Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88


Ìpín 88

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Joseph Smith ní Kirtland, Ohio, 27 àti 28 Oṣù Kejìlá 1832, àti 3 Oṣù Kínní 1833. Wòlíì ṣe àsàyàn rẹ̀ bií “‘ewé ólífì’… tí a já láti ara Igi ti Párádísè, ọ̀rọ̀ àlãfíà Olúwa sí wa.” Ìfihàn náà ni a fifúnni lẹ́hìn tí àwọn àlùfáà gíga gbàdúrà nínú ìpàdé àpéjọpọ̀ kan “ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ní sísọ̀rọ̀ sókè sí Olúwa lati fi ìfẹ́ inú Rẹ̀ han sí wa nípa ìkọ́sókè ti Síonì.”

1–5, Àwọn olõtọ́ Ẹni Mímọ́ gba Olùtùnú náà, èyí tí í ṣe ìlérí ayé àyérayé; 6–13, Ohun gbogbo ni a darí tí a sì ṣe àkóso wọn nípa Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì; 14–16, Àjínde wá nípasẹ̀ Ìràpadà; 17–31, Ìgbọ́ràn sí òfin sẹ̀lẹ́stíà, tẹ̀rẹ́stríà, tàbí tẹ̀lẹ́stíà npèsè àwọn èniyàn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọ̀ba àti ògo wọnnì; 32–35, Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti dúró sínú ẹ̀ṣẹ̀ wà nínú èérí síbẹ̀; 36–41, Gbogbo àwọn ìjọ̀ba ni a ṣe àkóso wọn nípa òfin; 42–45, Ọlọ́run ti fi ofin kan fúnni sí ohun gbogbo; 46–50, Èniyàn yíò ní òye àní Ọlọ́run pẹ̀lú; 51–61, Òwe ti ọkùnrin náà tí ó nrán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí inú oko àti tí ó sì nṣe ìbẹniwò sí wọn láti ọ̀dọ̀ ẹnikàn sí òmíràn; 62–73, Súnmọ́ Olúwa, ìwọ yíò sì rí ojú Rẹ̀; 74–80, Ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì kọ́ ara yín ní àwọn ẹ̀kọ́ ti ìjọ̀ba náà; 81–85, Olúkúlùkù ènìyàn tí a ti kìlọ̀ fún níláti kìlọ̀ fún aládùúgbò rẹ̀; 86–94, Àwọn àmì, ìdàrúdàpọ̀ ti àwọn ohun ti ó gbé ilé ayé dúró, àti àwọn ángẹ́lì ni ó ntún ọ̀nà ṣe fún bíbọ̀ Olúwa; 95–102, Àwọn fèrè bíi ti ángẹ́lì pe àwọn òkú jade ní ẹsẹẹsẹ wọn; 103–116, Àwọn fèrè bíi ti ángẹ́lì kéde ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere náà, ìṣubú ti Bábílónì, àti ogun ti Ọlọ́run títóbi; 117–126, Wá ìmọ̀ kún ìmọ̀, ṣe ìdásílẹ̀ ilé Ọlọ́run (tẹ́mpìlì kan), àti kí ẹ sì wọ ara yín ní aṣọ pẹ̀lú ìdè ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́; 127–141, Ètò ti Ilé ẹ̀kọ́ àwọn Wòlíì ni a gbé jade, nínú èyítí ìlànà ẹsẹ̀ wíwẹ̀ wà.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín ẹ̀yin tí ẹ kó ara yín jọ pọ̀ láti gba ìfẹ́ inú rẹ̀ nípa yín:

2 Kíyèsíi, èyí jẹ́ dídùn inú sí Olúwa yín, àwọn ángẹlì sì nyọ̀ nítorí yín; àwọn ìtọrẹ àánú, àwọn àdúrà yín ti gòkè sí etí Olúwa Sábáótì, a sì kọ wọ́n sílẹ̀ nínú ìwé orúkọ, àwọn tí a ti yà sí mímọ́, àní àwọn tí ayé sẹ̀lẹ́stíà.

3 Nítorínáà, èmi fi Olùtùnú míràn ránṣẹ́ sí orí yín nísìsìyìí, àní sí orí ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, kí ó lè máa gbé nínú ọkàn yín, àní Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìlérí; Olùtùnú míràn tí ó jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú èyítí èmi ṣe ìlérí rẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, bí a ṣe kọọ́ sílẹ̀ nínú ẹ̀rí Jòhánnù.

4 Olùtùnú yìí ni ìlérí náà èyí tí mo fi fún yín ti ìyè àìnípẹkun, àní ògo ti ìjọba sẹ̀lẹ́stíà náà;

5 Ògo èyítí ṣe ti ìjọ Àkọ́bí náà, àní ti Ọlọ́run, ẹni mímọ́ jùlọ, nípasẹ̀ Jésù Krístì Ọmọ rẹ̀—

6 Òun ẹnití ó gòkè lọ sí ibi gíga, bí ó ṣe sọ̀kalẹ̀ sí abẹ́ ohun gbogbo bákannáà, nítorípé òun ní ìmọ ohun gbogbo, kí òun ó lè wà nínú ohun gbogbo àti kí ó lè la ohun gbogbo kọjá, ìmọ́lẹ̀ náà ti òtítọ́;

7 Òtítọ́ èyítí ó ntàn. Èyí ni ìmọ́lẹ̀ Krístì. Bí òun ṣe wà nínú oòrùn bákannáà, àti ìmọ́lẹ̀ ti oòrùn, àti agbára inú rẹ̀ nípa èyí tí a dá a.

8 Bí òun ṣe wà nínú òṣùpá bákannáà, òun sì ni ìmọ́lẹ̀ ti òṣùpá, àti agbára inú rẹ̀ nípa èyí tí a dá a;

9 Bíi ìmọ́lẹ̀ ti àwọn ìràwọ̀ bákannáà, àti agbára inú wọn nípa èyí tí a dá wọn;

10 Àti ilẹ̀ ayé bákannáà, àti agbára inú rẹ̀, àní ilẹ̀ ayé náà ní orí èyí tí ẹ̀yin dúró.

