Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 43


Orí 43

Álmà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wãsù ọ̀rọ̀ nã—Àwọn ará Sórámù àti àwọn ènìyàn Nífáì míràn tí ó yapa di àwọn ènìyàn Lámánì—Àwọn ará Lámánì dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ogun—Mórónì ṣe ìgbáradì fún àwọn ará Nífáì pẹ̀lú ìhámọ́ra ìdábòbò-ara-ẹni—Olúwa fi ète àwọn ará Lámánì han Álmà—Àwọn ará Nífáì dábõ bò ilé, àwọn òmìnírá, àwọn ẹbí àti ẹ̀sìn nwọn—Àwọn ọmọ ogun Mórónì àti Léhì yí àwọn ará Lámánì kãkiri. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ọmọ Álmà kọjá lọ lãrín àwọn ènìyàn nã, láti kéde ọ̀rọ̀ nã fún nwọn. Álmà pẹ̀lú, fúnrarẹ̀, kò sì lè sinmi, òun nã sì jáde.

2 Nísisìyí a kò ní sọ̀rọ̀ mọ́ nípa ìwãsù tí nwọ́n ṣe, àfi pé nwọ́n wãsù ọ̀rọ̀ nã, àti òtítọ́ nã, ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ òun ìfihàn; nwọ́n sì wãsù gẹ́gẹ́bí ti ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run nípa èyítí a ti pè nwọ́n.

3 Àti nísisìyí èmi sì padà sí órí ọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ogun lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, ní ọdún kejìdínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́.

4 Nítorí kíyèsĩ, ó ṣe tí àwọn ará Sórámù di àwọn ará Lámánì; nítorínã, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kejìdínlógún àwọn ará Nífáì ríi pé àwọn ará Lámánì mbọ̀wá láti kọlũ nwọ́n; nítorínã nwọ́n ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun; bẹ̃ni, nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun nwọn jọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì.

5 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì dé ní ẹgbẽgbẹ̀rún nwọn; nwọ́n sì wá sínú ilẹ̀ Ántíónọ́mù, tí íṣe ilẹ̀ àwọn ará Sórámù; ọkùnrin kan tí à npe orúkọ rẹ̀ ní Sẹrahẹ́múnà sì ni olórí nwọn.

6 Àti nísisìyí, nítorípé àwọn ará Ámálẹ́kì ní ìwà búburú àti ìpànìyàn lọ́wọ́ ju àwọn ará Lámánì lọ, tìkàra nwọn, nítorínã, Sẹrahẹ́múnà yan àwọn olórí ọmọ ogun lé àwọn ará Lámánì lórí, gbogbo nwọn sì jẹ́ ará Ámálẹ́kì àti ará Sórámù.

7 Nísisìyí ó ṣe eleyĩ kí ó lè pa ìkórira nwọn sí àwọn ará Nífáì mọ́, kí ó lè mú nwọn sí ábẹ́ àṣeyọrí ète rẹ̀.

8 Nítorí kíyèsĩ, ète rẹ̀ ni pé kí ó rú àwọn ará Lámánì sókè ní ìbínú sí àwọn ará Nífáì; èyí ni ó ṣe láti lè fi ipá lo agbára nlá lórí nwọn, àti pẹ̀lú pé kí ó lè gba agbára lórí àwọn ará Nífáì nípa mímú nwọn sínú oko-ẹrú.

9 Àti nísisìyí ète àwọn ará Nífáì ni láti dábõbò ilẹ̀ nwọn, àti ilé nwọn, àti àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, láti pa nwọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; àti pẹ̀lú pé kí nwọn ó lè pa ẹ̀tọ́ òun ànfãní nwọn mọ́, bẹ̃ni, àti òmìnira nwọn pẹ̀lú, pé kí nwọn ó lè sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti fẹ́.

10 Nítorítí nwọn mọ̀ pé bí àwọn bá subu sọ́wọ́ àwọn ará Lámánì, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá sin Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́, Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè, ni àwòn ará Lámánì yíò parun.

