Àwọn Ìwé Mímọ́
Mọ́mọ́nì 6


Orí 6

Àwọn ara Nífáì ko ara wọn jọ sínú ilẹ̀ Kùmórà fún àwọn ìjà ti ìgbẹ̀hìn—Mọ́mọ́nì gbe àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã pamọ́ sínú òkè Kùmórà—Àwọn ara Lamanì ní ìṣẹ́gun, wọn sì pa orílẹ̀-èdè àwọn ara Nifaí run—Ọgọ́run ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni wọn fi idà pa. Ní ìwọ̀n ọdun 385 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, mo parí àkọsílẹ̀ mi nípa ìparun àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì. O sì ṣe ti a sì kọjá lọ níwájú àwọn ara Lámánì.

2 Emí, Mọ́mọ́nì, sì kọ èpístélì kan sí ọba àwọn ara Lámánì, mo sì bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí o gbà fún wa láti kó àwọn ènìyàn wa lọ sí ilẹ̀ Kùmórà, ní ẹbà òkè kan tí a npè ní Kùmórà, ní ibẹ̀ ní àwa yíò sì lè dojúkọ wọn ní ìjà.

3 O sì ṣe tí ọba àwọn ara Lámánì sì gbà fún mi nípa ohun ti èmi bèrè.

4 O sì ṣe tí àwa kọjá lọ sí ilẹ̀ Kùmórà, tí a sì pàgọ́ wa yí okè Kùmórà nã ká; ó sì wà lórí ilẹ̀ èyítí ó ní omi púpọ̀, àwọn odò, àti àwọn orísun omi; níbíyĩ ni àwa sì ni ìrètí pé àwa yíò lè borí àwọn ara Lámánì nã.

5 Nígbàtí ọ̀rìn lé lọ̃dúnrún ọdún ó lé mẹ́rin sì ti kọjá lọ, àwa ti kó gbogbo àwọn ènìyàn wa tí ó kù jọ sínú ilẹ̀ Kùmórà.

6 O sì ṣe nígbàtí a sì ti kó gbogbo àwọn ènìyàn wa jọ sí ọ̀kan ninu ilẹ̀ Kùmórà, ẹ kíyèsĩ, emí, Mọ́mọ́nì ti ndarúgbó; nítorítí mo sì ti mọ́ pe ìgbìyànjú ikẹhin ni ó jẹ fún àwọn ènìyàn mi, tí Olúwa sì ti pa á láṣẹ fún mi láti máṣe jẹ́ ki àwọn àkọsílẹ̀ nã èyítí a ti gbé fún wa láti ọwọ́ àwọn baba wa, tí wọn sì jẹ mímọ́, kí wọn ó bọ sí ọwọ àwọn ará Lamanì, (nítorítí àwọn ara Lámánì yíò pa wọ́n run) nítorínã ni emí ṣe kọ àkọsílẹ̀ yĩ láti inú àwo Nífáì, ti mo sì gbé gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ tí a ti fifún mi fún ipamọ láti ọwọ Olúwa pamọ́ sínú òkè Kùmórà, àfi àwọn àwo díẹ̀ wọ̀nyí tí mo gbe fún ọmọ mi Mórónì.

7 O sì ṣe tí àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, sì rĩ tí àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Lamanì nbọ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn; wọ́n sì duro de wọn nínú ìbẹ̀rù nla fún ikú, irú èyítí í kún ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn búburú.

8 O sì ṣe tí wọ́n wá, láti dojú ìjà kọ wá, tí gbogbo ọkan sì kún fun ẹ̀rù nítorí bí iye wọn ti pọ̀ tó.

9 O sì ṣe tí wọ́n sì kọlũ àwọn ènìyàn mi pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú ọrún, àti pẹ̀lú ọfà, àti pẹ̀lú ãké, àti pẹ̀lu onírúurú àwọn ohun ìjà ogun.

10 O sì ṣe tí wọ́n ké àwọn ọmọ ogun mi lulẹ̀, bẹ̃ni, àní àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wã mí tí wọ́n wà pẹ̀lú mi, mo sì ṣubú pẹ̀lú ọgbẹ́ lãrín wọn; àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Lámánì nã sì kọjá ní ara mi, tí wọn kò sì fi opin si ẹmi mi.

11 Nígbàtí wọ́n sì ti kọjá lọ tí wọ́n sì ti ké gbogbo àwọn ènìyàn mi lulẹ̀ tan, afi àwa mẹ́rìnlélógún, (nínú èyítí ọmọ mi Mórónì wà), lẹ́hìn tí àwa sì ti bọ́ lọ́wọ́ ikú tí ó pa àwọn ènìyàn wa, a rĩ ni ọjọ keji, nígbàtí àwọn ara Lámánì ti padà sí àgọ́ wọn, láti ori òkè Kùmórà, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa nínú àwọn ènìyàn mi ti wọn ké lulẹ̀, àwọn tí emí wà níwajú wọn bí olùdarí.

12 Bákannã a sì rí àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa nínú àwọn ènìyàn mi àwọn ẹ̀nítí ọmọ mi Mórónì síwájú.

13 Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa ènìyàn ti Gídgídónà ti ṣubù, òn pẹ̀lú sì wà ní ãrín wọn.

14 Àti Lámà nã ni ó ṣubú pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Gílgálì nã ni ó ṣubú pẹ̀lu ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Límhà nã ni ó ṣubú pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Jénéúmì nã ni ó ṣubú pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Kumeníhà nã, àti Móróníhà nã, àti Ántíónọ́mù nã, àti Ṣíblọ́mù nã, àti Ṣẹ́mù nã, àti Jọ́ṣì nã, ní o ṣubu pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wã-mẹ́wã wọn.

15 O sì ṣe ti àwọn mẹwa míràn ṣubú nipa idà, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa-mẹwa wọn; bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn ènìyàn mi, bíkòṣe àwọn mẹ́rìnlélógún nnì tí wọ́n wà pẹ̀lú mi, àti àwọn díẹ̀ bákannã tí wọ́n sá lọ sínú àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà gũsù, àti àwọn díẹ̀ ti ó kọ̀ wá sílẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ara Lámánì, ní ó ti subú; ti ẹran ara wọn àti àwọn egungun wọn àti ẹ̀jẹ̀ wọn sì wà ní orí ilẹ̀ ayé, nítorítí àwọn tí ó pa wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ kí wọn ó jẹrà lórí ilẹ̀, àti ki wọn ó fọ́ sí wẹ́wẹ́, kí wọn ó sì padà sínú ilẹ̀.

16 Ọkàn mi sì gbọgbẹ́ pẹ̀lú àròkàn, nitori pipa tí a pa àwọn ènìyàn mi, èmi sì kígbe wipe:

17 A! ẹ̀yin arẹwà ènìyàn, báwo ni ẹ̀yin ha se yísẹ̀padà kúrò nínú ọ̀na Olúwa! A! ẹyin arẹwà ènìyàn, báwo ní ẹ̀yin ha ṣe kọ̀ Jésu, ẹnití ó dúró pẹ̀lú ìṣípá láti gbà yín!

18 Ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin kò bá ti ṣe eleyĩ, ẹ̀yin kì bá tí ṣubú. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin ti ṣubú, èmi si nṣọ̀fọ̀ àdánù yín.

19 A! ẹ̀yin arẹwà ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ̀yin bàbá àti ìyá, ẹ̀yin ọkọ àti aya, ẹyin arẹwà ènìyàn, báwo ni ẹ̀yin ha ṣe ṣubú!

20 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹyin ti lọ, ìrora ọkàn mi kò sì lè mu yin padà wá.

21 Ọjọ nã sì dé tán tí ara yín ti ayé yĩ yíò gbé ara ti àìkú wọ̀, àwọn ara wọ̀nyí tí wọ́n sì njẹrà nínú ìdíbàjẹ́ gbọ́dọ̀ di ara tí kò lè díbàjẹ́; nígbànã ni ẹ̀yin gbọ́dọ̀ dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, kí a lè ṣe ìdàjọ́ yín gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ yín; bí ó bá si jẹ́ wípé olódodo ní ẹ̀yin í ṣe, nígbànã ní ẹ̀yin ó di alábùkún-fún pẹ̀lú àwọn baba yín tí wọ́n ti lọ ṣãjú yín.

22 A! ẹyin ìbá sì ti ronúpìwàdà kí ìparun nlá yĩ ó tó dé bá yín. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti lọ, àti pe Bàbá nã, bẹ̃ni, Bàbá Ayérayé tí ọ̀rún, mọ̀ ipò tí ẹ̀yin wà; o sì nṣe sí yín gẹ́gẹ́bí àìṣègbè àti ãnú rẹ̀.