Àwọn Ìwé Mímọ́
4 Nífáì 1


Nífáì Kẹrin

Iwé ti Nífáì
Ẹnití Í Ṣe Ọmọ Nífáì—Ọ̀kan Nínú Àwọn Ọmọ-Ẹ̀hin Jésù Krístì

Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn Nífáì, gégẹ́bí àkọsílẹ̀ rẹ̀.

Ori 1

A yi àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì lọ́kànpadà sí ọdọ Olúwa—Wọ́n ṣe àjùmọ̀ní ohun gbogbo, won ṣe iṣẹ́ ìyanu, wọn sì ṣe rere ní ilẹ̀ nã—Lẹ́hin igba ọdún, awọn ìyapa, ìwà ibi, àwọn ìjọ èké, àti inúnibíni dìde ní ãrín wọn—Lẹ́hìn ọ̃dúnrún ọdun, àti àwọn ara Nífàí àti àwọn ara Lámánì di ènìyàn búburú—Ámmórọ́nì gbé àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã pamọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 35 sí 321 nínú ọjọ Olúwa wa.

1 O sì ṣe tí ọdun kẹrìnlélọ́gbọ̀n kọjá lọ, àti ọdun karundínlógójì, ẹ sì kíyèsĩ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù tí da ìjọ Krístì sílẹ̀ nínú gbogbo ilẹ̀ tí ó yí wọn ka. Gbogbo àwọn ẹniti o bá sì tọ̀ wọ́n wa, tí wọn sì ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní tõtọ́, ní a rìbọmi ní ọrúkọ Jésù; wọ́n sì gbà Ẹ̀mí Mímọ́.

2 O sì ṣe nínú ọdún kẹrìndínlógójì, gbogbo àwọn ènìyàn nã ní a sì yí lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, ní ori ilẹ̀ nã, àti àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì, kò sì sí ìjà àti àríyàn-jiyàn kankan ní ãrín wọn, wọ́n sì nfi òdodo bá ara wọn lò.

3 Wọn sì jùmọ̀ ní ohun gbogbo papọ̀; nítorínã kò sí olówó àti tálákà, òndè àti òmìnira, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni a sọ di òmìnira, àti alábãpín ẹ̀bùn ọ̀run nã.

4 O sì ṣe ti ọdun kẹtadínlógójì nã kọjá lọ, àlafíà sì wà síbẹ̀ nínú ilẹ̀ nã.

5 Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jesu sì ṣe àwọn iṣẹ́ nla tí ó yanilẹ́nu, tóbẹ̃ tí wọn mú àwọn aláìsàn lára dá, tí wọn sì jí òkú dìde, tí wọn sì mú kí àwọn amúkun ó rìn, tí wọn sì mu kí àwọn afọ́jú ó riran, àti kí odi ó gbọ́ràn; àti onírurú àwọn iṣẹ́ ìyanu ni wọ́n ṣe ni ãrín àwọn ọmọ ènìyàn; wọn kò sì ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan bíkòṣe ní orukọ Jésù.

6 Bayĩ sì ni ọdun kejìdínlógójì kọjá lọ, àti ikọkandinlógójì pẹ̀lú, àti ìkọkànlelogoji, àti ìkejìlélógójì, bẹ̃ni, titi ọdun kọkàndínlãdọ́ta fi kọjá lọ, àti ọdun kọkànlélãdọta pẹ̀lú, àti ikéjìlelãdọta; bẹ̃ni, àti titi ọdun mọ́kàndínlọ́gọ́ta nã fi kọjá lọ.

7 Olúwa sì mú wọn ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí wọn sì tún kọ́ àwọn ìlú-nlá sí àwọn ibití a tí jo wọn níná tẹ́lẹ̀.

8 Bẹ̃ni, àní ìlú-nlá nnì Sarahẹ́múlà ní wọn mú kí a túnkọ́.

9 Ṣugbọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá ni ó wà ti wọ́n ti rì, tí omi ti jáde sókè ní ipò wọn; nitorinã a kò lè tún wọn kọ́.

10 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì sì nlagbára síi, tí wọn sì npọ̀ síi lọ́pọ̀lọpọ̀, tí wọn sì di ènìyàn tí ó lẹ́wà tí ó sì wuni lọ́pọ̀lọpọ̀.