11 Àti ìmọ́lẹ̀ èyítí ó ntàn, èyí tí ó nfún yín ní ìmọ́lẹ̀, jẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀ ẹnití ó nfi òye fún ojú yín, èyítí ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ kannáà tí ó nsọ àwọn ìmọ̀ yín di alààyè;

12 Ìmọ́lẹ̀ èyí tí ó tàn jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti kún gbogbo àlàfo tí kò ní òpin—

13 Ìmọ́lẹ̀ náà èyítí ó wà nínú ohun gbogbo, èyítí ó nfi ìyè fún ohun gbogbo, èyítí ó jẹ́ òfin nípa èyítí a nṣe àkóso ohun gbogbo, àní agbára Ọlọ́run ẹnití ó jókòó ní orí ìtẹ́ rẹ̀, ẹni tí ó wà ní oókan àyà ayérayé, ẹnití ó wà ní ààrin ohun gbogbo.

14 Nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé nípasẹ̀ ìràpadà náà èyítí a ṣe fún yín ni a mú kí àjínde kúrò nínú òkú ó ṣeéṣe.

15 Àti pé ẹ̀mí àti ara ni ó jẹ́ wíwà ẹ̀dá ènìyàn.

16 Àti pé àjínde kúrò nínú òkú jẹ́ ìràpadà ti ẹ̀dá náà.

17 Ìràpadà ẹ̀dá sì jẹ́ nípasẹ̀ ẹni náà tí a sọ ohun gbogbo di alààyè, nínú oókan àya ẹnití a paá láṣẹ pé àwọn aláìní àti oníwà tútù ayé yíó jogún rẹ̀.

18 Nítorínáà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ dandan pé kí á yàá sí mímọ́ kúrò nínú àìṣododo gbogbo, kí á lè pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún ògo ti sẹ̀lẹ́stíà;

19 Nítorí lẹ́hìn ìgbàtí ó bá ti kún ojú òsùwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀, a ó dé e ní adé ògo, àní pẹ̀lú wíwà níbẹ̀ ti Ọlọ́run Bàbá;

20 Pé àwọn ara tí wọ́n jẹ́ ti ìjọba sẹ̀lẹ́stíà lè jogún rẹ̀ láé ati títí láèláé; nítorí, fún ìdí èyí ni a ṣe dá a atí tí a ṣe ẹ̀dá rẹ̀, àti fún ìdí èyí ni a ṣe yà wọ́n sí mímọ́.

21 Àti pé àwọn tí a kò yà sí mímọ́ nípasẹ̀ òfin náà èyítí èmi ti fi fún yín, àní òfin ti Krístì, gbọ́dọ̀ jogún ìjọba míràn, àní èyíinì tí íṣe ìjọba tẹ̀rẹ́stríà, tàbí èyíinì tí iṣe ìjọba tẹ̀lẹ́stíà.

22 Nítorí ẹnití kò bá lè ṣe ìgbọràn sí òfin ti ìjọba sẹ̀lẹ́stíà kì yíò lè fi ara da ògo sẹ̀lẹ́stíà.

23 Àti pé ẹni tí kò bá lè ṣe ìgbọràn sí òfin ti ìjọba tẹ̀rẹ́stríà kì yíò lè fi ara da ògo tẹ̀rẹ́stríà.

24 Àti ẹni náà tí kò lè ṣe ìgbọràn sí òfin ti ìjọba tẹ̀lẹ́stíà kì yíò lè fi ara da ògo tẹ̀lẹ́stíà; nítorínáà òun kò yẹ fún ìjọba ògo kan. Nítorínáà òun gbọ́dọ̀ fi ara da ìjọba kan èyítí kìí ṣe ìjọba ògo.

25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ilẹ̀ ayé ṣe ìgbọràn sí òfin ti ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, nítorí òun kún ojú òsùnwọ̀n ti ìṣẹ̀dá rẹ̀, kò sì ré òfin náà kọjá—

26 Nítorínáà, a ó yà á sí mímọ́; bẹ́ẹ̀ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun yíò kú, a ó sọ ọ́ di alààyè lẹ́ẹ̀kan síi, òun yíò sì fi ara da agbára náà nípasẹ̀ èyítí a sọ ọ́ di alààyè, olódodo ni yíò sì jogún rẹ̀.

27 Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kú, bákannáà wọn yíò tún jí dìde lẹ́ẹ̀kansíi, ara ti ẹ̀mí kan.

28 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí ti sẹ̀lẹ́stíà yíò gba ara kannáà èyítí ó jẹ́ ara àdánidá; àní ẹ̀yin yíò gba àwọn ara yín, ògo yín yíò sì jẹ́ ògo èyíinì nípasẹ̀ èyítí a sọ àwọn ara yín di alààyè.

29 Ẹ̀yin ẹnití a sọ di alààyè nípasẹ̀ apákan ògo ti sẹ̀lẹ́stíà yíò gba nígbànáà lára òun kannáà, àní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ rẹ̀.

30 Àti àwọn ẹni tí a sọ di alààyè nípasẹ̀ apákan ògo ti tẹ̀rẹ́stríà yíò gba nígbànáà lára òun kannáà, àní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ rẹ̀.

31 Àti bákannáà àwọn tí a sọ di alààyè nípasẹ̀ apákan ògo ti tẹ̀lẹ́stíà yíò gba nígbànáà lára òun kannáà, àní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ rẹ̀.

32 Àti àwọn ẹnití ó ṣẹ́kù ni a ò sọ di alààyè bákannáà; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọn yíò padà lẹ́ẹ̀kansíi sí ààyè tiwọn, láti jẹ ìgbádùn èyíinì tí wọ́n ní ìfẹ́ sí lati gbà, nitorítí wọn kò ní ìfẹ́ láti jẹ ìgbádùn èyíinì tí wọn lè ti rí gbà.

