Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 41


Orí 41

Ní àjĩnde nã àwọn ènìyàn yíò jáde sínú ipò ayọ̀ aláìlópin tàbí ìbànújẹ́ aláìlópin—Ìwà búburú kò jẹ́ inú dídùn rí—Àwọn ènìyàn nipa ti ara wà láìní Ọlọ́run nínú ayé yĩ—Ní ìgbà ìmúpadàbọ̀sípò, olúkúlùkù yíò tún gba àwọn ìwà àti ìmọ̀ tí ó ti ní ní ìní nígbà ayé rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo ní ohun kan láti sọ nípa ìmúpadàbọ̀sípò nípa èyítí mo ti sọ ṣãjú; nítorípé kíyèsĩ, àwọn míràn ti yí ọ̀rọ̀ ìwé-mímọ́ po, nwọn sì ti kùnà púpọ̀ nítorínã. Èmi sì wòye pé ọkàn rẹ dãmú pẹ̀lú nípa ohun yĩ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi yíò ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.

2 Mo wí fún ọ, ọmọ mi, pé ìlànà ìmúpadàbọ̀sípò nã wà ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run; nítorípé ohun tí ó yẹ ni kí a mú ohun gbogbo padàbọ̀sípò nwọn dáradára. Kíyèsĩ, ó yẹ ó sì tọ́, ní ìbámu pẹ̀lú agbára àti àjĩnde Krístì, pé kí a mú ọkàn ènìyàn padàbọ̀sípò pẹ̀lú ara rẹ̀, àti pé kí a mú gbogbo ẹ̀yà ara padàbọ̀sípò pẹ̀lú ara rẹ̀.

3 Ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run pé kí àwọn ènìyàn gba ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn; bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn ní ayé yĩ bá sì jẹ́ rere, tí ìfẹ́-inú ọkàn nwọn bá sì jẹ́ rere, ní ọjọ́ ìkẹhìn, a ó sì mú nwọn padàbọ̀sípò sínú èyítí ó jẹ́ rere.

4 Bí iṣẹ́ nwọn bá sì jẹ́ búburú, a ó ṣe ìmúpadàbọ̀sípò fún nwọn sí búburú. Nítorínã, ohun gbogbo ni a ó mú padàbọ̀sípò sí ipa nwọn bí ó ti yẹ, ohun gbogbo sí ẹ̀yà àdánidá rẹ̀—gbé ikú dìde sí àìkú, ìdibàjẹ́ sí àìdibàjẹ́—tí a ó gbé e dìde sí ayọ̀ tí kò lópin láti jogún ìjọba Ọlọ́run, tàbí sí ìbànújẹ́ tí kò lópin láti jogún ìjọba ti èṣù, ọ̀kan ní apá kan, ìkejì ní apá kejì—

5 Èyítí a gbé dìde sínú ayọ̀ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀ fún ayọ̀, tàbí rere gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀ fún rere; àti èyí kejì sí búburú gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀ fún búburú; nítorípé gẹ́gẹ́bí ó ti ni ìfẹ́ fún ṣíṣe búburú ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, bẹ̃ nã ni yíò rí ẹ̀san búburú nígbàtí alẹ́ bá dé.

6 Bákannã ní ó sì rí ni ọ̀nà kéjì. Bí òun bá ti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì lépa òdodo títí di òpin ọjọ́ ayé rẹ̀, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni yíò rí ẹ̀san sí ti òdodo.

7 Àwọn yìi ni àwọn tí Olúwa ti ràpadà; bẹ̃ni àwọn yĩ ni àwọn tí a ti yọ jáde, tí a ti yọ kúrò nínú ìgbà àṣálẹ́ aláìlópin nnì; bẹ̃sì ni nwọn yíò dúró tàbí kí nwọn ṣubú; nítorí kíyèsĩ, onídàjọ́ ara nwọn ni nwọ́n jẹ́, bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú.

8 Báyĩ, àṣẹ Ọlọ́run wà láìyípadà; nítorínã, a ti pèsè ọ̀nà nã sílẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ lè rìn nínú rẹ̀ kí a sì gbã là.

9 Àti nísisìyí kíyèsĩ, ọmọ mi, máṣe dáwọ́lé ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ sí Ọlọ́run rẹ nípa ti àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ mímọ́, èyítí ìwọ ti dáwọ́lé láti dẹ́ṣẹ̀ títí di àkokò yĩ.

10 Máṣe rò wípé, nítorípé a ti sọ̀rọ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò, pé a ó mú ọ padàbọ̀sípò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ sínú ìdùnú. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, ìwà búburú kò jẹ́ inú dídùn rí.

11 Àti nísisìyí, ọmọ mi, gbogbo ènìyàn tí ó bá wà ní ipò ẹni àdánidá ti ayé, tàbí kí nwípé, nínú ipò ara, wà nínú ipò ìkorò òrõró àti nínú ìgbèkùn àìṣedẽdé; nwọ́n wà láìní Ọlọ́run nínú ayé yĩ, nwọ́n sì ti wà ní ìlòdìsí ìwà-bí-Ọlọ́run; nítorínã, wọ́n wà ní ipò tí ó lòdì sí ìwà inú dídùn.

12 Àti nísisìyí kíyèsĩ, njẹ́ ìtumọ̀sí ọ̀rọ̀ nã tí à npè ní ìmúpadàbọ̀sípò ha í ṣe pé kí a mú ohun tí ó wà ní ipò àdánidá ara ti ayé kí a sì fi sí ipò ti kĩ ṣe àdánidá, tàbí pé kí a fi sí ipò tí ó tako ti àdánidá rẹ̀?

13 A!, ọmọ mi, èyí kò rí bẹ̃; ṣùgbọ́n ìtumọ̀sí ọ̀rọ̀ nã tí à npè ní ìmúpadàbọ̀sípò ni pé kí a mú búburú fún èyí tí íṣe búburú, tàbí ti ara fún ti ara, tàbí ti èṣù fún ẹni ti èṣù—rere fún èyítí í ṣe rere; òdodo fún èyítí íṣe òdodo; ohun ti o tọ́ fún èyítí ó tọ́, ãnú fún èyítí íṣe ãnú.

14 Nítorínã, ọmọ mi, ríi pé o jẹ́ alãnú sí àwọn arákùnrin rẹ; ṣe èyítí ó tọ́, ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì máa ṣe rere títí lọ; bí ìwọ bá sì ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí ìgbànã ni ìwọ yíò gba èrè rẹ; bẹ̃ni, ìwọ yíò tún rí ìmúpadàbọ̀sípò ãnú gba; ìwọ yíò tún rí ìmúpadàbọ̀sípò àìṣègbè gbà; ìwọ yíò tún rí ìmúpadàbọ̀sípò ìdájọ́ gbà; ìwọ yìó tún rí ẹ̀san rere gbà padà.

15 Nítorípé ohun èyítí ìwọ bá fi ránṣẹ́ síta yíò tún padà sọ́dọ̀ rẹ, tí yíò sì di ìmúpadàbọ̀sípò; nítorínã, ọ̀rọ̀ nã tí à npè ní ìmúpadàbọ̀sípò dá ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi púpọ̀ síi, kò sì dáa láre rárá.