Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 12


Orí 12

Álmà bá Sísrọ́mù jà—Àwọn olótĩtọ́ níkan ni a lè fún ní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run—A ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí èrò, ìgbàgbọ́, ọ̀rọ̀ àti ìṣe nwọn—Àwọn ènìyàn búburú yíò gba èrè ikú ẹ̀mí—Ìpò ayé yĩ jẹ́ ti ìdánwò—Ìlànà ìràpadà mú àjĩnde nã wá, àti nípa ìgbàgbọ́, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀—Ẹnití ó bá ronúpìwàdà yíò rí ãnú gbà nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí nígbàtí Álmà ríi pé ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì ti pa Sísrọ́mù lẹ́nu mọ́, nítorítí ó wòye pé Ámúlẹ́kì ti já ọgbọ́n irọ́ àti ẹ̀tàn rẹ̀ láti pa á run, tí ó sì ríi pé ó bẹ̀rẹ̀sĩ wá rìrì nínú ipò ẹ̀bi rẹ̀, ó la ẹnu rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀sí bã sọ̀rọ̀, àti láti fi ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì mulẹ̀, àti láti se àlàyé ohun gbogbo, láti se àlàyé àwọn ìwé-mímọ́ síwájú síi, ju èyítí Ámúlẹ́kì ti ṣe.

2 Nísisìyí àwọn ọ̀rọ̀ tí Álmà sọ fún Sísrọ́mù dé etí àwọn ènìyàn yí kãkiri; nítorítí ọ̀gọ̃rọ̀ àwọn ènìyàn nã pọ̀ púpọ̀, ó sì sọ̀rọ̀ báyĩ:

3 Nísisìyí Sísrọ́mù, ìwọ ríi pé a ti mú ọ nínú irọ́ àti ọgbọ́n àrékérekè rẹ, nítorítí ìwọ ko purọ́ fún ènìyàn nìkan ṣùgbọ́n ìwọ ti purọ́ fún Ọlọ́run; nítorí kíyèsĩ, ó mọ̀ gbogbo èrò ọkàn rẹ, ìwọ sì ríi pé gbogbo èrò ọkàn rẹ ni Ẹ̀mí rẹ̀ ti fi hàn wá;

4 Ìwọ sì ti rí i pé àwa mọ̀ pé ète rẹ jẹ́ àrékérekè, gẹ́gẹ́bí ti èṣù, láti purọ́ kí ó sì tan àwọn ènìyàn yí pé kí ìwọ lè gbé nwọn takò wá, láti pẹ̀gàn wa, kí nwọ́n sì lé wá jáde—

5 Nísisìyí èyí sì jẹ́ ète ọ̀tá rẹ nnì, tí òun sì ti lo agbára rẹ̀ nínú rẹ. Nísisìyí, èmi ní ìfẹ́ pé kí ìwọ ó rántí pé ohun tí èmi bá ọ sọ, èmi sọọ́ fún ènìyàn gbogbo.

6 Sì kíyèsĩ, èmi wí fún gbogbo yín pé èyí yĩ jẹ́ ikẹkun ọ̀tá nnì, èyítí ó ti dẹ sílẹ̀ láti mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti mú yín wá sí abẹ́ rẹ̀, pé kí ó lè fi ìdè rẹ̀ so yín yíká, pé kí òun kí ó sì so ọ́ mọ́lẹ̀ títí fi dé ìparun ayérayé, gẹ́gẹ́bí agbára ìgbèkun rẹ̀.

7 Nísisìyí Álmà sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Sísrọ́mù bẹ̀rẹ̀sí gbọ̀n lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorítí ó ti gba ìdánilójú agbára Ọlọ́run púpọ̀púpọ̀; ó sì ti ní ìdánilójú wípé Álmà àti Ámúlẹ́kì ní ìmọ̀ nípa òun, nítorítí ó ní ìdánilójú wípé nwọn mọ́ èrò àti ète ọkàn òun; nítorítí a fún nwọn ní agbára kí nwọ́n lè mọ́ ohun wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí ti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀.