33 Nítorí èrè kínni ó jẹ́ fún ènìyàn bí a bá fi ẹ̀bùn kan fún un, tí òun kò sì gbà ẹ̀bùn náà? Kíyèsí, òun kò yọ̀ nínú ohun náà èyítí a fi fún un, tàbí kí ó yọ̀ nínú ẹni náà tí ó jẹ́ olùfúnni ní ẹ̀bùn náà.

34 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èyíinì tí a ṣe àkóso rẹ̀ nípa òfin ni a pamọ́ nípa òfin ó sì di pípé àti yíyà sí mímọ́ nípa ọ̀kannáà.

35 Èyí tí ó bá rú òfin kan, tí kò sì ṣe ìgbọràn nípa òfin, ṣùgbọ́n tí ó nwá ọ̀nà láti jẹ́ òfin fún ara rẹ̀, àti tí ó ní ìfẹ́ láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀, àti tí ó wà nínú ẹ̀ṣẹ pátápátá, kì yíò lè jẹ́ yíyàsímímọ́ nípa òfin, bóyá nípa àánú, òdodo, tàbí ìdájọ́. Nítorínáà, wọ́n gbọ́dọ̀ dúró nínú èérí síbẹ̀.

36 Gbogbo àwọn ìjọba ní òfin kan tí a fifún wọn;

37 Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọba ni ó sì wà; nítorí kò sí àlàfo kan nínú èyítí kò sí ìjọba; kò sì sí ìjọba kan inú èyítí kò sí àlàfo, bóyá títóbí tàbí kíkéré ìjọba.

38 Àti sí olukúlùkù ìjọba ni a fi òfin kan fún; àti sí olukúlùkù òfin ni àwọn ààlà tí ó dájú wà bákannáà àti àwọn ipò.

39 Gbogbo ẹ̀dá tí kò bá dúró nínú àwọn ipò wọnnì ni a kò dá láre.

40 Nítorí ẹ̀mí òye nfi ara mọ́ ẹ̀mí òye; ọgbọ́n ngba ọgbọ́n; òtítọ́ ngba òtítọ́ mọ́ra; ìwà ọ̀run ní ìfẹ́ ìwà ọrun; ìmọ́lẹ̀ nfi ara mọ́ ìmọ́lẹ̀; àánú ní ìyọ́nú ní orí àánú ó sì ngba àwọn tírẹ̀; òtítọ́ tẹ̀síwájú ní ọ̀nà rẹ̀ ó sì gba àwọn tírẹ̀; ìdájọ́ nlọ sí iwájú ẹni náà tí ó jókòó ní orí ìtẹ́ ó sì ndarí àti pé ó nṣe ohun gbogbo.

41 Òun mọ ohun gbogbo, ohun gbogbo sì wà ní iwájú rẹ̀, àti pé ohun gbogbo wà yíká rẹ̀; óun sì ga ju ohun gbogbo lọ, àti nínú ohun gbogbo, òun sì la ohun gbogbo já, àti pé ó wà yíká ohun gbogbo; ohun gbogbo sì wà nípasẹ̀ rẹ̀, àti lati ọ̀dọ̀ rẹ̀, àní Ọlọ́run, láé àti títí láéláé.

42 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, òun ti fi òfin kan fún ohun gbogbo, nípasẹ̀ èyítí wọ́n nrìn ní àwọn àkókò wọn àti àwọn ìgbà wọn;

43 Àti pé àwọn ipa ọ̀nà wọn jẹ́ èyí tí a ti pinnu, àní àwọn ipa ọ̀nà ti àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, èyítí ó mọ ayé àti gbogbo àwọn ohun tí nyipo òòrùn.

44 Wọ́n sì nfi ìmọ́lẹ́ fún ara wọn ni àwọn àkókò wọn àti ní àwọn ìgbà wọn, ní àwọn ìṣẹ́jú wọn, ní àwọn wákàtí wọn, ní àwọn ọjọ́ wọn, ní àwọn ọ̀sẹ̀ wọn, ní àwọn oṣù wọn, ní àwọn ọdún wọn—gbogbo ìwọ̀nyìí jẹ́ ọdún kan pẹ̀lú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì íṣe pẹ̀lú ẹ̀nìyàn.

45 Ìlẹ̀ ayé nyí ní orí apá rẹ̀, àti pé òòrùn náà nfúnni ní ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ní ojú ọjọ́, òṣùpá sì nfúnni ní ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ní òru, àti àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú nfúnni ní ìmọ́lẹ̀ wọn, bí wọ́n ṣe nyí ní orí apá wọn nínú ògo wọn, ní ààrin agbára Ọlọ́run.

46 Kínni èmi yíò fi àwọn ìjọba wọ̀nyìí wé, kí ó lè yée yín?

47 Kíyèsíi, gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìjọba, àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ti rí èyíkéyìí tàbí èyí tí ó kéré jù nínú nkan wọ̀nyìí ti rí Ọlọ́run bí ó ṣe nrìn nínú ọlá-nlá àti agbára rẹ̀.

48 Èmi wí fún yín, òun ti rí i; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹni náà tí ó tọ àwọn tirẹ̀ wá kò di mímọ̀.

49 Ìmọ́lẹ̀ náà tàn nínú òkùnkùn, òkùnkùn náà kò sì mọ̀ ọ́, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọjọ́ náà yíò dé nígbàtí ẹ̀yin yíò mọ̀ àní Ọlọ́run, ní sísọ yín di alààyè nínú rẹ̀ àti nípasẹ̀ rẹ̀.

50 Nígbànáà ni ẹ̀yin yíò mọ̀ pé ẹ̀yin tí rí mi, pé èmi ni, àti pé èmi ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà tí ó wà nínú yín, àti pé ẹ̀yin wà nínú mi; bíbẹ́ẹ̀kọ́ ẹ̀yin kò lè ṣe rere.

51 Kíyèsíi, èmi yíò fi àwọn ìjọba wọ̀nyìí wé ọkùnrin kan tí ó ní oko kan, òun sì rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí inú oko náà láti wa ilẹ̀ nínú oko náà.

