Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 53


Orí 53

Àwọn ará Lámánì tí nwọn kó lẹ́rú ni nwọ́n lò láti mọ́ odi yí ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀—Àwọn ìyapa lãrín àwọn ará Nífáì mú kí àwọn ará Lámánì ní ìṣẹ́gun—Hẹ́lámánì di olùdarí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹgbẹ̀rún méjì ti àwọn ènìyàn Ámọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 64 sí 63 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí nwọ́n fi àwọn ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ àwọn ará Lámánì nã tí nwọ́n kó lẹ́rú, tí nwọ́n sì pã láṣẹ fún nwọn láti jáde lọ kí nwọ́n sì sin àwọn òkú ara nwọn, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú àwọn òkú àwọn ará Nífáì tí a ti pa; Mórónì sì fi àwọn ènìyàn tì nwọ́n láti máa ṣọ́ nwọn bí nwọ́n ṣe nṣiṣẹ́ nwọn gbogbo.

2 Mórónì sì lọ sí ìlú-nlá Múlẹ́kì pẹ̀lú Léhì, ó sì gba àkóso ìlú-nlá nã ó sì fi lé ọwọ́ Léhì. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, Léhì yí jẹ́ ẹnití ó ti wà pẹ̀lú Mórónì ní ìgbà púpọ̀ nínú àwọn ogun tí ó jà; ó sì jẹ́ ẹnìkan tí ó dàbí Mórónì, nwọ́n sì yọ̀ nínú ìwàlálãfíà àwọn ara nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n fẹ́ràn ara nwọn, gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì ni ó sì fẹ́ràn nwọn.

3 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ará Lámánì ti sin àwọn ẹnití ó kú nínú àwọn ará wọn àti àwọn ará Nífáì tán, a dá nwọ́n padà lọ sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; tí Tíákúmì, nípa àṣẹ Mórónì, sì mú kí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ nípa gbígbẹ́ ọ̀gbun yí ilẹ̀ nã ká tàbí pé ìlú-nlá nnì, Ibi-Ọ̀pọ̀.

4 Ó sì mú kí nwọn kọ́ ọgbà tí a fi igi rírẹ́ ṣe sí ọwọ́ inú ọ̀gbun nã; nwọn sì kó amọ̀ ti ọgbà nã èyítí nwọn fi igi rírẹ́ ṣe; báyĩ sì ni nwọ́n ṣe mú àwọn ará Lámánì nã ṣiṣẹ́ títí nwọ́n fi yí ìlú-nlá nnì Ibi-Ọ̀pọ̀ ká kiri pẹ̀lú odi tí ó lágbára tí nwọ́n mọ́ pẹ̀lú igi rírẹ́ àti amọ̀, tí ó sì ga sókè lọ́pọ̀lọpọ̀.

5 Ìlú-nlá yí sì di ibi ìsádi láti ìgbà yí lọ títí; nínú ìlú-nlá yĩ ni nwọ́n sì ti nṣọ́ àwọn ará Lámánì tí nwọ́n kó lẹ́rú; bẹ̃ni, àní nínú odi tí nwọn ti mú kí nwọn ó kọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara nwọn. Nísisìyí Mórónì níláti mú àwọn ará Lámánì ṣiṣẹ́, nítorípé ó rọrùn láti ṣọ́ nwọn bí nwọ́n bá nṣiṣẹ́; ó sì fẹ́ kí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pé nígbàtí òun yíò bá kọlu àwọn ará Lámánì nã.

6 Ó sì ṣe tí Mórónì nípa ṣíṣe báyĩ ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí ó lágbára jùlọ, tí ó sì ti gba ìlú-nlá Múlẹ́kì, èyítí íṣe ọ̀kan nínú àwọn tí ó lágbára jùlọ nínú àwọn ìlú-nlá àwọn ará Lámánì nínú ilẹ̀ àwọn ará Nífáì; báyĩ nã ni a sì ṣe kọ́ ibi ìsádi pẹ̀lú láti kó àwọn ẹrú rẹ̀ sí.

7 Ó sì ṣe tí kò lépa láti bá àwọn ará Lámánì jagun mọ́ nínú ọdún nã, ṣùgbọ́n ó mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun, bẹ̃ni, àti pé kí nwọn ó ṣe ìgbáradì sílẹ̀ de àwọn ará Lámánì, bẹ̃ni, àti lati gba àwọn obìnrin nwọn àti àwọn ọmọ nwọn lọ́wọ́ ìyàn àti ìpọ́njú, àti pípèsè oúnjẹ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn.

8 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, ní ẹ̀gbẹ́ òkun tí ó wà ní apá ìwọ oòrùn, tí ó wà ní apá gúsù nígbàtí Mórónì kò sí lãrín nwọn, tí àwọn ará Nífáì kan sì dìtẹ̀, èyítí ó fa ìyapa lãrín nwọn, tí nwọ́n sì ti gbà nínú ilẹ̀ àwọn ará Nífáì, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n ti gbà nínú àwọn ìlú-nlá nwọn tí ó wà ní apá ilẹ̀ nã.

