Àwọn Ìwé Mímọ́
Ómúnì 1


Ìwé ti Ómúnì

Ori 1

Ómúnì, Ámárọ́nì, Kẹ́míṣì, Ábínádọ́mù, àti Ámálẹ́kì, kọ ìwé ìrántí ní ọkàn lẹ́hìn ìkejì—Mòsíà ṣe alábápàdé àwọn ará Sarahẹ́múlà, tí nwọ́n wá láti Jerúsálẹ́mù ní àkókò Sẹdẹkíàh—A fi Mòsíà ṣe ọba lórí nwọn—Àwọn ọmọ Múlẹ́kì tí nwọ́n wà ní Sarahẹ́múlà ti ṣe alábápàdé Kóríántúmúrì, èyítí ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Járẹ́dì—Ọba Bẹ́njámínì rọ́pò Mòsíà—Ènìyàn níláti fi ẹ̀mí nwọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọrẹ sí Krístì. Ní ìwọ̀n ọdún 323 sí 130 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí èmi, Ómúnì, tí bàbá mi Járọ́mù pàṣẹ fún, pé kí èmi kọ díẹ̀ sínú àwọn àwo wọ̀nyí, fún pípa ìtàn ìdílé wa mọ́.

2 Nítorí-èyi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, èmi fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé mo jà púpọ̀ pẹ̀lú idà fún ìpamọ́ àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, láti ma jẹ́ kí nwọ́n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi pãpã jẹ́ ènìyàn búburú, èmi kò sì pa àwọn ìlànà àti àwọn òfin Olúwa mọ́ bí ó ṣe yẹ ki emi ṣe.

3 Ó sì ṣe, tí ọgọ̃rún méjì ọdún àti ãdọ́rin àti mẹ́fà ti kọjá, a sì ní àlãfíà fún ìgbà pípẹ́; a sì ní ogun gbígbóná àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Bẹ̃ni, ní àkópọ̀, ọgọ̃rún ọdún méjì àti ọgọ̃rin àti méjì ti kọjá lọ, èmi sì ti pa àwọn àwo yĩ mọ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ àwọn bàbá mi; èmi sì fi nwọ́n fún ọmọ mi Ámárọ́nì. Mo sì fi òpin sĩ.

4 Àti nísisìyí èmi, Ámárọ́nì, kọ gbogbo àwọn ohun èyíkeyĩ tí mo kọ, tí nwọ́n jẹ́ díẹ̀, sí inú ìwé bàbá mi.

5 Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ọgọ̃rún mẹ́ta àti ogun ọdún ti kọjá lọ, tí àwọn tí ó burú jù nínú àwọn ará Nífáì ti ṣègbé.

6 Nítorítí Olúwa kì yíò jẹ́ kí nwọ́n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, lẹ́hìn tí ó ti mú nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, bẹ̃ni, kì yíò jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ ṣe aláì di mímọ̀, èyí tí ó sọ fún àwọn bàbá wa, wípé: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin kò ní ṣe rere ní orí ilẹ̀ nã.

7 Nítorí-èyi, Olúwa bẹ̀ wọ́n wò nínú ìdájọ́ nlá; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó pa àwọn olódodo mọ́, kí nwọn ma bã parun, pẹ̀lú pé ó gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn.

8 Ó sì ṣe, tí èmi gbé àwọn àwo nã lé arákùnrin mi Kẹ́míṣì lọ́wọ́.

9 Nísisìyĩ èmi, Kẹ́míṣì, kọ àwọn ohun díẹ̀ tí èmi kọ, nínú ìwé kan nã pẹ̀lú arákùnrin mi; nítorí kìyésĩ, èmi rí èyí tí ó kọ gbẹ̀hìn, pé ó kọọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀; ó sì kọọ́ ní ọjọ́ tí ó fi nwọ́n lé mi lọ́wọ́. Báyĩ ni àwa ṣe kọ ìwé ìtán wọ̀nyí, nítorí ó jẹ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ àwọn bàbá wa. Èmi sì fi òpin si.

