Àwọn Ìwé Mímọ́
Mọ́mọ́nì 9


Orí 9

Mórónì pè àwọn tí kò gbà Krístì gbọ́ láti ronúpìwàdà—O kéde Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu, tí í fúnni ní ìfihàn àti tí í dà àwọn ẹ̀bùn àti àmì le ori àwọn olótĩtọ́—Iṣẹ ìyanu dáwọ́ dúró nitori àìgbàgbọ́—Àwọn àmì a máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ—A rọ̀ àwọn ènìyàn láti jẹ ọlọgbọ́n kí wọn ó sì pa àwọn òfin mọ. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, emí sọ̀rọ̀ pẹlu nípa àwọn ẹniti kò gbà Krístì gbọ́.

2 Ẹ kíyèsĩ, njẹ ẹ̀yin ó ha gbàgbọ́ ni ọjọ ìbẹ̀wò yin—Ẹ kíyèsĩ, nígbàtí Olúwa yíò wa, bẹ̃ni, àní ní ọjọ́ nlá nã nígbàtí ayé yíò di kíká pọ̀ bí ìwé, tí àwọn ẹ̀yà inú rẹ̀ yíò yọ́ nínú ìgbóná õru, bẹ̃ni, ní ọjọ nla nã nígbàtí a ó mú yín dúró níwájú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run—nigbànã ni ẹ̀yin ó ha wípé Ọlọ́run kò sí bi?

3 Nígbànã ni ẹ̀yin ó ha tún sẹ́ Krístì nã síi bí, tábi njẹ ẹ̀yin lè fí ojú rí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nã bi? Njẹ́ ẹyin ha rò wípé ẹ ó bã gbé pọ̀ nínú ìmọ̀ ìdálẹ́bi yín bí? Njẹ́ ẹ̀yin ha rò wípé ẹyin lè ní inú dídùn láti bá Ẹni mímọ́ nnì gbé pọ̀ bi, nígbàtí ìmọ̀ ìdálẹ́bi ngbo ọkàn yin pé gbogbo ìgbá ní ẹ̀yin a mã rú òfin rẹ́ bí?

4 Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé ẹ̀yin yíò wà ní ipò òtòsì bí ẹ́ bá ngbé pọ pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́ olódodo, nínú ìmọ̀ ìwà ọ̀bùn yin níwájú rẹ̀, jú kí ẹyin ó bá àwọn ọkàn tí ó ti ṣègbé gbé pọ̀ nínú ọ̀run àpãdì.

5 Nitori ẹ kíyèsĩ, nígbàtí á ó bá mú yín láti lè rí ìhòhò yín níwájú Ọlọ́run, àti pẹ̀lú ogo Ọlọ́run, àti mímọ́ Jésù Krístì, yíò tàn ìna tí a kò lè pa lè yín lórí.

6 A! bí ó bá rí bẹ̃ ẹ̀yin aláìgbàgbọ́, ẹ yípadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa; ẹ́ kígbe kíkan-kíkan pè Baba ní orúkọ Jésù, pe bóyá a ó rí yín ni ipò àìlábàwọ́n, ní mímọ́, ní rirẹwà, àti ní funfun, lẹhinti a ti fi ẹjẹ Ọ̀dọ́-àgùtàn wẹ̀ yín mọ́, ní ọjọ nla tí ó kẹ́hìn.

7 Àti pẹ̀lú mo bá yin sọ̀rọ̀ ẹ̀yin tí ó nsẹ́ àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run, tí o wípé a tí dáwọ́ wọn dúró, pé kò sí àwọn ìfihàn mọ, tabi àwọn i sọtẹlẹ, tabi àwọn ẹbun, tabi ìwòsàn, tabi fifi onírúrú èdè fọ̀, àti ìtumọ̀ onírúrú èdè;

8 Ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹniti ó bá sẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí kò mọ̀ ìhìn-rere Krístì; bẹ̃ni, kò tí ì kà àwọn ìwé-mímọ́; bí ó bá sì ti kà wọ́n, wọn kò yé e.

9 Nitori njẹ àwa kò ha rí i kà pé Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí láé, àti nínú rẹ̀ ni kò sì sí ìyípadà tàbí òjìji àyídà?

10 Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá ti rò nínú ọkàn yín nípa òrìṣà nã tí í máa yípadà àti nínú ẹnití òjiji àyípadà wà, nígbànã ni ẹ̀yin ti rò nínú ọkan yín nípa òrìṣa tí kì í ṣe Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu.

11 Ṣugbọn ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu hàn yín, àní Olọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù; àti pé Ọlọ́run nnì oun kannã ni ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn.

12 Ẹ kíyèsĩ, ó da Ádámù, àti pe nípasẹ̀ Ádámù ní ìṣubú ènìyàn fi wá. Nítorí ìṣubú ènìyàn sì ni Jésù Krístì fi wá, àní Bàbá àti Ọmọ; nítorí Jésù Krístì sì ni ìràpadà ènìyàn fi wá.

