Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 87


Ìpín 87

Ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀ lorí ogun, tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní tàbí nítòsí Kirtland, Ohio, 25 Oṣù Kejìlá 1832. Ní àkókò yìí àwọn àríyànjiyàn ní United States lórí òwò ẹrú àti Gúsù Carolina tí ó fagilé àwọn owó orí ti ìjọba àpapọ̀ gbòdekan. Ìtàn ti Joseph Smith sọ pé “àwọn ìfarahàn wàhálà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè” ti ndi “ohun tí ó hànde síi” sí Wòlíì “ju bí wọn ti wà tẹ́lẹ̀rí láti ìgbà tí Ìjọ ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ jáde nínú aginjù.”

1–4, A sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun láàrin àwọn Ìpínlẹ̀ Àríwá àti àwọn Ìpínlẹ̀ Gúsù; 5–8, Àwọn ìdààmú nlá yíò sọ̀kalẹ̀ wá sí orí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.

Lóotọ́, báyìí ni Olúwa wí nípa àwọn ogun tí yíò wá sí ìmúṣẹ láìpẹ́, bẹ̀rẹ̀ níbi ìṣọ̀tẹ̀ ti Gúsù Carolina, èyítí yíò yọrí ní ìgbẹ̀hìn sí ikú àti òṣì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹmí;

Àti pé àkókò náà yíò dé tí ogun yíò jẹ́ títú jáde sí orí gbogbo àwọn orílẹ̀ ède, bẹ̀rẹ̀ láti ìhín yìí.

Nítorí kíyèsíi, àwọn Ìpínlẹ̀ Gúsù ni a ó pín ní ìdojúkọ àwọn Ìpínlẹ̀ Àríwá, àti pé àwọn Ìpínlẹ̀ Gúsù náà yíò pe àwọn orílẹ̀-èdè míràn, àní orílẹ̀-èdè ti Great Britain, bí a ṣe npèé, àwọn pẹ̀lú yíò sì ké pe àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ní ọ̀nà áti gbèjà ara wọn ní ìdojúkọ àwọn orílẹ̀-èdè míràn; àti nígbànáà ni ogun yíò jẹ́ títú jáde sí orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

Yíò sì ṣe, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwọn ẹrú yíò sì dìde dojúkọ àwọn olúwa wọn, àwọn ẹnití a ó tò lẹ́sẹsẹ àti tí a ó báwí fún ogun.

Yiò sì ṣe pẹ̀lú pé àwọn ìyókù tí a fi sílẹ̀ ní orí ilẹ̀ náà ni wọn yíò tò lẹ́sẹsẹ fúnra wọn, wọn yíò sì bínú gidigidi, wọn yíò sì yọ àwọn Kèfèrí lẹ́nu pẹ̀lú ìyọlẹ́nu tí ó dunni púpọ̀.

Àti báyìí, pẹ̀lú idà àti nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀ àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé yíò ṣọ̀fọ̀; àti pẹ̀lú ìyàn, àti àjàkálẹ̀ àrùn, àti ilẹ̀ ríru, àti ààrá ti ọ̀run, àti pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná tí ó rorò àti tí ó hàn gbangba, ni a ó mú kí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ó ní ìmọ̀lára ìbínú, àti ìrúnú, àti ọwọ́ ìbáwí Ọlọ́run Alágbára Jùlọ, títí tí ìparun tí a pàṣẹ rẹ̀ yíò fi ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìparí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;

Kí igbe àwọn ẹni mímọ́, àti ti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́, ó lè dẹ́kun wíwá sí etí Olúwa Sábáótì, lati ilẹ̀ ayé, sí gbígba ẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn.

Nítorínáà, ẹ dúró ní àwọn ibi mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ṣípò padà, títí tí ọjọ́ Olúwa yíò fi dé; nítori kíyèsíi, ó nbọ̀ kánkán, ni Olúwa wí. Àmín.