Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 41


Ìpín 41

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Ìjọ, ní Kirtland, Ohio, 4 Oṣù Kejì 1831. Ìfihàn yìí fi àṣẹ fún Wolíì náà ati àwọn alàgbà Ìjọ láti gbàdúrà lati gba “òfin” ti Ọlọ́run (wo ìpín 42). Joseph Smith ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Kirtland láti New York, àti Leman Copley, ọmọ Ìjọ kan ní itòsí Thompson, Ohio, “béèrè lọ́wọ́ Arákùnrin Joseph àti Sidney [Rigdon] … gbé pẹ̀lú rẹ̀ òun ó sì pèsè àwọn ilé àti àwọn ìpèsè fún wọn.” Ìfihàn tí ó tẹ̀lé ṣe àfọ̀mọ́ ibití Joseph ati Sidney gbọdọ̀ gbé àti bákannáà ó pe Edward Patridge lati jẹ́ bíṣọpù àkọ́kọ́ ti Ìjọ.

1–3, Àwọn alàgbà yíò ṣe àkóso Ìjọ pẹ̀lú ẹ̀mí ìfihàn; 4–6, Àwọn ọmọ ẹ̀hìn tòótọ́ yíò gba òfin Olúwa wọn yíò sì pa á mọ́; 7–12, Edward Partridge ni a dárúkọ gẹgẹ́bí bíṣọ́pù kan fún ìjọ.

1 Ẹ fetísílẹ̀ kí ẹ sì gbọ́, Áà ẹ̀yin ènìyàn mi, ni Olúwa àti Ọlọ́run yín wí, ẹ̀yin tí èmi ní inú dídùn sí láti bùkún fún pẹ̀lú èyí tí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ìbùkún, ẹ̀yin tí ẹ gbọ́ mi; àti ẹ̀yin tí ẹ kò gbọ́ mi ni èmi yíò fi bú, tí ẹ ti jẹ́wọ́ orúkọ mi, pẹ̀lú èyítí ó wúwo jùlọ nínú gbogbo àwọn ìfibú.

2 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi tí mo ti pè, kíyèsíi èmi fi òfin kan fún yín, pé kí ẹ pe ara yín jọ pọ̀ láti fi ohùn ṣọ̀kan ní orí ọ̀rọ̀ mi;

3 Àti nípa àdúrà ìgbàgbọ́ yín ẹ̀yin yíò gba òfin mi, kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ bí ẹ ó ti ṣe àkóso ìjọ mi àti tí ẹ̀yin yíò fi ṣe ohun gbogbo ní yíyẹ́ níwajú mi.

4 Èmi yíò sì jẹ́ alákoso yín nígbàtí èmi bá dé; àti kíyèsíi, èmi nbọ̀ kánkán, ẹ̀yin yíò sì ríi pé òfin mi jẹ́ pípa mọ́.

5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà òfin mi tí ó sì ṣe é, òun kan náà ni ọmọ ẹ̀hìn mi; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wí pé òun gbà á tí kò sì ṣe é, òun kan náà kìí ṣe ọmọ ẹ̀hìn mi, a ó sì ta á nù lààrin yín;

6 Nítorí kò tọ́ pé kí a fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ ìjọba fún àwọn wọnnì tí kò yẹ, tàbí fún àwọn ajá, tàbí kí á ju àwọn pealì sí iwájù ẹlẹ́dẹ̀.

7 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ó tọ́ pé kí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kekere, ní ilé kan tí yíò kọ́, níbití yíò má a gbé tí yíò sì ti máa túmọ̀.

8 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ó tọ́ pé kí ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon ó gbé bí ó bá ṣe rí i pé ó dára, níwọ̀nbí òun bá ti pa àwọn òfin mi mọ́.

9 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi ti pe ìránṣẹ́ mi Edward Partridge; èmi sì fi òfin kan fúnni, pé kí á yàn án pẹ̀lú ohùn ìjọ, kí á sì yàn án bíi bíṣọpù kan fún ìjọ, láti fi ọjà títà rẹ̀ sílẹ̀ kí òun lo gbogbo àkókò rẹ̀ fún ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìjọ;

10 Láti mójútó ohun gbogbo bí a ó ṣe yàn án fún un nínú àwọn òfin mi ní ọjọ́ tí èmi yíò bá fi wọ́n fúnni.

11 Àti èyí nítorípé ọkàn rẹ̀ jẹ́ mímọ́ níwájú mi, nítorí òun dàbí Nathanaẹ́lì ìgbàanì, nínú ẹnití a kò rí ẹ̀tàn.

12 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a fi fún yín, wọ́n sì jẹ́ mímọ́ níwájú mi; nítorínáà, ẹ kíyèsára bí ẹ̀yin yíò ṣe mú wọn, nítorí àwọn ọ̀kàn yín yíò dáhùn fún wọn ní ọjọ́ ìdájọ́. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.