9 Báyĩ sì ni ó rí nítorí ti àìṣedẽdé tí ó wà lãrín nwọn, bẹ̃ni, nítorí ìyapa àti ọ̀tẹ̀ lãrín ara nwọn, nwọ́n bọ́ sínú ipò tí ó léwu púpọ̀ jùlọ.

10 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo ní ohun kan tí èmi yíò sọ nípa àwọn ènìyàn Ámọ́nì, ní ìbẹ̀rẹ̀, ará Lámánì ni nwọn í ṣe; ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí pé nípasẹ̀ agbára àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ti yí nwọn padà sí ọ́dọ̀ Olúwa; a sì ti mú nwọn wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí àwọn ará Nífáì sì ti ndãbò bò nwọ́n láti ìgbà nã.

11 Àti nítorí ti májẹ̀mú nwọn, nwọ́n ti yẹra fún gbígbé ohun ìjà-ogun ní ìdojúkọ àwọn arákùnrin nwọn; nítorítí nwọ́n ti dá májẹ̀mú pé àwọn kò ní tàjẹ̀sílẹ̀ mọ́ láé; àti pé ní ìbámu pẹ̀lú májẹ̀mú nwọn, nwọn iba ti parun; bẹ̃ni, nwọn iba ti gbà kí nwọ́n ṣubú sí ọ́wọ́ àwọn arákùnrin nwọn, bí kò bá ṣe ti ãnú àti ìfẹ́ nlá ti Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní fún nwọn.

12 Nítorí ìdí èyí ni nwọ́n sì ṣe mú nwọn jáde wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; tí nwọ́n sì ti nrí ìdãbò bò àwọn ará Nífáì láti ìgbà nã.

13 Ṣùgbọ́n ó ṣe nígbàtí nwọ́n rí ewu nã, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú àti wàhálà tí àwọn ará Nífáì faradà nítorí nwọn, ãnú ṣe nwọ́n, nwọ́n sì ní ìfẹ́ láti gbé ohun ìjà-ogun fún ìdãbò orílẹ̀-èdè nwọn.

14 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ní kété tí nwọn fẹ́ gbé àwọn ohun ìjà ogun nwọn, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ yí nwọn lọ́kàn padà, nítorítí nwọn ṣetán láti sẹ́ májẹ̀mú tí nwọ́n ti dá.

15 Hẹ́lámánì sì bẹ̀rù pé bí nwọ́n bá ṣe báyĩ nwọn yíò sọ ẹ̀mí nwọn nù; nítorínã gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ti dá májẹ̀mú yĩ ni nwọ́n níláti máa wo àwọn arákùnrin nwọn bí nwọ́n ṣe nla ipọ́njú wọn kojá, nínú ipò ewu tí nwọ́n wà ní àkokò yĩ.

16 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí nwọ́n ní àwọn ọmọkùnrin púpọ̀, tí nwọn kò tĩ dá májẹ̀mú nã pé àwọn kò ní gbé ohun ìjà-ogun láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; nítorínã nwọn kó ara nwọn jọ ní àkokò yĩ, gbogbo àwọn tí ó lè gbé ohun ìjà-ogun, nwọn sì pe ara nwọn ní ará Nífáì.

17 Nwọ́n sì dá májẹ̀mú pé àwọn yíò jà fún òmìnira àwọn ará Nífáì, bẹ̃ni, láti dãbò bò ilẹ̀ nã, sí fifi ẹmí nwọn lelẹ; bẹ̃ni, àní nwọ́n dá májẹ̀mú pé àwọn kò ní jọ̀wọ́ òmìnira nwọn láéláé, ṣùgbọ́n àwọn yíò jà lórí ohun gbogbo láti dãbò bò àwọn ará Nífáì àti ara nwọn kúrò nínú oko-ẹrú.

18 Nísisìyí kíyèsĩ, ẹgbẹ̀rún méjì ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nnì í ṣe, tí nwọ́n dá májẹ̀mú yĩ tí nwọ́n sì gbé ohun ìjà-ogun nwọn láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn.

19 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí ó ti jẹ́ wípé nwọ́n kò mú ídíwọ́ bá àwọn ará Nífáì látẹ̀hìnwá, nísisìyí nwọ́n tún jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nlá ni àkókò yĩ; nítorítí nwọ́n gbé ohun ìjà-ogun nwọn, nwọ́n sì fẹ́ kí Hẹ́lámánì jẹ́ olórí nwọn.

20 Ọ̀dọ́mọkùnrin sì ni gbogbo nwọn í ṣe nwọ́n sì jẹ́ akíkanjú nínú ìgboyà, àti nínú agbára àti ìṣe; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, eleyĩ nìkan kọ́—nwọ́n jẹ́ olõtọ́ ní gbogbo ìgbà nínú ohunkóhun tí nwọ́n bá fi lé nwọn lọ́wọ́.

21 Bẹ̃ni, nwọ́n jẹ́ ẹni olótĩtọ́ àti aláìrékọjá, nítorítí a ti kọ́ nwọn láti pa òfin Ọlọ́run mọ́ àti láti máa rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú rẹ̀.

22 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Hẹ́lámánì lọ níwájú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún méjì rẹ̀, fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ó wà níbi ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù ní ẹ̀gbẹ́ òkun apá ìwọ̀-oòrùn.

23 Báyĩ sì ni ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin.