Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 3


Ìpín 3

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith, ní Harmony, Pennsylvania, ní oṣù Keje 1828, tí ó níí ṣe pẹ̀lú sísọnù ojú ewé ìwé mẹ́rindinlọgọ́fà tí a fi ọwọ́ kọ ìtumọ̀ rẹ̀ láti inú abala àkọ́kọ́ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì, èyí tí a pè ní ìwé ti Lehi. Wòlíì náà ti fi ìlọ́ra fi ààyè sílẹ̀ kí àwọn ojú ewé ìwé náà kúrò ní ìpamọ́ rẹ̀ bọ́ sí ọ̀dọ̀ Martin Harris, ẹnití ó ti ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ bíi akọ̀wé nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìfihàn yìí ni a fi fúnni nípasẹ̀ Urímù àti Túmímù. (Wo ìpín 10.)

1–4, Ipa ọ̀nà Olúwa jẹ́ ọ̀kan yípo ayeraye; 5–15, Joseph Smith gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà tàbi kí ó pàdánù ẹ̀bùn láti túmọ̀; 16–20, Ìwé Ti Mọ́mọ́nì wá láti gba irú ọmọ Léhì là.

1 Àwọn iṣẹ́, àti àwọn àgbékalẹ̀, àti àwọn èrò Ọlọ́run kò ṣeé bàjẹ́, wọn kò sì le di asán.

2 Nítorí Ọlọ́run kìí rìn ní àwọn ipa ọ̀nà tí ó wọ́, tàbí kí ó yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì, òun kìí yípadà kúrò ní orí ohun náà tí ó ti sọ, nítorínáà àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ipa ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kan yípo ayérayé.

3 Ránti, rántí pé kìí ṣe iṣẹ́ ti Ọlọ́run ni a mú díbàjẹ́, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ti ènìyàn.

4 Nítorí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfihàn, àti agbára láti ṣe ọ̀pọlọpọ̀ iṣẹ́ títóbi, síbẹ̀ tí ó bá nṣògo nínú ipá ti ara rẹ̀, tí ó sì ka awọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run sí asán, tí ó sì ntẹ̀lé àwọn èrò ti ara rẹ̀ àti ìfẹ́ ti ẹran ara, òun gbọdọ̀ ṣubú kí ó sì gba ẹ̀san Ọlọ́run òdodo sí orí rẹ̀.

5 Kíyèsíi, a ti fa àwọn ohun wọ̀nyí lé ọ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n báwo ni àwọn òfin rẹ ṣe le tó; kí o sì rántí bákannáà àwọn ìlérí tí a ṣe fún ọ, bí ìwọ kò bá ré wọn kọjá.

6 Àti pé kíyèsíi, ìgbà púpọ̀ ni o ti ré àwọn àṣẹ ati òfin Ọlọ́run kọjá, tí o sì ti tẹ̀síwájú nínú ìyílọ́kànpadà ti àwọn ènìyàn.

7 Nítorí, kíyèsíi, ìwọ kò nílati bẹ̀rù ènìyàn ju Ọlọ́run lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ènìyàn kò ka ìmọ̀ràn Ọlọ́run sí, síbẹ̀ wọn kẹ́gàn àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀—

8 Síbẹ̀ ó yẹ kí o jẹ́ olõtọ́, àti pé òun ìbá na apá rẹ̀ kí ó sì dáàbò bò ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọfà iná ọ̀tá; òun ìbá sì wà pẹ̀lú rẹ ní gbogbo ìgbà wàhálà.

9 Kíyèsíi, ìwọ ni Joseph, a sì ti yàn ìwọ láti ṣe iṣẹ́ Olúwa, ṣùgbọ́n nítorí ìrékọjá, bí ìwọ kò bá kíyèsára ìwọ yío ṣubú.

10 Ṣùgbọ́n rantí, aláànú ni Ọlọ́run, nítorínáà, ronúpìwàdà ní orí ohun náà tí ìwọ ti ṣe èyítí ó lòdì sí òfin tí mo fi fún ọ, àti pé ìwọ náà ni a yàn síbẹ̀síbẹ̀, a sì tún ti pè ọ́ sí iṣẹ́ náà.

11 Bíkòṣe pé ìwọ bá ṣe èyí, a o jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ ìwọ yíò sì dàbí àwọn ènìyàn míràn, ìwọ̀ kì yíò sì ní ẹ̀bùn mọ́.

12 Àti pé nígbàtí ìwọ bá jọ̀wọ́ ohun náà èyí tí Ọlọ́run ti fún ọ ní ìríran àti agbára láti túmọ̀, ìwọ jọ̀wọ́ ohun náà èyí tí ó jẹ́ mímọ́ sí ọwọ́ ènìyàn búburú,

13 Ẹnití ó ti ka àwọn ìmọràn Ọlọ́run sí asán, àti tí ó ti sẹ́ àwọn ìlérí mímọ́ jùlọ tí a ṣe níwájú Ọlọ́run, àti tí ó ti gbé ara lé ìdájọ́ ti ara rẹ̀ tí ó sì ṣògo nínú ọgbọ́n ti ara rẹ̀.

14 Àti pé èyí ni ìdí tí ìwọ fi pàdánù àwọn ànfaní rẹ fún ìgbà kan—

15 Nítorí ìwọ ti fi ààyè gba ìmọ̀ràn olùdarí rẹ lati di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ láti àtètèkọ́ṣe.

16 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ mi yíò mã tẹ̀ síwájú, níwọ̀nbí ìmọ̀ nípa Olùgbàlà kan ti di mímọ̀ fún ayé, nípasẹ̀ ẹ̀rí láti ẹnu àwọn Júù, àní bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ nípa Olùgbàlà kan yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi—

17 Àti sí àwọn ará Néfì, àti àwọn ará Jákọ́bù, àti àwọn ará Jósefù, àti àwọn ará Sórámù nípasẹ̀ ẹ̀rí àwọn bàbá wọn—

18 Àti pé ẹ̀rí yìí yíò wá sí ìmọ àwọn ará Lámánì, àti àwọn ará Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn Iṣmaẹ́lì, tí wọn ti rẹ̀hin nínú àìgbàgbọ́ nítorí àìṣedéédé àwọn bàbá wọn, àwọn ẹnití Olúwa gbà láàyè láti pa àwọn arákùnrin wọn awọn ará Néfì run, nítorí àwọn àìṣedéédé àti àwọn ìríra wọn.

19 Àti pé nítorí ìdí èyí gãn ni a ṣe pa àwọn àwo wọ̀nyí mọ́, èyí tí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí nínú—kí àwọn ìlérí Olúwa baà lè wá sí ìmúṣẹ, èyí tí ó ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀.

20 Àti pé kí àwọn ará Lámánì le ní ìmọ̀ nípa àwọn bàbá wọn, àti kí wọn le mọ àwọn ìlérí Olúwa, àti kí wọn le gbà ìhìnrere gbọ́ kí wọn ó sì le gbẹ́kẹ̀lé àwọn iṣẹ́ òdodo Jesu Kristi, ati kí wọn ó di ìṣelógo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀, àti pé nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà wọn kí a lè gbà wọ́n là. Amín.