Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 24


Orí 24

Àwọn ará Lámánì gbógun ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run—Àwọn Kòṣe-Nífáì-Léhì yọ̀ nínú Krístì, àwọn ángẹ́lì sì bẹ̀ nwọ́n wò—Nwọ́n yàn láti kú ju pé kí nwọ́n dãbò bò ara nwọn—Nínú àwọn ará Lámánì tún yípadà síi. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì àti àwọn ará Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ámúlónì, àti ní ilẹ̀ Hẹ́lámì pẹ̀lú, àti tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, ní kúkúrú, tí nwọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní àyíká, tí nwọn kò tĩ yípadà, tí nwọn kò sì tĩ jẹ́ orúkọ Kòṣe-Nífáì-Léhì, ni àwọn ará Ámálẹ́kì pẹ̀lú àwọn ará Ámúlónì rú sókè, ní ìrunú sí àwọn arákùnrin nwọn.

2 Ìkórira nwọn sì pọ̀ púpọ̀ sí nwọn, àní tó bẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣọ̀tẹ̀ sí ọba nwọn, tó bẹ̃ tí nwọn kò fẹ́ kí ó jẹ́ ọba fún nwọn mọ́; nítorínã, nwọ́n kó ohun ìjà jọ sí àwọn Kòṣe-Nífáì-Léhì.

3 Nísisìyí ọba gbé ìjọba rẹ̀ lé ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Kòṣe-Nífáì-Léhì.

4 Ọba sì kú ní ọdún nã èyítí àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ ogun láti kọlu àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

5 Nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí nwọ́n ti jáde wá pẹ̀lú rẹ̀ rí gbogbo ìmúrasílẹ̀ tí àwọn ará Lámánì ti ṣe láti pa àwọn arákùnrin nwọn, nwọ́n kọjá lọ sí ilẹ̀ Mídíánì, níbẹ̀ sì ni Ámọ́nì bá gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pàdé; tí nwọ́n sì ti ibẹ̀ wá sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, láti lè ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú Lámónì àti pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ Kòṣe-Nífáì-Léhì, ohun tí nwọn yíò ṣe láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.

6 Nísisìyí kò sí ẹ̀yọ ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn nã èyítí a ti yí lọ́kàn padà sọ́dọ̀ Olúwa tí yíò gbé ohun ìjà ti arákùnrin nwọn; rárá, nwọn kò tilẹ̀ ní ṣe ìpalẹ̀mọ́ kankan fún ogun; bẹ̃ni, ọba nwọn pẹ̀lú pàṣẹ fún nwọn láti má ṣe eleyĩ.

7 Nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ó bá àwọn ènìyàn nã sọ nípa ọ̀rọ̀ nã: Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi, ẹ̀yin ènìyàn àyànfẹ́ mi, pé Ọlọ́run wa tí ó tóbi, nínú dídára rẹ̀ ran àwọn arákùnrin wa yĩ, àwọn ará Nífáì, sì wá láti wãsù fún wa, àti láti yí wa lọ́kàn padà kúrò nínú àwọn àṣà àwọn bàbá búburú wa.

8 Sì kíyèsĩ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi tí ó tóbi, pé ó ti fún wa ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti dẹ ọkàn wa, tí àwa sì ti ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin yĩ, àwọn ará Nífáì.

9 Sì kíyèsĩ, mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi, pé nípa ìrẹ́pọ̀ yĩ, àwa ti yí ọkàn padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpànìyàn tí àwa ti ṣe.

10 Èmi sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi, bẹ̃ni, Ọlọ́run mi tí ó tóbi, pé ó ti yọ̃da wa láti ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ohun wọ̀nyí, àti pé ó ti dáríjì wá lórí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìpànìyàn tí a dá, tí ó sì ti mú ẹ̀bi kúrò lọ́kàn wa, nípasẹ̀ ìtóyè Ọmọ rẹ̀.