10 Kíyèsĩ, Èmi, Ábínádọ́mù, jẹ́ ọmọ Kẹ́míṣì. Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí èmi rí ogun àti ìjà lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, àti àwọn ará Lámánì; èmi sì ti fi idà mi gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Lámánì ní dídá àbò bò àwọn arákùnrin mi.

11 Sì kíyèsĩ, ìwé ìrán àwọn ènìyàn yĩ wà ní fífín lé orí àwọn àwo tí ó wà lọ́wọ́ àwọn ọba, láti ìran dé ìran; èmi kò sì mọ́ ìfihàn míràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti kọ, tàbí àsọtẹ́lẹ̀ míràn; nítorí-èyí: èyí tí ó tọ́ ni a ti kọ. Èmi sì fi òpin si.

12 Kíyèsĩ, èmi ni Ámálẹ́kì, ọmọ Ábínádọ́mù. Kíyèsĩ, èmi yíò bá nyín sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa Mòsíà, ẹnití a fi jẹ ọba lórí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; nítorí kíyèsĩ, ẹnití a ti kìlọ̀ fún nípasẹ̀ Olúwa, pé kí ó sá kúrò ní ilẹ̀ Nífáì, àti pé gbogbo àwọn tí nwọn yíò gbọ́ran sí ohùn Olúwa níláti fi ìlú nã sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ, lọ sínú aginjù—

13 Ó sì ṣe tí ó ṣe gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pàṣẹ fún un. Nwọ́n sì fi ìlú nã sílẹ̀ lọ sínú aginjù, gbogbo àwọn tí nwọn yíò gbọ́ran sí ìpè Olúwa; a sì darí nwọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀. A sì ngbà nwọ́n ní ìyànjú nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; a sì ndarí nwọn nípa agbára ọwọ́ rẹ̀, lãrín aginjù títí nwọn fi dé inú ilẹ̀ èyítí à npè ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

14 Nwọ́n sì ṣe alabapade àwọn ènìyàn kan láìròtẹ́lẹ̀, tí à npè ní àwọn ènìyàn Sarahẹ́múlà. Nísisìyí, àjọyọ̀ púpọ̀ wa lãrín àwọn ará Sarahẹ́múlà; Sarahẹ́múlà nã sì yọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú, nítorí Olúwa ti ran àwọn ará Mòsíà pẹ̀lú àwọn àwo idẹ èyítí a kọ ìwé ìtàn àwọn Jũ le.

15 Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí Mòsíà ní òye pé àwọn ará Sarahẹ́múlà wa láti Jerúsálẹ́mù ní ìgbà tí a mú Sẹdẹkíàh, ọba Júdà ní ìgbèkùn lọ sí Bábílọ́nì.

16 Nwọ́n sì rin ìrìn àjò nínú aginjù, a sì mú wọn la omi nlá nã já nípa ọwọ́ Olúwa, sí inú ilẹ̀ nã níbití Mòsíà ṣe alabapade nwọn; nwọ́n sì ngbé ibẹ̀ láti ìgbà nã lọ.

17 Nígbàtí Mòsíà ṣe alabapade nwọn, nwọ́n ti pọ̀ púpọ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun àti ìjà púpọ̀, nwọ́n sì tì ṣubú nípasẹ̀ idà láti ìgbà dé ìgbà; èdè nwọn sì ti dàrú; nwọn kò sì mú ìwé ìtàn kankan wá pẹ̀lú nwọn; nwọ́n sì sẹ́ wíwà Ẹlẹ́dã nwọn; ati Mòsíà tàbí àwọn ènìyàn Mòsià kò lè gbọ́ wọn yé.

18 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Mòsíà jẹ́ kí a kọ́ nwọ́n ní èdè rẹ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti kọ́ nwọn ní èdè Mòsíà, ti Sarahẹ́múlà fún nwọn ní ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ó ṣe rántí; a sì kọ wọ́n, ṣùgbọ́n kĩ ṣe sí orí àwo wọ̀nyí.

19 Ó sì ṣe tí àwọn ará Sarahẹ́múlà àti ti Mòsíà, parapọ̀, a sì yan Mòsíà ni ọba nwọn.

20 Ó sì ṣe ní àwọn ọjọ́ ti Mòsíà, a gbé òkúta nlá kan tí ó ní fífín lórí rẹ̀ tọ̃ wá; ó sì túmọ̀ fífín nã nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run.

