Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 14


Orí 14

Jésù pàṣẹ pé: Ẹ máṣe dání ní ẹjọ́; ẹ bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹ máa kíyèsára fún àwọn wòlĩ èké—Ó ṣe ìlérí ìgbàlà fún àwọn tí ó bá ṣe ìfẹ́ ti Bàbá—A fi orí ìwé yĩ wé Máttéù 7. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó tún yíjú padà sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ó sì tún la ẹnu rẹ̀ sí wọn, wípé: Lóotọ́, lóotọ́, èmi wí fún yín, Ẹ máṣe dání ní ẹjọ́, kí a má bã dá yín ní ẹjọ́.

2 Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni á ó ṣe fún yín; àti pé irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n, òun ni á ó sì fi wọ̀n fún yín.

3 Èétiṣe tí ìwọ sì nwo ẽrún igi tí nbẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kò kíyèsí ìtí igi tí nbẹ ní ojú ara rẹ?

4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé: Jẹ́ kí èmi ó yọ ẽrún igi tí nbẹ ní ojú rẹ kúrò—sì wõ, ìtí igi nbẹ ní ojú ìwọ tìkararẹ̀?

5 Ìwọ àgàbàgebè, tètèkọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná; nígbànã ni ìwọ yíò sì ríràn kedere láti yọ ẽrún igi tí nbẹ ní ojú arákùnrin rẹ̀ kúrò.

6 Ẹ máṣe fi ohun tí iṣe mímọ́ fún àwọn ajá, kí ẹ má sì ṣe sọ péálì yín síwájú ẹlẹ́dẹ̀, kí wọn ó má bã fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, tí wọn a sì tún yípadà, wọn a sì bù yín ṣán.

7 Ẹ bẽrè, a ó sì fi fún yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín.

8 Nítorípé ẹnikẹ́ni tí ó bá bẽrè, nrí gbà; ẹnití ó bá sì wá kiri nrí; ẹnití ó bá sì kànkùn, ni a ò síi sílẹ̀ fún.

9 Tàbí tani ọkùnrin nã tí mbẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ bèrè àkàrà, tí yíò fí òkúta fún un?

10 Tàbí bí ó bèrè ẹja, tí yíò fún un ní ejò?

11 Njẹ́ bí ẹ̀yin tí íṣe ènìyàn búburú, bá mọ̀ bí a ti fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, melomelo ni Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run yíò fi ohun rere fún àwọn tí ó bá bẽrè lọ́wọ́ rẹ̀?

12 Nítorínã, gbogbo ohunkóhun tí ẹ̀yin bá nfẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ̃ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́, nítorí-èyí ni òfin àti àwọn wòlĩ.

13 Ẹ bá ẹnu-ọ̀nà híhá wọlé; nítorí gbõrò ni ẹnu-ọ̀nà nã, fífẹ̀ sì ni ojú-ọ̀nà nã, èyítí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ẹnití nbá ibẹ̀ wọlé;

14 Nítorípé híhá ni ẹnu-ọ̀nà nã, tõró sì ni ojú-ọ̀nà nã, èyítí ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn ẹnití nríi.

15 Ẹ máa kíyèsára nítorí àwọn wòlĩ èkè, tí wọn ntọ̀ yín wá nínú awọ àgùtàn, ṣùgbọ́n apanijẹ ìkòkò ni wọ́n nínú.

16 Ẹ̀yin yíò mọ̀ wọ́n nípa èso wọn. Njẹ́ ènìyàn a máa ká èso àjàrà lórí ẹ̀gún ọ̀gàn, tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀wọ̀n bí?

17 Gẹ́gẹ́ bẹ̃ gbogbo igi rere ni íso èso rere; ṣùgbọ́n igi búburú ni íso èso búburú.

18 Igi rere kò lè so èso búburú, bẹ̃ni igi búburú kò sì lè so èso rere.

19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a ó ké lulẹ̀, a ó sì wọ̃ sínú iná.

20 Nítorí-èyí, nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọ́n.

21 Kì íṣe gbogbo ẹnití npè mi ní Olúwa, Olúwa, ni yíò wọlé sínú ìjọba ọ̀run; bíkòṣe ẹnití nṣe ìfẹ́ ti Bàbá mi tí nbẹ ní ọ̀run.

22 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yíò wí fún mi ní ọjọ́ nã pé: Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ bí, àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi lé àwọn èṣù jáde, àti ní orúkọ rẹ ni a fi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu nlá?

23 Nígbànã ni èmi ó sì jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí; ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

24 Nítorínã, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi sọ wọ̀nyí tí ó sì nṣe wọ́n, èmi ó fi wé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, tí ó kọ́ ilé rẹ sí orí àpáta—

25 Òjò sì rọ̀, ìkun omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, ó sì bìlu ilé nã; kò sì wó, nítorí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.

26 Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí tí kò sì ṣe wọ́n, òun ni èmi ó fi wé aṣiwèrè ènìyàn kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn—

27 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bìlu ilé nã; ó sì wó, ìwọ rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.