11 Àti nísisìyí kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, níwọ̀n ìgbàtí ó ti jẹ́ ohun tí ó yẹ kí àwa ó ṣe (nítorípé àwa ni a kùnà jù nínú gbogbo ènìyàn) láti ronúpìwàdà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa àti gbogbo ìpànìyàn tí àwa ti ṣe, kí àwa kí ó sì jẹ́ kí Ọlọ́run yọ eleyĩ kúrò lọ́kàn wa, nítorípé èyí ni ohun tí ó tọ́ fún wa láti ṣe, pé kí àwa kí ó ronúpìwàdà pátápátá níwájú Ọlọ́run, kí ó lè mú àbàwọ́n wa kúrò—

12 Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n jùlọ, níwọ̀n ìgbàtí Ọlọ́run ti mú àwọn àbàwọ́n wa kúrò, tí àwọn idà wa sì ti mọ́, nítorínã, ẹ jẹ́ kí a dẹ́kun fífi ẹ̀jẹ́ àwọn arákùnrin wa ṣe àbàwọ́n fún idà wa.

13 Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín, rárá, ẹ jẹ́ kí a pa idà wa mọ́ kúrò lọ́wọ́ àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa; nítorípé bóyá, bí àwa bá tún fi àbàwọ́n bá idà wa, nwọn kò ní di wíwẹ̀mọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Ọmọ Ọlọ́run wa tí ó tóbi; èyítí yíò ta sílẹ̀ fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ wa.

14 Ọlọ́run tí ó tóbi nã sì ti ṣãnú fún wa, ó sì ti fi àwọn ohun wọ̀nyí yé wa kí àwa má bã ṣègbé; bẹ̃ni, òun sì ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ fún wa ní ìṣãjú, nítorítí ó fẹ́ràn ẹ̀mí wa gẹ́gẹ́bí ó ti fẹ́ràn àwọn ọmọ wa; nítorínã, nínú ãnú rẹ̀ ni ó nbẹ̀wá wò nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì rẹ̀, pé kí ìlànà ìgbàlà nã lè di mímọ̀ fún wa àti fún àwọn ìran tí nbọ̀ lẹ́hìn ọ̀la.

15 Áà, báwo ni ãnú Ọlọ́run wa ti tó! Àti nísisìyí kíyèsĩ, nígbàtí àwa ti ṣe èyí láti mú àbàwọ́n kúrò lára wa, tí a sì ti mú idà wa mọ, ẹ jẹ́ kí a fi nwọ́n pamọ́, kí nwọ́n bá lè wà ní mímọ́, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí Ọlọ́run wa ní ọjọ́ ìkẹhìn, tàbí ní ọjọ́ tí a ó mú wa dúró níwájú rẹ̀ fún ìdájọ́, pé àwa kò fi àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa bá idà wa láti ìgbà nã tí ó ti kọ́ wa ní ọ̀rọ̀ rẹ, tí òun sì ti mú wa mọ nípasẹ̀ èyí.

16 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, bí àwọn arákùnrin wa bá lépa láti pa wá run, ẹ kíyèsĩ, àwa yíò fi idà wa pamọ́, bẹ̃ni, àní àwa yíò rì nwọ́n mọ́lẹ̀, kí nwọn lè wà ní mímọ́, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí pé àwa kò lò nwọ́n rí, ní ọjọ́ ìkẹhìn; bí àwọn arákùnrin wa bá sì pa wá run, ẹ kíyèsĩ, àwa yíò lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, a ó sì yè.

17 Àti nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí ọba ti parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí gbogbo àwọn ènìyàn nã sì péjọ, nwọ́n kó idà nwọn, pẹ̀lú gbogbo ohun ìjà nwọn èyítí nwọn ti lò fún títa ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, nwọ́n sì rì nwọ́n mọ́lẹ̀ pátápátá.

18 Èyí ni nwọ́n sì ṣe, nítorípé lọ́kàn nwọn, èyí jẹ́ ẹ̀rí sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn pẹ̀lú, pé nwọn kò ní lo ohun ìjà mọ́ láéláé fún ìtàjẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ mọ́; nwọ́n sì ṣe èyí, ní ìpinnu àti májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, pé kàkà kí nwọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin nwọn sílẹ̀, nwọn yíò fi ẹ̀mí ara nwọn lélẹ̀; àti pé kàkà kí nwọ́n gba ti ọmọnìkejì ẹni, nwọn yíò fún un; àti pé kàkà kí nwọ́n gbé ìgbé ayé ọ̀lẹ, nwọn yíò ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ nwọn.

