Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 29


Orí 29

Ìjádewá Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ohun àmì kan pé Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ láti kó Ísráẹ́lì jọ àti láti mú àwọn májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ—Àwọn tí ó bá kọ̀ àwọn ìfihàn ọjọ́ ti ìkẹhìn rẹ̀ àti àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ ni a ó fi bú. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé nígbàtí Olúwa yíò ríi nínú ọgbọ́n rẹ̀, láti mú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún àwọn Kèfèrí gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbãnà ni ẹ̀yin ó tó mọ̀ pé májẹ̀mú tí Bàbá ti dá pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, nípa ìmúpadà wọn sínú ilẹ̀ ìní wọn, ti bẹ̀rẹ̀sí di ìmúṣẹ.

2 Ẹ̀yin yíò sì lè mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa, èyítí àwọn wòlĩ mímọ́ ti sọ, yíò di mìmúṣẹ; kí ẹ̀yin ó má sì ṣe sọ wípé Olúwa yíò fa àbọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sẹ́hìn.

3 Kí ẹ̀yin ó má sì ròo ní ọkàn yín pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ jẹ́ asán, nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa yíò rántí májẹ̀mú rẹ̀ èyítí ó ti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ ti ìdílé Ísráẹ́lì dá.

4 Nígbàtí ẹ̀yin ó bá sì ríi tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí njáde wá lãrín yín, nígbànã ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ kẹ́gàn àwọn ohun tí Olúwa nṣe mọ́, nítorí àìṣègbè idà rẹ mbẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ, ní ọjọ́ nã, bí ẹ̀yin ó bá kẹ́gàn àwọn ohun tí Olúwa nṣe, òun yíò mú kí idà òtítọ́ rẹ̀ ó ré lù yín ní àìpẹ́.

5 Ègbé ni fún ẹni nã tí ó nkẹ́gàn àwọn ohun tí Olúwa nṣe; bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni nã tí yíò sẹ́ Krístì àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀!

6 Bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni nã tí yíò sẹ́ àwọn ìfihàn Olúwa, àti tí yíò sọ wípé Olúwa kò ṣiṣẹ́ rẹ̀ nípa ìfihàn mọ́, tàbí nípa ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa àwọn ẹ̀bùn, tabí nípa àwọn èdè, tàbí nípa ṣíṣe ìwòsàn, tàbí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́!

7 Bẹ̃ni, ègbé sì ni fún ẹni nã, ní ọjọ́ nã, kí ó lè rí èrè, tí yíò wípé Jésù Krístì kì yíò ṣe iṣẹ́ ìyanu rárá; nítorítí ẹnití ó bá wí báyĩ ni yíò dàbí ọmọ-egbé nnì, ẹnití kò sí ãnú fún, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Krístì!

8 Bẹ̃ni, kí ẹ̀yin ó má sì ṣe ìyọṣùtì sí tàbí kẹ́gàn tàbí fi àwọn Jũ ṣe ẹlẹ́yà mọ́, tàbí èyíkéyĩ nínú àwọn ìyókù ìdílé Ísráẹ́lì; nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa yíò rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú wọn, yíò sì ṣe fún wọn ní ìbámu pẹ̀lú bí ó ti jẹ́ èjẹ́ pẹ̀lú wọn.

9 Nítorínã kí ẹ̀yin ó máṣe rò pé ẹ̀yin lè pa ọwọ́ ọ̀tun Olúwa dà sí òsì, kí ó ma lè ṣe ìdájọ́ sí ti ìmúṣẹ májẹ̀mú èyítí ó ti dá pẹ̀lú ìdílé Ísráẹ́lì.