nínú ẹ̀kunrẹ́rẹ́ rẹ̀, a ó sì ṣe yín logo nínú mi bí èmi ṣe wà nínú Bàbá; nítorínáà, mo wí fún yín, ẹ̀yin yíò gba oore ọ̀fẹ́ fún oore ọ̀fẹ́.

21 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi wà ní àtètèkọ́ṣe pẹ̀lú Bàbá, emi sì ni Àkọ́bí;

22 Àti gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí nípasẹ̀ mi jẹ́ alábapín nínú ògo ti ọ̀kannáà, àwọ́n sì ni ìjọ Àkọ́bí.

23 Ẹ̀yin pẹ̀lú wà ní àtètèkọ́ṣe pẹ̀lú Bàbá; èyíinì tí í ṣe Ẹ̀mí, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà;

24 Òtítọ́ sì jẹ́ ìmọ̀ àwọn nkan bí wọ́n ṣe wà, àti pé bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀ rí, àti bí wọn yíò ṣe wá;

25 Àti pé ohunkóhun tí ó pọ̀ tàbí keré jù èyí jẹ́ ẹ̀mí ti ẹni búburú nnì ẹni tí ó jẹ́ èké láti àtètèkọ́ṣe.

26 Ẹ̀mí òtítọ́ jẹ́ ti Ọlọ́run. Èmi ni Ẹ̀mí ti òtítọ́ náà, Jòhánnù sì jẹ́rìí ti èmi, ní wíwípé: Òun gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ kan ti òtítọ́, bẹ́ẹ̀ni, àní ti gbogbo òtítọ́;

27 Àti pé kò sí ẹnìkan tí ó lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ kan bíkòṣe pé òun pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.

28 Ẹ̀ni náà tí ó pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ gba òtítọ́ àti ìmọ́lẹ̀, títí tí a ó fi ṣe é lógo nínú òtítọ́ àti tí òun yío mọ ohun gbogbo.

29 Ènìyàn wà bákannáà ní àtètèkọ́ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀mí òye, tàbí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́, ni a kò dá tàbí ṣe, dájúdájú a kò sì le dá wọn.

30 Gbogbo òtítọ́ wà ní òmìnira ní ipò náà èyítí Ọlọ́run fi í sí, láti ṣiṣẹ́ fúnra rẹ̀, bíi gbogbo ẹ̀mí òye bákannáà; bíbẹ́ẹ̀kọ́ kò sí wíwà.

31 Kíyèsíi, níhĩn ni agbára ènìyàn láti yàn, àti níhĩn ni ìdálẹ́bi ènìyàn; nítorípé èyíinì tí ó ti wà láti àtètèkọ́ṣe ni ó hàn kedere sí wọn, wọn kò sì gba ìmọ́lẹ̀.

32 Àti olúkúlùkù ènìyàn ẹnití ẹ̀mí rẹ̀ kò gba ìmọ́lẹ̀ náà wà lábẹ́ ìdálẹ́bi.

33 Nítorí ènìyàn jẹ́ ẹ̀mí. Àwọn ohun tí ó gbé ayé ró jẹ́ ayérayé, ati ẹ̀mí ati àwọn ohun tí ó gbé ayé ró, ti wọ́n so mọ́ ara wọn láì lè pínyà, yíò gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀;

34 Àti pé nígbatí a bá pín wọn níyà, ènìyàn kò lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀.

35 Àwọn ohun tí ó gbé ayé ró náà jẹ́ àgọ́ ti Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ni, ènìyàn ni àgọ́ ti Ọlọ́run, àní àwọn tẹ́mpìlì; èyíkéyìí tẹ́mpìlì tí a bá sọ di àìmọ́, Ọlọ́run yíò pa tẹ́mpìlì náà run.

36 Ògo Ọlọ́run ni ẹ̀mí òye, tàbí, ní ọ̀nà míràn, ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́.

37 Ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ kọ èyí tí ṣe ẹni búburú nnì sílẹ̀.

38 Olúkúlùkù ẹ̀mí ènìyàn ni ó jẹ́ aláìlẹ́bi ní ìbẹ̀rẹ̀; àti pé Ọlọ́run, lẹ́hìn tí ó ti ra ènìyàn padà kúrò nínú ìṣubú, lẹ́ẹ̀kansíi ènìyàn tún di, ní ìgbà ọmọ-ọwọ́ wọn, aláìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run.