11 Bẹ̃ni, nwọ́n sì mọ́ ọ̀pọ̀ ìkórira tí àwọn ará Lámánì ní fún àwọn arákùnrin nwọn, tĩ ṣe àwọn ènìyàn tí Kòṣe-Nífáì-Léhì, tí à npè ní àwọn ènìyàn Ámọ́nì—Tí nwọn kò sì ní gbé ohun ìjà-ogun, bẹ̃ni, nwọn ti dá májẹ̀mú, nwọn kò sì ní sẹ́ẹ—nítorínã, bí nwọn bá bọ́ sọ́wọ́ agbára àwọn ará Lámánì, a ó pa wọn run.

12 Àwọn ará Nífáì kò sì fé kí nwọn pa nwọ́n run; nítorínã nwọ́n fún nwọn ní ilẹ̀ fún ìní nwọn.

13 Àwọn ènìyàn Ámọ́nì sì fún àwọn ará Nífáì ní èyítí ó pọ̀ nínú ohun ìní nwọn láti ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ ogun nwọn; báyĩ sì ni ó di dandan pé kí àwọn ará Nífáì, nìkan, kọlũ àwọn ará Lámánì, tí nwọn íṣe àdàpọ̀ ìran Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn ọmọ Íṣmáẹ́lì, àti gbogbo àwọn tí nwọ́n ti yípadà kúrò lára àwọn ará Nífáì, tí nwọn í ṣe ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Sórámù, àti àwọn ìran àwọn àlùfã Nóà.

14 Nísisìyí àwọn ìran nã fẹ́rẹ̀ pọ̀ tó àwọn ará Nífáì; báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ará Nífáì fi níláti bá àwọn arákùnrin nwọn jà dandan, àní títí dé ojú ìtàjẹ̀sílẹ̀.

15 Ó sì ṣe bí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì ti kó ara nwọn jọ ní ilẹ̀ Ántíónọ́mù, kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì ti múrasílẹ̀ láti dojúkọ nwọn ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì.

16 Nísisìyí, olórí àwọn ará Nífáì, tàbí pé ẹnití nwọn ti yàn láti jẹ́ ọ̀gágun lórí àwọn ará Nífáì—nísisìyí ọ̀gágun nã ṣe àkóso lórí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì—orúkọ rẹ̀ sì ni Mórónì;

17 Mórónì sì ṣe àkóso, àti ìdarí gbogbo àwọn ogun nwọn. Ó sì jẹ́ ọmọ ogún ọdún àti mãrún nígbàtí a yàn án gẹ́gẹ́bí ọ̀gágun lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì.

18 Ó sì ṣe tí ó kọlũ àwọn ará Lámánì ní ibi ìhà ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì di ìhámọ́ra ogun pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú ọrun, àti onírurú àwọn ohun ìjà ogun.

19 Nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì ríi pé àwọn ènìyàn Nífáì, tàbí pé Mórónì, ti ṣe ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìgbayà àti pẹ̀lú ìhámọ́ra tí nwọ́n fi bò apá nwọn, bẹ̃ni, àti asà láti dábõbò orí nwọn, nwọ́n sì wọ ẹ̀wù tí ó nípọn pẹ̀lú—

20 Nísisìyí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sẹrahẹ́múnà kò ṣe irú ìmúrasílẹ̀ báyĩ; idà nwọn àti símẹ́tà nwọn nìkan ni nwọ́n ní, ọrùn nwọn àti ọfà nwọn, òkúta nwọn àti kànnà-kànnà nwọn; nwọ́n sì wà ní ìhòhò, àfi fún ti awọ tí nwọ́n sán mọ́ ìbàdí nwọn; bẹ̃ni, gbogbo nwọn ni ó wà ní ìhòhò, àfi àwọn ará Sórámù, àti àwọn ará Ámálẹ́kì;

21 Ṣùgbọ́n nwọn kò ṣe ìhámọ́ra pẹ̀lú igbaya-ogun, tàbí apata—nítorínã, nwọn kún fún ìbẹ̀rù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì fún ti ìhámọ́ra nwọn, l’áìṣírò ti iye nwọn tí ó pọ̀ púpọ̀ ju ti àwọn ará Nífáì lọ.

