Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 30


Orí 30

Àwọn Kèfèrí ọjọ́ ti ìkẹhìn ni a pàṣẹ fún pé kí wọn ó ronúpìwàdà, kí wọn ó wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí a sì kà wọ́n mọ́ ìdílé Ísráẹ́lì. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ẹ tẹ́tísílẹ̀, A! ẹ̀yin Kèfèrí, kí ẹ sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè, èyítí ó ti pàṣẹ pé kí èmi ó wí fún yín nípa yín, nítorí, ẹ kíyèsĩ ó pàṣẹ fún mi pé kí èmi ó kọ sílẹ̀, wípé:

2 Ẹ yí padà, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí, kúrò ní àwọn ọ̀nà búburú yín; kí ẹ sì ronúpìwàdà kúrò nínú ibi ṣíṣe yín, kúrò nínú irọ́ pípa àti ìwà ẹ̀tàn yín, àti ìwà àgbèrè yín, àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀yin nṣe ní ìkọ̀kọ̀, àti àwọn ìbọ̀rìṣà yín, àti àwọn ìpànìyàn yín, àti àwọn iṣẹ́ àlùfã àrékérekè yín, àti ìlara yín, àti àwọn ìjà yín, àti kúrò nínú gbogbo ìwà búburú àti iwa ìríra yín, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí a sì ṣe ìrìbọmi fun yín ní orúkọ mi, kí ẹ̀yin ó lè gba ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, kí a lè kà yín mọ́ àwọn ènìyàn mi tí wọn íṣe ti ìdílé Ísráẹ́lì.