52 Ó sì wí fún èkínní: Ìwọ lọ kí o sì ṣiṣẹ́ nínú oko náà, àti pé ní wákàtí àkọ́kọ́ èmi yíò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ yíò sì kíyèsí ayọ̀ ìwò ojú mi.

53 Òun sì wí fún èkejì: Ìwọ lọ́ bákannáà sí inú oko, àti pé ni wákàtí kejì èmi yíò bẹ̀ ọ́ wò pẹ̀lú ayọ̀ ti ìwò ojú mi.

54 Àti bákannáà sí ẹ̀kẹta, ní wíwí pé: Èmi yíò bẹ̀ ọ́ wò;

55 Àti sí ẹ̀kẹrin náà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí èkejìlá.

56 Olúwa ti oko náà sì lọ sí ọ̀dọ̀ èkínní ní wákàtí àkọ́kọ́, ó sì dúró pẹ̀lú rẹ̀ ní gbogbo wákàtí náà, a sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ìwò ojú olúwa rẹ̀.

57 Àti nígbànáà ó kúrò ní ọ̀dọ̀ èkínní kí òun ó lè ṣe àbẹ̀wò sí èkejì pẹ̀lú, àti ẹ̀kẹta, àti ẹ̀kẹrin, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí èkejìlá.

58 Àti báyìí ni gbogbo wọn gba ìmọ́lẹ̀ ti ìwò ojú olúwa wọn, olúkúlùkù ènìyàn ní wákàtí tírẹ̀, àti ní àkókò tirẹ̀, àti ní ìgbà tirẹ̀—

59 Bẹ̀rẹ̀ láti èkínní, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí èyí tí ó kẹ́hìn, àti láti èyí tí ó kẹ́hìn sí èkínní, àti láti èkínní sí èyi tí ó kẹ́hìn;

60 Olúkúlùkù èniyàn nínú ètò tirẹ̀, títí tí wákàtí rẹ̀ fi parí, àní gẹ́gẹ́bí olúwa rẹ̀ ṣe pàṣẹ fún un, pé kí á lè yin olúwa rẹ̀ logo nínú rẹ̀, àti òun nínú olúwa rẹ̀, pé kí gbogbo wọn le di ẹni ìṣelógo.

61 Nítorínáà, sí òwe yìí ni èmi yíò fi gbogbo àwọn ìjọba wọ̀nyìí wé, àti àwọn olùgbé inú wọn—olúkúlùkù ìjọba ní wákàtí rẹ̀, àti ní àkókò rẹ̀, àti ní ìgbà rẹ̀, àní ní ìbámu sí àṣẹ èyítí Ọlọ́run ti ṣe.

62 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, èmi fi àwọn ọ̀rọ̀ sísọ wọ̀nyìí sílẹ̀ pẹ̀lú yín láti ṣe àṣarò nínú ọkàn yín, pẹ̀lú àṣẹ yìí èyítí èmi fi fún yín, pé ẹ̀yin yíò ké pèmí nígbàtí èmi wà nítòsí—

63 Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi èmi yíò sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ yín; ẹ wá mi lójú méjèèjì ẹ̀yin yíò sì rí mi; ẹ béèrè, ẹ̀yin yíò sì rí gbà; ẹ kàn ìlẹ̀kùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.

64 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ́ mi a ó fi fún yín, èyí jẹ́ yíyẹ fún yín;

65 Bí ẹ̀yin bá sì beerè ohunkóhun tí kò yẹ fún yín, òun yíò yípadà sí ìdálẹ́bi fún yín.

66 Kíyèsíi, èyíinì tí ẹ̀yin gbọ́ jẹ́ bí ohùn ẹ̀nikan tí nkígbe ní ijù—ní ijù, nítorítí ẹ̀yin kò lè rí i—ohùn mi, nítorípé ohùn mi jẹ́ Ẹ̀mí, Ẹ̀mí mi jẹ́ òtítọ́; òtítọ́ dúró kò sì ní òpin; bí ó bá sì wà nínú yín òun yíò pọ̀ síi.

67 Àti pé bí àfojúsùn yín bá jẹ́ sí ògo mi nikan, gbogbo ara yín ni yío kún fún ìmọ́lẹ̀, kì yíò sì sí òkùnkùn nínú yín; àti pé ara náà tí ó kún fún ìmọ́lẹ̀ ní ìmọ ohun gbogbo.

68 Nítorínáà, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ọkan yín ó lè di ti Ọlọ́run nìkan, àti pé ọjọ́ náà yíò dé tí ẹ̀yin yíò rí i; nítorí òun yíò ṣí ìbòjú rẹ̀ síi yín, yíò sì jẹ́ ní àkókò tirẹ̀, àti ní ọ̀nà tirẹ̀, àti gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ tirẹ̀.

69 Ẹ rántí ìlérí nlá àti ti ìkẹhìn èyítí mo ti ṣe fún yín; ẹ ju àwọn èrò àìwúlò àti ẹ̀rín àrínjù jìnà sí yín.

70 Ẹ dúró pẹ́, ẹ dúró pẹ́ ní ìhín yìí, kí ẹ sì pe àpéjọ ọ̀wọ̀ kan, àní ti àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ ní ìjọba ìkẹhìn yìí.

71 Ẹ sì jẹ́kí àwọn ẹnití wọ́n ti kìlọ̀ fún ní ìrìnàjò wọn ó ké pe Olúwa, kí wọ́n ó sì ṣe àṣàrò ìkìlọ̀ náà nínú ọkàn wọn èyítí wọ́n ti gbà, fún ìgbà díẹ̀.

72 Ẹ kíyèsíi, ẹ sì wòó, èmi yíò ṣe ìtọ́jú àwọn agbo yín, èmi ó sì gbé àwọn alàgbà dìde láti rán sí wọn.