11 Wọ́n sì gbéyàwó, wọ́n sì fa ìyàwó fún ni, a sì bùkún fún wọn gẹ́gẹ́bí òpọ̀lọpọ́ ìlérí tí Olúwa ti ṣe fún wọn.

12 Wọn kò sì rìn ní ti ipa àwọn ìlànà àti ní ti òfin Mósè; ṣúgbọ́n wọn sì nrìn ní ti àwọn òfin ti wọn ti gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, tí wọn sì ntẹ̀síwájú nínú ãwẹ̀ gbígbà àti adura, àti nínú ìdàpọ̀ nígbàkũgbà láti gbàdúrà àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

13 O sì ṣe tí kò sì sí ìjà lãrín gbogbo ènìyàn nã, ní gbogbo ilẹ̀ nã; sugbọn tí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jesu se àwọn iṣẹ́ ìyànù nla-nla lãrín wọn.

14 O sì ṣe tí ọdun kọkànlélãdọ́rin kọjá lọ, àti ọdun kejilelãdọrin pẹ̀lú, bẹ̃ni, àti ni kúkúrú, títí tí ọdún kọkàndílọ́gọ́rin kọjá lọ; bẹ̃ni àní tí ọgọrun ọdun kọjá lọ, tí àwọn ọmọ èhìn Jesu, àwọn tí ó ti yàn, ti lọ sí párádísè Ọlọ́run, afi àwọn mẹ́ta nnì tí yíò durolẹ́hìn ní ayé; a sì yan àwọn ọmọ ẹ̀hìn miràn dípò wọn; àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú ìran nnì ni ó ti kọjá lọ.

15 O sì ṣe tí kò sì sí asọ̀ ní ilẹ̀ nã, nitori ifẹ Ọlọ́run èyítí o ngbé inu ọkàn àwọn ènìyàn nã.

16 Ko sì sí ìlara, tabi ìjà, tabi ìrúkèrúdò, tàbí ìwà àgbèrè, tabi irọ pípa, tabi ìpànìyàn, tabi irúkírú ìwà ìfẹ́kúfẹ̃; dájúdájú kò sì sí irú àwọn ènìyàn tí ó láyọ̀ jù wọn lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a ti ọwọ́ Ọlọ́run dá.

17 Ko sí ọlọ́ṣà, tabi apànìyàn, bẹ̃ni kò sí ara Lámánì, tabi irúkìrú èléyàmẹ̀yà; ṣùgbọ́n wọn wà ní íṣọ̀kan, àwọn ọmọ Krístì, àti ajogún ìjọba Ọlọ́run.

18 Báwo sì ní a tí bùkún wọn to! Nítorítí Olúwa nbùkún wọn nínú ohun gbogbo tí wọn nṣe; bẹ̃ni, àní Olúwa bùkún wọn o sì mú wọn se rere titi ọgọ́run ọdun o le mẹwa ti kọ́já lọ; àti ti ìran èkíní lẹ́hìn wíwá Krístì tí kọjá lọ, kò sì sí ìjà ní gbogbo ilẹ̀ nã.

19 O sì ṣe tí Nífáì, ẹnití ó kọ àkọsílẹ̀ èyítí ó kẹ́hìn yĩ, (on sì ti kọ ọ́ sí òrí àwọn àwo Nífáì) kú, ọmọ rẹ Amọsì sì kọ ọ ní ipò rẹ̀; on sì kọ ọ́ sí orí àwọn àwo Nífáì pẹ̀lú.

20 O sì kọ̀ ọ́ fun ọdun mẹrinlélọgọrín, alãfia sì wà ní ilẹ̀ nã, yàtọ̀ fún díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn nã tí wọn tí sọ̀tẹ̀ kúrò nínú ìjọ nã, tí wọ́n sì njẹ orúkọ àwọn ara Lámánì; nítorínã ni àwọn ara Lámánì sì tún bẹ̀rẹ̀sí wà nínú ilẹ̀ nã.

21 O sì ṣe tí Amọsì kú pẹ̀lú, (o sì jẹ́ ọgọrũn ọdun ati ãdọ́rún ati mẹrin láti ìgbà ti Kristi ti wá) ọmọ rẹ̀ Amọsì sì kọ àwọn àkọsílẹ̀ ní ipò rẹ̀; òn nã sì kọ ọ́ le orí àwo Nífáì; o sì kọ ọ́ sínú iwe Nífáì pẹ̀lú, èyítí í ṣe ìwé yĩ.

22 O sì ṣe tí igba ọdún ti kọjá lọ; ti gbogbo ìran kéjì tí kọjá lọ yàtọ̀ fún díẹ̀ nínú wọn.

23 Àti nísisìyí í, emí, Mọ́mọ́nì, fẹ́ kí ẹ̀yin ó mọ̀ pe àwọn ènìyàn yĩ ti pọ̀ síi, tóbẹ̃ ti wọn tànká gbogbo orí ilẹ̀ nã, àti ti wọ́n ti di ọlọ́rọ lọpọ̀lọpọ̀; nitori ìlọsíwájú wọn nínú Krístì.