13 Àti nitori ìràpadà ènìyàn, èyítí ó wá nípasẹ̀ Jésù Krístì, a mú wọn padà wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa; bẹ̃ni, nípa èyí ní a ra gbogbo ènìyàn padà, nítorípé ikú Krístì mú àjíndé wá sí ìmúṣẹ, èyítí ó sì mú ìràpadà kuro nínú õrun àìnípẹ̀kun wa sí ìmúṣe, nínú õrun èyíti gbogbo ènìyàn yíò jínde nípa agbara Ọlọ́run nígbàtí ìpè nã yíò dún; wọn yíò sì jáde wa, àti èyítí ó kere àti èyítí ó tóbi, gbogbo wọn ní yíò sì dúró ní iwájú ìdájọ́ rẹ̀, nítorípé á ti rà á padà a sì ti túu sílẹ̀ kuro nínú ìdè ikú ayérayé, ikú èyítí í ṣe ikú ti ara.

14 Nígbànã sì ni ìdájọ́ Ẹní Mímọ́ nnì yíò dé bá wọn; nigbanã sì ni àkókò nã yíò de tí ẹnití ó bá jẹ elẽrí yìò wá ní ipò èlẽrí síbẹ̀; ẹnití ó bá sì jẹ olódodo yíò wa ní ipò olododo síbẹ; ẹniti ó bá ní inúdídùn yíò wa ní ipò inúdídùn síbẹ̀; ẹniti o bá sì wa láìní inúdídùn yíò wa ní ipò aláìní inúdídùn síbẹ̀.

15 Àti nísisìyí, A! gbogbo ẹ̀yin ti ẹ́ ti rò nínú ọkàn yín nípa òrìṣà nã èyítí kò lè ṣe iṣẹ́ ìyánú, emí yíò bí yín lẽrè, njẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí ti rékọjá bí, àwọn ohun ti emí ti sọ nipa wọn? Njẹ òpin ti de bi? Ẹ kíyèsĩ mo wi fún yín, Rárá; Ọlọ́run kò sì dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu.

16 Ẹ kíyèsĩ, njẹ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe kò ha jẹ́ ìyanu ní ojú wa bí? Bẹ̃ni, tani ó sì lè mọ̀ àwọn iṣe Ọlọ́run tí ó yanilẹ́nu?

17 Tani yíò wípé kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu pé nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ ọrun àti aiyé ní lati wà; àti nipa agbara ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a da ènìyàn láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀; àti nipa agbara ọrọ rẹ̀ ni a ṣe àwọn iṣẹ iyanu?

18 Àti pé tani yíò wípé Jésù Krístì kò ṣe ọpọlọpọ iṣẹ ìyanu nla? Àwọn iṣẹ iyanu nla púpọ̀-púpọ̀ sì ni a ti ọwọ́ àwọn àpóstélì ṣe.

19 Bí wọ́n bá sì ṣe àwọn iṣẹ ìyanu ní ìgbà nã, kini idi rẹ̀ tí Ọlọ́run fi dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run onisẹ ìyanu àti síbẹ̀síbẹ̀ tí í sì í ṣe Ẹda tí a kò lè yípadà? Ẹ sì kíyèsĩ, mo wí fun yín kĩ yípadà; bí ó bá rí bẹ̃ oun yíò dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run; oun kò sì dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu.

20 Ìdí rẹ tí òun fi dẹ́kun láti ṣe iṣẹ́ ìyanu ní ãrín àwọn ọmọ ènìyàn ní nítorípé wọ́n rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì yẹ̀ kúrò nínú ọnà èyíti ó tọ́, wọn kò si mọ̀ Ọlọ́run nínú ẹnití ó yẹ kí wọn ó gbẹ́kẹ̀lé.

21 Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pe ẹnikẹni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Krístì, ní aisiyemeji rara, ohunkóhun tí ó bá bèrè lọ́wọ́ Bàbá ní orukọ Krístì a o fi fún un; ìlérí yĩ sì wà fún gbogbo ènìyàn, àní títí de ìkangun ayé.

22 Nítori ẹ kíyèsĩ, báyĩ ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run wí fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ àwọn ẹnití yíò dúró lẹ́hìn, bẹ̃ni, àti fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀, tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sì gbọ́ ọ pe: Ẹ lọ sínú gbogbo ayé, kí ẹ sì wãsù ìhìn-rere nã sí gbogbo ẹ̀dá;

23 Ẹniti ó bá sì gbàgbọ́, tí a sì rìbọmi ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n ẹnití kò bá gbàgbọ́ ní a ó dálẹ́bi;

24 Àwọn àmì wọ̀nyí sì ni yíò máa tẹ̀lé àwọn tí ó gbàgbọ́—ní orúkọ mi ni wọn yíò lé àwọn èṣù jáde; wọn yíò fí èdè titun sọ̀rọ̀; wọn yíò mú àwọn ejò soke; tí wọn bà sì mu ohunkóhun tí ó ní oró kì yíò pa wọ́n lára; wọn yíò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn a sì dà;

25 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà orúkọ mi gbọ́, tí kò siyèméjì rárá, sí ẹni bẹ̃ ni emí yíò fi idi gbogbo ọrọ mi mulẹ̀, àní titi dé ìkangun ayé.

