Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 49


Orí 49

Àwọn ará Lámánì ti ngbógun kó lè mú àwọn ìlú-nlá Amonáíhà àti Nóà tí a mọdisí—Amalikíà fi Ọlọ́run bú, ó sì pinnu láti mu ẹ̀jẹ̀ Mórónì—Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ̀síwájú láti mú ìjọ nã lọ́kàn le. Ní ìwọ̀n ọdún 72 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní oṣù kọkànlá ọdún kọkàndínlógún, ní ọjọ́ kẹwa oṣù nã, nwọ́n rí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí nwọ́n nbọ̀wá sínú ilẹ̀ Amonáíhà.

2 Àti kíyèsĩ, nwọ́n ti tún ìlú-nlá nã kọ́, Mórónì sì ti fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan sí àyíká ìlú-nlá nã, nwọ́n sì ti mọ́ ẹrùpẹ̀ jọ yíká láti dãbò bò nwọ́n lọ́wọ́ ọfà àti òkúta kékèké àwọn ará Lámánì; nítorí kíyèsĩ, òkúta kékèké àti ọfà ni nwọ́n fi jà.

3 Ẹ kíyèsĩ, mo sọ wípé nwọ́n ti tún ìlú-nlá Amonáíhà kọ́. Mo wí fún yín, bẹ̃ni, pé nwọn tún apá kan kọ́; àti nítorípé àwọn ará Lámánì ti pa á run ní ìgbà kan rí nítorí àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, nwọ́n rò wípé yíò tún rọrùn fún nwọn láti mú ní ìgbà yĩ.

4 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, báwo ni ìrètí nwọn ti di ṣíṣákì tó; nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì ti mọ́ odi amọ̀ yí ara nwọn ká, èyítí ó ga tóbẹ̃ tí àwọn ará Lámánì kò lè ju àwọn òkúta àti ọfà nwọn bà nwọ́n, bẹ̃ sì ni nwọn kò lè tọ̀ nwọ́n lọ àfi láti ẹnu ọ̀nà nwọn.

5 Nísisìyí ni àkokò yí ẹnu ya àwọn olórí-ológun àgbà àwọn ará Lámánì gidigidi, nítorí ọgbọ́n àwọn ará Nífáì ni ti ìpamọ́ àwọn ibi àbò nwọn.

6 Nísisìyí àwọn olórí àwọn ará Lámánì ti rò wípé, nítorí tí púpọ̀ ní iye nwọn, bẹ̃ni, nwọ́n rò wípé nwọn yíò ní ànfàní láti kọ lù nwọ́n bí nwọn ti í ṣe tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀; bẹ̃ni, nwọ́n si tún ti múrasílẹ̀ pẹ̀lú apata; àti pẹ̀lú ìgbayà-ogun; nwọ́n sì tún ti múrasílẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀wù awọ-ẹran, bẹ̃ni, ẹ̀wù tí ó ki lọ́pọ̀lọpọ̀ láti bò ìhõhò nwọn.

7 Nítorítí nwọ́n sì ti múrasílẹ̀ báyĩ nwọ́n rò wípé nwọn yíò borí àwọn arákùnrin nwọn pẹ̀lú ìrọ̀rùn tí nwọn yíò sì mú nwọn dè nínú àjàgà oko-ẹrú, tàbí kí nwọ́n gba ẹ̀mí nwọn, kí nwọ́n sì pa nwọ́n ní ìpakúpa ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnú nwọn.

8 Ṣùgbọ́n kíyèsí, sí ìyàlẹ́nu nwọn nlá, nwọ́n ti múrasílẹ̀ dè nwọ́n, ní ọ̀nà tí a kò rí rí lãrín àwọn ọmọ Léhì. Nísisìyí, nwọ́n ti múrasílẹ̀ de àwọn ará Lámánì, láti jagun ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Mórónì.

9 O sì ṣe tí àwọn ará Lámánì, tábí àwọn ará Amalikíà, ní ìyàlẹ́nu nlá lórí ìmúrasílẹ̀ fún ogun tí nwọ́n ṣe.

10 Nísisìyí, bí ọba Amalikíà bá ti jáde wá láti inú ilẹ̀ Nífáì, níwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, bóyá yíò ti mú kí àwọn ará Lámánì kọlũ àwọn ará Nífáì nínú ìlú-nlá tí í ṣe Amonáíhà; nítorí ẹ kíyèsĩ, kò kọ̀ bí nwọ́n bá pa àwọn ènìyàn rẹ̀.

11 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Amalikíà kò jáde wá sí ójú ogun tìkararẹ̀. Sì kíyèsĩ, àwọn olórí ogun rẹ̀ àgbà kò kọlũ àwọn ará Nífáì nínú ìlú-nlá tí íṣe Amonáíhà, nítorítí Mórónì ti ṣe àtúntò ìṣàkóso lãrín àwọn ará Nífáì, tóbẹ̃ tí ìrètí àwọn ará Lámánì fi ṣákì nípa ti ibi ìsádi nwọn, tí nwọn kò sì lè kọlũ nwọ́n.

12 Nítorínã nwọ́n pẹ̀hìndà sínú aginjù, nwọ́n sì kó àgọ́ nwọn, nwọ́n sì lọ sí apá ilẹ̀ Nóà, nítorítí nwọ́n rò pé ibẹ̀ ni ó tún dárajù lọ láti kọlũ àwọn ará Nífáì.

13 Nítorítí nwọn kò mọ̀ pé Mórónì ti mọ́ odi yíká, tàbí pé ó ti mọ́ odi yíká fún ì dãbò bò ìlú, fún gbogbo ìlú-nlá tí ó wà ní ilẹ̀ nã àti agbègbè nwọn; nítorínã, nwọ́n kọjá lọ sínú ilẹ̀ Nóà pẹ̀lú ìpinnu tí ó dúró ṣinṣin; bẹ̃ni, àwọn olórí-ogun nwọn àgbà jáde wá nwọ́n sì ṣe ìbúra pé àwọn yíò pa àwọn ará ìlú-nlá nã run.

14 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, sí ìyàlẹnu nwọn nlá, ìlú-nlá Nóà, èyítí ó jẹ́ ibi aláìlágbára tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó sì jẹ́ wípé nísisìyí, nípa àwọn Mórónì, ó ti di alágbára, bẹ̃ni, àní tayọ agbára ìlú-nlá Amonáíhà.

15 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, eleyĩ jẹ́ ohun ọgbọ́n fún Mórónì ní ṣíṣe; nítorípé ó ti ròo wípé nwọn yíò bẹ̀rù ní ìlú-nlá Amonáíhà; àti nítorípé bí ìlú-nlá Nóà ṣe jẹ́ ibi aláìlágbára jùlọ nínú ilẹ̀ nã tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorínã nwọn yíò kọjá lọ síbẹ̀ láti bá nwọn jagun; bẹ̃ sì ni ó rí ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn rẹ.

16 Sì kíyèsĩ, Mórónì ti yan Léhì láti jẹ́ olórí ogun àgbà lé àwọn ọmọ ogun ìlú nlá nã lórí; Léhì yĩ kannã ni ẹnití ó bá àwọn ará Lámánì jà nínú àfonífojì tí ó wà ní apá ilà õrùn odò Sídónì.

17 Àti nísisìyí sì kíyèsĩ ó sì ṣe, nígbàtí àwọn ará Lámánì ti ríi pé Léhì ni í ṣe olórí-ogun ìlú-nlá nã, ìrètí nwọn tún ṣákì, nítorítí nwọn bẹ̀rù Léhì púpọ̀púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn olórí-ogun nwọn àgbà ti búra pẹ̀lú ìbúra láti kọlũ ìlú-nlá nã; nítorínã, nwọn kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn jáde wá.

18 Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì kò lè wọ inú ibi ìsádi ãbò nwọn nípa ọ̀nà míràn bíkòṣe nípa ẹnu-ọ̀nà nítorí ti gíga odi tí nwọ́n ti mọ, àti jíjìn kòtò tí nwọ́n ti wà yíká, àfi bí nwọ́n bá gba ẹnu ọ̀nà.

19 Báyĩ sì ni àwọn ará Nífáì ti ṣe ìmúrasílẹ̀ láti pa gbogbo àwọn tí yíò lépa láti gùnkè láti wọ inú ibi ìsádi nã nípa ọ̀nà míràn, nípa sísọ àwọn òkúta àti ọfà lù nwọ́n.

20 Báyĩ ni nwọ́n ṣe ìmúrasílẹ̀, bẹ̃ni, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun nwọn tí ó lágbára jùlọ, pẹ̀lú idà nwọn àti kànnà-kànnà nwọn, láti ké gbogbo àwọn tí yíò lépa láti wá sí ibi ãbò nwọn lulẹ̀ nípa ibi ọ̀nà àbáwọlé; báyĩ sì ni nwọ́n ṣe ìmúrasílẹ̀ láti dábò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.

21 O sì ṣe tí àwọn olórí-ogun àwọn ará Lámánì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn wá sí ibi ọ̀nà àbáwọlé nã, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bá àwọn ará Nífáì jà, láti lè wọ inú ibi ãbò nwọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n lé nwọn padà ní onírurú ìgbà, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi pa nwọ́n ní ìpakúpa.

22 Nísisìyí nígbàtí nwọ́n ti ríi pé nwọn kò lè borí àwọn ará Nífáì nípa ọ̀nà àbáwọlé nã, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí fọ́ odi nwọn tí nwọ́n mọ́ kí nwọ́n lè la ọ̀nà fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn, kí nwọ́n lè ní ànfàní ọgbọgba láti jà; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nínú ipa yĩ nwọ́n di píparun lọ́wọ́ àwọn òkúta àti ọfà tí nwọ́n sọ lù nwọ́n; àti pé kàkà kí nwọ́n kún àwọn kòtò nwọn pẹ̀lú erùpẹ̀ tí nwọ́n fi mọ́ odi, àwọn òkú ènìyàn àti àwọn tí ó ti fara gbọgbẹ́ ni ó kún nwọn.

23 Báyĩ ni àwọn ará Nífáì ṣe borí àwọn ọ̀tá nwọn; báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì ṣe lépa láti pa àwọn ará Nífáì run títí nwọ́n fi pa àwọn olórí-ogun àgbà nwọn gbogbo; bẹ̃ni, nwọ́n sì pa àwọn ará Lámánì tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún; tí ó sì jẹ́ wípé ní ìdà kejì, kò sí ẹyọ kan nínú àwọn ará Nífáì tí a pa.

24 Àwọn bí ãdọ́ta ni ó fara gbọgbẹ́, àwọn tí ọfà àwọn ará Lámánì bá ní ibi ọ̀nà àbáwọlé, ṣùgbọ́n nwọ́n rí ìdábòbò lọ́wọ́ asà nwọn, àti ìgbàyà-ogun nwọn, àti ìhámọ́ra ìbòri-ogun nwọn, tóbẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé ẹsẹ̀ ni nwọ́n ti gbọgbẹ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyítí ó sì pọ̀ púpọ̀.

25 O sì ṣe, pé nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé nwọ́n ti pa olórí-ogun àgbà nwọn, nwọ́n sá wọ inú aginjù lọ. O sì ṣe tí nwọ́n padà sínú ilẹ̀ Nífáì, láti wí fún ọba nwọn, Amalikíà, ẹnití í ṣe ará Nífáì nípa bíbí rẹ̀, nípa àdánù nlá nwọn.

26 O sì ṣe tí ó bínú gidigidi sí àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorípé kò rí ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣe lórí àwọn ará Nífáì; kò rí nwọn mú dè nínú àjàgà oko-ẹrú.

27 Bẹ̃ni, ó bínú gidigidi, ó sì bú Ọlọ́run, àti Mórónì pẹ̀lú, tí ó sì búra nínú ìbúra pé òun yíò mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀; èyí sì rí bẹ̃ nítorípé Mórónì pa òfin Ọlọ́run mọ́ ní ti mímúrasílẹ̀ fún ãbò àwọn ènìyàn rẹ̀.

28 O sì ṣe, ní ìdà kejì, àwọn ará Nífáì fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run nwọn, nítorí agbára rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ tí ó fi gbà nwọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn.

29 Báyĩ sì ni ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin.

30 Bẹ̃ni, àlãfíà sì wà lãrín nwọn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀síwájú nlá nínú ìjọ-onígbàgbọ́ nã nítorípé nwọ́n fi tọkàn-tọkàn ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyítí Hẹ́lámánì sọ fún nwọn, àti Ṣíblọ́nì, àti Kòríátọ́nì, àti Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn tí a ti yàn nípa ti ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, tí a sì rì wọn bọmi sí ìrònúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, tí a sì ti rán nwọn jáde lọ wãsù lãrín àwọn ènìyàn nã.