24 Àti nísisìyí, nínú ọdun kọkànlérúgba yĩ ni àwọn kan bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín wọn tí wọn gbé ara wọn sókè nínú ìgbéraga, ní wíwọ̀ ẹ̀wù olowo-iyebíye, àti onírúurú ohun ẹ̀ṣọ́ dáradára, àti àwọn ohun dáradára ayé.

25 Àti láti igbanã lọ ni wọn kò sì ṣe àjùmọ̀ní ohun gbogbo mọ́ ní ãrin wọn.

26 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ àwọn ìjọ fun èrè jíjẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sẹ́ ìjọ Krístì tí í ṣe òtítọ́.

27 O sì ṣe nígbàtí igba ọdún àti mẹ́wã ti kọjá lọ àwọn ìjọ púpọ̀ sì wà lórí ilẹ nã; bẹ̃ni, àwọn ìjọ púpọ̀, tí wọn kéde mímọ̀ Krístì nã, síbẹ̀síbẹ̀ wọn a mã sẹ́ púpọ̀ nínú ìhìn-rere rẹ̀, tó bẹ̃ ti wọn sì fi àyè gba onírúurú iwa búburú, ti wọn sì nfi ohun ti í ṣe mímọ́ fun ẹniti kò tọ́ sí nitori àìtọ́ rẹ̀.

28 Ìjọ yĩ sì npọ̀sĩ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítori àìṣedẽdé, àti nitori agbara Sátánì ẹniti ó ti gba ọkàn wọn.

29 Àti pẹ̀lú, ìjọ mĩràn wà èyítí ó sẹ Krístì nã; wọ́n sì nṣe inúnibíni sí ijọ Krístì tí í ṣe òtítọ́, nitori iwa-ìrẹ̀lẹ̀ wọn, àti ìgbàgbọ́ wọn nínú Krístì; wọn a sì mã fi wọ́n sẹ̀sín nitori àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ isẹ́ ìyanu tí wọn nṣe ní ãrin wọn.

30 Nitorinã ní wọn sì nlo agbára àti àṣẹ lórí àwọn ọmọ ẹhin Jésù tí ó wà lãrín wọn, wọn sì jù wọn sínú tũbú; sùgbọ́n nípa agbara ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyítí ó wà nínú wọn, àwọn tũbú là sí méjì, wọ́n sì jáde lọ wọ́n sì nṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó tobi ní ãrin wọn.

31 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àti l’áìṣírò gbogbo àwọn isẹ iyanu wọnyĩ, àwọn ènìyàn nã sé ọkàn wọn le, wọn sì nlépa láti pa wọn, àní gẹ́gẹ́bí àwọn Jũ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ti lépa láti pa Jesu, gégẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

32 Wọ́n sì jù wọ́n sínú iná ìléru, wọn sì jáde wá ní aìní ìpalára.

33 Wọn sì jù wọn sinu ihò àwọn ẹranko búburú, wọn si nbá àwọn ẹranko búburú nã ṣere bí ọmọde tí í bá ọ̀dọ́-àgùtàn ṣere; wọn sì jáde kúrò ní ãrín wọn, ní àìní ìpalára.

34 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn nã se ọkàn wọn le, nítorítí àwọn ọ̀pọ̀ àlùfã àti àwọn wòlĩ èké ní ó ndari wọn láti kó ìjọ púpọ̀ jọ, àti láti ṣe onìrũrú aisedede. Wọn sì lù àwọn ènìyàn Jésù; sugbọn àwọn ènìyàn Jesu kò lù wọ́n padà. Báyĩ sì ni wọn rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ àti iwa búburú, ní ọdọ̃dún, àní títí igba ọdún ati ọgbọ̀n fi kọjá lọ.

35 Àti nísisìyí ó sì ṣe nínú ọdún yĩ, bẹ̃ni, nínú igba ọdun ati mọ́kànlé-lọ́gbọ̀n, ìyàpà nla wà lãrín àwọn ènìyàn nã.

36 O si ṣe nínú ọdun yĩ tí àwọn ènìyàn tí a npè ní àwọn ara Nífáì dide, wọn si jẹ onígbàgbọ́ òtítọ́ nínú Krístì; nínú wọn sì ni àwọn tí àwọn ara Lamanì npè ni—àwọn ara Jákọ́bù, àti àwọn ara Jósẹ́fù, àti àwọn ara Sórámù.

37 Nitorinã àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Krístì ní tõtọ́, àti àwọn olùsìn Krístì ní tõtọ́, (tí àwọn ọmọ ẹ̀hìn Jésù mẹ̀ta nnì tí yíò dúró lẹ́hìn wa lára wọn) ní wọn pè ní àwọn ara Nífáì, àti àwọn ara Jakọbu, àti àwọn ara Jóṣépù, àti àwọn ara Sórámù.

38 O sì ṣe tí a npè àwọn tí ó kọ ìhìn-rere nã ní àwọn ara Lámánì, àti àwọn ara Lémúẹ́lì, àti àwọn ara Iṣmaẹli; wọ́n kò sì rẹ̀hìn nínú àìgbàgbọ́, sùgbọ́n wọn a máa mọ̃mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí ìhìn-rere Krístì; wọn a sì máa kọ́ àwọn omọ wọn pé kí wọn ó máṣe gbàgbọ́, àní gẹ́gẹ́bí àwọn baba wọn ṣe rẹ̀hìn, láti ìbẹ̀rẹ̀ wá.

39 Èyí sì rí bẹ̃ nítorí iwà búburú àti ìwà ìríra àwọn baba wọn, àní gẹ́gẹ́bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Wọ́n sì kọ́ wọn láti kórìra àwọn ọmọ Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́bí wọn ti kọ́ àwọn ara Lamanì láti kórìra àwọn ọmọ Nífáì láti ìbẹ́rẹ̀ wá.

40 O sì ṣe ti igba ọdun àti ọdun mẹrinlélógójì ti kọjá lọ, báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn nã rí. Àwọn tí ó sì burú jù nínú àwọn ènìyàn nã sì pọ̀ síi nínú agbára, wọ́n sì pọ̀ púpọ̀ tayọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

41 Wọ́n sì ntẹ̀síwájú síbẹ̀síbẹ̀ láti kọ́ àwọn ìjọ fún ti ara wọn, tí wọ́n sì fi onírúurú àwọn ohun olówó-iyebíye ṣe wọ́n lọṣọ. Bayĩ sì ní igba ati ãdọta ọdún kọjá lọ, àti ọ̀tà lé rúgba ọdún pẹ̀lú.

42 O sì ṣe tí àwọn tí ó burú nínú àwọn ènìyàn nã tún bẹ̀rẹ̀sí fí àwọn ìmùlẹ̀ òkùnkùn àti àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn Gádíátónì lélẹ̀.

43 Àti pẹ̀lú, àwọn ènìyàn tí a pè ní àwọn ènìyàn Nífáì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìgbéraga nínú ọkàn wọn, nitorí ọrọ̀ wọn tí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ti wọ́n sì di aláinílarí bí àwọn arákùnrin wọn, àwọn ara Lamanì.

44 Láti ìgbà yí lọ ni àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã sì bẹ̀rẹ̀sí kẹ́dùn fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.

45 O sì ṣe nígbàtí ọ̃dúnrún ọdún ti kọjá lọ, àti àwọn ènìyàn Nífáì àti àwọn ara Lámánì ti di ènìyàn búburú púpọ̀-púpọ̀ ní ìkọ̀kan.

46 O sì ṣe tí àwọn ọlọ́sà Gádíátónì tàn ká orí ilẹ̀ nã; kò sì sí ẹnití ó jẹ́ olódodo, àfi àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù. Wọn sì kó wura àti fàdákà jọ púpọ̀-púpọ̀, tí wọn sì se ètò ìrìnnà ní orísirísi ọ̀nà.

47 O sì ṣe lẹ́hìntí ọ̃dúnrún ọdún ó lé ọdún marun tí kọjá lọ, (tí àwọn ènìyàn nã sì wa nínú ìwà búburú síbẹ̀síbẹ̀) tí Amọsì sì kú; àbúrò rẹ̀, Ámmárọ́nì sì nṣe àkọsílẹ̀ ní ipò rẹ̀.

48 O sì ṣe nígbàtí ọ̃dúnrún ó lé ogún ọdun ti kọjá lọ, Ámmárọ́nì, nipa ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́, sì gbé àwọn àkọsílẹ̀ èyítí í ṣe mímọ́ nã pamọ́—bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ tí a tí fifúnni láti ìran de iran, tí wọ́n jẹ mímọ́—àní titi de ọ̃dúnrún ọdun ó lé ogun ọdún láti ìgbà tí Krístì tí wá.

49 O sì gbé wọn pamọ́ nínú Olúwa, kí wọn ó lè tún padà wá sí ọ̀dọ̀ ìyókù ìdílé Jákọ́bù, gẹ́gẹ́bí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìlérí Olúwa. Báyĩ sì ni àkọsílẹ̀ Ámmárọ́ni dé òpin.