73 Kíyèsí, èmi yíò mú kí iṣẹ́ mi yá kánkán ní àkókò rẹ̀.

74 Èmi fi fún yín, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ nínú ìjọ̀ba tí ìkẹ́hìn yìí, òfin kan pé kí ẹ kó ara yín jọ papọ̀, kí ẹ sì ṣètò ara yín, kí ẹ sì gbaradì, àti pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́; bẹ́ẹ̀ni, ẹ sọ ọkàn yín di mímọ́, kí ẹ sì wẹ ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín mọ́ níwájú mi, kí èmi ó lè mú kí ẹ mọ́;

75 Kí èmi ó lè jẹ́rìí sí Bàbá yín, àti Ọlọ́run yín, àti Ọlọ́run mi, pé ẹ̀yin mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ìran búburú yìí; kí èmi ó lè mú ìlérí yìí ṣẹ, ìlérí nlá àti ti ìkẹ́hìn yìí, èyítí èmi ti ṣe fún yín, nígbàtí èmi fẹ́.

76 Bákannáà, èmi fi òfin kan fún yín pé kí ẹ̀yin ó tẹ̀síwájú ní gbígba àdúrà àti ààwẹ̀ láti àkókò yìí lọ.

77 Èmi sì fi òfin kan fún yín pé ẹ̀yin yíó máa kọ́ ara yín ní ẹ̀kọ́ ti ìjọba náà.

78 Ẹ kọ́ni láìsinmi, ore ọ̀fẹ́ mi yíò sì wà pẹ̀lú yín, kí á lè kọ́ yín ní pipe síi nínú àlàyé imọ̀, nínú ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, nínú ẹ̀kọ́, nínú òfin ti ìhìnrere, nínú ohun gbogbo tí ó ní ṣe sí ìjọba Ọlọ́run, tí ó yẹ fún yín láti mọ̀;

79 Nípa àwọn nkan ní ọ̀run àti ní ayé, àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀; àwọn ohun tí ó ti wà rí, àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ láìpẹ́; àwọn ohun tí ó wà nílé, àwọn ohun tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèrè; àwọn ogun náà àti ìpayà ti àwọn orílẹ̀-èdè, àti ìdájọ́ èyítí ó wà ní orí ilẹ̀ náà; àti ìmọ̀ kan pẹ̀lú ti àwọn orílẹ̀-èdè àti ti àwọn ìjọba—

80 Kí ẹ̀yin ó lè gbaradì nínú ohun gbogbo nígbàtí èmi yíò tún rán yín lẹ́ẹ̀kansíi láti gbé ìpè èyítí mo ti pè yín sí ga, àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú èyítí mo ti fi àṣẹ fún yín.

81 Kíyèsíi, èmi rán yín jade láti jẹ́rìí àti láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, ó sì di yíyẹ fún olúkúlùkù èniyàn tí a ti kìlọ̀ fún láti kìlọ̀ fún aládugbò rẹ̀.

82 Nítorínáà, wọn ó wà lainí àwáwí kankan, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wà ní orí àwọn tìkara wọn.

83 Ẹni tí ó bá wá mi ní kùtùkùtù yíò rí mi, a kì yíò sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

84 Nítorínáà, ẹ dúró pẹ́, kí ẹ sì ṣíṣẹ́ pẹ̀lú aápọn, kí á lè sọ yín di pípé nínú isẹ́ ìránṣẹ́ yín láti jáde lọ láàrin àwọn Kèfèrí fún ìgbà ìkẹ́hìn, bí ọ̀pọ̀ iye tí ẹnu Olúwa yíò dárúkọ, láti de òfin náà àti láti fi èdídí di ẹ̀rí, àti láti pèsè àwọn ẹni mímọ́ sílẹ̀ fún wákàtí ìdájọ́ èyítí yíò wá;

85 Pé kí ẹ̀mí wọn ó lè bọ́ lọ́wọ́ ìbínú Ọlọ́run, ìsọ̀dahoro ti ìríra tí ó ndúró de àwọn ènìyan búburú, ní ayé yìí àti ní ayé tí ó nbọ̀. Lõtọ́, ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí àwọn tí wọn kìí ṣe alàgbà àkọ́kọ́ tẹ̀síwájú nínú ọgbà àjàrà títí tí ẹnu Olúwa yíò fi pè wọ́n, nítorí àkókò wọn kò tíì dé; aṣọ wọn kò tíì mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ìran yìí.

86 Ẹ dúró nínú òmìnira náà nípa èyítí a sọ yín di òminira; ẹ máṣe fi ara yín sínú àjàgà ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọwọ́ yín ó mọ́, títí tí Olúwa yíò fi dé.

87 Nítorí kìí ṣe ọjọ́ púpọ̀ sí ìsisìyí ayé yíò sì wárìrì yíò sì ta gbọ̃ngbọ̃n síhĩn àti sọ́hũn bíi ọ̀mùtí ènìyàn; oòrun yíò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́, yíò sì kọ̀ láti mú ìmọ́lẹ̀ wá; àti pé òṣùpá yíò dàbí ẹ̀jẹ̀; àwọn ìràwọ̀ yíò sì bínú rékọjá; wọn yíò sì ju ara wọn lulẹ̀ bí ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ṣubú kúrò lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

88 Àti pé lẹ́hìn ẹ̀rí yín ni ìbínú àti ìrunú yíò dé sí orí àwọn ènìyàn.

89 Nítorí lẹ́hìn ẹ̀rí yín ni ẹ̀rí ti àwọn ilẹ̀ ríri yíò wá, èyí tí yíò mú ìkérora pọ̀ ní agbede méjì rẹ̀, àwọn ènìyàn yíò sì ṣubú lulẹ̀ wọn kì yíò sì le dìde dúró.

90 Àti bákannáà ẹ̀rí ti ohùn àwọn ààrá yíò wá, àti ohùn ti àwọn mọ̀nàmọ́ná, àti ohùn ti àwọn ẹ̀fúùfù líle, àti ohùn ti àwọn ìgbì omi òkun tí wọn yíò máa gbé ara wọn sókè rékọjá àlà wọn.

