Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 56


Orí 56

Hẹ́lámánì kọ ìwé ránṣẹ́ sí Mórónì, nínú èyítí ó ti sọ nípa bí ogun nã pẹ̀lú àwọn ará Lámánì ti nlọ—Ántípọ́sì pẹ̀lú Hẹ́lámánì ní ìṣẹ́gun nlá lórí àwọn ará Lámánì—Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹgbẹ̀rún méjì Hẹ́lámánì jà pẹ̀lú agbára ìyanu, kò sì sí èyítí nwọ́n pa nínú nwọn. Ẹsẹ 1, ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa; ẹsẹ 2 sí 19, ní ìwọ̀n ọdún 66 kí a tó bí Olúwa wa; àti ẹsẹ 20 sí 57, ní ìwọ̀n ọdún 65 sí 64 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ̀n ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ní ọjọ́ kejì nínú oṣù kíni, Mórónì gba ìwé láti ọ̀dọ̀ Hẹ́lámánì, tí ó sọ nípa ìṣesí àwọn ènìyàn tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ nã.

2 Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ, wípé: Arákùnrin mi ọ̀wọ́n, Mórónì, nínú Olúwa àti nínú ìpọ́njú ti ogun tí à njà; kíyèsĩ, arákùnrin mi ọ̀wọ́n, mo ní ohun kan láti wí fún ọ nípa ogun tí à njà ní agbègbè yĩ.

3 Kíyèsĩ, ẹgbẹ̀rún méjì nínú àwọn ọmọ àwọn ènìyàn tí Ámọ́nì kó jáde kúrò nínú ilẹ̀ Nífáì—nísisìyí ìwọ ti mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ àtẹ̀lé Lámánì, tĩ ṣe ọmọkùnrin tí ó dàgbà jùlọ nínú àwọn ọmọ bàbá wa Léhì;

4 Nísisìyí kò yẹ kí èmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún ọ nípa àwọn àṣà tàbí àìgbàgbọ́ nwọn, nítorítí ìwọ mọ̀ nípa gbogbo ohun wọ̀nyí—

5 Nítorínã ni ó ṣe tọ́ fún mi láti wí fún ọ pé ẹgbẹ̀rún méjì nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí ni ó ti kó àwọn ohun ìjà-ogun nwọn, tí nwọ́n sì fẹ́ kí èmi ó jẹ́ olórí nwọn; àwa sì ti jáde wá láti dãbò bò orílẹ̀-èdè wa.

6 Àti nísisìyí ìwọ sì mọ̀ nípa májẹ̀mú tí àwọn bàbá nwọn ti dá, pé àwọn kò ní gbé ohun ìjà nwọn sókè kọlũ àwọn arákùnrin nwọn fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.

7 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n, nígbàtí nwọ́n rí àwọn ìjìyà wa àti àwọn ìpọ́njú wa lórí nwọn, nwọ́n ṣetán láti sẹ́ májẹ̀mú nã èyítí nwọ́n ti dá kí nwọn sì gbé ohun ìjà-ogun nwọn fún ìdãbò bõ wa.

8 Ṣùgbọ́n èmi kò gbà fún nwọn pé kí nwọn sẹ́ májẹ̀mú yĩ èyítí nwọ́n ti dá, nítorípé èmi rõ pé Ọlọ́run yíò fún wa ni okun, tóbẹ̃ tí àwa kò ní jìyà mọ́ nítorí ti pípa májẹ̀mú nã mọ́ èyítí nwọ́n ti dá.

9 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohun kan nìyí nínú èyítí àwa lè ní ayọ̀ púpọ̀. Nítorí kíyèsĩ, nínú ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n nã, èmi; Hẹ́lámánì, lọ níwájú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹgbẹ̀rún méjì yĩ sí ìlú-nlá Jùdéà, láti ran Ántípọ́sì lọ́wọ́, ẹnití ìwọ ti yàn ní olórí lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní apá ilẹ̀ nã lórí.

