Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 54


Orí 54

Ámmórọ́nì àti Mórónì ṣe àdéhùn fún ṣíṣe pàṣípàrọ̀ àwọn ènìyàn nwọn tí nwọ́n kó lẹ́rú—Mórónì fẹ́ kí àwọn ará Lámánì kúrò lórí ilẹ̀ nwọn kí nwọ́n sì dáwọ́ ìwà ìpànìyàn nwọn dúró—Ámmárọ́nì fẹ́ kí àwọn ará Nífáì kó àwọn ohun ìjà nwọn lélẹ̀ kí nwọ́n sì wà lábẹ́ àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 63 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n àwọn onídàjọ́, tí Ámmórọ́nì ránṣẹ́ sí Mórónì pé òun fẹ́ kí ó ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn ènìyàn nwọn tí nwọ́n kó lẹ́rú.

2 Ó sì ṣe tí Mórónì ní inú dídùn púpọ̀púpọ̀ sí ìbẽrè yĩ, nítorítí ó fẹ́ àwọn oúnjẹ tí nwọn nlò fún ìtọ́jú àwọn ará Lámánì tí a kó lẹ́rú fún ìtọ́jú àwọn ènìyàn tirẹ̀; ó sì tún fẹ́ àwọn ènìyàn tirẹ̀ fún fífi agbára fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.

3 Nísisìyí àwọn ará Lámánì ti mú àwọn obìnrin àti ọmọ púpọ̀, tí kò sì sí obìnrin kan tàbí ọmọ kan lãrín àwọn tí a kó lẹ́rú tí í ṣe ti Mórónì, tàbí àwọn ẹrú tí Mórónì ti mú; nítorínã Mórónì pinnu lọ́nà ọgbọ́n àrékérekè láti gbà nínú àwọn ará Nífáì tí nwọn kó lẹ́rú lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì bí ó ti ṣẽṣe tó.

4 Nítorínã ó kọ ìwé, ó sì fi rán ìránṣẹ́ Ámmórọ́nì, ẹnití ó mú ìwé tọ Mórónì wá ní ìṣãjú. Nísisìyí àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ó kọ ránṣẹ́ sí Ámmórọ́nì, wípé:

5 Kíyèsĩ, Ámmórọ́nì, èmi kọ̀wé sí ọ nípa ti ogun yĩ tí ìwọ nbá àwọn ènìyàn mi jà, tàbí kí a wípé èyítí arákùnrin rẹ nbá wọn jà, àti tí ìwọ ṣì pinnu láti máa jàlọ lẹ́hìn ikú rẹ̀.

6 Kíyèsĩ, èmí yíò sọ ohun kan fún ọ nípa àìṣègbè Ọlọ́run, àti idà ìbínú nlá rẹ̀, èyítí ó gbé sókè sí ọ àfi bí ìwọ bá ronúpìwàdà kí o sì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ padà sínú ilẹ̀ rẹ, tàbí ilẹ̀ ìní rẹ, èyítí í ṣe ilẹ̀ Nífáì.

7 Bẹ̃ni, èmi sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún ọ bí ìwọ bá lè ṣe ìgbọràn sí nwọn; bẹ̃ni, èmi yíò sọ fún ọ nípa ọ̀run àpãdì búburú nnì tí ó ndúró láti tẹ́wọ́gba àwọn apànìyàn bí ìrẹ àti arákùnrin rẹ ti jẹ́, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà tí ẹ sì dẹ́kun ète ìpànìyàn nyin gbogbo, kí ẹ sì padà pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nyín sínú ilẹ̀ nyín.

8 Ṣùgbọ́n nítorípé ẹ̀yin ti kọ àwọn ohun wọ̀nyí nígbà kan rí, tí ẹ sì ti bá àwọn ènìyàn tí í ṣe ti Olúwa jà, bẹ̃gẹ́gẹ́ ni èmi nretí pé ẹ̀yin yíò tún ṣeé lẹ̃kan síi.

9 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwa ti múrasílẹ̀ láti dojúkọ nyín; bẹ̃ni, àti pé àfi bí ẹ̀yin bá kọ ète nyín sílẹ̀, ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò fa ìbínú Ọlọ́run nnì èyí tí ẹ̀yin ti kọ̀ sí órí nyín, àní títí dé ìparun nyín pátápátá.

10 Ṣùgbọ́n, bí Olúwa ti wà lãyè, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa yíò kọlũ nyín àfi bí ẹ̀yin bá padà, láìpẹ́ ni a ó sì bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ikú, nítorítí àwa yíò di àwọn ìlú-nlá wa àti àwọn ilẹ̀ wa mú; bẹ̃ni, àwa yíò sì gbé ẹ̀sìn wa ró àti ipa ọ̀nà ìfẹ́ Ọlọ́run wa.

11 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo lérò wípé èmi nbá nyín sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lásán ni; tàbí pé mo lérò wípé ọmọ ọ̀run àpãdì ni ìwọ í ṣe; nítorínã èmi yíò parí ìwé mi nípa sísọ fún ọ pé èmi kò ní ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn ènìyàn tí a kó lẹ́rú, àfi bí ẹ̀yin yíò bá jọ̀wọ́ ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, fún ẹyọ ẹnìkan tí a mú lẹ́rú; bí ẹ̀yin yíò bá ṣe èyí, èmi yíò ṣe pàṣípàrọ̀.

