Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 58


Orí 58

Hẹ́lámánì, Gídì, àti Tíómnérì fi ẹ̀tàn mú ìlú-nlá Mántì—Àwọn ará Lámánì fà sẹ́hìn—Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn ènìyàn Ámọ́nì ni a pamọ́ bí nwọ́n ṣe wà ní ìdúróṣinṣin nínú ìdãbò òmìnira àti ìgbàgbọ́ nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 63 sí 62 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Sì kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe pé ohun tí ó kàn fún wa láti ṣe ni láti mú ìlú-nlá Mántì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, kò sí bí a ṣe le kó nwọn jáde kúrò nínú ìlú-nlá nã nípa ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa kékeré. Nítorí kíyèsĩ, nwọ́n rántí ohun èyítí àwa ti ṣe ṣãju; nítorínã àwa kò lè tàn nwọ́n kúrò ní àwọn ìsádi nwọn.

2 Nwọ́n sì pọ̀ púpọ̀ ju àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí àwa kò lè dáa laba láti lọ kọlũ nwọ́n nínú àwọn ibi ìsádi nwọn.

3 Bẹ̃ni, ó sì di dandan fún wa láti lo àwọn ọmọ ogun wa láti ṣọ́ àwọn apá ilẹ̀ nã tí àwa ti mú ní ìní; nítorínã ó di dandan fún wa láti dúró, kí àwa kí ó lè gba agbára síi láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà àti àwọn ìpèsè oúnjẹ ní àkọ̀tun.

4 Ó sì ṣe tí èmi ṣe báyĩ rán ikọ̀ sí bãlẹ ilẹ̀ wa, láti jẹ́ kí ó mọ́ ipò tí àwọn ènìyàn wa wà. Ó sì ṣe tí àwa sì dúró láti lè gba ìpèsè oúnjẹ àti agbára láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

5 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ànfàní tí a rí nínú eleyĩ kéré; nítorítí àwọn ará Lámánì nã pẹ̀lú ngba agbára púpọ̀ lójojúmọ́, àti ìpèsè oúnjẹ púpọ̀púpọ̀; báyĩ sì ni ó rí fún wa ní àkokò yí.

6 Àwọn ará Lámánì sì njáde wá láti kọlũ wá láti ìgbà dé ìgbà, nwọ́n sì nta ọgbọ́n láti pa wá run; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwa kò lè jáde wá láti dojú ìjà kọ nwọn, nítorí ti ibi ãbò nwọn àti ibi ìsádi nwọn.

7 Ó sì ṣe tí àwa sì wà nínú ipò ìṣòro yĩ fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, àní títí àwa fi fẹ́rẹ̀ kú fun àìní óunjẹ.

8 Ṣùgbọ́n ó ṣe tí àwa rí oúnjẹ gbà, èyítí àwọn ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún méjì gbé fún wa fún ìrànwọ́ wa; èyí sì ni gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí a rí gbà, láti dãbò bò ara wa àti orílẹ̀-èdè wa kúrò lọ́wọ́ ìṣubú sí ọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, bẹ̃ni, láti bá àwọn ọ̀tá nnì tí kò níye jà.

9 Àti nísisìyí ìdí tí a fi rí irú sísú wọ̀nyí, tàbí pé ìdí tí nwọn kò fi fi ohun ìrànlọ́wọ́ ránṣẹ́ sí wa síi, àwa kò mọ̀; nítorínã ni inú wa fi bàjẹ́ tí a sì kún fún ìbẹ̀rù, pé kí ìdájọ́ Ọlọ́run má bã wá sí órí ilẹ̀ wa, sí ìṣubú àti ègbé wa pátápátá.

10 Nítorínã ni àwa ṣe tú ọkán wa jáde sí Ọlọ́run, nínú adura pé kí ó fún wa ní ágbára kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, bẹ̃ni, kí ó sì fún wa ní ágbára láti lè di àwọn ìlú-nlá wa mú, àti àwọn ilẹ̀ wa, àti àwọn ìní wa, fún ìtọ́jú àwọn ènìyàn wa.

11 Bẹ̃ni, ó sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run wa bẹ̀ wá wò pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yíò gbà wá; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí ó sì fi àlãfíà fún ọkàn wa, tí ó sì fún wa ní ìgbàgbọ́ nlá, tí ó sì mú wa ní ìrètí nínú rẹ̀ fún ìdásílẹ̀ wa.

12 Àwa sì tún ní ìgboyà lákọ̀tun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun kékeré tí a ti gbà, a sì ní ìpinnu tí ó múná láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wa, àti láti di àwọn ilẹ̀ wa mú, àti àwọn ìní wa, àti àwọn ìyàwó wa, àti àwọn ọmọ wa, àti ìjà-òmìnira wa nã.

13 Báyĩ ni àwa sì jáde lọ pẹ̀lú gbogbo agbára wa láti kọlũ àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n wà ní ìlú-nlá Mántì; àwa sì pàgọ́ wa sí ẹ̀bá aginjù nã, èyítí ó wà nítòsí ìlú-nlá nã.

