Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 119


Ìpín 119

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Far West, Missouri, 8 Oṣù Keje 1838, ní ìdáhùn sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀: “Olúwa! Fi hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí èyí tí ìwọ béèrè nínú àwọn ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ ti pọ̀ tó fún ìdámẹ́wàá.” Òfin ìdámẹ́wàá, bí ó ṣe yé wa ní àkókò yìí, ni a kò tíì fifún ìjọ ṣaájú ìfihàn yìí. Ohun tí a pè ní ìdámẹ́wàá nínú àdúra tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún sọ àti nínú àwọn ìfihàn ti ìṣaájú (64:23; 85:3; 97:11) kò túmọ̀ sí ìdá kan nínú mẹ́wàá nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹbọ-ọrẹ àtinúwá tàbí àwọn ìdáwó, sínú àwọn ìkójọpọ̀ owó ìjọ. Ṣaájú, Olúwa ti fún ìjọ ní òfin ti yíya sí mímọ́ àti iṣẹ́ ìríjú ti àwọn ohun ìní, èyítí àwọn ọmọ ìjọ (ní pàtàkì àwọn alàgbà àṣíwájú) wọ inú rẹ̀ nípasẹ̀ májẹ̀mú kan èyí tí ó yẹ kí ó jẹ́ ti àìlópin. Nítorí ti kíkùnà lati ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní pípa májẹ̀mú yìí mọ́, Olúwa gbà á padà fún àkókò kan àti dípò rẹ̀, ó fi òfin ti ìdámẹ́wã fún gbogbo ìjọ. Wòlíì béèrè lọ́wọ́ Olúwa bí nínú ohun ìní àwọn ènìyàn náà yíò ṣe pọ̀ tó èyíti Òun béèrè fún àwọn èrò mímọ́. Ìdáhùn náà ni ìfihàn yìí.

1–5, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ níláti san àníṣẹ́kù ohun ìní wọn àti nígbànáà fi fúnni, bíí ìdámẹ́wàá, ìdá kan nínú mẹ́wàá ti èrè wọn lọ́dọọdún; 6–7, Irú ọ̀nà kan báyìí yíò ya ilẹ̀ Síónì sí mímọ́.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí, èmi béèrè gbogbo àníṣẹ́kù ní orí ohun ìní wọn láti kó lé ọwọ́ bíṣọ́pù ti ìjọ mi ní Síónì,

2 Fún kíkọ́ ilé mi, àti fún fífi ìpìlẹ̀ Síónì lélẹ̀ àti fún oyè àlùfáà, àti fún àwọn gbèsè ti Àjọ Ààrẹ ti Ìjọ mi.

3 Èyí ni yíò sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìdámẹ́wàá àwọn ènìyàn mi.

4 Àti lẹ́hìn èyí, àwọn wọnnì tí wọ́n ti san ìdámẹ́wàá wọn báyìí yíò san ìdá kan nínú mẹ́wàá ti gbogbo àníkún wọn ní ọdọọdún; èyí yíò sì jẹ́ òfin kan tí yíó dúró fún wọn títí láé, fún oyè àlùfáà mímọ́ mi, ní Olúwa wí.

5 Lõtọ́ ni mó wí fún yín, yíò sì ṣe pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá péjọ sí ilẹ̀ Síónì yíò san ìdámẹ́wàá ti àníkún àwọn ohun ìní wọn, wọn yíò sì pa òfin yìí mọ́, tàbí a kì yíó rí wọn bíi ẹni ìkàyẹ láti gbé ní ààrin yín.

6 Èmi sì wí fún yín, bí àwọn ènìyàn mi kò bá kíyèsí òfin yìí, láti pa á mọ́ ní mímọ́, àti nípa òfin yìí ya ilẹ̀ Síónì sí mímọ́ sí mi, kí àwọn òfin mi àti àwọn ìdájọ́ mi ó lè jẹ́ pípamọ́ ní ibẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, òn kì yíò jẹ́ ilẹ̀ Síónì sí yín.

7 Èyí yíò sì jẹ́ àpẹrẹ kan sí gbogbo àwọn èèkàn Síónì. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.