12 Àti kíyèsĩ, bí ẹ̀yin kò bá ṣe eleyĩ, èmi yíò kọlù nyín pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi; bẹ̃ni, àní èmi yíò di ìhámọ́ra ogun fún àwọn obìnrin àti ọmọdé mi, èmi yíò sì kọlu nyín, èmi yíò sì tẹ̀lé nyin àní wọ inú ilẹ̀ ara nyín, èyítí í ṣe ilẹ̀ ìní wa àkọ́kọ́; bẹ̃ni, yíò sì jẹ́ ẹ̀jẹ̀ fún ẹ̀jẹ̀, bẹ̃ni, ẹ̀mí fún ẹ̀mí; èmi yíò sì gbógun tì nyín àní títí a ó fi pa nyín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

13 Kíyèsĩ, mo wà nínú ìbínú mi, àti àwọn ènìyàn mi pẹ̀lú; ẹ̀yin ti wá ọ̀nà láti pa wá, àwa sì wá ọ̀nà láti dãbò bò ara wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá lépa síi láti pa wá run àwa yíò lépa láti pa nyín run; bẹ̃ni, àwa yíò sì lépa láti gba ilẹ̀ wa, ilẹ̀ ìní wa àkọ́kọ́.

14 Nísisìyí mo parí ìwé mi. Èmi ni Mórónì, tí í ṣe olórí àwọn ènìyàn ará Nífáì.

15 Nísisìyí ó sì ṣe tí Ámmórọ́nì, lẹ́hìn tí ó ti gba ìwé yĩ, ó bínú; ó sì kọ ìwé míràn ránṣẹ́ sí Mórónì, àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ, tí ó wípé:

16 Èmi ni Ámmórọ́nì, ọba àwọn ará Lámánì; èmi ni arákùnrin Amalikíà ẹnití ẹ̀yin ti pa. Kíyèsĩ, èmi yíò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lára nyín, bẹ̃ni, èmi yíò sì kọ lù nyín pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi, nítorítí èmi kò bẹ̀rù àwọn ẽmí ìkìlọ̀ rẹ.

17 Nítorí ẹ kíyèsĩ, àwọn bàbá nyín ṣẹ àwọn arákùnrin nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n jà nwọ́n lólè ẹ̀tọ́ nwọn sí ìjọba nígbàtí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ nwọn.

18 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin yíò bá kó àwọn ohun ìjà ogun nyín lélẹ̀, kí ẹ sì jọ̀wọ́ ara nyín fún àwọn tí ó tọ́ sí láti ṣe ìjọba lée nyín lórí, nígbànã ni èmi yíò mú kí àwọn ènìyàn mi kó àwọn ohun ìjà ogun nwọn lélẹ̀ tí nwọn kò sì ní bá nyín jagun mọ́.

19 Kíyèsĩ, ìwọ ti mí ẽmí ìkìlọ̀ púpọ̀ sí èmi àti àwọn ènìyàn mi; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa kò bẹ̀rù àwọn ẽmí ìkìlọ̀ rẹ.

20 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi yíò gbà láti ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú gẹ́gẹ́bí ó ti bẽrè, tayọ̀tayọ̀, kí èmi ó lè ní oúnjẹ ní ìpamọ́ fún àwọn ọmọ ogun mi; àwa yíò sì bá ọ jagun èyítí yíò jẹ́ títí láé, yálà sí mímú àwọn ará Nífáì sí abẹ́ ìjọba wa tàbí sí rírun nwọ́n títí láé.

21 Àti nípa ti Ọlọ́run nnì ẹnití ìwọ wípé àwa ti kọ̀, kíyèsĩ, àwa kò mọ́ irú ẹ̀dá bẹ̃; bákannã ni ẹ̀yin kò mọ̀; ṣùgbọ́n bí ó bá rí bẹ̃ pé irú ẹ̀dá bẹ̃ wà, àwa lérò wípé ó ṣeéṣe pé òun ni ó dá àwa àti ẹ̀yin.

22 Bí ó bá sì jẹ́ wípé èṣù àti ọ̀run àpãdì nbẹ, kíyèsĩ njẹ́ kò ha rán ọ lọ síbẹ̀ láti gbé pẹ̀lú arákùnrin mi tí ìwọ ti pa, ẹnití ìwọ ti sọ wípé ó ti lọ sí ibẹ̀? Ṣùgbọ́n kíyèsĩ àwọn ohun wọ̀nyí kò jámọ́ nkan.

23 Èmi ni Ámmórọ́nì, mo sì jẹ́ ìran Sórámù, ẹnití àwọn bàbá nyín fi ipá mú láti jáde kúrò nínú Jerúsálẹ́mù.

24 Ẹ sì kíyèsĩ nísisìyí, ará Lámánì tí ó gbóyà ni mí; ẹ kíyèsĩ, ogun yĩ ni a jà láti gbẹ̀san nwọn, àti láti gba ẹ̀tọ́ nwọn sí ìjọba; èmi sì parí ìwé mi sí Mórónì.