26 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, tani ó há lè dojúkọ iṣẹ́ Olúwa? Tani ó ha lè sẹ́ àwọn ohun tí ó sọ? Tani yíò ha dide sí agbara Olúwa títóbi julọ? Tani yíò ha kẹ́gàn iṣẹ́ Olúwa? Tani yíò ha kẹ́gàn àwọn ọmọ Krístì? Ẹ kíyèsĩ, gbogbo ẹyin tí í fi iṣẹ́ Olúwa ṣẹ̀sín, nitori ẹnú yíò ya yín ẹ ó sì parun.

27 A! nigbanã kí ẹ má sì ṣe kẹgan, ki ẹnu ó ma sì yà yín, sugbọn ẹ tẹ́tísí ọrọ Olúwa, kí ẹ sì bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ni orúkọ Jésù fun ohunkóhun tí ẹ̀yin ṣe aláìní. Ẹ máṣe ṣiyemejì, ṣùgbọ́n kí ẹ gbàgbọ́, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ gẹgẹbí ìgbà àtijọ́, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkan yín, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ ìgbàlà yin pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì níwájú rẹ̀.

28 Ẹ jẹ ọlọgbọ́n ní ọjọ ìdánwò yín; ẹ mú gbogbo ìwà àìmọ́ kuro nínú yín; ẹ máṣe bẽrè fun ohun kan láti lè lò ó fun ìfẹ́kúfẹ ara yín, ṣùgbọ́n kí ẹ bẽrè pẹ̀lú ìdúró-ṣinṣin láì siyèméjì, pé kí ẹ máṣe gbà àdánwò lãyè, ṣùgbọ́n pé ẹ̀yín yíò máa sìn Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè.

29 Kí ẹ rí i pe ẹ̀yin kò ṣe ìrìbọmi ní àìpé; kí ẹ ríi pé ẹyin ko jẹ nínú àmì májẹ̀mú ní àìpé; ṣùgbọ́n kí ẹ rí i pe ẹyin ṣe ohun gbogbo ni pípé, kí ẹ sì ṣe é ní orukọ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè; bí ẹyin bá sì ṣe èyí, ti ẹ sì forítì í de òpin, a kì yíò ta yín nù.

30 Ẹ kíyèsĩ, mo nbá yín sọrọ bí ẹnipé láti ipo-oku ní emí ti nsọ̀rọ̀; nítorípé mo mọ̀ pé ẹyin yíò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

31 Ẹ máṣe dá mi lẹ́bi nítori àwọn àbùkù mi, tabi baba mi, nitori àwọn àbùkù rẹ̀, tabi àwọn tí ó ti kọ̀wé ṣãjú rẹ̀; sugbọn kí ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run pé o ti fi àwọn àbùkù wa hàn sí yín, kí ẹyin ó lè kọ́ láti jẹ́ ọlọgbọ́n jù bí àwa tí jẹ́.

32 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, awá ti kọ àkọsílẹ̀ yĩ gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú bí àwa ti í kọ̀wé ní ãrin wa èyítí a npè ni àtúnṣe èdè Égíptì, èyítí a gbé lé wa lọ́wọ́ láti ìran kan dé òmíran tí a sì yípadà, ni ìbámu pẹ̀lú èdè wa.

33 Bí ó bá sì ṣe pe àwọn àwo wa tóbi tó ni àwa ìbá ti kọ ìwe yìi ni èdè Hébérù; ṣùgbọ́n a ti yí ede Hébérù nã padà pẹ̀lú; bí ó bá sì ṣe pé àwa lè kọ̀wé ní ede Hébérù, kíyèsĩ, ẹ̀yin kì bá tí rí àìpé kankan nínú àkọsílẹ̀ wa.

34 Ṣugbọn Olúwa mọ àwọn ohun tí a kọ, àti pẹ̀lú pe kò sí àwọn ènìyàn miràn ti ó mọ̀ èdè wa; àti nítorípé kò sí àwọn ènìyàn miràn ti o mọ̀ èdè wa, nitorinã ni o ti pèsè ọ̀na fun ìtúmọ̀ rẹ̀.

35 Àwọn ohun wọnyĩ ní a sì kọ kí àwa ó le wẹ̀ asọ̀ wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa, tí wọn tì rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́.

36 Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ohun wọ̀nyí ni a fẹ́ nípa àwọn arákùnrin wa, bẹ̃ni, àní ìmúpadà sí inú ìmọ̀ Krístì, wà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó ti gbé inú ilẹ̀ nã rí.

37 Kí Jésù Krístì Olúwa jẹ kí adura wọn ó gbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn; àti kí Ọlọ́run tí í ṣe Baba ranti májẹ̀mú èyítí ó ti dá pẹ̀lú idile Isráẹ́lì; àti ki o sì bùkúnfún wọn titi láé, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù Krístì. Àmín.