8 Sísrọ́mù sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìwádí tọkàn-tọkàn lọ́wọ́ nwọn, kí òun lè ní ìmọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Ó sì wí fún Álmà: Kíni ìtumọ̀ èyí tí Ámúlẹ́kì ti wí nípa àjĩnde òkú, pé gbogbo ènìyàn yíò jínde kúrò nínú ipò òkú, àwọn tí ó jẹ́ ẹni tí ó tọ àti àwọn ẹni aláìtọ́, tí a ó sì mú wọn dúró níwájú Ọlọ́run fún ìdájọ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ ọwọ́ nwọn.

9 Àti nísisìyí, Álmà bẹ̀rẹ̀sí ṣe àlàyé àwọn ohun wọ̀nyí fún un pé: A fi fún ọ̀pọ̀ láti mọ́ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a fi nwọ́n sí abẹ́ òfin tí ó múná pé nwọn kò gbọ́dọ̀ fi nwọ́n hàn àfi gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ èyítí ó bá gbà fún àwọn ọmọ ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ìgbọ́ran àti ìtẹramọ́ èyítí nwọ́n bá fi fún un.

10 Nítorínã, ẹnití ó bá sé àyà rẹ le, èyĩ yí ni yíò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àìkún; ẹnití kò bá sì sé àyà rẹ le, òun ni a ó fún ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ nã, títí a ó fi fún un ní ìmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, títí yíò fi mọ̀ nwọ́n ní kíkún.

11 Àwọn tí nwọn bá sì sé àyà nwọn le, àwọn ni a ó fún ní àìkún ọ̀rọ̀ nã, títí tí nwọn kò lè mọ́ ohunkóhun nípa ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀; tí a ó sì mú nwọn ní ìgbèkùn sí ipa èṣù, tí a ó sì tọ́ nwọ́n nípa ìfẹ́ rẹ̀ sí ìhà ìparun. Nísisìyí, èyí ni à npè ní ìdè ẹ̀wọ̀n ọ̀run àpãdì.

12 Ámúlẹ́kì sì ti sọ̀rọ̀ ní pàtó nípa ikú, àti àjĩnde kúrò ní ipò ikú sí ipò àìkú, àti mímú ènìyàn wá sí iwájú itẹ Ọlọ́run, láti dá lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wa.

13 Bí ọkàn wa bá sì ti sé le, bẹ̃ni, bí àwa bá ti sé ọkàn wa le sí ọ̀rọ̀ nã, tí kò sì sí nínú wa, bẹ̃ sì ni ipò wa yíò sì di ẹni ìdálẹ́bi.

14 Nítorítí ọ̀rọ̀ wa yíò dá wa lẹ́bi, bẹ̃ni gbogbo ìṣẹ wa ni yíò dá wa lẹ́bi; àwa kò ní wà láìlábàwọ́n; àwọn èrò ọkàn wa yíò sì dá wa lẹ́bi pẹ̀lú; nínú ipò búburú yĩ àwa kì yíò lè gbé ojú sókè wo Ọlọ́run; àwa yíò sì kún fún ayọ̀ tí àwa bá pàṣẹ fún àpáta àti àwọn òkè pé kí nwọ́n wó lù wá, kí àwa lè sá pamọ́ kúrò níwájú rẹ̀.

15 Ṣùgbọ́n, èyí kò lè rí bẹ̃; a níláti jáde wá, kí a dúró níwájú rẹ̀ nínú ògo rẹ̀, àti nínú agbára rẹ̀, àti nínú títóbi rẹ̀, àti ọlá-nlá àti ìjọba rẹ̀, tí yíò sì fi ìtìjú wa hàn títí ayé pé o tọ́ ni ìdájọ́ rẹ̀; pé òun tọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, àti pé òun nṣãnú fún àwọn ọmọ ènìyàn gbogbo, àti pé òun ní agbára láti gba ẹnìkẹ́ni tí ó bá gba orúkọ òun gbọ́, tí ó sì nṣe iṣẹ́ èyítí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.

16 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé lẹ́hìn èyí ni ikú, àní ikú kejì èyítí íṣe ikú ti ẹ̀mí; èyítí íṣe àkokò tí ẹnikẹni tí ó bá kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nípa ikú ti ara, yíò kú ikú ti ẹ̀mí pẹ̀lú; bẹ̃ni, yíò kú níti àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òdodo.