14 Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé àwa wà ní agbègbè ẹ̀bá aginjù èyítí ó wà nítòsí ìlú-nlá nã, ni nwọ́n rán àwọn amí nwọn kãkiri sí wa kí nwọ́n lè mọ̀ bí a ti pọ̀ tó àti bí agbára wa ti tó.

15 Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ríi pé àwa kò pọ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ti pọ̀ tó, àti nítorítí nwọ́n bẹ̀rù pé àwa yíò ké wọn kúrò lára ìrànlọ́wọ́ nwọn àfi bí nwọ́n bá jáde wá láti bá wa jagun kí nwọn sì pa wá, àti pẹ̀lú pé nwọ́n rõ pé nwọ́n lè pa wá run ní ìrọ̀rùn pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn, nítorínã ni nwọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ láti jáde wá láti bá wa jagun.

16 Nígbàtí àwa sì ríi pé nwọ́n nṣe ìmúrasílẹ̀ láti jáde wá láti kọlù wá, kíyèsĩ, mo mú kí Gídì, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun díẹ̀, kí ó farapamọ́ nínú aginjù, àti pé kí Tíómnérì àti àwọn ọmọ ogun díẹ̀ farapamọ́ pẹ̀lú sínú aginjù.

17 Nísisìyí Gídì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní apá ọ̀tún àti àwọn tí ó kù sì wa ní apá òsì; nígbàtí nwọ́n sì ti fi ara nwọn pamọ́ báyĩ, kíyèsĩ, èmi dúró, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó kù, ní ibití àwa ti pàgọ́ wá sí ni àkọ́kọ́ di ìgbànã tí àwọn ará Lámánì yíò jáde wá láti jagun.

18 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì jáde wá pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn láti kọlù wá. Nígbàtí nwọ́n sì ti wá tí nwọ́n sì fẹ́ láti kọlù wá pẹ̀lú idà nwọn, èmi mú kí àwọn ọmọ ogun mi, àwọn tí nwọ́n wà lọ́dọ̀ mi, kí nwọ́n sá padà sínú aginjù.

19 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì nã sá tẹ̀lé wa ní kánkán, nítorítí nwọ́n ní ìfẹ́ láti lé wa bá kí nwọn ó sì pa wá; nítorínã ni nwọ́n ṣe tẹ̀lé wa wọ inú aginjù lọ; àwa sì kọjá lãrín Gídì àti Tíómnérì, tóbẹ̃ tí àwọn ará Lámánì kò rí nwọn.

20 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ti kọjá tán, tàbí pé nígbàtí ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã ti kọjá tán, Gídì àti Tíómnérì jáde kúrò ni ibi tí nwọ́n sápamọ́ sí, tí nwọ́n sì ká àwọn amí àwọn ará Lámánì mọ́ kí nwọn ó má lè padà sínú ìlú-nlá nã.

21 Ó sì ṣe, nígbàtí nwọ́n ti ká nwọn mọ́, nwọ́n sáré lọ sínú ìlú-nlá nã nwọ́n sì kọ lu àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó kù tí ó nṣọ́ ìlú-nlá nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n pa nwọ́n run tí nwọ́n sì mú ìlú-nlá nã ní ìní.

22 Nísisìyí nwọ́n ṣe eleyĩ nítorípé àwọn ará Lámánì jẹ́ kí nwọ́n ó darí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn lọ sínú aginjù, àfi àwọn ẹ̀ṣọ́ díẹ̀.

23 Ó sì ṣe tí Gídì àti Tíómnérì nípa ọ̀nà yĩ ti rí àwọn ibi ìsádi nwọn gbà ní ìní. Ó sì ṣe tí àwa tẹ̀ síwájú, lẹ́hìn tí a ti rìn jìnà wọ inú aginjù lọ sí apá ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

24 Nígbàtí àwọn ará Lámánì sì rí i pé nwọ́n nkọjá lọ sí apá ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ẹ̀rù bà nwọ́n gidigidi, ní ìbẹ̀rù pé bóyá ète wa ni láti pa nwọ́n run; nítorínã ni nwọ́n ṣe tún bẹ̀rẹ̀sí padà sẹ́hìn sínú aginjù, bẹ̃ni, àní padà sí ọ̀nà ibití nwọ́n ti wá.

25 Sì kíyèsĩ, ilẹ̀ ṣú nwọ́n sì pàgọ́ nwọn, nítorítí àwọn olórí-ológun àwọn ará Lámánì rò pé àwọn ará Nífáì ti nṣãrẹ̀ nítorí ìrìnàjò nwọn; tí nwọ́n sì tún rò pé nwọ́n ti lé gbogbo àwọn ọmọ ogun nwọn nítorínã ni nwọn kò ṣe ronú nípa ìlú-nlá Mántì.

26 Nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí ilẹ̀ ṣú, mo mú kí àwọn ọmọ ogun mi ó má sùn, ṣùgbọ́n pé kí nwọn ó kọjá lọ síwájú ní ọ̀nà míràn sí ilẹ̀ Mántì.

