Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 131


Ìpín 131

Àwọn ìtọ́sọ́nà láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith, tí a fifúnni ní Ramus, Illinois, 16 àti 17 Oṣù Karun 1843.

1–4, Ìgbéyàwó sẹ̀lẹ́stíà jẹ́ pàtàkì sí ìgbéga ológo ní ibi gíga jùlọ ní ọ̀run; 5–6, Bí a ṣe nfi èdìdí di àwọn ènìyàn sí ìyè ayérayé ni a ṣe àlàyé rẹ̀; 7–8, Gbogbo ẹ̀mí jẹ́ ohun èlò.

Nínú ògo ti sẹ̀lẹ́stíà àwọn ọ̀run tàbí àwọn ìpele mẹ́ta ni wọ́n wà;

Àti ní ètò láti gba èyí tí ó ga jùlọ, ènìyàn gbọdọ̀ wọlé sí inú ètò ti oyè àlùfáà yìí [tí ó túmọ̀ sí májẹ̀mú titun àti àìlópin ti ìgbéyawó];

Bí òun kò bá sì ṣe é, òun kò le gbà á.

Òun lè wọ inú òmíràn, ṣùgbọ́n èyí ni yíò jẹ́ òpin ìjọba rẹ̀; òun kì yíò ní àlékún kan.

(Oṣù Karun 17, 1843.) Ọ̀rọ̀ àṣọtẹ́lẹ̀ tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ jù túmọ̀ sí pé ènìyàn ní ìmọ̀ pé a fi èdìdi di òun sí ìyè ayérayé, nípasẹ̀ ìfihàn àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, nípasẹ̀ agbára ti Oyè Àlùfáà Mímọ́.

Kò ṣeéṣe fún ènìyàn kan láti di gbígbàlà nínú àìmọ̀kan.

Kò sí irú ohun náà bíi àìwúlò. Gbogbo ẹ̀mí ni ohun èlò, ṣùgbọ́n ó jẹ́ dídara tàbí àìlábàwọ́n, a sì le dáa mọ̀ nípa ojú tí ó jẹ́ àìlábàwọ́n jù nìkan;

A kò lè rí i; ṣùgbọ́n nígbàtí ara wa bá di sísọ di mímọ́ àwa yíò lè ríi pé gbogbo rẹ̀ jẹ́ ohun èlò.