39 Ẹni búburú nnì sì wá òun sì mú ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ lọ kúrò, nípasẹ̀ àìgbọ́ràn, lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn, àti nítorí àṣa àwọn bàbá wọn.

40 Ṣùgbọ́n èmi ti pàṣẹ fún yín láti tọ́ àwọn ọmọ yín nínú ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́.

41 Ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams, ìwọ ti tẹ̀síwájú lábẹ́ ìdálẹ́bi yìí;

42 Ìwọ kò kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin náà; àti pé ẹni búburú nnì ti ní agbára, nísisìyí, ní orí rẹ, èyí ni ó sì fa ìpọ́njú rẹ.

43 Àti nísisìyí òfin kan ni èmi fi fún ọ—bí a ó bá gbà ọ́ sílẹ̀ ìwọ yíò ṣe ilé rẹ létòlétò, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan ni ó wà tí kò tọ́ nínú ilé rẹ.

44 Lõtọ́, ni mo wí fún ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon, pé nínú àwọn ohun kan òun kò pa àwọn òfin mọ́ nípa ti àwọn ọmọ rẹ̀; nítorínáà, kọ́kọ́ ṣe ilé rẹ létòlétò.

45 Lõtọ́, ni mo wí fún ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, tàbí ní ọ̀nà míràn, èmi yíò pe yín ní ọ̀rẹ́, nitorí ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin í ṣe, ẹ̀yin yíò sì ní ogún kan pẹ̀lú mi—

46 Èmi pè yín ní ìránṣẹ́ nítorí ti ayé, ẹ̀yin sì jẹ́ ìránṣẹ́ wọn nítorí tèmi—

47 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún Joseph Smith Kékeré—Ìwọ kò pa àwọn òfin mọ́, o sì gbọ́dọ̀ dúró ní fífibú níwájú Olúwa;

48 Àwọn ẹbí rẹ gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí wọn ó sì fi àwọn ohun kan sílẹ̀, àti kí wọ́n ó ní ìtara sí i láti kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ sísọ rẹ, tàbí kí á mú wọn kúrò ní ààyè wọn.

49 Ohun tí èmi wí fún ẹnìkan mo wí fún ẹni gbogbo; máa gbàdúrà nígba gbogbo bíbẹ́ẹ̀kọ́ kí ẹni búburú nní má lè ní agbára nínú rẹ, kí á sì mú ọ kúrò ní ààyè rẹ.

50 Ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney bákannáà, bíṣọpù kan ní ìjọ mi, nílò lati jẹ́ bíbáwí, kí òun sì ṣe ẹbí rẹ̀ létòlétò, àti kí ó rí i pé wọ́n ní aápọn àti ìfiyèsí ní ilé, kí wọn ó gbàdúrà nígbàgbogbo, tàbí wọn yío di mímú kúrò ní ààyè wọn.

51 Nísìsìyìí, mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹkí ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon ó lọ sí ìrìnàjò rẹ̀, kí òun sì yára, àti bákannáà kí ó kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà Olúwa, àti ìhìnrere ìgbàlà, bí èmi yíò ṣe fún un ní ọ̀rọ̀ sísọ; àti nípa àdúrà ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú ìfìmọ̀ ṣọ̀kan èmi yíò gbé e ró.

52 Ẹ sì jẹ́kí àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti Frederick G. Williams ó yára bákannáà, a ó sì fi fún wọn àní gẹ́gẹ́bí àdúrà ìgbàgbọ́; àti níwọ̀nbí ẹ̀yin bá pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́ ẹ̀yin kì yíò dààmú ní ayé yìí, tàbí ní ayé tí ó nbọ̀.

53 Àti, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ìfẹ́ inú mi ni pé kí ẹ yára láti túmọ̀ àwọn ìwé mímọ́ mi, àti láti gba òye ìwé ìtàn, àti ti àwọn orílẹ̀-èdè, àti ti àwọn ìjọba, ti àwọn òfin Ọlọ́run àti ènìyàn, àti gbogbo ìwọ̀nyìí fún ìgbàlà Síónì. Amín.