91 Ohun gbogbo yíò sì wà ní ìrúkèrúdò; àti dájúdájú, àyà àwọn ènìyàn yíò já wọn kulẹ̀; nítorí ìbẹ̀rù yíò wá sí orí gbogbo ènìyàn.

92 Àwọn ángẹ́lì yíò sì fò kọjá ní agbede méjì ọ̀run, ní pípariwo pẹ̀lú ohùn rara, ní fífọn fèrè Ọlọ́run, wípé: Ẹ múrasílẹ̀, ẹ múrasílẹ̀, Áà ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ ayé; nítorí ìdájọ́ Ọlọ́run wa ti dé. Ẹ kíyèsíi, ẹ sì wòó, Ọkọ́ Iyàwó náà dé; ẹ jade lọ láti pàdé rẹ̀.

93 Àti pé lọ́gán àmi nlá kan yíò farahàn ní ọ̀run, gbogbo ènìyàn ni wọn yíò sì rí i lápapọ̀.

94 Ángẹ́lì míràn yíò sì fọn fèrè rẹ̀, wípé: Ìjọ nla nnì, tí ṣe ìyá àwọn ìríra, tí ó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ó mu nínú ọtí wáìnì ìrunú ti àgbéèrè rẹ̀, tí ó ṣe inúnibíni àwọn ẹni mímọ́ Ọlọ́run, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀—òun ẹnití ó jókòó ní orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn omi, àti ní orí àwọn erékùsù òkun—ẹ kíyèsíi, òun ni èpò ti ilẹ̀ ayé; a dì í jọ ní àwọn ìtí; àwọn ìdè rẹ̀ ni a mú ní agbára, ẹnikẹ́ni kì yíò le tú wọn sílẹ̀; nítorínáà, òun ti múra tán láti di jíjóná. Òun yíò sì fọn fèrè rẹ̀ pẹ́ àti ní ohùn rara, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yíò sì gbọ́ ọ.

95 Ìdákẹ́-rọ́rọ́ yíò sì wà ní ọ̀run fún àlàfo àbọ̀ wákàtí kan, àti pé lọ́gán lẹ́hìn náà ni a ó tú àṣọ títa ọrun sílẹ̀, bí a ṣe ntú ìwé kíká lẹ́hìntí a ti káa wọnú ara rẹ̀, ojú Olúwa ni yíó sì jẹ́ àìbò;

96 Àti pé àwọn ẹni mímọ́ tí wọn wà ní ori ilẹ̀ ayé, tí wọ́n wà ní ààyè, ni a ó sọ di alààyè tí a ó sì gbà wọ́n sókè láti pàdé rẹ̀.

97 Àti àwọn tí wọ́n ti sùn nínú ibojì wọn yíò jade wá, nítorí a ó ṣí àwọn ibojì wọn; àti pé àwọn pẹ̀lú ni a ó gbà sókè láti pàdé rẹ̀ ní agbedeméjì ọ̀wọ̀n ti ọ̀run—

98 Wọ́n jẹ́ ti Krístì, àwọn èso àkọ́kọ́, àwọn ẹnití yíò kọ́kọ́ sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú rẹ̀, àti àwọn ẹnití wọ́n wà ní orí ilẹ̀ ayé àti nínú àwọn ibojì wọn, ẹnití a kọ́kọ́ gbà sókè láti pàdé rẹ̀; àti gbogbo èyí nípa ohùn ti dídún fèrè ángẹ́lì Ọlọ́run.

99 Àti lẹ́hìn èyí ángẹ́lì míràn yíò fọn, èyítí í ṣe ìpè èkejì; àti nigbànáà ni ìràpadà àwọn tí wọ́n jẹ́ ti Krístì ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ yíò dé, àwọn ẹnití wọ́n ti gba ipa tiwọn nínú túbú nnì èyítí a ti pèsè fún wọn, pé kí wọ́n ó lè gba ìhìnrere, kí a sì ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́bí ti àwọn ènìyàn nínú ẹran ara.

100 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ìpè míràn yíò dún, èyítí ṣe ìpè ẹ̀kẹta; àti nígbànáà ni ẹ̀mí àwọn ènìyàn tí a ó dá lẹ́jọ́ yíò wá, tí a sì rí lábẹ́ ìdálẹ́bi;

101 Ìwọnyí sì ni àwọn tí ó kù nínú àwọn òkú; wọn kì yíò sì tún wà láàyè mọ́ títí tí ẹgbẹ̀rún ọdún yíò fi parí, tàbí lẹ́ẹ̀kansíi, títí di òpin ilẹ̀ ayé.

102 Ìpè míràn yíò sì dún, èyítí í ṣe ìpè ẹ̀kẹrin, wípé: Níbẹ̀ ni a rí lára àwọn wọnnì tí wọn yío dúró títí di ọjọ́ nlá àti ìkẹ́hìn nnì, àní òpin náà, ẹnití yíò tún wà nínú èérí síbẹ̀.

103 Ìpè míràn yíò sì dún, èyítí í ṣe ìpè karũn, èyítí í ṣe ángẹ́lì ìkarũn ẹnití ó fi ìhìnrere àìlópin—tí nfò la agbedeméjì ọ̀run já, fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn;

104 Èyí ni yíò sì jẹ́ ìró fèrè rẹ̀, ní wíwí fún gbogbo ènìyàn, ní ọ̀run àti ní ayé, àti tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀—nítorí olúkúlùkù etí ni yíò gbọ́ ọ, àti olúkúlùkù eékún ni yíò wólẹ̀, àti olúkúlùkù ahọ́n ni yíò jẹ́wọ́, nígbàtí wọ́n bá gbọ ìró fèrè náà, wípé: Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un ẹnití ó jókòó ní orí ìtẹ́ náà, láéláé àti títí láé; nítorí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ ti dé.