19 Báyĩ, àwa ríi pé, nígbàtí àwọn ará Lámánì yíi ti gbàgbọ́ tí nwọn sì ti mọ ọ̀títọ́, nwọ́n dúró ṣinṣin, nwọn yíò sì faradà ìyà àní títí fi dé ojú ikú kàkà kí nwọ́n gbẹ̀ṣẹ̀; báyĩ ni àwa sì ríi pé nwọ́n ri ohun ìjà nwọn mọ́lẹ̀ fún àlãfíà, tàbí pé nwọ́n ri àwọn ohun ìjà ogun, nítorí àlãfíà.

20 Ó sì ṣe tí àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun, tí nwọ́n sì kọjá wá sí ilẹ̀ Nífáì láti pa ọba run, àti láti fi ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀, àti láti pa àwọn ènìyàn Kòṣe-Nífáì-Léhì run kúrò lórí ilẹ̀ nã.

21 Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn nã rí i pé nwọn nbọ̀wá láti gbógun tì nwọ́n, nwọ́n jáde láti lọ pàdé nwọn, nwọ́n sì wólẹ̀ níwájú nwọn lórí ilẹ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Olúwa; ipò yĩ ni nwọ́n sì wà nígbàtí àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí kọlũ nwọ́n, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n pẹ̀lú idà.

22 Báyĩ sì ni ó rí láìrí àtakò, tí nwọ́n pa ẹgbẹ̀rún àti mãrún nínú nwọn; àwa sì mọ̀ pé nwọ́n jẹ́ alábùkún-fún, nítorítí nwọ́n ti lọ gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nwọn.

23 Nísisìyí nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé àwọn arákùnrin nwọn kọ̀ láti sá fún idà, tàbí pé kí nwọ́n yí sí ọ̀tún tàbí sí òsì, ṣùgbọ́n pé nwọn ndùbúlẹ̀, nwọn sì nparun, tí nwọ́n sì nyin Ọlọ́run àní bí nwọ́n ṣe nparun lọ́wọ́ idà—

24 Nísisìyí, nígbàtí àwọn ará Lámánì rí èyí, nwọ́n dá ara nwọn lẹ́kun láti má pa nwọ́n; àwọn tí ọkàn nwọn sì ti dàrú nínú nwọn fún àwọn arákùnrin nwọn tí nwọ́n ti parun nípasẹ̀ idà sì pọ̀, nítorítí nwọ́n ronúpìwàdà fún àwọn ohun tí nwọ́n ti ṣe.

25 Ó sì ṣe tí nwọ́n da àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀, tí nwọn kò sì gbé nwọn mọ, nítorítí ìrora bá nwọn fún gbogbo ìpànìyàn tí nwọ́n ti ṣe; nwọn sì wólẹ̀, àní gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọ́n sì nwojú ãnú àwọn tí nwọ́n gbọ́wọ́ sókè láti pa nwọ́n.

26 Ó sì ṣe tí àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọjọ́ nã ju iye àwọn tí nwọ́n ti pa; àwọn tí nwọ́n sì ti pa jẹ́ olódodo ènìyàn, nítorínã, àwa kò ní ìdí kan láti ṣiyèméjì pé a ti gbà nwọ́n là.

27 Kò sì sí ẹni búburú kan nínú àwọn tí nwọ́n pa; ṣùgbọ́n àwọn tí a mú wá sí ìmọ̀ òdodo ju ẹgbẹ̀rún lọ; báyĩ ni àwa ríi pé Ọlọ́run nṣiṣẹ́ ní oríṣiríṣi ọ̀nà fún ìgbàlà àwọn ènìyàn rẹ̀.

28 Nísisìyí àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì ni ó pọ̀ jù nínú àwọn ará Lámánì tí ó pa àwọn arákùnrin wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, púpọ̀ nínú nwọn sì jẹ́ ti ipa àwọn Néhórì.

29 Nísisìyí, nínú àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Olúwa, kò sí àwọn ará Ámálẹ́kì tàbí àwọn ará Ámúlónì, tàbí èyí tí í ṣe ti ipa Néhórì, ṣùgbọ́n ìran Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì ni nwọn íṣe.

30 Báyĩ sì ni àwa mọ̀ dájúdájú pé lẹ́hìn tí a bá ti fún àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ nípa Ẹ̀mí-Ọlọ́run lẹ̃kan, tí nwọ́n sì ti ní ìmọ̀ nlá nípa èyítí í ṣe ti òdodo, tí nwọ́n sì ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwàìrékọjá, nwọn yíò burú síi, nípa èyí, ipò nwọn yíò burú jù bí èyítí nwọn kò mọ ohun wọ̀nyí rí.