Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 21


Orí 21

A ó kó Ísráẹ́lì jọ nígbàtí Ìwé ti Mọ́mọ́nì bá jáde wá—A ó fi àwọn Kèfèrí lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ènìyàn olómìnira ní Amẹ́ríkà—A o gbà wọn là bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì ṣe ìgbọràn; bíkòṣebẹ̃, a ó ké wọn kúrò a ó sì pa wọn run—Ísráẹ́lì yíò kọ́ Jerúsálẹ́mù Titun, àwọn ẹ̀yà tí ó ti sọnù yíò sì padà. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi fún yín ní àmì kan, kí ẹ̀yin ó lè mọ́ àkokò nã tí àwọn ohun wọ̀nyí ti fẹ́rẹ̀ ṣẹlẹ̀—nígbàtí èmi yíò kó àwọn ènìyàn mi jọ, A! ìdílé Ísráẹ́lì, kúrò nínú ipò ìfọ́nká rẹ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́, tí èmi yíò sì tún padà fi ìdí Síónì mí mulẹ̀ lãrín nwọn.

2 Ẹ sì kíyèsĩ, èyí ni ohun tí èmi yíò fifún ọ gẹ́gẹ́bí àmì—nítorí lóotọ́ ni mo wí fún yín, nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi wí fún yín, àti tí èmi yíò tún wí fún yín lẹ́hìn èyí nípa ara mi, àti nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ èyítí Bàbá yíò fi fún yín, yíò di mímọ̀ fún àwọn Kèfèrí kí wọn ó lè mọ̀ nípa àwọn ènìyàn tí íṣe ìyókù ìdílé Jákọ́bù, àti nípa àwọn ènìyàn mi yìi tí wọn yíò fọ́nká.

3 Lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí yíò di mímọ̀ sí wọn nípasẹ̀ Bàbá, tí yíò sì jáde wá nípasẹ̀ Bàbá, láti ọ̀dọ̀ wọn sí yín;

4 Nítorítí ohun ọgbọ́n ni nínú Bàbá láti fi wọ́n lélẹ̀ nínú ilẹ̀ yí, kí a sì fi wọ́n lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ènìyàn olómìnira nípa agbára Bàbá, kí àwọn ohun wọ̀nyí ó lè jáde wá láti ọ̀dọ̀ wọn sí ọ̀dọ̀ ìyókù àwọn irú-ọmọ yín, kí májẹ̀mú Bàbá ó lè di mímúṣẹ èyítí ó ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, A! ìdílé Ísráẹ́lì;

5 Nítorínã, nígbàtí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí àti àwọn iṣẹ́ tí a ó ṣe lãrín yín lẹ́hìn èyí yíò jáde wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, sí àwọn irú-ọmọ yín tí wọn yíò rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ nítorí àìṣedẽdé;

6 Nítorítí ó jẹ́ ìfẹ́ Bàbá pé kí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí jáde wá, kí òun lè fi agbára rẹ̀ hàn sí àwọn Kèfèrí, fún ìdí èyí, pe awọn Kèfèrí, bí wọn kò bá sé àyà wọn le, kí nwọn ó lè ronúpìwàdà kí wọn ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi kí a sì ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ mi kí wọn ó sì mọ́ àwọn òtítọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí a lè kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì;

7 Nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí bá sì ti ṣẹ tí àwọn irú-ọmọ yín sì bẹ̀rẹ̀sí mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí—yíò jẹ́ ohun àmì fún wọn, kí wọn ó lè mọ̀ pé iṣẹ́ Bàbá ti bẹ̀rẹ̀ láti lè mú májẹ̀mú nnì ṣẹ èyítí ó ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí íṣe ìdílé Ísráẹ́lì.

8 Nígbàtí ọjọ́ nã yíò sì dé, yíò sì ṣe tí àwọn ọba yíò pa ẹnu wọn mọ́; nítorípé wọn ó rí ohun tí a kò sọ fún wọn nípa rẹ̀; wọn yíò sì ní òye nípa èyítí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀.

9 Nítorítí ní ọjọ́ nã, nítorí mi ni Bàbá yíò ṣe iṣẹ́ kan, èyítí yíò jẹ́ iṣẹ́ títóbi àti ìyanu lãrín wọn; a ó sì rí nínú wọn tí kò jẹ́ gba iṣẹ́ nã gbọ́, bí ẹnìkan tilẹ̀ sọ̃ fún wọn.

10 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀mí ìránṣẹ́ mi yíò wà ní ọwọ́ mi; nítorínã wọn kò lè pã lára, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a ó bã jẹ́ nítorí wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yíò wõ sàn, nítorítí èmi yíò fihàn wọ́n pé ọgbọ́n mi tóbi ju ọgbọ́n-àrékérekè èṣù lọ.

11 Nítorínã yíò sì ṣe, ẹnìkẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, pé èmi ni Jésù Krístì, èyítí Bàbá yíò mú kí ó mú jáde tọ àwọn Kèfèrí lọ, tí yíò sì fún un ní agbára láti mú wọn jáde tọ àwọn Kèfèrí lọ, (a ó ṣeé gẹ́gẹ́bí Mósè ti sọ) a ó ké wọn kúrò lãrín àwọn ènìyàn mi tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú nã.

12 Àwọn ènìyàn mi tí íṣe ìyókù ìdílé Jákọ́bù yíò sì wà lãrín àwọn Kèfèrí, bẹ̃ni, lãrín wọn bí kìnìún lãrín àwọn ẹranko igbó, àti bí ọmọ kìnìún lãrín àwọn agbo àgùtàn, èyítí, bí ó bá kọjá lãrín wọn, yíò tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, yíò tún fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì sí ẹnití yíò gbà wọ́n là.

13 A ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí órí àwọn ọ̀tá wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá wọn ni a ó sì ké kúrò.

14 Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn Kèfèrí bíkòṣe pé wọn ronúpìwàdà; nítorí yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, ni Bàbá wí, tí èmi yíò ké àwọn ẹṣin yín kúrò lãrín yín, èmi yíò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin yín run;

15 Èmi yíò sì ké àwọn ìlú-nlá inú ilẹ̀ yín kúrò, èmi ó sì bi gbogbo àwọn ibi gíga yín lulẹ̀;

16 Èmi yíò sì ké gbogbo ìṣe-oṣó kúrò nínú ilẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yíò sì ní àwọn aláfọ̀ṣẹ mọ́;

17 Àwọn ère fífín yín pẹ̀lú ni èmi ó ké kúrò, àti àwọn ère yín ni èmi ó ké kúrò lãrín rẹ̀, ẹ̀yin kì ó sin iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́;

18 Èmi ó sì fa àwọn igbó sũrù yín tu kúrò lãrín yín; bákannã ni èmi yíò pa àwọn ìlú-nlá yín run.

19 Yíò sì ṣe tí gbogbo irọ́-pípa àti ẹ̀tàn gbogbo, àti ìlara, àti ìjà, àti àwọn iṣẹ́ àlùfã alárèkérekè, àti àwọn ìwà-àgbèrè, ni a ó mú kúrò.

20 Nítorítí yíò sì ṣe, ni Bàbá wí, pé ní ọjọ́ nã ẹnìkẹ́ni tí kò bá ronúpìwàdà kì ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Àyànfẹ́ Ọmọ mi, àwọn ni èmi yíò ké kúrò lãrín àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì;

21 Èmi yíò sì gbẹ̀san ní ìbínú lori nwọn, ani gẹgẹbi lori awọn aboriṣa, irú èyítí wọn kò gbọ́ rí.

22 Ṣùgbọ́n bí wọn ó bá ronúpìwàdà tí wọ́n sì fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, tí wọn kò sì sé ọkàn wọn le, èmi yíò fi ìjọ mi lélẹ̀ lãrín wọn, wọn yíò sì dá májẹ̀mú nã a ó sì kà wọn mọ́ àwọn ìyókù ìdílé Jákọ́bù, àwọn tí èmi ti fi ilẹ̀ yĩ fún ní ìní fún wọn;

23 Wọn yíò sì ran àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́, àwọn ìyókù ìdílé Jákọ́bù, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ìdílé Ísráẹ́lì tí yíò bá wá, kí wọn ó lè kọ́ ìlú-nlá kan, èyítí a ó pè ní Jerúsálẹ́mù Titun.

24 Àti nígbànã ni wọn yíò ran àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ kí àwọn tí a ti fọ́nká kiri gbogbo orí ilẹ̀ nã lè di kíkójọ pọ̀ sínú Jerúsálẹ́mù Titun.

25 Àti nígbànã ni agbara ọrun yíò sọ̀kalẹ̀ sí ãrin wọn; èmi pãpã yíò sì wà lãrín wọn.

26 Àti nígbànã ni iṣẹ́ Bàbá yíò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ nã, àní nígbàtí a ó wãsù ìhìn-rere yĩ lãrín àwọn ìyókù àwọn ènìyàn yĩ. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, ní ọjọ́ nã ni iṣẹ́ Bàbá yíò bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn mi tí ó fọ́nká, bẹ̃ni, àní àwọn ẹ̀yà tí ó sọnù, tí Bàbá ti darí jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

27 Bẹ̃ni, iṣẹ́ nã yíò bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn mi tí ó fọ́nká, pẹ̀lú Bàbá tí yíò palẹ̀ ọ̀nà mọ́ èyítí wọn ó gbà wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọn ó lè ké pe Bàbá ní orúkọ mi.

28 Bẹ̃ni, nígbànã sì ni iṣẹ́ nã yíò bẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú Bàbá lãrín orílẹ̀-èdè gbogbo fún pípalẹ̀ ọ̀nà mọ́ nínú èyítí a ó gbà láti kó àwọn ènìyàn rẹ̀ wọlé lọ sí ìlẹ̀ ìní wọn.

29 Wọn yíò sì jáde lọ láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo; wọn kì yíò yára jáde, bẹ̃ni wọn kì yíò fi ìkánjú lọ, nítorí èmi yíò ṣãjú wọn, ni Bàbá wí, èmi yíò sì tì wọn lẹ́hìn.