Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 27


Orí 27

Olúwa pàṣẹ fún Ámọ́nì pé kí ó kó àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì lọ sí ibi àìléwu—Nígbàtí Ámọ́nì bá Álmà pàdé, ayọ̀ rẹ dáa lágara—Àwọn ará Nífáì fún àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì—A sì npè nwọ́n ní awọn ènìyàn Ámọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì nnì tí nwọ́n ti lọ jagun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì ti ríi pé ohun asán ni láti wá ìparun fún nwọn lẹ́hìn tí nwọ́n ti gbìyànjú púpọ̀púpọ̀ láti pa nwọ́n run, nwọ́n tún padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì.

2 Ó sì ṣe tí àwọn ará Ámálẹ́kì bínú gidigidi, nítorí àdánù nwọn lójú ogun. Nígbàtí nwọ́n sì ríi pé nwọn kò lè gbẹ̀san lára àwọn ará Nífáì, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí rú àwọn ènìyàn nã sókè ní ìbínú sí àwọn arákùnrin wọn, àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n run.

3 Nísisìyí àwọn ènìyàn yí tún kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun nwọn, nwọ́n sì jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ fún pípa ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-inú àwọn ọ̀tá nwọn.

4 Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ rí iṣẹ́ ìparun yí lãrín àwọn tí wọ́n fẹ́ràn púpọ̀púpọ̀, àti lãrín àwọn tí ó fẹ́ràn nwọn púpọ̀púpọ̀—nítorítí nwọ́n hùwà sí nwọn bí pé ángẹ́lì tí Ọlọ́run rán sí nwọn láti gbà nwọ́n lọ́wọ́ ìparun ayérayé—nítorínã, nígbàtí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ rí iṣẹ́ ìparun nlá yĩ, nwọ kún fún ọ̀pọ̀ ãnú, nwọ́n sì wí fún ọba pé:

5 Ẹ jẹ́ kí a kó àwọn ènìyàn Olúwa wọ̀nyí jọ, kí àwa sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa àwọn ará Nífáì, kí àwa sì sálọ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, kí àwa má bá ṣègbé.

6 Ṣùgbọ́n ọba wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì yíò pa wá run, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpànìyàn àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ èyítí àwa ti hù sí wọn.

7 Ámọ́nì sì wípé: Èmi yíò lọ ṣe ìwádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, bí òun bá sì sọ fún wa pé kí a kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa, njẹ́ ẹ̀yin ó lọ bí?

8 Ọba sì wí fún un pé: Bẹ̃ni, bí Olúwa bá wí fún wa pé kí a lọ, àwa yíò kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwa yíò sì jẹ́ ẹrú fún nwọn, títí àwa yíò fi ṣe àtúnṣe pẹ̀lú nwọn lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpànìyàn àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ èyítí àwa ti hù sí nwọn.

9 Ṣugbọ́n Ámọ́nì wí fún pé: Ó tako òfin àwọn arákùnrin wa, èyítí bàbá mi fi lẹ́lẹ̀, pé kí ẹrú ó wà lãrín nwọn; nítorínã, ẹ jẹ́ kí àwa ó kọjá lọ kí àwa sì gbẹ́kẹ̀lé ãnú àwọn arákùnrin wa.

10 Ṣùgbọ́n ọba nã wí fún un pe: Wádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, bí òun bá sì wí fún wa pé kí a lọ, àwa yíò lọ; bíkòjẹ́bẹ̃, àwa yíò ṣègbé ní ilẹ̀ nã.

11 Ó sì ṣe, tí Ámọ́nì lọ ó sì wádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí fún un pé:

12 Kó àwọn ènìyàn yĩ jáde kúrò ní ilẹ̀ yĩ, kí nwọn má bã ṣègbé; nítorítí Sátánì ti gba ọkàn àwọn ará Ámálẹ́kì, tí nwọ́n nrú àwọn ará Lámánì lọ́kàn sókè ní ìbínú sí àwọn arákùnrin nwọn láti pa nwọ́n; nítorínã ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ yĩ; alábùkún-fún sì ni àwọn ènìyàn yĩ ní ìran yĩ, nítorítí èmi yíò pa nwọ́n mọ́.

13 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Ámọ́nì lọ tí ó sì sọ fún ọba gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún un.

14 Nwọ́n sì kó gogbo àwọn ènìyàn nwọn jọ, bẹ̃ni, gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa, nwọ́n sì kó gbogbo agbo àti ọ̀wọ́ ẹran nwọn jọ, nwọ́n sì jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, nwọ́n sì dé inú aginjù èyítí ó pãlà ilẹ̀ Nífáì àti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì bọ́ sí agbègbè ìhà ilẹ̀ nã.

15 Ó sì ṣe tí Ámọ́nì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi yíò kọjá lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ẹ̀yin yíò sí dúró níbíyĩ títí àwa ó fi padà wá; àwa yíò sì mọ̀ bí ọkàn àwọn arákùnrin wa ṣe rí, bí nwọ́n bá ní ìfẹ́ pé kí ẹ̀yin kí ó wọ inú ilẹ̀ nwọn.

16 Ó sì ṣe bí Ámọ́nì ṣe nkọjá lọ sínú ilẹ̀ nã, tí òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pàdé Álmà, ní ibi èyítí a ti sọ nípa rẹ̀ ṣãjú; sì wõ ìpàdé ayọ̀ ni eleyĩ jẹ́.

17 Nísisìyí ayọ̀ Ámọ́nì pọ̀ púpọ̀ tí ó kún rẹ́rẹ́; bẹ̃ ni, ayọ̀ nínú Ọlọ́run rẹ̀ gbée mì, àní títí ó fi dáa lágara; ó sì tún ṣubú lulẹ̀.

