Ìpín 48
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 10 Oṣù Kẹta 1831. Wòlíì náà ti béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ọ̀nà ìgbésẹ̀ ti ríra àwọn ìlẹ̀ fún títẹ̀dó àwọn Ènìyàn Mímọ́. Èyí jẹ́ ohun pàtàkì bí a bá wo ìrìn àjò àwọn ọmọ ìjọ ní ṣíṣí láti ìhà ìlà oòrun Ìlẹ̀ Amẹ́ríkà, ní ìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa wípé wọ́n níláti kó ara wọn jọ ní Ohio (wo àwọn ìpín 37:1–3; 45:64).
1–3, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Ohio níláti pín àwọn ilẹ̀ wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn; 4–6, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nílati ra àwọn ilẹ̀, kọ́ ilú kan, àti kí wọn ó tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn olórí wọn.
1 O ṣe dandan pé kí ẹ̀yin ó dúró ní àwọn ibi ìtẹdó tí ẹ wà ní àkókò yìí, nítorí yíò wà ní ìbámu sí àwọn ipò yín.
2 Àti pé níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin bá ní ilẹ̀, ẹ̀yin yíò pín fún àwọn arákùnrin yín ní ìlà oòrùn.
3 Àti níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin kò bá ní ilẹ̀, ẹ jẹ́ kí wọn rà fún àkòkò yìí ní àwọn agbègbè yíká, bí wọ́n ṣe ríi pé ó dára, nítorí ó gbọdọ̀ di dandan pé kí wọn ní àwọn ibi tí wọn yíò gbé fún àkókò yìí.
4 Ó gbọdọ̀ jẹ́ dandan pé kí ẹ̀yin ó ṣe ìpamọ́ gbogbo owó tí ẹ bá le fi pamọ́, àti pé kí ẹ̀yin gba gbogbo ohun tí ẹ bá lè gbà nínú ìṣòdodo, pé ní àìpẹ́ ẹ̀yin yíò lè ra ilẹ̀ fún ogún ìní, àní ìlú náà.
5 Ibi ilẹ̀ náà ni a kò tíì fi han; ṣùgbọ́n lẹ́hìn ìgbà tí àwọn arákùnrin yín bá dé láti ìlà oòrùn nígba náà ni a ó yàn àwọn ènìyàn kan, àti pé a ó fi fún wọn láti mọ ibẹ̀, tàbí sí wọn ní a ó fi hàn.
6 A ó sì yàn wọ́n láti ra awọn ilẹ̀ náà, àti lati ṣe bíbẹ̀rẹ̀ sí máa fi ìpìlẹ̀ ìlú náà lélẹ̀; àti nígbà náà ni a ó bẹ̀rẹ̀ sí kóo yín jọ pẹ̀lú àwọn ẹbí yín, ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu sí ẹbí rẹ̀, ní ìbámu sí àwọn ipò tí rẹ̀, àti bí a ṣe yàn án fún un láti ọwọ́ àjọ ààrẹ àti bíṣọ́ọ̀pù ìjọ, ní ìbámu sí àwọn òfin àti àṣẹ èyítí ẹ̀yin ti gbà, àti èyí tí ẹ̀yin yíò gbà lẹ́hìnwá. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.