17 Èyĩ ni ìgbà nã tí ìrora nwọn yíò dàbĩ ti adágún iná àti imí ọjọ́, ọ̀wọ́ iná èyítí ó nru sókè láé àti láéláé nígbànã ni a ó gbé nwọn dè mọ́lẹ̀ sí ìparun àìlópin, gẹ́gẹ́bí agbára àti ìgbèkun Sátánì, ẹnití ó ti tẹ̀ nwọ́n bá sí ìfẹ́ẹ rẹ̀.

18 Ní ìgbà nã mo wí fún yín, nwọn yíò wà bí ẹni pé a kò ṣe ìràpadà; nítorípé a kò lè rà nwọ́n padà, ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run; nwọn kò sì lè kú, nítorípé kò sí ìdibàjẹ́ mọ́.

19 Nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí Álmà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ, ẹnu túbọ̀ ya àwọn ènìyàn nã síi;

20 Ṣùgbọ́n ẹnìkan wà tí à npè ní Ántíónà, ẹnití ó jẹ́ alákõso àgbà lãrin nwọn, ó jáde ó sì wí fún un pé: Kíni èyí tí ìwọ wí, pé ènìyàn yíò dìde kúrò ní ipò òkú tí yíò sì yípadà kúrò ní ipò-òkú ara yĩ sí ipò-àìkú, pé ẹ̀mí kò lè kú?

21 Kíni ìwé-mímọ́ túmọ̀ sí, èyítí ó sọ wípé Ọlọ́run fi kérúbímù pẹ̀lú idà iná sí apá ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì, kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ máṣe wọ inú ibẹ̀ kí nwọ́n sì jẹ nínú èso igi ìyè nã, kí nwọn sì wà títí láéláé? Àwa sì ríi pé kò sí ọ̀nà tí nwọ́n fi lé wa títí láéláé.

22 Nísisìyí, Álmà wí fún un pé: Èyí ni ohun tí èmi ṣetán láti ṣe àlàyé rẹ̀. Nísisìyí àwa ríi pé Ádámù ṣubú nípa jíjẹ nínú èso àìgbọdọ̀jẹ jẹ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; báyĩ ni àwa sì ríi, pé nípa ìṣubú rẹ̀, gbogbo ènìyàn di ẹni ègbé àti ẹni ìṣubú.

23 Nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé bí ó bá ṣeéṣe pé Ádámù jẹ nínú èso igi ìyè nã ní ìgbà nã, ikú kì bá ti wà, ọ̀rọ̀ kò bá sì jẹ́ òfo, tí yíò sì ṣe Ọlọ́run ní òpùrọ́, nítorítí ó wípé: Tí ìwọ bá jẹẹ́, ìwọ yíò kú dájúdájú.

24 Àwa sì ríi pé ikú dé bá ọmọ-ènìyàn, bẹ̃ni, ikú èyítí Ámúlẹ́kì ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe ikú ti ara; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àkokò kan wà tí a fún ọmọ ènìyàn, nínú èyítí ó lè ronúpìwàdà, nítorínã, ayé yĩ jẹ́ ipò ìdánwò; àkokò tí ó múrasílẹ̀ láti bá Ọlọ́run pàdé; àkokò láti múrasílẹ̀ fún ipò àìlópin nnì èyítí àwa ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe lẹ́hìn àjĩnde òkú.

25 Nísisìyí, tí kò bá ṣe ti ìlànà ìràpadà, èyítí a ti fi lélẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, kì bá ti sí àjĩnde òkú; ṣùgbọ́n ìlànà ìràpadà kan wà tí a fi lélẹ̀, èyítí yíò mú àjĩnde kúrò nínú ipò òkú wá sí ìmúṣẹ, èyítí a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

26 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, tí o bá ti rí bẹ̃ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti lọ jẹ lára igi ìyè nã nwọn ìbá ti wà nínú ipò ìròbìnújẹ́ títí láéláé, nítorítí nwọn kò ní ipò ìmúrasílẹ̀; nítorínã ìlànà ìràpadà ìbá ti jẹ́ asán, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ìbá sì ti jẹ́ òfo tí kò sì já mọ́ ohunkóhun.