22 Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe tí nwọn kò wá láti dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ibi ìhà ilẹ̀ Jẹ́ṣónì; nítorínã nwọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ántíónọmù lọ sínú aginjù nã, nwọ́n sì rin ìrìn-àjò nwọn káakiri nínú aginjù nã, kọjá lọ sí ibi orísun odò Sídónì, kí nwọ́n lè wá sínú ilẹ̀ Mántì láti mú ilẹ̀ nã ní ìkógun; nítorítí nwọn kò lérò pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì yíò mọ́ ibití àwọn ti lọ.

23 Ṣùgbọ́n ó ṣe, ní kété tí nwọ́n ti kọjá lọ sínú aginjù, Mórónì rán àwọn amí lọ sínú aginjù láti ṣọ́ àgọ́ nwọn; àti Mórónì, pẹ̀lú, nítorípé ó mọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Álmà, rán àwọn ènìyàn kan sí i, pé kí ó bẽrè lọ́wọ́ Olúwa ibití àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì yíò lọ láti lè dábõbò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.

24 Ó sì ṣe tí ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Álmà wá, tí Álmà sì wí fún àwọn oníṣẹ́ Mórónì, pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì nrìn kãkiri nínú aginjù, kí nwọn ó lè kọjá sínú ilẹ̀ Mántì, kí nwọ́n lè bẹ̀rẹ̀sí dojú ìjà kọ àwọn apá ibití àwọn ènìyàn nã ti ṣe aláì lágbára tó bẹ̃. Àwọn oníṣẹ́ nã sì lọ láti jíṣẹ́ nã fún Mórónì.

25 Nísisìyí lẹ́hìn tí Mórónì ti fi apá kan nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sílẹ̀ sí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, ní ìfòyà pé apá kan nínú àwọn ará Lámánì lè wá lọ́nàkọnà sínú ilẹ̀ nã kí nwọ́n sì mú ìlú nã ní ìkógun, ó mú ìyókù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Mántì.

26 Ó sì mú kí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ nã kó ara nwọn jọ bá àwọn ará Lámánì jagun, láti dãbò bò ilẹ̀ nwọn àti orílẹ̀-èdè nwọn, ẹ̀tọ́ nwọn àti òmìnira nwọn; nítorínã nwọn ṣe ìmúrasílẹ̀ de ìgbà nã tí àwọn ará Lámánì yíò de.

27 Ó sí ṣe tí Mórónì mú kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ farapamọ́ nínú àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Sídónì, èyítí ó wà ní apá ìwọ oòrùn odò Sídónì, nínú aginjù nã.

28 Mórónì sì fi àwọn alamí kãkiri ibẹ̀, kí òun lè mọ̀ ígbàtí àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì yíò bá dé.

29 Àti nísisìyí, nítorípé Mórónì ti mọ́ ète àwọn ará Lámánì nã, pé ète nwọn ni láti pa àwọn arákùnrin nwọn run, tàbí pé kí nwọn ó mú nwọ́n sínú ìgbèkùn kí nwọn lè fi ìjọba lélẹ̀ fún ànfãní ara nwọn lórí gbogbo ilẹ̀ nã;

30 Àti nítorípé òun mọ̀ pé ìfẹ́ kanṣoṣo tí àwọn ará Nífáì ní ni láti ṣe ìpamọ́ àwọn ilẹ̀ nwọn, àti òmìnira nwọn, àti ìjọ nwọn, nítorínã òun kò kã sí ẹ̀ṣẹ̀ láti dábò bò nwọ́n lọ́nà ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí; nítorínã, ó mọ̀ nípasẹ̀ àwọn alamí rẹ̀ ọ̀nà tí àwọn ará Lámánì yíò gbà.

31 Nítorínã, ó pín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ó sì mú apá kan nínú nwọn wá sínú àfonífojì nã, ó sì fi nwọn pamọ́ sí ìhà apá ìlà-oòrùn, àti ní apá gũsù òkè Ríplà;

32 Àwọn tí ó kù ni ó sì fi pamọ́ sí àfonífojì ti ìwọ̀-oòrùn, ní apá ìwọ̀-oòrùn odò Sídónì, àti bẹ̃bẹ̃ títí fi dé ìhà agbègbè ìpẹ̀kun ilẹ̀ Mántì.

33 Bí ó sì ti pín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sí ibití ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣetán láti dojúkọ nwọ́n.

