Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 21


Akọsílẹ̀ nípa ìwãsù Áárọ́nì, àti Múlókì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn, sí àwọn ará Lámánì.

Èyítí a kọ sí àwọn orí 21 títí ó fi dé 26 ní àkópọ̀.

Orí 21

Áárọ́nì nkọ́ àwọn ará Ámálẹ́kì ní ẹ̀kọ́ nípa Krístì àti ètùtù rẹ̀—Nwọ́n gbé Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ jù sínú túbú ní Mídónì—Lẹ́hìn ìtúsílẹ̀ nwọn, nwọ́n nkọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù, nwọ́n sì yí ọ̀pọ̀ lọ́kàn padà—Lámónì fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì ní òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn tí ó bá wù wọ́n. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ ya ara nwọn sílẹ̀ ní etí-ìlú ti ilẹ̀ àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ, Áárọ́nì mú ọ̀nà ìrìn-àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìhà ilẹ̀ èyítí àwọn ará Lámánì npè ní Jerúsálẹ́mù, tí nwọ́n sọ lórúkọ ilẹ̀ ìbí àwọn bàbá nwọn; ó sì jìnà síwájú, tí ó wa lẹ́bá etí-ìlú Mọ́mọ́nì.

2 Nísisìyí, àwọn ará Lámánì pẹ̀lú àwọn ará Ámálẹ́kì, àti àwọn ènìyàn Ámúlónì ti kọ́ ilu nlá kan, èyítí nwọn pe orúkọ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.

3 Nísisìyí, àwọn ará Lámánì jẹ́ ọlọ́kàn líle ènìyàn, ṣùgbọ́n, àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì síbẹ̀síbẹ̀ le lọ́kàn jù nwọ́n lọ; nítorínã, nwọ́n jẹ́ kí ọkàn àwọn ará Lámánì túbọ̀ le síi, pé kí nwọ́n lágbára síi nínú ìwà búburú àti ìwà ìríra nwọn gbogbo.

4 Ó sì ṣe tí Áárọ́nì wá sí ìlú-nlá Jerúsálẹ́mù, tí ó sì kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ará Ámálẹ́kì. Ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí nwọn nínú àwọn sínágọ́gù nwọn, nítorítí nwọ́n ti kọ́ àwọn sínágọ́gù bí àwọn tí ipa Néhórì; nítorípé púpọ̀ nínú àwọn ará Ámálẹ́kì pẹ̀lú àwọn ará Ámúlónì jẹ́ ti ipa ti Néhórì.

5 Nítorínã, bí Áárọ́nì ti wọ inú ọ̀kan àwọn sínágọ́gù nwọn láti wãsù sí àwọn ènìyàn nã, bí ó sì ṣe nbá nwọn sọ̀rọ̀ lọ, kíyèsĩ, ará Ámálẹ́kì kan dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ta kõ, wípé: Kíni èyí nnì tí ìwọ jẹ́rĩ sí? Ìwọ ha ti rí ángẹ́lì bí? Kíni àwọn ángẹ́lì kò ṣe farahàn sí wá? Kíyèsĩ, ṣe àwọn ènìyàn yí kò dára tó àwọn ènìyàn rẹ ni?

6 Ìwọ wípé, afi bí àwa bá ronúpìwàdà, àwa yio ṣègbé. Báwo ni ìwọ ṣe mọ́ èrò àti ìfẹ́ inú ọkàn wa? Báwo ni ìwọ ṣe mọ̀ pé ó yẹ fún wa láti ronúpìwàdà? Báwo ni ìwọ ṣe mọ̀ wípé àwa kĩ ṣe ènìyàn rere? Kíyèsĩ, àwa ti kọ́ àwọn ibi-mímọ́, àwa sì máa nkó ara wa jọ láti sin Ọlọ́run. Àwa gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run yíò gba ènìyàn gbogbo là.

7 Nísisìyí Áárọ́nì sọ fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ wípé Ọmọ Ọlọ́run yíò wá láti ra aráyé padà kurò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn?

8 Ọkùnrin nã sì wí fún un pé: Àwa kò gbàgbọ́ pé ìwọ mọ́ èyí tí ó jẹ́ bẹ̃. Àwa kò gbàgbọ́ nínú àwọn àṣà aṣiwèrè wọ̀nyí. Àwa kò gbàgbọ́ pé ìwọ mọ́ àwọn ohun èyítí nbọ̀wá bẹ̃ni àwa kò sì gbàgbọ́ pé àwọn bàbá rẹ àti àwọn bàbá wa mọ̀ nípa àwọn ohun tí nwọ́n sọ, nípa èyítí nbọ̀wá.