27 Àti nítorí ìrìn wa ní òru yĩ, kíyèsĩ, ní ọjọ́ kejì àwa ti kọjá àwọn ará Lámánì, tóbẹ̃ tí àwa dé inú ìlú-nlá Mántì ṣãju nwọn.

28 Ó sì ṣe, pé nípa ọgbọ́n yĩ ni àwa ṣe mú ìlú-nlá Mántì láé ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

29 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì dé itòsí ìlú-nlá nã, tí nwọ́n ríi tí àwa ti ṣe ìmúrasílẹ̀ láti dojúkọ nwọ́n, ẹnu yà nwọ́n gidi, ẹ̀rù sì bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi sálọ sínú aginjù.

30 Bẹ̃ni, ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sá kúrò ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ nã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé pẹ̀lú nwọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã.

31 Gbogbo àwọn ìlú-nlá tí àwọn Lámánì sì ti gba, ni ó wà lọ́wọ́ wa ní àkokò yĩ; tí àwọn bàbá wa àti àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa sì npadà sí ilẹ̀ nwọn, gbogbo nwọn àfi àwọn tí nwọ́n ti mú lẹ́rú tí àwọn Lámánì sì ti kó lọ.

32 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa kéré láti ṣọ́ àwọn ìlú-nlá tí ó pọ̀ báyĩ àti ohun ìní tí ó pọ̀ báyĩ.

33 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run wa ẹnití ó ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí àwa fi gba àwọn ìlú-nlá nã àti àwọn ilẹ̀ nã, tí í ṣe tiwa.

34 Nísisìyí àwa kò mọ́ ìdí rẹ̀ tí ìjọba kò fi fún wa ní ọmọ ogun síi; bẹ̃ sì ni àwọn ọmọ ogun tí nwọ́n wá sí ọ́dọ̀ wa kò mọ́ ìdí rẹ̀ tí àwa kòì rí ọmọ ogun púpọ̀ gbà síi.

35 Kíyèsĩ, awa kò mọ ṣugbọn bóyá kò ṣeéṣe fún ọ ni, tí ìwọ sì ti kó gbogbo àwọn ọmọ ogun sí ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè ọ̀hún; bí ó bá rí bẹ̃, àwa kò ní ìfẹ́ láti kùn.

36 Bí kò bá sì rí bẹ̃, kíyèsĩ, àwa ní ìbẹ̀rù pé ẹ̀yà wà nínú ìjọba nã, tí nwọn kò fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí wa síi fún ìrànlọ́wọ́ wa; nítorítí àwa mọ̀ wípé nwọ́n pọ̀ ju èyítí nwọ́n fi ránṣẹ́.

37 Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, kò já mọ́ nkankan—àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíò gbà wá, l’áìṣírò ailagbara ẹgbẹ́ ọmọ-ogun wa, bẹ̃ni, yíò sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.

38 Kíyèsĩ, èyí ni ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n, nígbàtí ó fẹ́rẹ̀ dópin, àwa sì ní àwọn ilẹ̀ wa ní ìní; àwọn ará Lámánì sì ti sálọ sí ilẹ̀ Nífáì.

39 Àwọn ọmọdékùnrin àwọn ènìyàn Ámọ́nì nnì, tí èmi ti sọ̀rọ̀ nípa nwọn, sì wà pẹ̀lú mi nínú ìlú-nlá Mántì; Olúwa si ti ràn nwọ́n lọ́wọ́, bẹ̃ni, ó sì ti gbà nwọ́n lọ́wọ́ ikú idà, tóbẹ̃ tí a kò pa ẹyọkan nínú nwọn.

40 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n ti fi ara gba ọgbẹ́ púpọ̀púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n dúró ṣinṣin nínú òmìnira nã nínú èyítí Ọlọ́run ti sọ nwọ́n di òmìnira; nwọ́n sì fi Olúwa Ọlọ́run nwọn sí ọ́kàn lojojúmọ́; bẹ̃ni, nwọ́n sì gbìyànjú láti pa àwọn ìlànà rẹ̀, àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀, àti àwọn òfin rẹ̀ mọ́ nígbà-gbogbo; ìgbàgbọ́ wọn sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ sĩ nínú àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tí nbọ̀wá.

41 Àti nísisìyí, arákùnrin mi ọ̀wọ́n, Mórónì, kí Olúwa Ọlọ́run wa, ẹnití ó ti rà wá padà tí ó sì ti sọ wá di òmìnira, kí ó pa ọ́ mọ́ títí níwájú rẹ̀; bẹ̃ni, kí ó sì fi ojú rere fún àwọn ènìyàn yĩ, àní kí ẹ̀yin ó ní àṣeyọrí láti lè gba gbogbo àwọn ohun tí àwọn ará Lámánì ti gbà lọ́wọ́ wa padà, èyítí ó wà fún ìrànlọ́wọ́ wa. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, èmi fi òpin sí ọ̀rọ̀ mi. Èmi ni Hẹ́lámánì, ọmọ Álmà.