34 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì kọjá wá sí apá ìhà àríwá òkè nã, níbití díẹ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì farapamọ́ sí.

35 Nígbàtí àwọn ará Lámánì sì ti kọjá òkè Ríplà, tí nwọn dé inú àfonífojì nã, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí dá odò Sídónì kọjá, ẹgbẹ́ ọmọ ogun èyítí ó ti farapamọ́ sí apá gũsù òkè nã, tí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ íṣe Léhì sì jẹ́ olórí nwọn, ó sì darí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jáde wá ó sì yí àwọn ará Lámánì ká ní apá ìlà-oòrùn ní ẹ̀hìn nwọn.

36 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì, nígbàtí nwọ́n rí àwọn ará Nífáì tí nwọ́n nbọ̀ láti ẹ̀hìn nwọn wá, nwọ́n yípadà nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Léhì jà.

37 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa ara nwọn lápá méjẽjì, ṣùgbọ́n apá àwọn ará Lámánì ni ó ti burú jù, nítorítí wíwà ní ìhõhò nwọn mú kí nwọ́n fi ara gba ọgbẹ́ àwọn ará Nífáì nípasẹ̀ idà nwọn àti símẹ́tà nwọn, èyítí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo lílù rẹ̀ ni ó mú ikú wa.

38 Ṣùgbọ́n ẹ̀wẹ̀, lãrín àwọn ará Nífáì enítere-èjìtere ni ènìyàn ṣubú nípasẹ̀ idà nwọn àti ìpàdánù ẹ̀jẹ̀, nítorípé nwọ́n dãbò bò àwọn ẹ̀yà ara nwọn tí ó ṣe pàtàkì, tàbí pé àwọn ẹ̀yà ara nwọn tí ó ṣe pàtàkì ni nwọ́n dãbò bò lọ́wọ́ lílù àwọn ará Lámánì, nípasẹ̀ àwo àyà nwọn, àti pẹ̀lú ìhámọ́ra tí nwọ́n fi bò apá nwọn, àti ìhámọ́ra àṣíborí nwọn; báyĩ sì ni ará Nífáì tẹ̀síwájú nínú pípa àwọn ará Lámánì.

39 Ó sì ṣe tí ẹ̀rù bá àwọn ará Lámánì, nítorí ìparun nlá èyítí ó wà lãrín nwọn, àní tó bẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí sálọ sí apá ìhà odò Sídónì.

40 Léhì àti àwọn ará rẹ̀ sì sá tẹ̀lé nwọ́n; Léhì sì lé nwọn sínú omi Sídónì, nwọ́n sì la omi Sídónì kọjá. Léhì sì dá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dúró ní etí bèbè odò Sídónì, pé kí nwọ́n má da kọjá.

41 Ó sì ṣe tí Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ bá àwọn ará Lámánì pàdé ní inú àfonífojì nã, ní òdì kejì odò Sídónì, nwọ́n sì npa nwọ́n.

42 Àwọn ará Lámánì sì tún sá níwájú nwọn, sí apá ilẹ̀ Mántì; àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì sì tún bá nwọn pàdé.

43 Nísisìyí ní báyĩ àwọn ará Lámánì jà kíkan-kíkan; bẹ̃ni, a kò ríi rí kí àwọn ará Lámánì ó jà pẹ̀lú agbára kíkan-kíkan àti ìgboyà bẹ̃, kò rí bẹ̃ pẹ̀lú láti ìbẹ̀rẹ̀ wá.

44 Nwọ́n sì gba agbára láti ọwọ́ àwọn ará Sórámù àti àwọn ará Ámálẹ́kì, tí nwọn jẹ́ olórí ológun nwọn àti olùdarí nwọn, àti Sẹrahẹ́múnà, tĩ ṣe ọ̀gágun àti olùdarí àgbà nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n jà bí drágónì, tí a sì pa púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì nípasẹ̀ ọwọ́ nwọn, bẹ̃ni, nítorítí nwọ́n la púpọ̀ nínú àwọn ìhámọ́ra nwọn tí nwọ́n fi bò orí sí méjì, nwọ́n sì gún púpọ̀ nínú àwọn ìhámọ́ra àwo àyà nwọn, nwọ́n gé púpọ̀ nínú apá nwọn kúrò; báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì ṣe pa àwọn ará Nífáì nínú ìgbóná ìbínú nwọn.

