Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 4


Ìpín 4

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí baba rẹ̀, Joseph Smith Àgbà, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Kejì 1829.

1–4, Síṣe iṣẹ́-ìsìn akíkanjú kó àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yọ; 5–6, Àwọn ìwà bbíi ti Ọlọ́run mú wọn yẹ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́; 7, Àwọn ohun ti Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ lílépa.

Nísisìyí kíyèsíi, isẹ́ ìyanu kan ti fẹ́ jáde wá láàrin àwọn ọmọ ènìyàn.

Nítorínáà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run, ẹ ríi wípé ẹ sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ipá, iyè àti okun, kí ẹ̀yin baà lè dúró láì ní ìdálẹ́bi níwájú Ọlọ́run ní ọjọ́ ìkẹhìn.

Nítorínáà, bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run, a pè yìn sí iṣẹ́ náà;

Nítorí, kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè; sì wòó, ẹnití ó bá fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, òun náà ni ó kórè sínú àká kí òun má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó mú ìgbàlà wá fún ẹ̀mí rẹ̀;

Àti pé ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ àti ìfẹ́, pẹ̀lú fífi ojú sí ògo Ọlọ́run nìkan, mú un yẹ fún iṣẹ́ náà.

Ẹ rántí ìgbàgbọ́, ìwà rere, ìmọ̀, àìrékọjá, sùúrù, inú rere sí ọmọnìkejì, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìrẹ̀lẹ̀, aápọn.

Ẹ béèrè, ẹ̀yin yíò sì rí gbà; ẹ kan ilẹ̀kùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. Àmín.