10 Èmi sì dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ẹgbẹ̀rún méjì pọ̀, (nítorí nwọ́n yẹ lati pè ní ọmọ) mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì, nínú agbára èyítí Ántípọ́sì dunnú gidigidi; nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ti dín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kù nítorípé àwọn ọmọ ogun nwọn ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa, nítorí ìdí èyítí àwa ṣọ̀fọ̀.

11 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwa lè tu ara wa nínú ní ti òtítọ́ yĩ, pé nwọ́n kú nínú ìjà-òmìnira ti orílẹ̀-èdè nwọn àti ní ti Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, inu nwọn dun.

12 Àwọn ará Lámánì sì ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́rú, gbogbo nwọ́n sì jẹ́ àwọn olórí ológun, nítorítí kò sí ẹlòmíràn tí ó wà lãyè. Àwa sì rõ wípé ní àkoko yĩ nwọ́n wà nínú ilẹ̀ Nífáì; báyĩ ni ó sì rí bí nwọ́n kò bá pa nwọ́n.

13 Àti nísisìyí àwọn wọ̀nyí ni àwọn ìlú-nlá ti àwọn ará Lámánì ti gbà fún ìní nípa títa ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa akíkanjú sílẹ̀:

14 Ilẹ̀ Mántì, tàbí ìlú-nlá Mántì, àti ìlú-nlá Sísrọ́mù, àti ìlú-nlá Kúménì, àti ìlú-nlá Ántípárà.

15 Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n gbà fún ìní nígbàtí mo dé inú ìlú-nlá Jùdéà; tí mo sì rí Ántípọ́sì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí nwọn nṣiṣẹ́ tagbáratagbára láti dãbò bò ìlú-nlá nã.

16 Bẹ̃ni, nwọ́n sì kãárẹ̀ ní ara àti ní ẹ̀mí, nítorítí nwọ́n ti jà tagbáratagbára ní ọ̀sán tí nwọ́n sì ṣiṣẹ́ ní alẹ́ láti pa àwọn ìlú-nlá nwọn mọ́; báyĩ sì ni ìyà nlá-nlà lóríṣiríṣi ṣe jẹ nwọ́n.

17 Àti nísisìyí nwọ́n ti pinnu láti ní ìṣẹ́gun ní ibí yĩ tàbí kí nwọ́n kú; nítorínã ìwọ lè rõ pé àwọn ọmọ ogun díẹ̀ tí èmi mú wá pẹ̀lú mi yĩ, bẹ̃ni, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi wọnnì, fún nwọn ní ìrètí nlá àti ọ̀pọ̀ ayọ̀.

18 Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé Ántípọ́sì ti gba agbára kún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, nípa àṣẹ Ámmórọ́nì ni nwọn kò ṣe kọlu ìlú-nlá Jùdéà, tàbí kọlũ wá, ní ogun.

19 Báyĩ sì ni àwa ṣe rí ojú rere Olúwa; nítorípé tí nwọ́n bá kọlu wá ní ipò àìlera yĩ nwọn ìbá ti pa ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa kékèké run; ṣùgbọ́n báyĩ ni Olúwa ṣe pa wá mọ́.

20 Ámmórọ́nì pàṣẹ fún nwọn láti pa àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti mú mọ́. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n parí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n ni àwa sì palẹ̀ ìlú-nlá wa àti ara wa mọ́ fún ìdãbò bò.

21 Nísisìyí àwa ní ìfẹ́ kí àwọn ará Lámánì wá kọlũ wá; nítorítí àwa kò ní ìfẹ́ láti kọlũ nwọ́n nínú ibi ìsádi nwọn.

22 Ó sì ṣe tí àwa fi àwọn alamí sí àwọn àyíká wa, láti ṣọ́ ìrìn àwọn ará Lámánì, láti má lè kọjá wá ní alẹ́ tàbí ní ọ̀sán láti kọlu àwọn ìlú-nlá wa yókù tí nwọ́n wà ní apá àríwá.