105 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ángẹ́lì míràn yíò fọn ìpè rẹ̀, èyítí í ṣe ángẹ́lì kẹfà, wípé: Ó ti ṣubú ẹnití ó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ó mu nínú ọtí wáìnì ìrunú ti àgbéèrè rẹ̀; ó ti ṣubú, ó ṣubú!

106 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ángẹ́lì míràn yíò fọn ìpè rẹ̀, èyítí í ṣe ángẹ́lì keje, wípé: Ó parí; ó parí! Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ọlọ́run ti bòrí, òun sì ti nìkan tẹ ohun èlò ìfúntí wáìnì, àní ìfúntí wáìnì ti gbígbóná ìbínú Ọlọ́run Alágbára Jùlọ.

107 Àti pé nígbànáà ni a ó dé àwọn ángẹ́lì ní adé pẹ̀lú ògo agbára rẹ̀, àwọn èniyàn mímọ́ yíò sì kún fún ògo rẹ̀, wọn yíò sì gba ogún wọn a ó sì mú wọ́n dọ́gba pẹ̀lú rẹ̀.

108 Àti nígbànáà ni ángẹ́lì àkọ́kọ́ yíò tún fọn ìpè rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi sí etí gbogbo alààyè, yíò sì fi ìṣe ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn hàn, àti àwọn iṣẹ́ agbára nlá Ọlọ́run ní ẹ̀gbẹ̀rún ọdún àkọ́kọ́.

109 Àti nígbànáà ni ángẹ́lì kejì náà yíò fọn ìpè rẹ̀; yíò sì fi àwọn ìṣe ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn hàn, àti èrò àti ète ọkàn wọn, àti àwọn iṣẹ́ agbára nlá Ọlọ́run ní ẹgbẹ̀rún ọdún èkejì—

110 Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, títí tí ángẹ́lì keje náà yíò fi fọn ìpè rẹ̀; òun yíò sì dúró ní orí ilẹ̀ ati ní orí òkun, yíò búra ní orúkọ ẹni náà tí ó jókòó ni orí ìtẹ́, pé kì yíò sí àkókò mọ́; a ó sì gbé Sátánì dè, ejò ìgbà àtijọ́ nnì, ẹnití a pè ní èṣù, a kì yíò sì tú u sílẹ̀ ni àlàfo ẹgbẹ̀rún kan ọdún.

111 Àti nígbànáà ni a ó tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, kí òun lè kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ papọ̀.

112 Àti Míkáẹ́lì, ángẹ́lì keje, àní olórí ángẹ́lì náà, yíò kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ papọ̀, àní àwọn ogun ọ̀run.

113 Èṣù yíò sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ papọ̀; àní àwọn ogun ọrun àpáàdì, wọn yíò sì wá láti dojú ogun kọ Míkáẹlì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

114 Àti nígbànáà ni ogun ti Ọlọ́run títóbi yíò dé; a ó sì ju èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọnù sí ààyè wọn, pé kí wọn ó má lè ní agbára ní orí àwọn èniyàn mímọ́ mọ́ rárá.

115 Nítorí Míkáẹlì yíò ja àwọn ogun wọn, yíò sì borí ẹni náà tí ó nwá ìtẹ́ ti ẹnití ó jóko ní orí ìtẹ́, àní Ọ̀dọ́-Àgùtàn náà.

116 Èyí ni ògo Ọlọ́run, àti yíyà sí mímọ́; wọn kì yíò sì rí ikú mọ́ rárá.

117 Nítorínáà, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ pè àpèjọ ọ̀wọ̀ yín, bí èmi ṣe pàṣẹ fún yín.

118 Àti pé bí gbogbo ènìyàn kò ṣe ní ìgbàgbọ́, ẹ wá kiri pẹ̀lú aápọn kí ẹ sì kọ́ ara yín ní àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n; bẹ́ẹ̀ni, ẹ wá àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n nínú àwọn ìwé tí ó dára jùlọ; ẹ wá ẹ̀kọ́ kíkọ́, àní nípa ṣíṣe àṣàrò àti bákannáà nípa ìgbàgbọ́.

119 Ẹ ṣe ètò ara yín; ẹ pèsè olúkúlúkù ohun tí ẹ nílò; kí ẹ sì gbé ilé kan kalẹ̀, àní ìlé àdúrà, ilé ààwẹ̀ gbígbà, ilé ìgbàgbọ́, ilé ẹ̀kọ́ kíkọ́, ilé ògo, ilé elétò, ilé Ọlọ́run;

120 Kí àwọn ìwọlé yín ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa; kí àwọn ìjádelọ yín ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa; kí àwọn ìkíni yín ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa, pẹ̀lú ìgbọ́wọ́ sókè sí Ọ̀gá Ogo Jùlọ.

121 Nítorínáà, ẹ jáwọ́ kúrò nínú gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀fẹ̀ yín, kúrò nínú gbogbo ẹ̀rín, kúrò nínú gbogbo àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yín, kúrò nínú gbogbo ìgbéraga àti àìlèronújinlẹ̀ yín, àti kúrò nínú àwọn ìṣe búburú yín gbogbo.

122 Ẹ yan olùkọ́ kan láàrin ara yín, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí gbogbo ènìyàn jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ lẹ́ẹ̀kan náà; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ẹnìkan ó sọ̀rọ̀ ní ìgbà kan ẹ sì jẹ́kí gbogbo ènìyàn ó tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, pé nígbàtí gbogbo ènìyàn bá ti sọ̀rọ̀ kí gbogbo ènìyàn ó lè dàgbàsókè láti ọwọ́ gbogbo ènìyàn, àti kí olúkúlùkù ènìyàn ó lè ní ànfàní ní ọgbọ̃gba.

123 Ẹ ríi pé ẹ fẹ́ràn ara yín; ẹ jáwọ́ nínú ṣíṣe ojú kòkòrò; ẹ kọ́ láti máa fi fún ara yín bí ìhìnrere ṣe béèrè.