21 Nwọ́n sì sọ nípa Kóríántúmúrì kan, àti àwọn tí a pa nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. A sì ṣe alabapade Kọriantumuri nípasẹ̀ àwọn ará Sarahẹ́múlà; ó sì gbé pẹ̀lú nwọn ní ìwọ̀n òṣùpá mẹ́sán.

22 Ó tún sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn bàbá rẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ àkọ́kọ́ sì wá láti ile ìṣọ́ gíga nã, ní ìgbà èyítí Olúwa da èdè àwọn ènìyàn nã rú; ìrorò Olúwa sì bọ́ sórí wọn gẹ́gẹ́bí ìdájọ́ rẹ̀, àwọn èyítí ó tọ́; egungun nwọn sì wà ní ìfọ́nká nínú ilẹ̀ apá àríwá.

23 Kíyèsĩ, èmi, Ámálẹ́kì, ni a bí ní àwọn ọjọ́ ti Mòsíà; èmi sì wà títí mo fi rí ikú rẹ̀; Bẹ́njámínì, ọmọ rẹ̀, sì jọba dípò rẹ̀.

24 Sì wõ, èmi ti rí, ní àwọn ọjọ́ Bẹ́njámínì ọba, ogun tí ó gbóná, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì ní ànfàní púpọ̀ lórí nwọn; bẹ̃ni tóbẹ̃gẹ́ tí Bẹ́njámínì ọba lé nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

25 Ó sì ṣe, tí èmi bẹ̀rẹ̀sí darúgbó; tí èmi kò sì ní irú-ọmọ, tí mo sì mọ́ wípé Bẹ́njámínì ọba jẹ́ ènìyàn tí ó tọ́ níwájú Olúwa, nítorí-èyi, èmi yíò gbé àwọn àwo nã fún un, tí mo sì ngba gbogbo ènìyàn níyànjú pé kí nwọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì, kí nwọ́n sì gbàgbọ́ nínú ìsọtẹ́lẹ̀, àti nínú ìfihàn, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti nínú ẹ̀bùn fífi èdè fọ̀, àti nínú títúmọ̀ èdè, àti nínú gbogbo ohun tí ó dára; nítórítí kò sí ohun tí ó dára bí kò bá ṣe wípé ó wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa: Èyítí ó sì jẹ́ búburú wá láti ọ̀dọ̀ èṣù.

26 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, èmi rọ̀ yín pé kí ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, ẹnití ìṣe Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì, kí ẹ́ sì pín nínú ìgbàlà rẹ̀, àti agbára ìràpadà rẹ̀. Bẹ̃ni, ẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi gbogbo ẹ̀mí yín fún un gẹ́gẹ́bí ọrẹ, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ãwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ sì forítì í dé òpin; gẹ́gẹ́bí Olúwa sì ti wà, a ó gbà yín là.

27 Àti nísisìyí, èmi yíò sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tí nwọ́n lọ sínú aginjù kí nwọ́n lè padà sí ilẹ̀ Nífáì; nítorítí nwọ́n pọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ láti jogún ilẹ̀ ìní nwọn.

28 Nítorí-èyi, nwọ́n kọjá lọ sí aginjù. Olórí nwọ́n jẹ́ alágbára ènìyàn, àti ọlọ́runlíle, nítorí-èyi ó dá ìjà sílẹ̀ lãrín nwọn; a sì pa gbogbo nwọn, àfi ãdọ́ta, nínú aginjù nã, nwọ́n sì tún padà sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

29 Ó sì ṣe tí nwọ́n tún mú àwọn díẹ̀ sĩ, nwọ́n sì tún mú ìrìnàjò nwọn lọ sínú aginjù.

30 Èmi, Ámálẹ́kì, sì ní arákùnrin kan tí òun nã lọ pẹ̀lú nwọn; èmi kò sì mọ̀ nípa nwọn láti ìgbà nã. Èmi sì fẹ́rẹ̀ dùbúlẹ̀ nínú ibojì mi; àwọn àwo yĩ sì ti kún. Mo sì fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ mi.