Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 63


Orí 63

Ṣíblọ́nì àti Hẹ́lámánì gba àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã—Àwọn ará Nífáì púpọ̀ rin ìrìnàjò lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá—Hágọ́tì kọ́ àwọn ọkọ̀ ojú omi, tí ó lọ sínú òkun ti apá ìwọ oòrùn—Móróníhà borí àwọn ará Lámánì ní ogun. Ní ìwọ̀n ọdún 56–52 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹrìndínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Ṣíblọ́nì gba àwọn ohun mímọ́ nnì èyítí Álmà ti gbé fún Hẹ́lámánì.

2 Ẹ̀nìti o tọ́ ni í sì í ṣe, ó sì rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run; ó sì tẹramọ́ ṣíṣe èyítí ó dára títí, láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ mọ́; arákùnrin rẹ̀ nã sì ṣe bẹ̃.

3 Ọ́ sì ṣe tí Mórónì kú pẹ̀lú. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìndínlógójì parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.

4 Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàdínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ọmọ ogun, àní tí o tó ẹgbẹ̀rún marun àti irínwó pẹ̀lú àwọn ìyàwó nwọn àti àwọn ọmọ nwọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá.

5 Ó sì ṣe tí Hágọ́tì, ẹnití í ṣe ọlọfintoto ènìyàn, nítorínã ni ó jáde lọ tí osì kọ́ ọkọ̀ ojú omi nlá kan fún ara rẹ̀, ní ibi ìpẹ̀kun ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, nítòsí ilẹ̀ Ibi-Ahoro, tí ó sì tĩ sínú omi tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní ẹ̀bá ilẹ̀ tõró èyítí ó já sí ilẹ̀ tí o wà ní apá àríwá.

6 Ẹ kíyèsĩ, púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì ni ó wọ inú rẹ̀ lọ tí nwọn sì kó pẹ̀lú ìpèsè oúnjẹ tí ó pọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé; nwọ́n sì mú ìrìnàjò nwọn lọ sí apá àríwá. Báyĩ, sì ni ọdún kẹtàdínlógójì ṣe dópin.

7 Àti ní ọdún kejìdínlógójì, ọkùnrin yĩ kọ́ àwọn ọkọ̀ míràn. Ọkọ̀ ìkínní nnì sì padà, àwọn ènìyàn púpọ̀ síi sì wọ inú rẹ̀; nwọ́n si kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèsè oúnjẹ, nwọ́n sì tún ṣíkọ̀ lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá.

8 Ó sì ṣe tí a kò gburo nwọn mọ́. Àwa sì rò wípé nwọ́n ti rì nínú ìsàlẹ̀ omi òkun ni. Ó sì ṣe tí ọkọ̀ míràn nã tún ṣíkọ̀ jáde lọ; àwa kò sì mọ́ ibití ó lọ sí.

9 Ó sì ṣe nínú ọdún yìi kannã tí àwọn ènìyàn tí o kọjá lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá pọ̀ púpọ̀. Báyĩ sì ni ọdún kejìdínlógójì parí.

10 Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, Ṣíblọ́nì kú pẹ̀lú, Kọ̀ríántọ́nì sì ti jáde lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá nínú ọkọ̀, láti gbé ìpèsè oúnjẹ fún àwọn tí ó ti jáde lọ sínú ilẹ̀ nã.

11 Nítorí ìdí èyí, ó jẹ́ èyítí ó yẹ fún Ṣíblọ́nì láti gbé àwọn ohun mímọ́ nnì, ṣãju ikú rẹ̀, lé ọwọ́ ọmọ Hẹ́lámánì, ẹnití í ṣe Hẹ́lámánì, tí a fi orúkọ bàbá rẹ̀ pè é.

12 Nísisìyí kíyèsĩ, gbogbo àwọn ohun fífín nnì tí nwọ́n wà lọ́wọ́ Hẹ́lámánì ni a kọ jáde, tí a sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ènìyàn jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, àfi àwọn ibití Álmà ti pàṣẹ pé kí a máṣe fi ránṣẹ́ sí.

13 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ohun wọ̀nyí ni nwọ́n níláti pamọ́ ní mímọ́, tí a sì gbé lé ọwọ́ nwọn láti ìran kan dé òmíràn; nítorínã nínú ọdún yìi, a ti gbé nwọ́n lé ọwọ́ Hẹ́lámánì kí Ṣíblọ́nì ó tó kú.

14 Ó sì ṣe pẹ̀lú nínú ọdún yĩ tí àwọn olùyapa kan wà tí nwọn ti jáde lọ bá àwọn ará Lámánì; tí nwọ́n sì tún rú nwọn sókè nínú ìbínú sí àwọn ará Nífáì.

15 Àti pẹ̀lú nínú ọdún yĩ kannã nwọ́n sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun láti bá àwọn ará Móróníhà jagun, tàbí láti bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Móróníhà jà, nínú èyítí nwọ́n nà nwọ́n, nwọn sì lé nwọ́n padà sínú ilẹ nwọn, tí nwọ́n sì pàdánù lọ́pọ̀lọpọ̀.

16 Báyĩ sì ni ọdún kọkàndínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ará Nífáì dópin.

17 Báyĩ sì ni a pari ọ̀rọ̀ nípa Álmà àti Hẹ́lámánì ọmọ rẹ̀, àti Ṣíblọ́nì pẹ̀lú, ẹnití í ṣe ọmọ rẹ̀.