Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 31


Ìpín 31

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Thomas B. Marsh, Oṣù Kẹsãn 1830. Ìgbà yìí jẹ́ kété lẹ́hìn ìpàdé àpéjọpọ̀ kan ti ìjọ (wo àkọlé ìpín 30). A ti ri Thomas B. Marsh bọmi saájú nínú oṣù náà a sì ti yàn án gẹ́gẹ́bí alàgbà nínú Ìjọ kí á tó fi ìfihàn yìí fúnni.

1–6, Thomas B. Marsh ni a pè láti wàásù ìhìnrere a sì mú àlãfíà àwọn ẹbí rẹ̀ dá a lójù; 7–13, A gbà á nímọ̀ràn láti ṣe sùúrù, láti máa gbàdúrà nígbà gbogbo, àti lati máa tẹ̀lé Olùtùnú náà.

1 Thomas, ọmọ mi, ìbùkún ni fún ọ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú iṣẹ́ mi.

2 Kíyèsíi, ìwọ ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú nítorí ẹbí rẹ; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi yíò bùkún fún ìwọ àti ẹbí rẹ, bẹ́ẹ̀ni, àwọn ọmọdé rẹ; àti pé ọjọ́ náà dé tán tí wọn yíò gbàgbọ́ tí wọn yíò sì mọ òtítọ́ àti tí wọn yíò jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú rẹ nínú ìjọ mi.

3 Gbé ọkàn rẹ sókè kí o sì yọ̀, nítorí wákàtí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ti dé; a ó sì tú ahọ́n rẹ, àti pé ìwọ yíò kéde àwọn ìróyìn ayọ̀ nlá sí ìran yìí.

4 Ìwọ yíò kéde àwọn ohun tí a ti fi hàn fún ìránṣẹ́ mi, Joseph Smith Kékeré. Ìwọ yíò bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti àkókò yìí lọ, bẹ́ẹ̀ni, láti kórè nínú oko náà èyí tí ó ti funfun tán lati fi jóná.

5 Nítorínáà, fi dòjé rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti pé a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, ìwọ yíò sì kó àwọn ìtí sí ẹ̀hìn rẹ, nítorí alágbàṣe yẹ fún owó iṣẹ́ rẹ̀. Nítorínáà, àwọn ẹbí rẹ yíò yè.

6 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn fún àkókò díẹ̀, kí o sì kéde ọ̀rọ̀ mi, èmi yíò sì pèsè ààyè kan fún wọn.

7 Bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò ṣí ọkàn àwọn ènìyàn, wọn yíò sì gbà ọ́. Èmi yíò sì gbé ìjọ kan kalẹ̀ láti ọwọ́ rẹ;

8 Àti pé ìwọ yíò fún wọn ní okun ìwọ yíò sì mú wọn wà ní ìmúrasílẹ̀ de àkókò náà tí a ó kó wọn jọ.

9 Ṣe sùúrù nínú àwọn ìpọ́njú, má ṣe kẹ́gàn àwọn wọnnì tí wọn nkẹ́gàn. Ṣe àkóso ilé rẹ pẹ̀lú ọkàn tútù kí o sì dúró ṣinṣin.

10 Kíyèsíi, mo wí fún ọ pé ìwọ yíò jẹ́ oníṣègùn fún ìjọ, ṣùgbọ́n kìí ṣe fún gbogbo ayé, nítorí wọn kì yíò gbà ọ́.

11 Máa lọ ní ọ̀nà rẹ sí ibikíbi tí èmi bá fẹ́, a ó sì fi fún ọ láti ọwọ́ Olùtùnú ohun tí ìwọ yíò ṣe àti ibi tí ìwọ yíò lọ.

12 Máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, bí bẹ́ẹ̀kọ́ ìwọ yíò bọ́ sínú ìdánwò ìwọ yíó sì pàdánù ère rẹ.

13 Jẹ́ olõtọ́ títí dé òpin, sì wòó, èmi wà pẹ̀lú rẹ. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ti ènìyan tàbí ti àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ti èmi, àní Jésù Krístì, Olùràpadà rẹ, nípa ìfẹ́ ti Bàbá. Amin.