Àwọn Ìwé Mímọ́
Járọ́mù 1


Ìwé ti Járọ́mù

Ori 1

Àwọn ará Nífáì pa òfin Mósè mọ́, nwọn nretí bíbọ̀ Krístì, nwọ́n sì ṣe rere ní ilẹ̀ nã—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlĩ ni nwọ́n siṣẹ́ láti mú àwọn ènìyàn nã dúró ní ọ̀nà òdodo. Ní ìwọ̀n ọdún 399 sí 361 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èmi, Járọ́mù, kọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ gẹ́gẹ́bí àṣẹ bàbá mi, Énọ́sì, kí a bã pa ìtàn ìdílé wa mọ́.

2 Nítorípé àwọn àwo wọ̀nyí kéré, àti nítorípé a kọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ànfãní àwọn arákùnrin wa àwọn ará Lámánì, nítorí-èyi, ó di dandan kí èmi kọ díẹ̀; ṣùgbọ́n èmi kò ní kọ àwọn nkan ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí àwọn ìfihàn mi. Nítorí kíni èmi ìbá tún lè kọ ju èyí tí àwọn bàbá mi tĩ kọ? Njẹ́ nwọn kò ha ti fi ìlàna ìgbàlà hàn bí? Mo wí fún nyín, Bẹ̃ni; èyí sì ti tó fún mi.

3 Ẹ kíyèsĩ, ó yẹ kí a ṣe iṣẹ́ púpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn yĩ, nítorítí líle ọkàn nwọn, àti dídi etí nwọn, àti rírá iyè nwọn, àti líle ọrùn nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọlọ́run ní ãnú púpọ̀ lórí nwọn, kò sì tĩ gbá nwọ́n kúrò lórí ilẹ̀.

4 Púpọ̀ sì wà lãrín wa tí nwọ́n ní ìfihàn púpọ̀, nítorítí kĩ ṣe gbogbo nwọn nĩ ṣe ọlọ́run líle. Gbogbo àwọn tí nwọn kò sì jẹ́ ọlọ́rùn líle tí nwọ́n sì ní ígbàgbọ́, ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití ó fi ara rẹ̀ han àwọn ọmọ ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn.

5 Àti nísisìyí, sì kíyèsĩ, ọgọ̃rún méjì ọdún ti kọjá lọ, àwọn ará Nífáì sì ti di alágbára lórí ilẹ̀ nã. Nwọ́n pa òfin Mósè mọ́ nwọn sì ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ fún Olúwa. Nwọn kò sì sọ̀rọ̀ àìmọ́; tàbí ọ̀rọ̀ àìtọ́. Àwọn òfin ìlú nã sì tọnà púpọ̀.

6 Nwọ́n sì gbilẹ̀ sí ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àti àwọn ara Lámánì pẹ̀lú. Nwọ́n sì pọ̀ púpọ̀ ju àwọn ará Nífáì; nwọ́n sì fẹ́ràn ìpànìyàn, nwọn á sì máa mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹranko.

7 Ó sì ṣe tí nwọ́n kọlũ àwa ará Nífáì ní ìgbà púpọ̀, láti jagun. Ṣùgbọ́n àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa jẹ́ alágbára ènìyàn nínú ìgbàgbọ́ Olúwa; nwọ́n sì kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ọ̀nà Olúwa; nítorí-èyi a kọjú ìjà sí àwọn ará Lámánì, a sì lé nwọn jáde kúrò lórí àwọn ilẹ̀ wa, a sì bẹ̀rẹ̀ sí ndábóbò àwọn ìlú wa, tàbí gbogbo ibi ohun-ìní wa.

8 Àwa sí pọ̀ ní ìlọ́po-ìlọ́po, a sì tànká orí ilẹ̀ nã, a sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀ nínú wúrà àti fàdákà, àti nínú àwọn ohun iyebíye, àti nínú iṣẹ́ ọnà igi dáradára, ní àwọn ilé kíkọ́, àti nínú ẹ̀rọ, àti ní irin lílò, àti bàbà, àti idẹ, àti irin líle, a sì nrọ oríṣiríṣi ohun èlò tí a fi ndáko, àti ohun-ìjà ogun—bẹ̃ni, ọfà ẹlẹ́nu mímú, àti apó-ọfà, àti ọ̀kọ̀ kútúpú, àti ọ̀kọ̀, àti gbogbo ìmúrasílẹ̀ fún ogun.

9 Nítorípé a ti múrasílẹ̀ láti dojúkọ àwọn ará Lámánì, nwọn kò borí wa. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa di jíjẹ́rĩ sí, èyítí ó sọ fún àwọn bàbá wa, wípé: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã.

10 Ó sì ṣe tí àwọn wòlĩ Olúwa kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn Nífáì, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pé tí nwọn kò bá pa àwọn òfin nã mọ́, tí nwọ́n sì ṣubú sínú ìwà ìrekọjá, a o pa nwọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ nã.

11 Nítorí-èyi àwọn wòlĩ, àti àwọn àlùfã, àti àwọn olùkọ́ nã ṣiṣẹ́ láìsinmi, ní gbígba àwọn ènìyàn níyànjú sí ìtara, pẹ̀lú ìpamọ́ra; nwọ́n nkọ́ òfin Mósè, àti ìdí tí a fifún ni; nwọn nyí nwọn lọ́kàn padà pé kí nwọ́n fojúsọ́nà sí Messia, kí nwọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ pé ó nbọ̀ bí èyítí ó ti wá. Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe kọ́ nwọn.

12 Ó sì ṣe tí ó jẹ́ wípé ní ṣíṣe báyĩ nwọ́n pa nwọ́n mọ́ kúrò nínú ìparun lórí ilẹ̀ nã; nítorítí nwọ́n tọ́ ọkàn nwọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nã, nwọ́n sì ntawọ́njí láìdẹ́kun sí ìrònúpìwàdà.

13 Ó sì ṣe tí ọgọ̃rún méjì ọdún ó lé ọgbọ̀n àti méjọ ti kọjá—lẹ́hìn irú àwọn ogun àti ìjà, àti ìyapa fún ìwọ̀n ọjọ́ pípẹ́.

14 Èmi, Járọ́mù, kò kọ jù bẹ̃ lọ nítorítí àwọn àwo nã kéré. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ lè lọ sí àwọn àwo ti Nífáì míràn; nítorí kíyèsĩ, lórí wọn ni a gbẹ́ àkọsílẹ̀ ìwé ìtàn àwọn ogun tí a jà sí, gẹ́gẹ́bí kíkọ ti àwọn ọba, tàbí àwọn tí nwọ́n ní kí nwọ́n kọ.

15 Èmi sì fi àwọn àwo wọ̀nyí lé ọwọ́ ọmọ mi Ómúnì, kí a lè pa nwọ́n mọ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ àwọn bàbá mi.