Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 37


Ìpín 37

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ní ẹ̀bá Fayette, New York, Oṣù Kejìlá 1830. Nínú-èyí ni a fi òfin àkọ́kọ́ fúnni nípa àkójọpọ̀ kan fún ìgbà ìríjú yìí.

1–4, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a pè láti kóra jọ pọ̀ ní Ohio.

1 Ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín pé kò jẹ́ títọ́ nínú mi pé kí ẹ̀yin ó tún máa túmọ̀ síi títí tí ẹ̀yin yíò fi lọ sí Ohio, àti èyí nítorí àwọn ọ̀tá àti fún ti ara yín.

2 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín pé ẹ̀yin kì yíò lọ títí tí ẹ̀yin yíò fi wàásù ìhìnrere mi ní àwọn apá wọnnì, àti tí ẹ̀yin yío fi fún ìjọ ní okun ní ibikíbi tí a bá tí rí i, àti ní pàtàkì jùlọ ní Colesville; nítorí, kíyèsíi, wọ́n ngbàdúrà sí mi nínú ìgbàgbọ́ púpọ̀.

3 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, òfin kan ni mo fi fun ìjọ, pé ó ṣe ànfààní nínú mi pé kí wọn ó kó ara wọn jọ papọ̀ ní Ohio, ní ìpalẹ̀mọ́ fún àkókò náà tí ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery yíò padà bọ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn.

4 Kíyèsíi, ọgbọ́n nìyí, ẹ jẹ́ kí ẹni kọ̀ọ̀kan ó yàn fún ara rẹ̀ títí tí èmi yíò fi dé. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.