45 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ohun tí ó nta àwọn ará Nífáì jí dára ju ti àwọn ará Lámánì, nítorítí nwọn kò jà fún ìjọba tàbí àṣẹ, ṣùgbọ́n nwọn njà fún ilẹ̀ àti òmìnira nwọn, àwọn aya nwọn àti àwọn ọmọ nwọn, àti ohun gbogbo tí nwọ́n ní, bẹ̃ni, fún ìlànà ẹ̀sìn nwọn àti ìjọ-onígbàgbọ́ nwọn.

46 Nwọ́n sì nṣe èyítí nwọ́n lérò wípé íṣe ojúṣe èyítí ó tọ́ sí Ọlọ́run nwọn; nítorítí Olúwa ti sọ fún nwọn, àti fún àwọn bàbá nwọn pẹ̀lú pé: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kò jẹ̀bi ohun ìkọ̀sẹ̀ èkíní, tàbí èkejì, ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ fi ara nyín sílẹ̀ fún pípa nípasẹ̀ ọwọ́ àwọn ọ̀tá nyín.

47 Àti pẹ̀lú, Olúwa ti wípé: Ẹ̀yin yíò dãbò bò àwọn ìdílé nyín àní títí dé ojú ìtàjẹ̀sílẹ̀. Nítorínã fún ìdí èyí ni àwọn ará Nífáì ṣe njà pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, láti dãbò bò ara nwọn, àti àwọn ìdílé nwọn, àti ilẹ̀ nwọn, orílẹ̀-èdè nwọn, àti ẹ̀tọ́ nwọn, àti ẹ̀sìn nwọn.

48 Ó sì ṣe, nígbàtí àwọn arákùnrin Mórónì rí ìgbóná àti ìrunú àwọn ará Lámánì, nwọ́n ṣetán láti dáwọ́dúró kí nwọ́n sì sálọ kúrò níwájú nwọn. Mórónì nã, nítorítí ó rí ohun tí nwọ́n fẹ́ ṣe, ó ránṣẹ́ ó sì kì nwọ́n láyà pẹ̀lú èrò wọ̀nyí—bẹ̃ni, èrò nípa ilẹ̀ nwọn, òmìnira nwọn, bẹ̃ni, ìtúsílẹ̀ nwọn kúrò nínú ìgbèkùn.

49 Ó sì ṣe tí nwọ́n yí padà dojúkọ àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì jọ képe Olúwa Ọlọ́run nwọn ní ohun kan, fún òmìnira nwọn àti ìtúsílẹ̀ nwọn kúrò nínú ìgbèkùn.

50 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dojúkọ àwọn ará Lámánì pẹ̀lú agbára; àti pé ní wákàtí kannã tí nwọ́n ké pe Olúwa fún òmìnira nwọn, àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú nwọn; nwọ́n sì sá lọ àní sí odò Sídónì.

51 Nísisìyí, àwọn ará Lámánì pọ̀ jù nwọ́n lọ, bẹ̃ni, kọjá ọ̀nà ìlọ́po méjì iye àwọn ará Nífáì; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n lé nwọn tó bẹ̃ tí nwọ́n fi kó ara nwọn jọ ní agbo kanṣoṣo nínú àfonífojì nã, ní etí bèbè ní ẹ̀gbẹ́ odò Sídónì.

52 Nítorínã àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì yí nwọn ká, bẹ̃ni, àní ní ẹ̀gbẹ́ mèjèjì odò nã, nítorí kíyèsĩ, ní apá ìlà-oòrùn ni àwọn ènìyàn Léhì wà.

53 Nítorínã nígbàtí Sẹrahẹ́múnà rí àwọn ènìyàn Léhì ní apá ìlà-oòrùn odò Sídónì, àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ní apá ìwọ̀-oòrùn odò Sídónì, pé àwọn ará Nífáì ti yí nwọn ká, ìpayà bá nwọn.

54 Nísisìyí, nígbàtí Mórónì rí ìpayà nwọn, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí nwọ́n dáwọ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀ nwọn dúró.