Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 69


Ìpín 69

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 11 Oṣù Kọkànlá 1831. Àkójọpọ́ àwọn ìfihàn tí a ní lọ́kàn láti tètè tẹ̀ jade ni a ti fi ọwọ́ sí nínú ìpàdé àpéjọpọ̀ pàtàkì ti 1–2 Oṣù Kọkànlá. Ní 3 Oṣù Kọkànlá, ìfihàn tí ó farahàn ní ìhín bíi ìpín 133, tí a pè ní Àfikún lẹ́hìnwá, ni a fikún un. Oliver Cowdery ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti gbé àfọwọ́kọ àkójọ̀pọ̀ àwọn ìfìhàn àti àwọn òfin lọ sí Independence, Missouri, fún títẹ̀. Bákannáà òun yío mú owó tí a ti dá jọ fún kíkọ́ Ìjọ ní Míssouri lọ́wọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Ìfihàn yí fi òfin fún John Whitmer láti bá Oliver Cowdery lọ àti bákannáà ó darí Whitmer láti rin ìrìnajò kí ó sì gba àwọn ohun èlò onítàn nínú ìpè rẹ̀ bíi olùkọ̀tàn àti olùkọsílẹ̀ ti Ìjọ.

1–2, John Whitmer ni yíò bá Oliver Cowdery rìn lọ sí Missouri; 3–8, Òun náà yíò wàásù yío sì gbà, ṣe àkọsílẹ̀, yíò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé ìtàn.

Ẹ fetísílẹ̀ sí mi, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí, nítorí ti ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery’s. Kìí ṣe ọgbọ́n nínú mi pé kí á gbé àwọn ìwé òfin àti owó sí ìtọ́jú rẹ̀ èyítí òun yíò gbé lọ sí ilẹ̀ Síónì, bíkòṣe pé kí ẹ̀nikan lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹnití yíò jẹ́ olóotọ́ àti olóotọ́.

Nítorínáà, èmi, Oluwa, fẹ́ kí ìránṣẹ́ mi, John Whitmer, ó lọ pẹ̀lu ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery;

Àti bákannáà pé òun yíò tẹ̀síwájú nínú ìwé kíkọ àti ní kíkọ ìtàn kan nípa gbogbo àwọn ohun pàtàkì èyítí òun bá ṣe àkíyèsí àti tí ó mọ̀ nípa ìjọ mi;

Àti bákannáà pé kí òun ó gba ìmọ̀ràn àti ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery àti àwọn míràn.

Àti bákannáà, àwọn ìránṣẹ́ mi tí wọ́n wà ní òkèèrè káàkiri orí ilẹ̀ ayé níláti fi ìṣirò àwọn iṣẹ́ ìríjú wọn ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Síónì;

Nítorí ilẹ̀ Síónì ni yíò jẹ́ ìbùjókòó kan àti ibikan láti gbà àti láti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí.

Bí o tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi John Whitmer ó rìn ìrìnàjò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti ibi kan sí ibi kàn, àti láti ilé ìjọsìn sí ilé ìjọ́sìn, kí ó lè rọ̀ ọ́ lọ́rùn síi láti gba ìmọ̀—

Ní wíwàásù àti sísọ àsọyé, ní kíkọ ìwé, ṣíṣe ẹ̀dà, ní ṣíṣe àṣàyàn, àti ní gbígba ohun gbogbo èyítí yío jẹ́ fún ire ìjọ, àti fún àwọn ìran tó ndìde tí wọn yíò dàgbà sókè ní orí ilẹ̀ Síónì, láti ní i láti ìran dé ìran, láé àti títí láéláé. Àmín.