Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 15


Ìpín 15

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí John Whitmer, ní Fayette, New York, Oṣù Kẹfà 1829. (wo àkọlé sí ìpín 14). Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ohun tí ó kanni gbọ̀ngbọ̀n ati àtẹ̀mọ́ ti ara ẹni nítorí pé Olúwa sọ ohun tí ó jẹ́ mímọ̀ sí John Whitmer nìkan àti Òun Fúnra Rẹ̀. John Whitmer di ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlérìí Mẹ́jọ sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì lẹ́hìn náà.

1–2, Apá Olúwa wà kárí gbogbo ilẹ̀ ayé; 3–6, Láti wàásù ìhìnrere àti láti gba àwọn ọkàn là ni ohun tí ó níye ní orí jùlọ.

1 Fetísílẹ̀, ìranṣẹ́ mi John, kí o sì tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ Jésu Krísti, Olúwa rẹ àti Olùràpadà rẹ.

2 Nítorí kíyèsíi, èmi sọ̀rọ̀ sí ọ pẹ̀lú ohùn mímú àti pẹ̀lú agbára, nítorí apá mi wà ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé.

3 Àti pé èmi yíò sọ àwọn ohun kan fún ọ èyítí èniyàn kankan kò mọ̀ bíkòṣe èmi àti ìwọ nìkan—

4 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìwọ ti fẹ́ mọ̀ lati ọ̀dọ̀ mi èyíinì tí yíó ní iye ní orí jùlọ sí ọ.

5 Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ọ nítorí ohun yí, àti fún sísọ àwọn ọ̀rọ̀ mi èyí tí mo fi fún ọ gẹ́gẹ́bí àwọn òfin mi.

6 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé ohun kan tí yíó níye ní orí jùlọ fún ọ ni lati kéde ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn yìí, kí ìwọ baà lè mú àwọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ìwọ ó lè sínmi pẹ̀lú wọn ní ìjọba Bàbá mi. Amin.