9 Nísisìyí Áárọ́nì bẹ̀rẹ̀sí ṣí àwọn ìwé-mímọ́ fún nwọn nípa bíbọ̀ Krístì, àti nípa àjĩnde òkú, àti pẹ̀lú pé kò lè sí ìràpadà fún aráyé, bíkòṣe nípa ikú àti ìjìyà Krístì, àti ètùtù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

10 Ó sì ṣe, bí òun ṣe nla àwọn nkan wọ̀nyí yé nwọn, nwọ́n bínú síi, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fĩ ṣe ẹlẹ́yà; nwọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó nsọ mọ.

11 Nítorínã, nígbàtí ó ríi pé nwọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ òun mọ, ó jáde kúrò nínú sínágọ́gù nwọn, ó sì wá sí inú ìletò kan tí à npe orúkọ rẹ̀ ní Anai-Ántàì, níbẹ̀ ní ó sì rí Múlókì tí ó nwãsù ọ̀rọ̀-nã sí nwọn; pẹ̀lú Ámmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Nwọn sì njiyàn pẹ̀lú púpọ̀ nwọn nípa àwọn ọ̀rọ̀-nã.

12 Ó sì ṣe, tí nwọ́n ríi pé àwọn ènìyàn nã sé ọkàn nwọn le síbẹ̀, nítorínã nwọ́n jáde kúrò níbẹ̀ nwọ́n sì wá sí ilẹ̀ Mídónì. Nwọ́n sì wãsù ọ̀rọ̀-nã sí púpọ̀ àwọn ènìyàn nã, díẹ̀ sì gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí nwọ́n kọ́ nwọn.

13 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n mú Áárọ́nì àti àwọn kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ nwọ́n sì jù nwọn sínú túbú, àwọn tí o kú sì sa jáde kúrò nínú ilẹ̀ Mídónì lọ sí àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká.

14 Àwọn ti nwọ́n jù sínú túbú jẹ ìyà púpọ̀, a sì tú nwọn sílẹ̀ nípasẹ̀ Lámónì àti Ámọ́nì, a sì fún nwọn ní oúnjẹ, a sì wọ aṣọ fún nwọn.

15 Nwọ́n sì tún jáde lọ láti lọ wãsù ọ̀rọ̀-nã, báyĩ sì ni a ṣe tú nwọn sílẹ̀ nínú túbú nígbà àkọ́kọ́; báyĩ sí ni ìyà ṣe jẹ nwọ́n.

16 Nwọ́n sì jáde lọ, sí ibikíbi tí Ẹ̀mí-Olúwa darí nwọn sí, tí nwọ́n nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú gbogbo sínágọ́gù àwọn ará Ámálẹ́kì, tàbí ní ibi àpéjọ àwọn ará Lámánì tí nwọ́n bá gbà nwọ́n wọlé.

17 Ó sì ṣe tí Olúwa sí bẹ̀rẹ̀sí bùkún nwọn, tó bẹ̃ tí nwọ́n mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí ìmọ̀ òtítọ́; bẹ̃ni, nwọ́n yí púpọ̀ lọ́kàn padà nípa ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, àti nípa àṣà àwọn bàbá nwọn, tí kò tọ̀nà.

18 Ó sì ṣe tí Ámọ́nì àti Lámónì padà kúrò ní ilẹ̀ Mídónì, lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, èyítí íṣe ilẹ̀ íní nwọn.

19 Ọba Lámónì kò sì gbà kí Ámọ́nì sin òun, tàbí kí ó jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ òun.

20 Ṣùgbọ́n ó pàṣẹ kí nwọ́n kọ́ àwọn sínágọ́gù ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì; ó sì paṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀, tàbí àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀, kí nwọ́n kó ara nwọn jọ papọ̀.

21 Ó sì yọ nítorí nwọn, ó sì kọ́ nwọn ní ohun púpọ̀. Òun sì tún la ohun púpọ̀ yé nwọn pé ènìyàn tí ó wà lábẹ́ ìjọba òun ni nwọ́n íṣe, àti pé òmìnira-ènìyàn ni nwọ́n íṣe, pé a ti sọ nwọ́n di òmìnira kúrò nínú ìmúnisin ọba, tĩ ṣe bàbá òun; nítorípé bàbá òun ti fún òun ní àṣẹ láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, àti gbogbo ilẹ̀ tí ó yíi ká.

22 Ó sì tún fi yé nwọn pé nwọ́n ní ànfàní fún sísin Olúwa Ọlọ́run nwọn gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nwọn, ní ibikíbi tí nwọ́n bá wà, tí ó bá ti jẹ́ orí ilẹ̀ èyítí ó wà lábẹ́ ìjọba ọba Lámónì.

23 Ámọ́nì sì wãsù sí àwọn ènìyàn ọba Lámónì; ó sì ṣe tí ó kọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́ nípa ohun gbogbo nípa òdodo. Ó sì ngbà nwọ́n níyànjú lójojúmọ́, láìsinmi; nwọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, nwọ́n sì fi ìtara pa òfin Ọlọ́run mọ́.