124 Ẹ jáwọ́ nínú jíjẹ́ aláìníṣẹ́; ẹ jáwọ́ nínú jíjẹ́ àìmọ́; ẹ jáwọ́ nínú wíwá àṣìṣe ara yín; ẹ jáwọ́ nínú sísùn oorun jù bí ó ti yẹ lọ; ẹ tètè sìnmi sí ibùsùn yín, kí àárẹ̀ má baà mú yín; ẹ tètè jí, kí ara yín àti ọkàn yín ó lè ní agbára lákọ̀tun.

125 Àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ wọ ara yín ní aṣọ pẹ̀lú ìdè ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, bíi ẹ̀wù ìlékè, èyítí í ṣe ìdè jíjẹ́ pípé àti àlàfíà.

126 Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má baà ṣàárẹ̀, títí tí èmi yíò fi dé. Kíyèsíi, sì wòó, èmi nbọ̀ kánkán, èmi ó sì gbà yín sí ọ̀dọ̀ ara mi. Àmín.

127 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ètò ilé náà tí a pèsè fún àjọ ààrẹ ti ilé ẹ̀kọ́ àwọn wòlíì, tí a gbékalẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn nínú ohun gbogbo tí ó tọ́ fún wọn, àní fún gbogbo àwọn tí wọ́n di ipò mú nínú ìjọ, tàbi ní ọ̀nà míràn, àwọn wọnnì tí a pè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ìjọ, bẹ̀rẹ̀ láti àwọn àlùfáà gíga, àní dé ìsàlẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn díákónì—

128 Èyí ni yíò sì jẹ́ ètò ti ilé àjọ ààrẹ ilé ẹ̀kọ́ náà: Ẹni náà tí a bá yàn sí ipò ààrẹ, tàbí olùkọ́, ni a níláti rí ní ìdúró ní ipò rẹ̀, nínú ilé èyíti a ó pèsè fún un.

129 Nítorínáà, òun yíò jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ilé Ọlọ́run, ní ibi kan tí gbogbo ìjọ nínú ilé yíò ti lè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáradára àti ní ketekete, kìí ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ariwo.

130 Nígbàtí òun bá sì wá sí inú ilé Ọlọ́run, nítorí òun nílati jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ilé náà—kíyèsíi, èyí jẹ́ ohun tí ó rẹwà, kí òun ó lè jẹ́ àpẹrẹ—

131 Ẹ jẹ́ kí òun fi ara rẹ̀ sílẹ̀ nínú àdúrà ní orí eékún rẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ní àmì tàbí ìrántí ti májẹ̀mú àìlópin náà.

132 Àti nígbàtí ẹnikẹ́ni bá wọlé wa lẹ́hìn rẹ̀, ẹ jẹ́kí olùkọ́ náà dìde, àti, pẹ̀lú ìgbọ́wọ́ sókè sí ọ̀run, bẹ́ẹ̀ni, àní ní tààrà, kí òun kí arákùnrin tàbí àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí:

133 Njẹ́ arákùnrin kan tàbí arákùnrin púpọ̀ ni ẹ̀yin í ṣe? Mo kíi yín ní orúkọ Olúwa Jésù Krístì, ní àmì tàbí ìrántí májẹ̀mú àìlópin náà, nínú májẹ̀mú èyítí èmi gbà yín sí ìdàpọ̀, nínú ìpinnu tí a mú dúró, àìleyẹ̀, àti àìlèyípadà, láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àti arákùnrin yín nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú ìdìpọ̀ ti ìfẹ́, lati rìn nínú gbogbo àwọn òfin Ọlọ́run láìlẹ́bi, nínú ìdúpẹ́, láé àti láéláé. Àmín.

134 Àti ẹni náà tí a bá rí ní àìyẹ fún ìkíni yìí kì yíò ní ààyè láàrín yín; nítorí ẹ̀yin kì yíò jẹ́ kí ile mi ó dí àìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.

135 Àti ẹnití ó bá wọlé wá tí ó sì jẹ́ olõtọ́ níwájú mi, àti tí ó jẹ́ arákùnrin, tàbí bí wọ́n bá jẹ́ àwọn arákùnrin, yíò kí ààrẹ tàbí olùkọ́ pẹ̀lú gbígbé ọwọ́ sókè sí ọ̀run, pẹ̀lú àdúrà àti májẹ̀mú yìí kannáà, tàbí nípa wíwí pé Àmín, ní àmì ti ọ̀kannáà.

136 Kíyèsíi, lõtọ́, mo wí fún yín, èyí ni àpẹrẹ sí yín fún ìkíni sí ara yín nínú ilé Ọlọ́run, ní ile ẹ̀kọ́ àwọn Wòlíì.

137 Àti pé a pè yín láti ṣe èyí nípa àdúrà àti ìdúpẹ́, bí Ẹ̀mí náà yío ṣe fún yín ní ọ̀rọ̀ sísọ nínú gbogbo ìṣe yín nínú ilé Olúwa, ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn Wòlíì, kí ó lè di ibi mímọ́, àgọ́ kan ti Ẹ̀mí Mímọ́ sí ìdàgbàsókè yín.

138 Ẹ̀yin kì yíò sì gba ẹnikẹ́ni láàrin yín sí ilé ẹ̀kọ́ yìí bíkòṣe pé òun jẹ́ mímọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ti ìran yìí;

139 Àti pé ẹni náà ni a ó gbà nípa ìlànà ti ẹsẹ̀ wíwẹ̀, nítorí sí èyí ni a fi ìlànà ti ẹsẹ̀ wíwẹ̀ lélẹ̀.

140 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ìlànà ti ẹsẹ̀ wíwẹ̀ ni a nílati ṣe àkóso rẹ̀ nípasẹ̀ ààrẹ, tàbí alàgbà tí ó ndarí nínú ìjọ.

141 Ó níláti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà; àti lẹ́hìn tí a bá ti ṣe àbápín nínú àkàrà àti wáìnì, òun nílati di ara rẹ̀ ní àmùrè gẹ́gẹ́bí àwòṣe tí a fún ni ní ìpín kẹtàlá ẹ̀rí Jòhánnù nípa mi. Àmín.