Àwọn Ìwé Mímọ́
Mọ́mọ́nì 2


Orí 2

Mọ́mọ́nì ṣíwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ara Nífáì—Itàjẹsílẹ̀ àti ìparun nlá gba gbogbo ilẹ̀ nã—Àwọn ara Nífáì pohùnréré ẹkún wọn sì kẹ́dùn pẹ̀lú ìrora ọkàn ẹni ègbé—Ọjọ́ õre-ọ̀fẹ́ wọn ti kọjá—Mọ́mọ́nì gbà àwọn àwó Nífáì—Áwọn ogun tẹ̀síwájú. Ní ìwọ̀n ọdún 327 sí 350 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 O sì ṣe nínú ọdún kannã tí ogun kan tún bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì. Àti l’áìṣírò mo kere ní ọjọ́ orí, emí tóbi ní gíga sókè; nitorinã ni àwọn ara Nífáì yàn mí pé kí èmi jẹ́ olórí wọn, tabi olori àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.

2 Nitorinã o sì ṣe ni ọdun kẹrindinlogun ọjọ́ ori mi ni emí jáde lọ ṣíwájú ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì kan, ní ìkọlu àwọn ara Lamanì; nitorinã ọ̃dúnrún ọdún ó lé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ti kọjá lọ.

3 O sì ṣe tí ọ̃dúnrún ọdun ó lé mẹtadínlọ́gbọ̀n tí àwọn ara Lámáni wá kọlũ wá nínú ìgbóná agbara, tóbẹ̃ tí wọn dẹ́rùbà àwọn egbẹ ọmọ ọgun mi; nitorinã wọ̀n kọ̀ láti jà, wọ́n si bẹ̀rẹ̀sí fàsẹ́hìn sí àwọn orilẹ ede apá àríwá.

4 O sì ṣe tí a dé ìlú-nlá Àngólà, tí a sì mú ilẹ̀ nã ní ìní, àwa sì ṣe ìmúrasílẹ̀ láti dabò bò ara wa lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. O sì ṣe ti àwa fi gbogbo ipá wa mọ́ odi yika ìlú-nlá nã; sùgbọ́n, l’áìṣírò gbogbo imọdisí wa, àwọn ará Lámánì kọlũ wa wọ́n sì lé wa jáde kúrò nínú ìlú-nlá nã.

5 Wọ́n sì lé wa jáde pẹ̀lú, kuro nínú ilẹ̀ Dáfídì.

6 A sì kọjá lọ, a sì dé inú ilẹ̀ Jóṣúà, èyítí ó wà ní ibi agbègbè ilẹ̀ apá ìwọ oòrùn ní ẹ̀bá bèbè òkun.

7 O sì ṣe tí a kó àwọn ènìyàn wa jọ ní kánkán, kí á le kó wọn papọ̀ ní ara kanṣoṣo.

8 Ṣùgbọn ẹ kíyèsĩ, ilẹ̀ nã kún fún àwọn ọlọ́ṣà àti àwọn ara Lámánì; l’áìṣírò ìparun nla èyítí ó dó tì àwọn ènìyàn mi, wọn kò ronúpìwàdà kuro nínú àwọn ìwà ibi wọn; nitorinã ni ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìparun nlá tàn kálẹ̀ jákè-jádò oju gbogbo ilẹ̀ nã, ni ọ́dọ̀ àwọn ará Nífáì àti ni ọ́dọ̀ àwọn ara Lámánì pẹ̀lú; ó sì jẹ́ àṣe-parí ìṣọ̀tẹ̀ kan jákè-jádò gbogbo orí ilẹ̀ nã.

9 Àti nísisìyí, àwọn ará Lámánì ní ọba kan, orukọ rẹ sì ni Áárọ́nì; ó sì kọlu wá pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọna ogoji o le mẹrin. Ẹ sì kíyèsĩ, mo dojú kọ ọ́ pẹ̀lu ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé méjì. Ó sì ṣe tí mo lù ú pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi tí ó sì sá kúrò níwájú mi. Ẹ sì kíyèsĩ, gbogbo èyí ní a ṣe, ọ̃dúnrún ọdun ó lé ọgbọ̀n sì kọjá lọ.

