Àwọn Ìwé Mímọ́
Mọ́mọ́nì 1


Ìwé ti Mọ́mọ́nì

Orí 1

Ámmórọ́nì fí àṣẹ fún Mọ́mọ́nì nípa àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã—Ogun bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì—Àwọn ara Nífáì mẹ́ta nnì ní Olúwa mú lọ—Ìwà búburú, àìgbàgbọ́, ìṣóṣó àti ìṣàjẹ́, tàn kálẹ̀. Ní ìwọ̀n odun 321 sí 326, nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun tí mo ti rí àti tí mó tí gbọ́, mo sì pè é ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

2 Àti ní ìwọ̀n àkókò tí Ámmárọ́nì gbé àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́ sí Olúwa, ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, (èmi sì jẹ́ ìwọ̀n bí ọmọ ọdún mẹ́wã, mo sì bẹ̀rẹ̀sí ní òye tí ó tayọ gẹ́gẹ́bí ti òye àwọn ènìyàn mi) Ámmárọ́nì sì wí fún mi pé: èmi wòye pé ọmọ tí ó nronú jìnlẹ̀ ni ìwọ í ṣe, ìwọ sì yára láti ṣe àkíyèsí;

3 Nitorinã, nígbàtí ìwọ bá tó ọmọ odún mẹ́rìnlélógún, mo fẹ́ kí ìwọ ó rántí àwọn ohun tí ìwọ ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yí; nígbàtí ìwọ bá sì tí tó ọmọ ọjọ́ orí nã, lọ sí ilẹ̀ Ántúmù, sí ibi òkè kan ti a ó pè ní Ṣímù; níbẹ̀ ní èmi sì ti gbé gbogbo àwọn ìfín mímọ́ nipa àwọn ènìyàn yí pamọ́ sí Olúwa.

4 Sì kíyèsĩ, ìwọ yíò gbé àwọn àwo ti Nífáì sí ọ̀dọ̀ ara rẹ, àwọn èyítí ó kù ní ìwọ yíò fi sílẹ̀ ní ibití wọ́n wà; ìwọ́ yíò sì fín gbogbo ohun tí ìwọ tí ṣe àkíyèsí rẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yí sí orí àwọn àwo ti Nífáì.

5 Àti emí, Mọ́mọ́nì, tí i ṣe ìran Nífáì, (orukọ bàbá mi sì ni Mọ́mọ́nì) mo rántí àwọn ohun tí Ámmárọ́nì pa láṣẹ fún mi.

6 O sì ṣe ti èmi, nígbàtí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlá, bàbá mi gbé mi lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù, àní sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

7 Gbogbo ori ilẹ nã ti kún fún àwọn ilé, àwọn ènìyàn nã si ti pọ̀, ti wọn fẹ́rẹ̀ tó yànrín òkun.

8 O sì ṣe nínú ọdun yĩ tí ogun bẹ́ silẹ̀ lãrín àwọn ará Nefáì, tí wọn í ṣe àpapọ̀ àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Jákọ́bù àti àwọn ara Jósẹ́fù àti àwọn ará Sórámù; ogun yĩ sì wà lãrín àwọn ara Nífáì, àti àwọn ará Lámánì àti àwọn ara Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ara Íṣmáẹ́lì.

9 Nísisìyí àwọn ara Lámánì àti àwọn ara Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ara Íṣmáẹ́lì ni wọn npè ní àwọn ara Lámánì, àwọn ẹgbẹ méjẽjì ní àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì.

10 O sì ṣe tí ogun nã bẹ́ silẹ̀ lãrín wọn ni agbègbè ãlà Sarahẹ́mulà, ní ẹ̀bá omi Sídónì.

11 O sì ṣe tí àwọn ará Nífáì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn jọ, àní èyítí ó jù ẹgbẹ̀rún lọna ọgbọ̀n lọ. O sì ṣe tí wọn ja àwọn ogun tí ó pọ̀ díẹ̀ nínú ọdún yĩ, nínú èyítí àwọn ará Nífáì ṣẹ́gun àwọn ará Lámánì tí wọ́n sì pa púpọ̀ nínú wọn.

12 O sì ṣe tí àwọn ara Lámánì dáwọ́dúró nínú ète wọn, àlãfíà sì sọ̀kalẹ̀ sínú ilẹ̀ nã; àlãfíà sì wà fún ìwọ̀n bí ọdún mẹ́rin, tí kò sì sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ kankan.

13 Sugbọn ìwà búburú tàn kálẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ nã, tó bẹ̃ tí Olúwa fì mú àwọn àyànfẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ kúrò, iṣẹ́ ìyanu àti ìwòsàn sì dáwọ́dúró nítorí àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã.

14 Kò sì sí àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Ẹ̀mí Mímọ́ kò sì bàlé ẹnikẹ́ni, nitori ìwà búburú àti àìgbàgbọ́ wọn.

15 Àti emí, nígbàtí mo sì jẹ́ ọmọ ọdún márundínlogun, ti mo sì jẹ́ ẹnití ó nronú jinlẹ̀, nitorinã Olúwa bẹ̀ mí wò, mo sì tọ́ didara Jesu wò, mo sì mọ̃.

16 Mo sì gbìyànjú láti wãsù sí àwọn ènìyàn yĩ, ṣùgbọ́n ẹnu mi pa mọ́, a sì dá mi lẹ́kun láti wãsù sí wọn; nítorí kíyèsĩ wọn ti mọ̃mọ̀ sọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn; a sì mú àwọn àyànfẹ́ ọmọ ẹ̀hìn kúrò nínú ilẹ̀ nã, nitori àìṣedẽdé wọn.

17 Sugbọn emí wà ní ãrín wọn, sùgbọ́n a dá mi lẹ́kun láti wãsù sí wọn, nitori ọkàn líle wọn; àti nitori ọkàn líle wọn, ilẹ̀ nã di ìfibú nítorí wọn.

18 Àwọn ọlọ́sà Gádíátónì nnì tí wọ́n wà lãrín àwọn ara Lámanì, sì nyọ ilẹ̀ nã lẹ́nu, tóbẹ̃ tí àwọn tí ngbé ínú ilẹ̀ nã bẹ̀rẹ̀sí kó àwọn ohun ìní wọn pamọ́ sínú ílẹ̀; wọn kò sì rọ̀rùn láti kójọ, nítorítí Olúwa ti fi ilẹ̀ nã bú, wọn kò sì lè dì wọn mu, tàbí kí wọn ó tún ní wọn ní ìní.

19 O sì ṣe tí ìṣoṣó àti ìṣàjẹ́, àti idán pípa; tí agbára ẹni ibi nnì sì njà lórí gbogbo ilẹ̀ nã, àní títí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ Ábínádì di mímúṣẹ, àti pẹ̀lú ti Sámúẹ́lì ará Lámánì.