Ìpín 2
Àwọn ohun tí a fà yọ nínú ìwé ìtàn Joseph Smith ní ṣíṣe àtúnsọ àwọn ọ̀rọ ángẹ́lì Mórónì sí Wòlíì Joseph Smith, nígbàtí ó wà nínú ilé onígi àwọn Smith ní Palmyra, New York, ní ìrọ̀lẹ́ 21 Oṣù Kẹsan 1823. Moroni ni ìkẹhìn nínú àwọn ọ̀pọ̀ ònkọ̀tàn tí wọ́n ti ṣe àkọsílẹ̀ èyí tí ó wà níwájú gbogbo ayé nísisìyí bíi Ìwé ti Mọ́mọ́nì. (Fi wé Málákì 4:5–6; bákannáà àwọn ìpín 27:9; 110:13–16; àti 128:18.)
1, Elijah ni yíò fi oyè-àlùfáà hàn; 2–3, Àwọn ìlérí ti àwọn baba ni a gbìn sínú ọkàn àwọn ọmọ.
1 Kíyèsíi, èmi yíò fi oyè àlùfáà hàn sí ọ, láti ọwọ́ wòlíì Èlíjàh, ṣaájú bíbọ̀ ọjọ́ nlá àti bíbanilẹ́rù ti Olúwa.
2 Àti pé òun yíò gbìn sí ọkàn àwọn ọmọ awọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn baba, ọkàn ti àwọn ọmọ yíò sì yí sí ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn.
3 Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé ni yíò di fífiṣòfò pátápátá ní bíbọ̀ rẹ̀.