Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 129


Ìpín 129

Àwọn ìtọsọ́nà tí a gbà nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Nauvoo, Illinois, 9 Oṣù Kejì 1843, ní sísọ àwọn kọ́kọ́rọ́ pàtàkì mẹ́ta di mímọ̀ nípa ẹ̀yítí a lè fi dá ìṣẹ̀dá pípé ti àwọn ángẹ́lì oníṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ti àwọ̀n ẹ̀mí mọ̀ yàtọ̀.

1–3, Àwọn ara tí wọ́n ti jínde àti àwọn ara ti ẹ̀mí wà ní ọ̀run; 4–9, A fi àwọn kọ́kọ́rọ́ fúnni nípa èyítí a fi lè dá àwọn ìránṣẹ́ láti ìtayọ àṣọ ìkelè mọ̀.

Irú àwọn ẹ̀dá méjì ni wọ́n wà ní ọ̀run, orúkọ wọn ni: àwọn Ángẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti jínde, pẹ̀lú níní àgọ́ ara ti ẹran ara àti àwọn egungun—

Fún àpẹrẹ, Jésù wi pe: Ẹ dì mí mú kí ẹ sì wòó, nítorí ẹ̀mí kò ní ẹran ara àti àwọn egungun, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.

Lí ọ̀nà kejì: àwọn ẹ̀mí ti àwọn olóotọ́ ènìyàn tí a sọ di pípé, àwọn ẹnití a kò jí dìde, ṣùgbọ́n tí wọ́n jogún ògo kan náà.

Nígbàtí ìránṣẹ́ kan bá wá ní wíwí pé òun ní iṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ fún un kí o sì béèrè pé kí òun bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.

Bí òun bá jẹ́ ángẹ́lì kan òun yíò ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yíò sì ní ìmọlára ọwọ́ rẹ̀.

Bí òun bá jẹ́ ẹ̀mí ti olòotọ́ ènìyàn tí a sọ di pípé òun yíò wá nínú ògo rẹ̀; nítorí èyíinì ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí òun fi lè fi ara hàn—

Béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí òun bọ ọwọ́ pẹ̀lú rẹ, ṣùgbọ́n òun kì yíò ṣípo padà, nítorítí ó lòdì sí ètò ti ọ̀run fún olòotọ́ ènìyàn láti tanni jẹ; ṣùgbọ́n òun yíò jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ síbẹ̀.

Bí ó bá jẹ́ èṣù bíi ángẹ́lì ìmọ́lẹ̀, nígbàtí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ láti bọwọ́ pẹ̀lú rẹ òun yíò na ọwọ́ rẹ̀, ìwọ kì yíò sì ní ìmọlára kankan; nígbànáà ni ìwọ yío lè dá a mọ̀.

Ìwọ̀nyí ni àwọn kọ́kọ́rọ́ pàtàkì mẹ́ta nípa bí ìwọ ṣe lè mọ̀ bóyá èyíkéyìí ìpínfúnni jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.