10 Ó sì ṣe tí àwọn ara Nífáì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú iwa àìṣedẽdé wọn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ráhùn gégẹ́bí wòlĩ Sámúẹ́lì tí sọtẹ́lẹ̀; nítorí ẹ kíyèsĩ ẹnikẹ́ni kò lè pa èyítí í ṣe tirẹ̀ mọ́, nitori àwọn olè, àti àwọn ọlọ́ṣà, àti àwọn apànìyàn, àti idán pípa, àti ìwà ìṣòṣó àti ìsàjẹ́ èyítí ó wà nínú ilẹ̀ nã.

11 Báyĩ sì ni ó ṣe tí ọ̀fọ̀ àti ìpohùnréré-ẹkún wà nínú gbogbo ilẹ̀ nã nítorí àwọn ohun wọ̀nyí, àti pãpã ní ãrín àwọn ènìyàn Nífáì.

12 O sì ṣe nígbàtí emí, Mọ́mọ́nì, rí ìpohùnréré-ẹkún àti ọ̀fọ̀ wọn àti ìrora-ọkàn wọn níwájú Olúwa, ọkàn mí bẹ̀rẹ̀sí yọ̀ nínú mi, nítorítí mo mọ́ ọ̀pọ̀-ãnú àti ìrọ́jú Olúwa, nitorinã emí ní èrò wípé òn yíò ṣãnú fún wọn kí wọn ó lè tún padà di olódodo ènìyàn.

13 Sùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ayọ̀ mi yĩ já sí asán, nítorítí ìrora-ọkàn wọn kò wà fún ti ìrònúpìwàdà, nitori dídára Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ìrora-ọkàn ti ẹni-ègbé ní í ṣe, nítorítí Olúwa kì yíò gba fún wọn rárá láti máa yọ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀.

14 Wọn kò sì tọ Jésù wá pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ àti ìrora ọkàn, ṣugbọ́n wọn fi Ọlọ́run bú, wọn sì fẹ́ láti kú. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn a mã fi idà jà fún ẹ̀mí wọn.

15 O sì ṣe tí ìrora-ọkan mi tún padà si ọdọ mi, èmi sì ríi pé ọjọ õre-ọfẹ ti kọjá lọ pẹ̀lú wọn, ní ti ara àti ní ti ẹ̀mí; nítorítí mo ri ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nínú wọn tí a ké lulẹ̀ nínú ìṣọ̀tẹ̀ ojukòjú wọn sí Ọlọ́run wọn, tí wọ́n sì ko wọn jọ bí imí sí ori ilẹ̀ nã. Bayĩ sì ni ọ̃dúnrún ọdun o le mẹ́rìnlélógójì ti kọjá lọ.

16 O sì ṣe ní ọ̃dúnrún ọdun ó lé marundínlãdọ́ta tí àwọn ara Nífáì sì bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú àwọn ara Lámánì nã; wọn sì lé wọn títí wọn fi wọ̀ inú ilẹ̀ Jáṣónì, kí wọn ó tó lè dá wọn dúró nínú sísá padà wọn.

17 Àti nísisìyí, ìlú-nlá Jáṣọ́nì wà nítòsí ilẹ̀ nã níbití Ámmárọ́nì ti gbé àwọn àkọsílẹ̀ nnì pamọ́ si Olúwa, kí wọn ó má lè pa wọ́n run. Ẹ sì kíyèsĩ, mo sì ti ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ámmárọ́nì, mo sì gbé àwọn àwo Nífáì, mo sì kọ àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Ámmórọ́nì.

