Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 73


Ìpín 73

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ní Hiram, Ohio, 10 Oṣù Kínní 1832. Láti apákan ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù Kejìlá tí ó ṣaájú, Wòlíì náà àti Sidney ti lọ́wọ́ nínú wíwàásù, àti ní ọ̀nà yìí wọ́n ṣe àṣeyọrí púpọ̀ ní ṣíṣe àdínkù àwọn ìmọ̀lára àìníojúrere tí ó ti dìde tako ìjọ (wo àkọlé sí ìpín 71).

1–2, Àwọn alàgbà ni wọn yíò tẹ̀síwájú láti wàásù; 3–6, Joseph Smith àti Sidney Rigdon ni wọn yíò tẹ̀síwájú ní ṣiṣe ìtúmọ̀ Bíbélì títí tí yíò fi parí.

Nítorí lóotọ́, báyìí ni Olúwa wí, ó jẹ́ yíyẹ nínú mi pé kí wọ́n ó tẹ̀síwájú ní wíwàásù ìhìnrere, àti ní sísọ ọ̀rọ̀ ìyànjú sí àwọn ìjọ Ọlọ́run ní àwọn agbègbè yíkáàkiri, títí di ìpáde àpéjọpọ̀;

Àti nígbànáà, kíyèsíi, a ó sọ ọ́ di mímọ̀ fún wọn, nípa ohùn ìpàdé àpéjọpọ̀, onírúurú àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn.

Nísisìyí, lóotọ́ ni mo wí fún yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi, Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon, ni Olúwa wí, ó tọ̀nà láti túmọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi;

Àti pé, níwọ̀nbí ó bá ṣeéṣe, láti wàásù ní àwọn agbègbè yíkáàkiri títí ìpàdé àpéjọpọ̀; àti lẹ́hìn náà ó tọ̀nà kí iṣẹ́ ìtumọ̀ ó tẹ̀síwájú títí tí yíò fi parí.

Ẹ sì jẹ́ kí èyí jẹ́ àpẹrẹ kan sí àwọn alàgbà títí tí ìmọ̀ yíò fi tẹ̀ síwájú, àni bí a ṣe kọ ọ́.

Nísisìyí èmi kò fi fun yín mọ́ ní àkókò yìí. Ẹ di àmùrè yín kí ẹ sì ronújinlẹ̀. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.