23 Nítorítí àwa mọ̀ pé ní àwọn ìlú-nlá nnì nwọn kò lágbára tó láti dojúkọ nwọn; nítorínã ni àwa ṣe ní ìfẹ́, pé bí nwọ́n bá kọjá lára wa, láti kọlũ nwọ́n láti ẹ̀hìn, kí a sì bá nwọn jà ní apá ẹ̀hìn ní àkokò kannã tí nwọ́n bá nbá nwọn jà ní iwájú. Àwa rò wípé àwa leè borí nwọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa rí ìjákulẹ̀ lórí èrò wa yĩ.

24 Nwọn kò kọjá lára wa pẹ̀lú gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, bẹ̃ni nwọn kò kọjá pẹ̀lú díẹ̀ nínú nwọn, kí nwọ́n má bã wà láìlágbára tó kí nwọ́n ó sì ṣubú.

25 Bẹ̃ni nwọn kò sì kọjá lọ kọlu ìlú-nlá Sarahẹ́múlà; bẹ̃ni nwọn kò sì da orísun odò Sídónì kọjá lọ sínú ìlú-nlá Nífáìhà.

26 Àti báyĩ, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, nwọ́n pinnu láti di àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti gbà mú.

27 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní oṣù kejì ọdún yĩ, tí àwọn bàbá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ẹgbẹ̀rún méjì nnì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèsè oúnjẹ tọ̀ wá wá.

28 Àti pẹ̀lú a fi ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún méjì ránṣẹ́ sí wa láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Báyĩ sì ni àwa ṣe múrasílẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún mẹ́wã, àti ìpèsè oúnjẹ fún wọn, àti fún àwọn ìyàwó wọn pẹ̀lú àti àwọn ọmọ wọn.

29 Àti àwọn ará Lámánì, nítorípé nwọ́n ríi tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa npọ̀síi lójojúmọ́, tí àwọn ìpèsè oúnjẹ sì nwọlé fún ìtọ́jú wa, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sá jáde láti kọlũ wá, láti fi òpin síi fún wa bí ó bá lè rí bẹ̃ fun gbígba àwọn ìpèsè oúnjẹ àti agbára.

30 Nísisìyí nígbàtí a ríi pé àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí wà láìfọkànbalẹ̀ báyĩ, àwa ní ìfẹ́ láti ta ọgbọ́n kan fún wọn; nítorínã Ántípọ́sì pàṣẹ pé kí èmi ó kọjá lọ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi sínú ìlú-nlá kan tí ó wà nítosí, bí ẹnipé à nkó ìpèsè oúnjẹ lọ sínú ìlú-nlá kan tí ó wà nítosí.

31 Àwa sì níláti kọjá lọ nítòsí ìlú-nlá Ántípárà, bí ẹnipé à nlọ sí ìlú-nlá tí ó wà lókè réré, ní ibi ìhà ilẹ̀ létí bèbè òkun.

32 Ó sì ṣe tí àwa kọjá lọ, bí ẹnití nlọ pẹ̀lú ìpèsè oúnjẹ wa, láti lọ sínú ìlú-nlá nã.

33 Ó sì ṣe tí Ántípọ́sì kọjá lọ pẹ̀lú apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó sì fi àwọn tí ó kù sílẹ̀ láti dãbò bò ìlú-nlá nã. Ṣùgbọ́n kò kọjá lọ àfi ìgbàtí èmi ti kọjá lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi kékeré, tí mo sì ti súnmọ́ ìlú-nlá Ántípárà.

34 Àti nísisìyí, ní ìlú-nlá Ántípárà ni nwọ́n fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí ó lágbára jùlọ sí; bẹ̃ni, èyítí ó pọ̀ púpọ̀ jùlọ.

35 Ó sì ṣe, nígbàtí àwọn amí nwọn ti ṣe amí fún nwọn, nwọ́n jáde wá pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn nwọ́n sì kọlũ wá.

36 Ó sì ṣe tí àwa sì sá níwájú nwọn, lọ sí apá àríwá. Báyĩ sì ni àwa tan ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí ó lágbára jùlọ, lọ.

37 Bẹ̃ni, àní lọ sí ibití ó jìnà díẹ̀, tóbẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé nígbàtí nwọ́n rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì tí ó nsá tẹ̀lé wọn, pẹ̀lú agbára nwọn, nwọn kò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì, ṣùgbọ́n nwọ́n tẹ̀síwájú nínú sísá tẹ̀lé wa; àti pé gẹ́gẹ́bí àwa ṣe rò, èrò ọkàn wọn ni láti pa wá kí Ántípọ́sì tó bá wọn, èyí sì jẹ́ bẹ̃ kí àwọn ènìyàn wa má bã ká wọn mọ́.

38 Àti nísisìyí Ántípọ́sì, nígbàtí ó rí inú ewu tí a wà, ó mú kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ ó kọjá ní kánkán. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ilẹ̀ ti ṣú; nítorínã nwọn kò bá wa, bẹ̃ sì ni Ántípọ́sì kò bá wọn; nítorínã ni àwa ṣe pàgọ́ fún alẹ́ ọjọ́ nã.

39 Ó sì ṣe pé kí ilẹ̀ tó mọ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì nlé wa bọ̀. Nísisìyí, àwa kò lágbára tóbẹ̃ láti bá nwọ́n jà; bẹ̃ni, èmi kò ní jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ó ṣubú sí nwọn lọ́wọ́; nítorínã ni àwa ṣe tẹ̀síwájú nínú ìrìn wa, tí a sì kọjá lọ sínú aginjù.

40 Nísisìyí nwọn kò yà sí apá ọ̀tun tàbí apá òsì kí nwọn ó má bà lè ká nwọn mọ́; bẹ̃ sì ni emí kò ní yà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì kí nwọn ó má bà lè bá mi, àwa kò sì lè dojúkọ nwọ́n, bíkòṣepé nwọn ó pa wá, tí nwọn ó sì sálọ; bayĩ àwa si salọ sínú aginjù ní gbogbo ọjọ́ nã, àní títí ilẹ̀ fi ṣú.

41 Ó sì ṣe pé, nígbàtí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́ a rí àwọn ará Lámánì nã tí nwọ́n nbọ̀ wá bá wa, àwa sì sálọ níwájú nwọn.

42 Ṣùgbọ́n ó ṣe tí nwọn kò lé wa jìnà kí nwọn ó tó dúró; ó sì jẹ́ òwúrọ̀ ọjọ́ kẹ́ta nínú oṣù kéje.

43 Àti nísisìyí, bóyá Ántípọ́sì lé nwọn bá àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n èmi wí fún àwọn ọmọ ogun mi pé: Ẹ kíyèsĩ, àwa lérò wípé nwọ́n dúró nítorítí àwa yíò wá íkọlù nwọ́n, kí nwọn lè mú wa nínú ìkẹ́kùn wọn;

44 Nítorínã kíli ẹ̀yin wí, ẹ̀yín ọmọ mi, njẹ́ ẹ̀yin ó tọ̀ nwọ́n lọ ní ogun?

45 Àti nísisìyí èmi wí fún ọ, arákùnrin mi ọ̀wọ́n Mórónì, pé èmi kò rí irú ìgboyà tí ó tóbi tó èyí rí, rárá, kò sí lãrín àwọn ará Nífáì.

46 Nítorípé bí èmi ti npè nwọ́n ní ọmọ mi (nítorípé ọ̀dọ́mọdé ni gbogbo nwọn) gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti nwí fún mi pé: Bàbá, kíyèsĩ Ọlọ́run wa wà pẹ̀lú wa, òun kò sì ní jẹ́ kí a ṣubú; jẹ́ kí a jáde lọ nígbànã; àwa kò ní pa àwọn arákùnrin wa bí nwọ́n bá fi wá sílẹ̀; nítorínã jẹ́ kí a lọ, kí nwọn má bà lè borí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì.

47 Nísisìyí nwọn kò jà rí síbẹ̀síbẹ̀ nwọn kò bẹ̀rù ikú; nwọ́n sì ronú nípa òmìnira àwọn bàbá nwọn ju bí nwọ́n ti ronú nípa ẹ̀mí ara nwọn; bẹ̃ni, àwọn ìyà nwọn tí kọ́ nwọn, pé bí nwọ́n kò bá ṣiyèméjì, Ọlọ́run yíò kó nwọn yọ.

48 Nwọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ àwọn ìyá wọn fún mi, wípé: Àwa kò ṣiyèméjì pé àwọn ìyá wa mọ̀ bẹ̃.

49 Ó sì ṣe tí mo padà pẹ̀lú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì ní ìdojúkọ àwọn ará Lámánì tí nwọ́n lé wa. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì ti lé nwọn bá, ìjà líle sì ti bẹ̀rẹ̀.

50 Nítorítí ó ti rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì, nítorípé nwọ́n rin ọ̀nà tí ó jìn ní ìwọ̀n ọjọ́ kúkúrú, nwọ́n fẹ́rẹ̀ ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì; bíkòṣepé èmi padà pẹ̀lú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì nwọn ìbá ti ṣe gẹgẹbi ìpinnu nwọn.

51 Nítorítí Ántípọ́sì ti ṣubú nípasẹ̀ idà, àti púpọ̀ nínú àwọn olórí rẹ̀, nítorípé nwọ́n kãrẹ̀, èyítí ó rí bẹ̃ nítorípé nwọ́n kọjá lọ kánkán—nítorínã àwọn ọmọ ogun Ántípọ́sì, nítorípé ìdàmú bá nwọn nítorí ṣíṣubú àwọn olórí nwọn, bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú àwọn ará Lámánì.

52 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ní ìgbóyà, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí lé nwọn lọ; báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì nlé wọn lọ pẹ̀lú agbára nígbàtí Hẹ́lámánì kọlũ nwọ́n látẹ̀hìnwá pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ẹgbẹ̀rún méjì, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì nã dáwọ́dúró tí nwọ́n sì dojúkọ Hẹ́lámánì.

53 Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn Ántípọ̀sì ríi pé ará Lámánì ti yí ẹsẹ̀ padà, nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ nwọ́n sì tún padà láti kọlũ àwọn ará Lámánì láti ẹ̀hìn.

54 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwa, àwọn ènìyàn Nífáì, àwọn ènìyàn Ántípọ́sì, àti èmi pẹ̀lú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì, ká àwọn ará Lámánì mọ́, tí a sì pa nwọ́n; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi níláti kó àwọn ohun ìjà-ogun nwọn lélẹ̀ àti ara nwọn pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí àwọn tí a kó lẹ́rú nínú ogun.

55 Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí nwọ́n ti jọ̀wọ́ ara nwọn lé wa lọ́wọ́, kíyèsĩ, mo ka àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nnì tí nwọ́n ti jà pẹ̀lú mi, nítorítí ẹ̀rù bà mí bóyá nwọn ti pa púpọ̀ nínú nwọn.

56 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, sí ayọ̀ nlá mi, kò sí ẹyọkan nínú nwọn tí ó ṣubú lulẹ̀; bẹ̃ni, nwọ́n sì ti jà bí ẹnití ó nlo agbára Ọlọ́run; bẹ̃ni, a kò mọ́ ẹnití ó ti jà pẹ̀lú agbára ìyanu báyĩ rí; àti pẹ̀lú irú ipa títóbi báyĩ tí nwọ́n fi kọlũ àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n sì dẹ́rùbà nwọ́n; àti nítorínã ni àwọn ará Lámánì fi jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ bí ẹnití a kó lẹ́rú ní ogun.

57 Àti bí àwa kò ṣe ní ãyè fún àwọn tí a kó lẹ́rú, láti lè máa ṣọ́ nwọn kí a sì mú nwọn kúrò ní ìkáwọ́ ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àwọn ará Lámánì, nítorínã ni àwa ṣe kó nwọn lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun Ántípọ̀sì tí nwọn kò pa, pẹ̀lú nwọn; àwọn tí ó kù ni mo mú tí mo sì dàpọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ará Ámọ́nì nnì, a sì kọjá lọ padà sí ìlú-nlá Jùdéà.