18 Àti lórí àwọn àwo Nífáì ni èmi kọ nípa gbogbo àwọn ìwà búburú nnì àti àwọn ohun ìríra nã ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; sùgbọ́n lórí àwọn àwo wọ̀nyí ni èmi fà sẹ́hìn ní kíkọ nípa ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, nítorí ẹ kíyèsĩ, nígbà-gbogbo ni emí tí fi ojú mi rí àwọn ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra yĩ láti ìgbà tí emí ti dàgbà to láti ṣe àkíyèsí ìhùwàsí ọmọ ènìyàn.

19 Ìbànújẹ́ sì wà fún mi nítorí ìwà búburú wọn; nítorí ọkàn mi tí kún fún ìrora nitori ìwà búburú wọn, ní gbogbo ọjọ ayé mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo mọ̀ wípé a ó gbe mi sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.

20 Ó sì ṣe nínú ọdún yií tí wọ́n tún dọdẹ àwọn ènìyàn Nífáì tí wọ́n sì lé wọn. Ó sì ṣe tí wọ́n lé wa títí à fi dé ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, lọ sí ilẹ̀ èyítí wọn npè ní Ṣẹ́mù.

21 Ó sì ṣe tí a mọ́ odi sí ìlú-nlá Ṣẹ́mù, tí a sì kó àwọn ènìyàn wa jọ sínú rẹ̀ tó bí a ti lè ṣe, pé bóyá àwa lè gbà wọn lọ́wọ́ ìparun.

22 Ó sì ṣe nínú ọ̃dúnrún ọdun ó lé mẹ́rìndínlãdọ́ta tí wọn tún bẹ̀rẹ̀sí kọlù wá.

23 Ó sì ṣe tí mo bá àwọn ènìyàn mi sọ̀rọ̀, tí èmi sì rọ̀ wọ́n pẹlú agbára nla, pé kí wọn ó dojúkọ àwọn ara Lámánì pẹ̀lú ìgboyà, kí wọn ó sì jà fún àwọn aya wọn, àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn ilé wọn, àti àwọn ibùgbé wọn.

24 Ọ̀rọ̀ mi sì ru wọn sókè pẹ̀lú okun tí ó tayọ, tóbẹ̃ tí wọn kò sá fún àwọn ara Lámánì, ṣùgbọ́n tí wọ́n dúró pẹ̀lú ìgboyà ní ìdojúkọ wọn.

25 O sì ṣe tí àwa fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọ́nà ãdọ́ta jà. O sì ṣe tí àwa sì dúró níwájú wọn ní ìdúróṣinṣin tóbẹ̃ tí wọn sá kúrò níwájú wa.

26 O sì ṣe nígbàtí wọ́n ti sá kúrò tí àwa sì lé wọn pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun wa, tí a sì tún dojúkọ wọ́n ní íjà, ti a sì lù wọ́n; bíótilẹ̀ríbẹ̃ sibẹ agbára Olúwa kò wà pẹ̀lú wa; bẹ̃ni, àwa nìkan ní a dáwà, tí Ẹmí Olúwa kò sì wà pẹ̀lú wa; nítorínã àwa sì ti di aláìlágbára bí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì.

27 Ọkàn mi sì kérora nítorí ipò ìyọnu tí àwọn ènìyàn mí wà yí, nitori ìwà búburú àti ìwà ìríra wọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwa jáde lọ ní ìdojúkọ àwọn ara Lámánì àti àwọn ọlọ́ṣa Gádíátónì, títí àwa tún fi padà gbà àwọn ilẹ̀ ìnì wa.

28 Ọ̀ọ́dúnrún ọdun o le mọkàndínlãdọ́ta sì ti kọjá lọ. Nínú ọdun ọ̃dúnrún ó lé ãdọta, àwa bá àwọn ara Lámánì àti àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì ṣe àdéhùn, nínú èyítí àwa mú kí wọn ó pín ilẹ̀ ìní wa.

29 Àwọn ara Lámánì sì fún wa ní ilẹ̀ èyítí ó wà ní apá àríwá, bẹ̃ni, àní títí de ibi ọ̀nà tõró èyítí ó lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù. A si fun àwọn ara Lámánì ni gbogbo ilẹ ti o wa ni apá gũsu.