18 Nísisìyí njẹ́ eleyĩ kĩ ṣe ayọ̀ tí ó tayọ bí? Ẹ kíyèsĩ, èyí ni ayọ̀ tí ẹnìkan kò lè rí gbà bíkòṣe onírònúpìwàdà tõtọ́ àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ènìyàn tíi lépa àlãfíà.

19 Nísisìyí ayọ̀ Álmà pọ̀ púpọ̀ fún pípàdé àwọn arákùnrin rẹ̀, bákannã ni ayọ̀ Áárọ́nì, àti Òmnérì, àti Hímnì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ayọ̀ nwọn kò tó láti tayọ agbára nwọn.

20 Àti nísisìyí ó sì tún ṣe tí Álmà kó àwọn arákùnrin rẹ̀ padà lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; àní lọ sínú ilé rẹ̀. Nwọ́n sì lọ sọ fún adájọ́ àgbà àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn ní ilẹ̀ Nífáì, lãrín àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì.

21 Ó sì ṣe tí adájọ́ àgbà nã fi ìkéde ránṣẹ́ jákè-jádò orílẹ̀-èdè nã, láti mọ́ ohùn àwọn ènìyàn nã nípa gbígba àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọn í ṣe ará Kòṣe-Nífáì-Léhì.

22 Ó sì ṣe tí ohùn àwọn ènìyàn nã dé, wípé: Kíyèsĩ, àwa yíò yọ̃da ilẹ̀ nã ti Jẹ́ṣónì, èyítí ó wà ní apá ìlà-oòrùn lẹ́bã òkun, èyítí ó so mọ́ ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, èyítí ó wà ní apá gũsù ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; ilẹ̀ Jẹ́ṣónì yĩ sì ni àwa yíò yọ̃da fún àwọn arákùnrin wa fún ìjogún.

23 Sì kíyèsĩ, àwa yíò fi àwọn ọmọ ogun wa sí ãrin ilẹ̀ Jẹ́ṣónì àti ilẹ̀ Nífáì kí àwa kí ó lè dãbò bò àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì; èyí ni àwa sì ṣe fún àwọn arákùnrin wa, nítorípé nwọ́n bẹ̀rù, láti gbé ohun-ìjà ogun ti àwọn arákùnrin nwọn kí nwọn má bã dẹ́ṣẹ̀; ẹ̀rù nlá nwọn yĩ sì nbẹ nítorí ìrònúpìwàdà púpọ̀ tí nwọ́n ní, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpànìyàn àti ìwà búburú jọjọ tí nwọ́n ti hù.

24 Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa yíò ṣe èyí fún àwọn arákùnrin wa, kí nwọ́n lè jogún ilẹ̀ Jẹ́ṣónì; àwa yíò sì fi àwọn ọmọ ogun wa dãbò bò nwọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, bí nwọ́n bá ti lè fún wa nínú ohun ìní nwọn fún ìrànlọ́wọ́ fún wa láti lè tọ́jú àwọn ọmọ ogun wa.

25 Nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí Ámọ́nì ti gbọ́ eleyĩ, ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì, àti Álmà pẹ̀lú rẹ̀, sínú aginjù, níbití nwọ́n ti pàgọ́ nwọn sí, nwọ́n sì sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún nwọn, Álmà sì tún sọ fún nwọn nípa ti ìyílọ́kànpadà rẹ̀, àti ti Ámọ́nì àti Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.

26 Ó sì ṣe tí gbogbo nkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ayọ̀ nlá lãrín nwọn. Nwọ́n sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, nwọ́n sì ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì nã ní ìní; àwọn ará Nífáì sì npè nwọ́n ní àwọn ènìyàn Ámọ́nì; nítorínã, orúkọ nã ni a fi mọ̀ nwọ́n láti ìgbà yĩ lọ.

27 Nwọ́n sì wà lãrín àwọn ará Nífáì, a sì kà nwọ́n mọ́ àwọn ènìyàn tí í ṣe ti ìjọ-Ọlọ́run pẹ̀lú. A sì tún mọ̀ nwọ́n fún ìtara nwọn sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn; nítorítí nwọ́n jẹ́ olótĩtọ́ àti ẹni-dídúróṣinṣin nínú ohun gbogbo; nwọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ Krístì, àní títí dé òpin.

28 Nwọ́n sì ka ìtàjẹ̀sílẹ̀ arákùnrin wọn sí ohun-ìkórira nlá; ẹnìkẹ́ni kò sì lè yí nwọn lọ́kàn padà láti gbé ohun-ìjà ogun ti àwọn ènìyàn wọn; nwọn kò sì ka ikú sí ohun ìbẹ̀rù rárá, nítorí ìrètí nwọn àti ìmọ̀ nwọn nípa Krístì àti àjĩnde; nítorínã, ikú ti di gbígbé mì fún nwọn nípasẹ̀ ìṣẹ́gun Krístì lórí rẹ̀.

29 Nítorínã, nwọn yíò faradà ìyà ikú ní ọ̀nà tí ó pọ́n-ni-lójú àti èyítí ó burú jùlọ tí àwọn arákùnrin nwọn lè fi jẹ nwọ́n, kí nwọn ó tó gbé idà tàbí ohun-ìjà ogun míràn láti bá nwọn jà.

30 Báyĩ ni ó sì rí, tí nwọ́n jẹ́ onítara ènìyàn àti ẹni-àyànfẹ́, tí nwọ́n sì rí ọ̀pọ̀ ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.