27 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èyí kò rí bẹ̃; ṣùgbọ́n a yàn fún ènìyàn pé nwọ́n níláti kú; àti pé lẹ́hìn ikú, nwọ́n níláti wá sí ìdájọ́, àní ìdájọ́ nnì èyítí àwa ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe òpin.

28 Lẹ́hìn tí Ọlọ́run sì ti yàn án pé kí àwọn ohun wọ̀nyí dé bá ènìyàn, kíyèsĩ, nigbanã ó ríi pé ó tọ́ fún ènìyàn láti mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó ti yàn fún nwọn;

29 Nítorínã ó rán àwọn ángẹ́lì láti bá nwọn sọ̀rọ̀, tí nwọ́n sì jẹ́ kí ènìyàn rí nínú ògo rẹ̀.

30 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà nã lọ síwájú láti ké pé orúkọ rẹ̀; nítorínã Ọlọ́run nbá ènìyàn sọ̀rọ̀, òun sì fi ìlànà ìràpadà hàn nwọ́n, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; èyí ni ó sì fi hàn nwọ́n gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn àti ìrònúpìwàdà àti iṣẹ́ mímọ́ nwọn.

31 Nítorí-eyi, ó fún ènìyàn ní òfin, nítorípé nwọ́n ti rékọjá sí òfin àkọ́kọ́ nípa ti àwọn ohun tí íṣe ti ara, tí nwọ́n sì dàbí àwọn ọlọ́run, tí nwọ́n sì mọ́ rere yàtọ̀sí búburú, tí nwọ́n sì gbé ara nwọn sí ipò láti hùwà, tàbí tí a gbé nwọn sí ipò láti hùwà gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú àti ìdùnnú nwọn, bóyá láti ṣe búburú tàbí láti ṣe rere—

32 Nítorínã Ọlọ́run fún nwọn ní àwọn òfin, lẹ́hìn tí ó ti fi ìlànà ìràpadà hàn nwọ́n, pé kí nwọ́n máṣe ṣe búburú, èrè èyítí íṣe ikú kejì, tĩ ṣe ikú ayérayé nípa àwọn ohun tí íṣe ti òdodo; nítorípé lórí èyí ni ìlànà ìràpadà nã kó lè ni ágbára, nítorítí àwọn iṣẹ́ àìṣègbè kò lè parun, gẹ́gẹ́bí dídára Ọlọ́run tí ó tóbi jùlọ.

33 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ké pe ènìyàn, ní orúkọ Ọmọ rẹ̀, (èyítí íṣe ìlànà ìràpadà tí a ti fi lélẹ̀) wípé: Tí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, tí ẹ kò sì sé ọkàn yín le, ìgbànã ni èmi yíò ṣãnú fún un yín, nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo;

34 Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà, tí kò sì sé ọkàn rẹ le, òun ni yíò rí ãnú gbà nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo; àwọn yĩ ni nwọn yíò sì bọ́ sínú ìsinmi mi.

35 Ẹnìkẹ́ni tí yíò bá sì sé ọkàn rẹ le, tí yíò ṣe búburú, kíyèsĩ, èmi yíò búra nínú ìbínú mi pé òun kò ní bọ́ sínú ìsinmi mi.

36 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, pé bí ẹ̀yin bá sé ọkàn yín le, ẹ̀yin kò lè bọ́ sínú ìsinmi Olúwa; nítorínã ìwà búburú yín múu bínú tí ó sì rán ìbínú rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lé yín lórí gẹ́gẹ́bí ìmúbínú àkọ́kọ́ bẹ̃ni, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà ìmúbínú ìkẹhìn bĩ ti ìgbà àkọ́kọ́, títí dé ìparun ayérayé ti ẹ̀míi yín; nítorínã, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, títí dé ikú ìkẹhìn, àti ti àkọ́kọ́.

37 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, níwọ̀n ìgbàtí àwa ti mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí, àti pé òtítọ́ ni nwọn íṣe, ẹ jẹ́ kí a ronúpìwàdà, kí ẹ̀yin má sé ọkàn an yín le, kí àwa ma dan Olúwa Ọlọ́run wa wò láti fa ìbínú rẹ̀ lé wa lórí nínú àwọn òfin rẹ̀ kejì wọ̀nyí tí ó fún wa; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wọ inú ìsinmi Ọlọ́run lọ, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ.