Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 59


Orí 59

Mórónì mú kí Pahoránì fi agbára kún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hẹ́lámánì—Àwọn ará Lámánì gba ìlú-nlá Nífáìhà—Mórónì bínú sí ìjọba. Ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí ó sì ṣe ní ọgbọ̀n ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, lẹ́hìn tí Mórónì ti gbà tí ó sì ti ka ìwé Hẹ́lámánì, inú rẹ̀ dùn púpọ̀ nítorí àlãfíà, bẹ̃ni, àṣeyọrí dáradára tí Hẹ́lámánì ti ní, lórí gbígba àwọn ilẹ̀ tí ó ti sọnù padà.

2 Bẹ̃ni, ó sì ròyìn fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, nínú gbogbo ilẹ̀ tí ó wà yíká ní apá ibi nã tí ó wà, kí nwọn ó lè yọ̀ pẹ̀lú.

3 Ó sì ṣe tí ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí Pahoránì lójú ẹsẹ̀, pé kí ó mú kí àwọn ọmọ ogun péjọ láti fi kún agbára Hẹ́lámánì, tàbí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hẹ́lámánì, nínú èyítí yíò lè se àmójutò apá ilẹ̀ nã ní ìrọ̀rùn, èyítí Ọlọ́run ti fún un ní àṣeyọrí ní ọ̀nà ìyanu láti gbà padà.

4 Ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti fi ìwé yĩ ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe ètò láti lè gba àwọn ìní àti àwọn ìlú-nlá tí ó kù èyítí àwọn ará Lámánì ti gbà lọ́wọ́ nwọn.

5 Ó sì ṣe pé bí Mórónì ṣe nṣe ìmúrasílẹ̀ láti lọ kọlũ àwọn ará Lámánì ní ogun, kíyèsĩ, àwọn ènìyàn Nífáìhà, tí nwọ́n ti kójọ papọ̀ láti ìlú-nlá Mórónì àti ìlú-nlá Léhì àti ìlú-nlá Mọ́ríátọ́nì, ni àwọn ará Lámánì sì kọlù.

6 Bẹ̃ni, àní àwọn tí nwọ́n ti sá jáde kúrò nínú ilẹ̀ Mántì, àti kúrò nínú àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní àyíká, ni nwọ́n wá tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì ní apá ilẹ̀ yĩ.

7 Bí nwọ́n sì ti pọ̀ púpọ̀ báyĩ, bẹ̃ni, àti nítorípé nwọ́n ngba ìrànlọ́wọ́ ọmọ ogun lójojúmọ́, nípa àṣẹ Ámmórọ́nì nwọ́n jáde láti kọlũ àwọn ènìyàn Nífáìhà, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n ní ìpakúpa.

8 Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn sì pọ̀ púpọ̀ tí àwọn tí ó kù nínú àwọn ènìyàn Nífáìhà níláti sálọ níwájú nwọn; tí nwọ́n sì wá pẹ̀lú tí nwọn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì.

9 Àti nísisìyí nítorítí Mórónì ti lérò pé nwọn yíò fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sínú ìlú-nlá Nífáìhà, fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí yíò ṣọ́ ìlú-nlá nã, àti nítorípé ó mọ̀ pé ó rọrùn láti pa ìlú-nlá nã mọ́ láti má bọ́ sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì jù láti gbã padà lọ́wọ́ nwọn, ó lérò wípé nwọn yíò ṣọ́ ìlú-nlá nã ní ìrọ̀rùn.

10 Nítorínã ni ó ṣe dá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dúró láti ṣọ́ àwọn ibití nwọ́n ti gbà padà.

11 Àti nísisìyí, nígbàtí Mórónì ríi pé nwọ́n ti sọ ìlú-nlá Nífáìhà nù ó banújẹ́ púpọ̀púpọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣiyèméjì, nítorí ti ìwà búburú àwọn ènìyàn nã, pé bóyá nwọn kò ní ṣubú sí ọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn.

12 Nísisìyí èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn olórí ológun rẹ̀. Nwọ́n ṣiyèméjì ẹnu sì yà nwọ́n pẹ̀lú nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn nã, èyí sì rí bẹ̃ nítorí àṣeyọrí tí àwọn ará Lámánì ní lórí nwọn.

13 Ó sì ṣe tí Mórónì bínú sí ìjọba nã, nítorí àìnãní òmìnira orílẹ̀ èdè nwọn.